Kúbùsù Òtútù
O HA ti tẹjú mọ́ òjò dídì tí ń já bọ́, tí ó sì ti gbà ọ́ níyè lọ rí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé, ìwọ yóò gbà pé, èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun rírẹwà, tí ó sì máa ń mára tuni pẹ̀sẹ̀ jù lọ—ní pàtàkì bí o bá wà láàbò àti tí ara rẹ sì móoru nínú ilé, tí kò sì sí ìdí fún ọ láti rìnrìn àjò ní kánjúkánjú. Bí kúbùsù funfun náà ti ń ki sí i, ó jọ pé ó ń tan àlàáfíà jíjinlẹ̀ àti ìparọ́rọ́ kálẹ̀ níbi gbogbo. Kódà, ariwo àárín ìlú ńlá dín kù bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀gbọ̀n yìnyín náà ti ó rọra ń já bọ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, kò ha jẹ́ ìyàlẹ́nu bí ohun tí a ronú pé ó rọra ń rọ̀ bí òjò dídì ṣe lè di bàsèjẹ́? Àwọn ilú ńlá bíi New York, tí ó kún fún ìgbòkègbodò—tí a sábà máa ń ṣàpèjúwe bí “ìlú ńlá tí kò sùn rí”—lè dí èyí tí a dá ìgbòkègbodò ibẹ̀ dúró bí òjò dídì bá kóra jọ di òkìtì gíga.
Abájọ ti Ọlọrun fi bi ọkùnrin olódodo náà, Jobu, léèrè pé: “Ìwọ́ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ́ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí? Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu de ọjọ́ ogun àti ìjà.” (Jobu 38:22, 23) Òjò dídì lè jẹ́ ohun ìjà apániláyà ní ti gidi lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jehofa Ọlọrun.
Bí ó ti wù kí ó rí, òjò dídì sábà máa ń kó ipa kan nínú dídáàbò bo ìwàláàyè dípò bíbà á jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli sọ pé, Ọlọrun “fi òjò dídì fúnni bí irun àgùntàn [“òwú,” NW].” (Orin Dafidi 147:16) Báwo ni òjò dídì ṣe dà bí òwú? Bibeli lo òjò dídì àti òwú láti ṣàpẹẹrẹ ohun funfun àti àìlábàwọ́n. (Isaiah 1:18) Ṣùgbọ́n ìjọra mìíràn tún wà. A ń lo òjò dídì àti òwú gẹ́gẹ́ bí apata. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Òwú . . . ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí apata kúrò lọ́wọ́ òtútù àti ooru.” Nípa ti òjò dídì, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ World Book sọ pé, òun pẹ̀lú “ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí apata dáadáa. Òjò dídì ń ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo àwọn irúgbìn, ó sì máa ń jẹ́ ibi ìlùmọ́ fún àwọn ẹranko nígbà òtútù líle.”
Nítorí náà, nígbà míràn tí o bá ń wo òjò dídì tí ń já bọ́ láti ojú òfuurufú, ó yẹ kí o ronú nípa agbára ìyanu Ọlọrun. Tàbí kí o yàn láti ronú nípa ààbò tí ó rọra ń pèsè bí ó ti ń tẹ́ kúbùsù funfun náà sórí ìṣẹ̀dá rẹ̀, lọ́nà tí òbí onífẹ̀ẹ́ kan lè gbà fẹ̀sọ̀ fi aṣọ bo ọmọ kan sórí ibùsùn.