ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 12-14
  • Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Okùnfà Yánpọnyánrin Tí Ó Ti Mọ́ra
  • Bí A Óò Ṣe Wo Ilẹ̀ Ayé Sàn
  • “Jẹ́ Kí Inú Ayé Kí Ó Dùn”
  • Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ṣé Àwọn Èèyàn Ò Ní Ba Ayé Yìí Jẹ́ Kọjá Àtúnṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ilẹ̀ Ayé Wa—Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Sí i Lọ́jọ́ Iwájú?
    Jí!—2004
  • Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Ayé Yìí Máa Wà Títí Láé
    Jí!—2023
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 12-14

Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?

NÍ 200 ọdún sẹ́yìn, òṣèlú ọmọ America kan, Patrick Henry, sọ pé: “N kò mọ ohun tí ènìyàn tún fi lè mọ bí ọjọ́ ọ̀la yóò ti rí ju bí ìgbà tí ó ti kọjá ti rí lọ.” Ní ìgbà tí ó ti kọjá, àwọn ènìyàn ti ṣe ayé wa yìí báṣubàṣu. Wọn yóò ha bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà sí dáadáa ní ọjọ́ ọ̀la bí? Títí di báyìí, àmì tí a ń rí kò fúnni níṣìírí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn ti ní ìtẹ̀síwájú mélòó kan tí ó yẹ ní gbígbóríyìn fún, kò tí ì ju oréfèé lọ, fífi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ pa làpálàpá. Bí pákó ilé kan bá ń ju, kíkun pákó náà kò ní sọ pé kí ó máà wó. Kìkì àtúnṣe pátápátá lórí bí a ti kọ́ ọ ló lè gbà á là. Lọ́nà kan náà, àtúnṣe gbọ́dọ̀ wà nípa ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà lo pílánẹ́ẹ̀tì yìí. Ṣíṣàkóso ìbàjẹ́ tí a ń ṣe sí i lásán kò tó.

Nígbà tí ògbógi kan ń ṣàrúnkúnná àbájáde àbójútó àyíká tí a fi 20 ọdún ṣe ní United States, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “a kò lè ṣèkáwọ́ ìbàjẹ́ tí a ti ṣe sí ayé tán pátápátá, ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ dáwọ́ rẹ̀ dúró.” Ó ṣe kedere pé, ṣíṣèkáwọ́ ìbàyíkájẹ́ sàn ju ṣíṣẹ́pá àwọn àbájáde láabi tí ó ti fà lọ. Àmọ́ kí ọwọ́ tó lè tẹ irú ìlépa bẹ́ẹ̀, ó dájú pé yóò bèèrè ojúlówó ìyípadà nínú àwùjọ ènìyàn àti nínú ìfojúsùn iṣẹ́ òwò ràbàtà. Ìwé Caring for the Earth gbà pé bíbojú tó ilẹ̀ ayé ń bèèrè fún “àwọn ìlànà ìwà híhù, ipò ìṣúnná owó àti àwùjọ ènìyàn tí ó yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èyí tí ó gbalẹ̀ lónìí.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà ìwà híhù tí ó yẹ ní yíyí padà kí a baà lè gba pílánẹ́ẹ̀tì là?

Àwọn Okùnfà Yánpọnyánrin Tí Ó Ti Mọ́ra

Ìmọtara-ẹni-nìkan. Fífi ire pílánẹ́ẹ̀tì ṣíwájú ti àwọn ènìyàn akóninífà jẹ́ ìgbẹ́sẹ̀ àkọ́kọ́ síhà dída ààbò bo ayé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó lójú àwọn ènìyàn tó lè fínnúfíndọ̀ pa ọ̀nà ìgbésí ayé onígbẹdẹmukẹ tì, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ba píláánẹ̀tì jẹ́ fún àwọn ìrandíran wọn tí ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la pàápàá. Nígbà tí ìjọba Netherlands—ọ̀kan nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti sọ deléèérí jù lọ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe—gbìyànjú láti pààlà sí bí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ṣe ń rìnrìn àjò, gẹ́gẹ́ bí ìgbétáásì kan láti gbógun tí ìbàyíkájẹ́, àtakò ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́ ìwéwèé náà lọ́rùn pa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé títì Netherlands ni ọkọ̀ pọ̀ sí jù lọ lágbàáyé, àwọn awakọ̀ kò fẹ́ẹ́ gbà láti má lo òmìnira wọn.

Wíwá ire tara ẹni nìkan máa ń nípa lórí àwọn tí ń pinnu bí nǹkan yóò ti rí àti gbogbo àwọn ènìyàn lápapọ̀. Àwọn òṣèlú ń lọ́ tìkọ̀ láti gbé àwọn òfin tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká tí ó lè mú kí wọ́n pàdánù ìbò wọn kalẹ̀, àwọn onílé iṣẹ́ kò sì ní inú dídùn nínú ìwéwèé èyíkéyìí tí ó bá lè fi èrè àti ìbúrẹ́kẹ́ òwò wọn wewu.

Ìwọra. Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ti yíyan ọ̀kan láàárín èrè àti ìdáàbòbo nǹkan ìṣẹ̀dá, owó ni ó máa ń rọ́wọ́ mú jù. Àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá máa ń rìn ín láti lè mú kí àwọn ìkáwọ́ ìbàyíkájẹ́ tí à ń ṣe dín kù tàbí kí wọ́n tilẹ̀ yẹra fún àwọn òfin ìjọba pátápátá. Ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe sí ìpele ozone fi àpẹẹrẹ ìṣòro yìí hàn. Láti nǹkan bíi March 1988, ni alága ilé iṣẹ́ kẹ́míkà pàtàkì kan ní United States ti sọ pé: “Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tí ì fi hàn pé ó yẹ kí a jẹ́ kí kẹ́míkà CFC tí ń jáde dín kù pátápátá.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ilé iṣẹ́ yẹn kan náà ló dábàá pé, kí á máà mú kẹ́míkà àwọn chlorofluorocarbon (CFC) jáde mọ́ pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀. Ṣé ó ti yí ọkàn rẹ̀ padà ni? Mostafa Tolba, olórí olùdarí Ètò Ìṣàbójútó Àyíká ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNEP), sọ pé: “Ìyẹn kò ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn pé bóyá ó ń ba àyíká jẹ́ tàbí kò bà á jẹ́. Ọ̀ràn ta ni yóò jèrè [owó] láti inú rẹ̀ ni.” Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wá mọ̀ pé pípa tí àwọn ènìyàn ń pa ìpele ozone run jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àjálù ìbàyíkájẹ́ tí ó burú jù lọ tí ó jẹ́ àfọwọ́fà ènìyàn nínú ìtàn.

Àìmọ̀kan. Ohun tí a kò mọ̀ pọ̀ ju ohun tí a mọ̀ lọ. Peter H. Raven, olùdarí Ọgbà Ewéko ti Missouri, ṣàlàyé pé: “Ohun díẹ̀ rébété ni a ṣì mọ̀ nípa ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan abẹ̀mí tí ń bẹ nínú àwọn ẹgàn ilẹ̀ olóoru. Ó yani lẹ́nu pé, a mọ ohun púpọ̀—tí ó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ—nípa ojú òṣùpá.” Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa àyíká ilẹ̀ ayé. Báwo ni afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí a lè máa tú sí ojú sánmà yóò ti pọ̀ tó láìba ojú ọjọ́ àgbáyé jẹ́? Kò sí ẹni tí ó mọ̀. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ti sọ, “kò ní lọ́gbọ́n nínú láti fi ìṣẹ̀dá sábẹ́ ìdánwò kíkàmàmà tó bẹ́ẹ̀, nígbà tí a kò mọ ohun tí àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́, tí ríronú nípa ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ sì ń páni láyà tí a bá ronú nípa rẹ̀.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí àjọ UNEP ṣe ti sọ, ó ṣeé ṣe kí ìwọ̀n ozone tí a ó bà jẹ́ ní òpin ẹ̀wádún yìí máa fa ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àrùn jẹjẹrẹ ara tuntun lọ́dọọdún, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyín. A kò tí ì mọ bí yóò ti kan àwọn irè oko àti iṣẹ́ ẹja pípa tó síbẹ̀, àmọ́, a retí kí ó jẹ́ lọ́nà tí ó bùáyà.

Ojú ìwòye aláìrotẹ̀yìn-ọ̀la. Àwọn ìṣòro tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká kò dà bí àwọn àjálù míràn, wọ́n máa ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ wọlé tọ̀ wá wá. Èyí máa ń ṣèdènà fún ìyànjú tí àwọn ènìyàn lè gbà láti wá ìgbésẹ̀ àjùmọ̀gbé kan gbé kí ìbàjẹ́ lílé kenkà tó ṣẹlẹ̀. Ìwé Saving the Planet fi ipò tí a wà nísinsìnyí wé tí àwọn èrò tí ó ko àgbákò nínú ọkọ̀ ojú omi Titanic, tí ó bà jẹ́ ní 1912, nígbà tí ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn tó mọ̀ nípa bí ọ̀ràn ìbànújẹ́ tó fẹ́ẹ́ ṣẹlẹ̀ náà ti kàmàmà tó kò pọ̀.” Àwọn tí ó kọ ìwé náà gbà gbọ́ pé, a lè gba pílánẹ́ẹ̀tì là kìkì bí àwọn òṣèlú àti àwọn oníṣòwò bá dojú kọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ti gidi gan-an, tí wọ́n sì ronú nípa àwọn ojútùú tí ó lè ṣiṣẹ́ fún àkókò gígùn, dípò àwọn àǹfààní onígbà kúkurú.

Ìṣarasíhùwà àfèminìkan-ṣáá. Níbi ìpàdé Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé tí wọ́n ṣe ní 1992, mínísítà àgbà ilẹ̀ Spania, Felipe González, tọ́ka sí i pé “ìṣòro náà jẹ́ èyí tí ó kárí ayé, ojútùú rẹ̀ náà sì gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí ó kárí ayé.” Kò kúkú purọ́, àmọ́, rírí ojútùú tí yóò jẹ́ èyí tí gbogbo ènìyàn yóò tẹ́wọ́ gbà kárí ayé jẹ́ iṣẹ́ kan tí ń ko àárẹ̀ báni. Aṣojú United States kan tí ó lọ síbi ìpàdé Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé náà sọ ojú abẹ níkòó pé: “Àwọn ará America kò lè fi ọ̀nà ìgbàgbé ìgbésí ayé wọn sílẹ̀.” Ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ nípa ìṣàbójútó àyíká tí ó jẹ́ ará India kan, Maneka Gandhi, ṣàròyé pé “ọmọ kan ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ń jẹ oúnjẹ tí ó pọ̀ tó èyí tí ènìyàn 125 ń jẹ́ ní apá Ìlà Oòrùn.” Ó sọ pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àjẹkì apá Ìwọ̀ Oòrùn ní ń fa gbogbo ìbàyíkájẹ́ tí ń ṣẹlẹ̀ ní apá Ìlà Oòrùn.” Léraléra ni gbogbo ìsapá tí à ń ṣe jákèjadò orílẹ̀-èdè láti mú kí àyíká sunwọ̀n sí i ń forí ṣánpọ́n nítorí ìfẹ́ àfèminìkan-ṣáá ti orílẹ̀-èdè tí àwọn ènìyàn ní.

Láìka gbogbo àwọn lájorí ìṣòro wọ̀nyí sí, a ṣì ní ìdí láti wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn. Ọ̀kan nínú wọn jẹ́ nítorí ànímọ́ ìráragbaǹkan tí ètò ìgbógunti ohun àìfẹ́ pílánẹ́ẹ̀tì wá ní.

Bí A Óò Ṣe Wo Ilẹ̀ Ayé Sàn

Bí ara ẹ̀dá ènìyàn, ilẹ̀ ayé ní agbára àgbàyanu láti wo ara rẹ̀ sàn. Àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá ti èyí kan ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tí ó kọjá. Ní ọdún 1883, òkè ayọnáyèéfín erékùsù Krakatau (Krakatoa) ti Indonesia bú gbàù débi tí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 5,000 kìlómítà jìnnà sí i fi gbọ́ ọ. Ọ̀gbàrá pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ ìbúgbàù tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po ìlọ́po kìlómítà 21 tú dà sí ojú sánmà, ìdá méjì nínú mẹ́ta lára erékùṣù náà sì rilẹ̀ sábẹ́ òkun. Ní oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn rẹ̀, kìkì ohun ẹlẹ́mìí tí ó kù ni aláǹtakùn tínńtínní kan. Lónìí, àwọn ewéko jíjí pépé ti ilẹ̀ olóoru, tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀yà àwọn ẹyẹ, ẹranko afọ́mọlọ́mú, ejò àti kòkòrò fi ṣe ilé, bo gbogbo erékùṣù náà pitimọ. Kò sí iyè méjì pé ààbò tí a fún erékùṣù náà gẹ́gẹ́ bí ara Ọgbà Ìtura Orílẹ̀-Èdè ti Ujung Kulon ni ó kín ìpadàbọ̀sípò rẹ̀ lẹ́yìn.

A lè ṣàtúnṣe ìbàjẹ́ tí àwọn ènìyàn ṣe pẹ̀lú. Tí a bá fún ilẹ̀ ayé ní àkókò dáadáa, ó lè wo ara rẹ̀ sàn. Ìbéèrè tí ó kàn ní pé, Àwọn ènìyàn yóò ha fún ilẹ̀ ayé ní ìsinmi tí ó nílò bí? Bóyá ni yóò fi rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Ẹnì Kan wà tí ó ti pinnu láti jẹ́ kí pílánẹ́ẹ̀tì wa wo ara rẹ̀ sàn—Ẹni tí ó dà a.

“Jẹ́ Kí Inú Ayé Kí Ó Dùn”

Ọlọrun kò fìgbà kan ní in lọ́kàn rí pé kí àwọn ènìyàn run ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún Adamu láti “máa ro” ọgbà Edeni “àti láti máa ṣọ́ ọ.” (Genesisi 2:15) Àníyàn Jehofa láti dáàbò bo ayé ni ó tún hàn nínú ọ̀pọ̀ àwọn òfin tí ó fi fún àwọn ọmọ Israeli. Fún àpẹẹrẹ, ó sọ fún wọn pé, kí wọ́n fi ilẹ̀ sílẹ̀ láti sinmi ní ẹ̀ẹ̀kan ní gbogbo ọdún méjeméje—ọdún Sábáàtì. (Eksodu 23:10, 11) Nígbà tí àwọn ọmọ Israeli kò kọ ibi ara sí òfin yìí àti àwọn òfin mìíràn léraléra, Jehofa gba àwọn ará Babiloni láyè lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti dín iye àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kù, èyí tí ó wá dahoro fún 70 ọdún “títí ilẹ̀ náà yóò fi san ọdún ìsinmi rẹ̀.” (2 Kronika 36:21) Pẹ̀lú ohun kan tí ó fara jọ ọ́ nínú ìtàn yìí, kò yani lẹ́nu pé Bibeli sọ pé, Ọlọrun yóò “mú awọn wọnnì tí ń run ayé bàjẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́,” kí ilẹ̀ ayé baà lè padà bọ̀ sípò kúrò nínú ìbàyíkájẹ́ tí àwọn ènìyàn ti ṣe.—Ìṣípayá 11:18.

Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nìkan ni ìyẹn yóò jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè, Barry Commoner, ti sọ ọ́ lọ́nà tí ó bójú mu, lílàájá pílánẹ́ẹ̀tì yìí “sinmi lórí fífi tí a bá fi òpin sí ogun tí à ń bá ìṣẹ̀dá jà àti fífi tí a bá fi òpin sí ogun tí à ń bá ara wa jà, bákan náà.” Kí ọwọ́ wa baà lè tẹ góńgó yẹn, “Olúwa” gbọ́dọ̀ “kọ́” gbogbo àwọn ènìyàn orí ilẹ̀ ayé láti ṣìkẹ́ ara wọn àti láti ṣìkẹ́ ilé wọn orí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde, àlàáfíà wọn yóò “pọ̀.”—Isaiah 54:13.

Ọlọrun mú un dá wa lójú pé, àtúnṣe yóò wà fún ètò ìṣiṣẹ́ dídíjúpọ̀ ti àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Dípò lílọ sí ìparun láìdáwọ́dúró, àwọn aṣálẹ̀ yóò “tanná bíi lílì.” (Isaiah 35:1) Dípò àìtó oúnjẹ, “ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀.” (Orin Dafidi 72:16) Dípò tí àwọn odò yòó fi gbẹ nítorí ìbàyíkájẹ́, wọn yóò “máa ṣápẹ́.”—Orin Dafidi 98:8.

Nígbà wo ni irú àyípadà bẹ́ẹ̀ yóò ṣeé ṣe? Nígbà tí “Olúwa” bá “jọba.” (Orin Dafidi 96:10) Ìṣàkóso Ọlọrun yóò mú ìbùkún dá gbogbo ohun alààyè tí ó bá wà lórí ilẹ̀ ayé lójú. Olórin náà sọ pé: “Jẹ́ kí inú ayé kí ó dùn. Jẹ́ kí òkun kí ó hó, àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀; jẹ́ kí oko kí ó kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi igbó yóò kọrin fún ayọ̀.”—Orin Dafidi 96:11, 12, New International Version.

Ayé tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bù kún, tí ó sì ń ṣàkóso rẹ̀ pẹ̀lú òdodo yóò ní ọjọ́ ọ̀la kíkàmàmà. Bibeli ṣàpèjúwe àbájáde rẹ̀ pé: “Òdodo àti àlàáfíà ti fi ẹnu ko ara wọn ní ẹnu. Òtítọ́ yóò rú jáde láti ilẹ̀ wá: òdodo yóò sì bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá. Ní tòótọ́ Olúwa yóò fúnni ní èyí tí ó dára; ilẹ̀ wa yóò sì máa mú àsunkún rẹ̀ wá.” (Orin Dafidi 85:10-12) Nígbà tí ọjọ́ yẹn bá wọlé dé, pílánẹ́ẹ̀tì wa kò ní sí nínú ewu mọ́ láéláé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Bí ara ẹ̀dá ènìyàn, ilẹ̀ ayé ní agbára àgbàyanu láti wo ara rẹ̀ sàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́