ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwex àpilẹ̀kọ 1
  • “Mò Ń Ṣèwọ̀n Tí Mo Lè Ṣe”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mò Ń Ṣèwọ̀n Tí Mo Lè Ṣe”
  • Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Ará Wa Ní Caribbean Ṣe Jàǹfààní Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìrànwọ́ Tá À Ń Ṣe
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Sọ fún Wọn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Wọn
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • “Mi Ò Rí Irú Ìfẹ́ Báyìí Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwex àpilẹ̀kọ 1
Irma ń kọ lẹ́tà

“Mò Ń Ṣèwọ̀n Tí Mo Lè Ṣe”

Orílẹ̀-èdè Germany ni Irma ń gbé, ó sì ti fẹ́ pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún. Ẹ̀ẹ̀méjì ni ìjàǹbá ọkọ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí i rí, wọ́n sì ti ṣiṣẹ́ abẹ fún un nígbà mélòó kan, torí náà kò lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́ bó ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, lẹ́tà ló máa ń kọ láti fi wàásù fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ àtàwọn tó bá mọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí àti ti ìtùnú tó máa ń wà nínú lẹ́tà rẹ̀ máa ń wọni lọ́kàn débi pé àwọn èèyàn máa ń pè é láti mọ ìgbà tí wọ́n tún máa rí lẹ́tà míì gbà látọ̀dọ̀ ẹ̀. Wọ́n sì máa ń kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ sí i, wọ́n á ní kó tún kọ òmíì ránṣẹ́ sáwọn. Irma sọ pé, “Gbogbo èyí ń fún mi láyọ̀, kò sì jẹ́ kí n dẹwọ́ nípa tẹ̀mí.”

Irma

Irma tún máa ń kọ lẹ́tà sí àwọn tó wà níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó. Ó ní: “Obìnrin àgbàlagbà kan pè mí lórí fóònù, ó sì sọ pé lẹ́tà mi tu òun nínú gan-an nígbà tí ọkọ òun kú. Inú Bíbélì ẹ̀ ló tọ́jú lẹ́tà náà sí, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń kà á nírọ̀lẹ́. Obìnrin míì tí ọkọ rẹ̀ kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé, lẹ́tà mi ran òun lọ́wọ́ gan-an, kódà ó kọjá ìwàásù àlùfáà. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló fẹ́ bi mí, torí náà ó ní ṣé òun lè wá bá mi nílé.”

Ọ̀kan lára àwọn tí Irma mọ̀ dáadáa, àmọ́ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kó lọ síbòmíì tó jìnnà, àmọ́ ó ní kí Irma máa kọ lẹ́tà sóun. Irma sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Obìnrin náà tọ́jú gbogbo lẹ́tà tí mo kọ sí i.” Irma tún sọ pé, “Lẹ́yìn tó kú, ọmọ rẹ̀ obìnrin pè. Ó sọ fún mi pé òun ti ka gbogbo lẹ́tà tí mo kọ sí màmá òun, ó sì bẹ̀ mí pé kí n máa kọ lẹ́tà tó dá lórí Bíbélì sí òun náà.”

Irma ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ gan-an ni. Ó ní,“Mò ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi lókun tí màá lè máa fi sìn ín nìṣó.” Ó fi kún un pé, “Bí mi ò tiẹ̀ lè wàásù láti ilé dé ilé mọ́, mò ń ṣèwọ̀n tí mo lè ṣe.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́