Àwọn Ẹ̀là Ilẹ̀ Tí Ó Fara Sin
NÍ August 18, 1994, ó kéré tán nǹkan bí 171 ènìyàn ló kú ní Algeria nítorí ìsẹ̀lẹ̀ lílágbára kan. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ló fara pa, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló sì di aláìnílé. Ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan kí ó tó di ìgbà yẹn, ìsẹ̀lẹ̀ gígọntiọ kọ lu Bolivia, Colombia, àti Indonesia, tí àpapọ̀ iye ẹ̀mí tí ó sọnù sì jẹ́ àìmọye ọgọ́rùn-ún.
Ìwọ ha mọ̀ pé àwọn àjálù gígọntiọ báwọ̀nyí ṣẹlẹ̀ bí? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé o kò mọ̀, àyàfi tí ó bá jẹ́ pé ó kan ìwọ fúnra rẹ̀ tàbí tí o bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè tí ó múlé gbè wọ́n. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ gígọntiọ wáyé ní agbègbè California, U.S.A., kíá ni ìròyìn náà tàn kálẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ló ní àwọn ìṣirò ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìsẹ̀lẹ̀ náà lárọ̀ọ́wọ́tó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ohun tí ó fà á ni pé kò tí ì sí agbègbè tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ ní kúlẹ̀kúlẹ̀ bíi gúúsù California, níbi tí ohun èèlò tí ń wọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ju 700 lọ tí ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ kéré tó 1.5. Nítorí bí àwọn ohun èèlò tí a fi ń wọn ìsẹ̀lẹ̀ ti pọ̀ tó ní agbègbè yẹn, ìsọfúnni nípa ìsẹ̀lẹ̀ tí ń wá láti agbègbè yẹn pọ̀ gan-an.
Àwárí Lọ́ọ́lọ́ọ́ Kan
Ìwádìí jíjinlẹ̀ yìí ni ó dájú pé ó ti ran àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti lóye ìsẹ̀lẹ̀ àti láti lè gbìyànjú láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn lásìkò kí àwọn ènìyàn má baà fara pa pàápàá. Irú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọdọọdún ni nǹkan bí 40 ìsẹ̀lẹ̀ tí ó jẹ́ ńlá gan-an ń ṣẹlẹ̀ ní onírúurú apá ilẹ̀ ayé. Àwọn ìsẹ̀lẹ̀ kéékèèké tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè pani lára, ṣùgbọ́n tí wọ́n tóbi débi tí a fi lè mọ̀ pé wọ́n ṣẹlẹ̀ tún wà pẹ̀lú. Àwọn wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ ní 40,000 sí 50,000 ìgbà lọ́dún!
Ohun tí ó ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ni àwọn ìpele òkúta tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tí ń là, tí wọ́n sì ń rọ́ kẹ́kẹ́ sí ipò míràn nígbà tí nǹkan bá kì í mọ́lẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìsẹ̀lẹ̀ yìí máa ń wáyé níbi tí ìtẹ́jú ilẹ̀ bá ti sán. Wọ́n ń pe irú àwọn ẹ̀sán yìí ní ẹ̀là.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti yàwòrán ibi tí ẹ̀là yìí wà, kí wọn ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ ní pàtó àwọn agbègbè tí ó ti ṣeé ṣe kí ìsẹ̀lẹ̀ wáyé. Èé ṣe tí a fi sọ pé “lọ́pọ̀ ìgbà”? Nítorí pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti wá mọ̀ láìpẹ́ yìí pé àwọn àwòrán àwọn kò fi gbogbo nǹkan hàn tán gẹ́gẹ́ bí àwọn ti lérò tẹ́lẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ọkàn àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ dàrú láti mọ̀ nípa ìṣípayá àìpẹ́ yìí pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ṣeé wọ̀n tí ó wáyé ní California ń ṣẹlẹ̀ níbi àwọn ẹ̀là tí ó fara sin—ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ní àwọn agbègbè tí àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ilẹ̀ kà sí ibi tí ewu ìsẹ̀lẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé, Ross Stein ti U.S. Geological Survey àti Robert Yeats ti Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Oregon sọ, “àwọn ìtẹ́jú ilẹ̀ tí kò ṣe pẹrẹsẹ tàbí tí wọ́n ní òkè ní ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ilẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu, ó máa ń tu ènìyàn lára, dípò kí ó mú ọ̀ràn ewu wá sí ọkàn ènìyàn.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìwádìí wọn ti fi hàn pé àwọn ẹ̀là tí ó ṣeé ṣe kí ó di ìsẹ̀lẹ̀ wà lábẹ́ àwọn ìṣegannaku àpáta, èyí tí wọ́n ti wa epo tí ó wà nínú ọ̀pọ̀ lára wọn. Èé ṣe tí àwọn ẹ̀là abẹ́ ilẹ̀ wọ̀nyí kì í fi bọ́ sí ojútáyé, báwo sì ni ewu tí wọ́n lè gbé síwájú ènìyàn ṣe pọ̀ tó?
Ewu Kan Tí A Kò Gbọ́dọ̀ Gbójú Fò Dá
Ó ti pẹ́ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣesí ilẹ̀ ti ṣàkíyèsí pé àpáta ṣeé súnkì, ó sì lè ká bí ẹní àtẹ́ẹ̀ká tí ó ká jọ. Ṣùgbọ́n ohun tí gbogbo wọn rò ni pé èyí máa ń ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀, lẹ́sẹ̀ẹ̀sọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí tí wọ́n ṣe nípa bí àpáta ṣe ń ká fi hàn pé wọ́n máa ń ta gbùrù sókè lójijì—ní nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mítà márùn-ún ní ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀! Ìkákò yìí máa ń tẹ àpáta tí ó wà lábẹ́ pọ̀. Ìkìmọ́lẹ̀ tí ó ń tibẹ̀ jáde sì máa ń jẹ́ kí àpáta tí ó wà lábẹ́ pátápátá là, ẹ̀là kan yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí í sùn lórí èkejì. Àwọn ìsúnkì tí ó dà bí èyí tí kò léwu nígbà tí ó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ yìí, tí ó máa ń ní ẹ̀là tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ló máa ń fa ìsẹ̀lẹ̀ kí àwọn onímọ̀ nípa ohun èèlò tí a fi ń wọn ìsẹ̀lẹ̀ tó ráyè rí wọn. Irú àwọn ẹ̀là abẹ́ ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè fa àwọn ìsẹ̀lẹ̀ lílágbára, gan-an bíi ti àwọn ẹ̀là ńlá, tí ó ṣeé rí lórí ilẹ̀.
Àpẹẹrẹ ohun tí ẹ̀là tí ó fara sin lè ṣe kan ni ti ìsẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé ní January 17, 1994, ní Northridge, ní agbègbè Los Angeles. Ẹ̀là tí ó wà lábẹ́lẹ̀ lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún láàárín nǹkan bíi kìlómítà 8 sí 19 lábẹ́lẹ̀ ló fa ìsẹ̀lẹ̀ yìí. Kí ìsẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò mọ̀ pé ẹ̀là náà wà níbẹ̀. Ẹ̀là tí ó fara sin yìí fa ìparun ohun ìní lílé kenkà, ìpalára fún àwọn ènìyàn tí ó ju 9,000 lọ, àti ikú àwọn ènìyàn 61.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fura pé àwọn ẹ̀là tí ó fara sin náà ní ń ṣokùnfà ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsẹ̀lẹ̀, kì í ṣe ní California nìkan, ṣùgbọ́n ní Algeria, Argentina, Armenia, India, Iran, Japan, Kánádà, New Zealand, àti Pakistan pẹ̀lú. Jálẹ̀ àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló ti kú ní àwọn ilẹ̀ yìí nítorí ìsẹ̀lẹ̀ tí ó ti lè jẹ́ pé àwọn ẹ̀là tí ó fara sin ló fà á.
Ìpènijà tí ó wá dojú kọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ni ti wíwá ibi tí àwọn ẹ̀là tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń là lọ́wọ́ ti ń ṣẹlẹ̀, kí wọn ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ewu ìsẹ̀lẹ̀ tí ó lè tibẹ̀ jáde. Ní báyìí ná, wọn kò tún jẹ́ fojú tẹ́ḿbẹ́lú agbára ìpanirun tí ilẹ̀ tí kò tẹ́jú tí ó dà bí èyí tí kò lè pani lára ní.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Los Angeles Ha Ń Súnkì Bí?
Ìpọ̀yamùrá àwọn ẹ̀là àti ìsúnkì àpáta tí ó so kọ́ra wọn tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ Los Angeles, California, mú kí agbègbè yìí jẹ́ ibi tí ó léwu lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó dà bi ẹni pé kòtò jìnmìràrà Los Angeles ń gba ọ̀pọ̀ ìkìmọ́lẹ̀ tí ìṣẹ́jọ Ẹ̀là Òkúta San Andreas tí ó wà nítòsí ń fa. (Wo ìtẹ̀jáde Jí!, July 22, 1994, ojú ewé 15 sí 18.) Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣesí ilẹ̀ tí ó wà ní àdúgbò ibẹ̀ fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, àwọn ìkájọ tí ìkìmọ́lẹ̀ yìí ń fà lè máa mú kí ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè kòtò jìnmìràrà Los Angeles dín kù pẹ̀lú ìdá mẹ́rin eékà kan lọ́dún.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
Globe: Mountain High Maps™ copyright © 1993 Digital Wisdom, Inc.