ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 19-22
  • Àrùn Aids Ní Áfíríkà—Báwo Ni Kirisẹ́ńdọ̀mù Ṣe Jẹ̀bi Rẹ̀ Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Aids Ní Áfíríkà—Báwo Ni Kirisẹ́ńdọ̀mù Ṣe Jẹ̀bi Rẹ̀ Tó?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsìn—Ó Ha Kó Ipa Kan Bí?
  • Bí Ilẹ̀ Áfíríkà Ṣe Di “Kristian”
  • Eré Ìnàjú Apá Ìwọ̀ Oòrùn Ayé Wọ Àárín Wọn
  • Ojútùú sí Yánpọnyánrin Náà
  • Ìṣirò Nípa Àrùn Éèdì Ń Kóbànújẹ́ Ńláǹlà Báni!
    Jí!—2001
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 19-22

Àrùn Aids Ní Áfíríkà—Báwo Ni Kirisẹ́ńdọ̀mù Ṣe Jẹ̀bi Rẹ̀ Tó?

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Áfíríkà

Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, a lò ọ̀rọ̀ náà “Kirisẹ́ńdọ̀mù” fún ìsìn Kristian aláfẹnujẹ́, ní òdì kejì sí ìsìn Kristian ti inú Bibeli.

Kirisẹ́ńdọ̀mù

“Àwọn apá ibi ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ti jẹ́wọ́ pé Kristian ni àwọn lágbàáyé.”—Webster’s New World Dictionary.

Àrùn AIDS

“Ipò àkóràn ìwólulẹ̀ agbára ìdènà àrùn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú èèràn tí àwọn kòkòrò àrùn ń fà nínú sẹ́ẹ̀lì ètò ìgbékalẹ̀ àjẹsára.” —Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary.

ÀRÙN AIDS jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn. Iye tí a fojú díwọ̀n sí mílíọ̀nù 17 àwọn ènìyàn ni kòkòrò HIV, kòkòrò àrùn tí ń fa àrùn AIDS, ti ràn. Ó sì ń tàn kálẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àfiyèsí ni a ti fún àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ ìṣègùn, ìṣèlú, àti ìmí ẹ̀dùn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn yìí, ohun tí a tí ì sọ lórí àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn nípa rẹ̀ kò tó nǹkan. Wàyí o, èrò síso ìsìn pọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ àrùn AIDS lè dà bí ohun tí kò bára tan lójú àwọn òǹkàwé kan. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe ohun tí kò bára tan bí o bá gbé ipò nǹkan ní ilẹ̀ Áfíríkà yẹ̀ wò.

Àrùn AIDS ti ran ilẹ̀ Áfíríkà gan-an lọ́nà kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀.a Àwọn kan sọ pé ilẹ̀ náà ti di ilé fún ìpín 67 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí àrùn AIDS ń ṣe. Ní Chad, àwọn ọ̀ràn àrùn yìí tí a fi tó àwọn aláṣẹ létí jálẹ̀ ọdún márùn-ún tí ó kọjá tí lọ́po lọ́nà 100. Síbẹ̀, fojú díwọ̀n rẹ̀ pé kìkì ìdá kan nínú gbogbo àwọn ọ̀ràn àrùn náà ni a tí ì fi tó àwọn aláṣẹ létí. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí Báǹkì Àgbáyé sọ, àrùn AIDS ti di ohun tí ó wọ́pọ̀ jù lọ tí ń fa ikú láàárín àwọn àgbàlagbà ní ọ̀pọ̀ àwọn ìgboro ìlú Áfíríkà.

Ìsìn—Ó Ha Kó Ipa Kan Bí?

Ó dájú pé kì í ṣe ìsìn Kristian—ìsìn tí Jesu Kristi fi kọ́ àwọn ènìyàn—ni a lè sọ pé ó jẹ̀bi ọ̀ràn bíbani nínú jẹ́ yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn ní ìsàlẹ̀, ọ̀rọ̀ náà, “Kirisẹ́ńdọ̀mù,” kó gbogbo ilẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti fi ìdánilójú sọ pé Kristian ni àwọn pọ̀. Ọ̀ràn náà sì lọ́ mọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ́rùn. Kì í ṣe pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n dá àrùn AIDS sílẹ̀, tàbí pé àwọn gan-an ni wọ́n jẹ́ kí ó tàn kálẹ̀. Ṣùgbọ́n, àrùn AIDS tàn kálẹ̀ ní Áfíríkà, ní pàtàkì jù lọ nítorí àwọn ìṣe ìbẹ́yà-kejì lòpọ̀ oníṣekúṣe.b Nípa báyìí, a lè pe àrùn AIDS ní ìṣòro ìwà híhù, nígbà tí ọ̀ràn sì rí báyìí, ó fa àwọn ìbéèrè kan tí ń dani láàmú tí ó jẹ mọ́ ti ìsìn. Ó ṣe tán, láti àwọn ilẹ̀ apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé ni “ìsìn Kristian” tí ó wà ní Áfíríkà ti wá. Àwọn aṣááju ṣọ́ọ̀ṣì ti ọrùn bọ yíyí àwọn ọmọ Áfíríkà padà sí irú ẹ̀yà ìsìn tiwọn, nípa fífìdánilójú sọ pé ó fi ọ̀nà ìyè tí ó dára ju ọ̀nà ti ìsìn ìbílẹ̀ Áfíríkà lọ han ni. Ipa tí ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ní ha mú kí ọ̀nà ìwà híhù àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn padà dára sí i ní tòótọ́ bí? Yánpọnyánrin àrùn AIDS fi hàn gbangba gbàǹgbà pé òdì kejì ni ọ̀ràn já sí ní ti gidi.

Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ti orílẹ̀-èdè Chad yẹ̀ wò. Nínú mẹ́rin lára àwọn ìlú ńlá rẹ̀, mẹ́ta ló jẹ́ èyí tí àwọn “Kristian” pọ̀ sí jù lọ. Ẹ̀kẹrin jẹ́ èyí tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí. Síbẹ̀, ìlú “Kristian” mẹ́ta náà ni kòkòrò àrùn náà ti ń jà jù lọ! Ohun kan náà ní ń ṣẹlẹ̀ káàkiri gbogbo àgbáálá ilẹ̀ náà. Àárín gbùngbùn àti gúúsù Áfíríkà, tí wọ́n jẹ́ Kristian ajórúkọ lásán, ní àwọn tí èèràn náà ń ràn ju Àríwá Áfíríkà, tí àwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù lọ.

Bí Ilẹ̀ Áfíríkà Ṣe Di “Kristian”

Èé ṣe tí kòkòrò àrùn yìí fi ń tàn kálẹ̀ bí iná ọ̀yẹ láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi? Ní tòótọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará Áfíríkà pe ara wọn ní Kristian, ìwọ̀nba díẹ̀ kéréje ló ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù ti ìsìn Kristian, tí a lànà rẹ̀ sílẹ̀ nínú Bibeli. Ó dà bí ẹni pé èyí jẹ́ àbájáde tààràtà fún ọ̀nà tí àwọn míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù gbà ṣe “ìyílọ́kànpadà” àwọn ènìyàn Áfíríkà.

Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù wá sábẹ́ àtakò. Ìṣelámèyítọ́ gíga jù di ohun tí ó gbajúmọ̀, tí ó sì ń bu Bibeli kù di ìwé ìgbàanì lásán kan lójú ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn. Àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n náà tún bẹ̀rẹ̀ síí ní ìtẹ́wọ́gbà, àní láàárín àwọn àlùfáà pàápàá. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iyè méjì. Àwọn ènìyàn gbé ìbéèrè dìde sí ìgbàgbọ́ nínú Ìwé Mímọ́. Pẹ̀lú gbogbo bí nǹkan ṣe rí yìí, kò yani lẹ́nu pé àwọn ìsapá Kirisẹ́ńdọ̀mù láti “yí” àwọn ará Áfíríkà “lọ́kàn padà” dá lórí àwọn ọ̀ràn tí kò ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn. Àwọn míṣọ́nnárì ṣọ́ọ̀ṣì wàásù ìhìn rere ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, nípa gbígbé ìtẹnumọ́ tí ó pọ̀ ka orí ṣíṣe àwọn iṣẹ́ aláàánú ju ríran àwọn ẹni tí a yí lọ́kàn padà láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli lórí ìwà híhù lọ. Bóyá láìmọ̀ pé àwọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì lọ́wọ́ sí sísọ ipò ìwà rere tí ó wà dìbàjẹ́ ní ti gidi.

Fún àpẹẹrẹ, níní alábàágbéyàwó púpọ̀ ti jẹ́ àṣà ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀dálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣekúṣe ṣọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹ̀yà ìran ló ní òfin mímúná nípa panṣágà. Joseph Darnas, olùkọ́ kan tí ó ti fẹ̀yìn tì, tí ó gbajúmọ̀ ní Chad, sọ fún Jí! pé, kí àwọn míṣọ́nnárì ṣọ́ọ̀ṣì tó dé, “àwọn ènìyàn máa ń rò pé ìwà panṣágà máa ń mú orí burúkú wá.” Nítorí èyí, “wọ́n máa ń fìyà jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi rẹ̀ gan-an nítorí tí ó kó gbogbo àwùjọ sínú ewu—lọ́pọ̀ ìgbà nípa pípa á.” Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ha ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n irú àwọn ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ kí ìṣekúṣe gbalẹ̀.

Ìgbà tó yá ni àwọn míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù dé. Wọ́n wàásù lòdì sí níní alábàágbéyàwó púpọ̀, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe láti mú kí àwọn ènìyàn máa lo ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli lórí ìwà híhù kò tó nǹkan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bibeli sọ pé ó yẹ kí a yọ àwọn alágbèrè àti àwọn onípanṣágà tí kò bá ronú pìwàdà kúrò nínú ìjọ Kristian, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù kì í sábàá fún àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀ ní ìbáwí. (1 Korinti 5:11-13) Títí tí ó fi di òní yìí, ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú ará Áfíríkà tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀ ni wọn kò lórúkọ rere nítorí ìṣekúṣe wọn, síbẹ̀, wọ́n ṣì jẹ́ mẹ́ḿbà tí ó ní ìdúró rere nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ìṣòtítọ́ nínú ìgbeyàwó ṣọ̀wọ́n láàárín àwọn Kristian ajórúkọ lásán ní ilẹ̀ Áfíríkà.

Àpẹẹrẹ búburú tí àwọn mẹ́ḿbà àlùfáà fúnra wọn fi lélẹ̀ tún wà níbẹ̀. Nínú ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ràn níní ìdílé yìí, ó jẹ́ ohun tí ó wà déédéé láti gbéyàwó kí a sì bí ọmọ púpọ̀. Bóyá ìdí nìyí tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn àlùfáà Kátólíìkì ṣe rò pé àwọn kò lẹ́bi tí àwọ́n bá tàpá sí ẹ̀jẹ́ tí àwọ́n jẹ́ láti jẹ́ oníwà mímọ́ àti láti wà láìláya. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times, ti May 3, 1980, ròyìn pé: “Ní apá ibi púpọ̀ ní agbègbè oko, . . . àwọn àlùfáà àti àwọn bíṣọ́ọ̀bù jẹ́ olóbìnrin púpọ̀.”

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, irú ìgbeyàwó bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kì í forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ní ti gidi ohun tí àwọn “ìyàwó” náà sì jẹ́ kò ju àlè lásán lọ. Irú ìwà ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ ní a kò lè gbójú fò dá bí ohun tí kò já mọ́ pàtàkì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Times ṣe sọ, “àlùfáà Kátólíìkì kan tí ó gbajúmọ̀” jẹ́wọ́ pé “àwọn àlùfáà ilẹ̀ Áfíríkà jẹ́ àmì ọlá àṣẹ, àwọn ẹni agbára, dípò kí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jesu Kristi.” Ó dà bíi pé ọ̀rọ̀ tí ń jáde láti ọ̀dọ̀ “àwọn ẹni agbára” wọ̀nyí ni, “Ṣe bí mo ṣe sọ, àmọ́ máà ṣe bí mo ṣe ń ṣe.”

Eré Ìnàjú Apá Ìwọ̀ Oòrùn Ayé Wọ Àárín Wọn

Ohun mìíràn tí kò tún yẹ kí á gbójú fò dá ni agbami eré ìnàjú oníṣekúṣe tí ó ti rọ́ wọ ilẹ̀ Áfíríkà ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Ní Chad, àwọn ilé ìwòran fídíò tí àwọn àgbà kì í bojú tó tí ó máa ń fi irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ hàn ti gba ibi gbogbo—ní àwọn ilé àdáni, ní àwọn gáréèjì, àti lọ́pọ̀ ìgbà, ní àwọn àgbàlá ilé nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú. Àwọn ìran tí wọ́n ń fi hàn yìí kì í wọ́nwó, ohun tí ó ń ná ènìyàn kò ju owó franc 25 (sẹ́ǹtì 5, U.S.). Àwọn ọmọdé máa ń lọ síbẹ̀. Ibo ní àwọn nǹkan yìí ti pilẹ̀? Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ jẹ́ láti United States—ilẹ̀ tí ó sọ pé àwọn Kristian ló pọ̀ jù nínú àwọn ènìyàn òun!

Ṣùgbọ́n, ìrọ́wọlé àwọn àṣà ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé yìí ha ti ní ipa gidi kan lórí àwọn òǹwòran bí? Míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, tí ó ti ní ìrírí ní Àárín gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà fún ọdún 14, sọ pé: “Ìfarakanra tí àwọn ènìyàn àdúgbò ní pẹ̀lú àwọn ènìyàn ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé kò pọ̀, bí kò bá ṣe ohun tí wọ́n ń rí lórí àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò. Wọ́n fẹ́ láti dà bí àwọn ará ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé tí wọ́n rí nínú àwọn àwòrán sinimá wọ̀nyí. Kì í ṣe pé mo ti rí ìwádìí kan tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ láti fi ti èyí lẹ́yìn ni, àmọ́ ó dà bí ẹni pé ó ṣe kedere sí ọ̀pọ̀ ènìyàn níhìn-ín pé irú eré ìnàjú bẹ́ẹ̀ ń fún ìṣekúṣe ní ìṣírí.”

Ẹ wò ó bí ó ti jẹ́ ohun tí ó ta kora tó pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníṣẹ́ ìlera ń gbìyànjú ní gbogbo ọ̀nà láti dáwọ́ ìtànkálẹ̀ àwọn àrùn aṣekúpani tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ dúró, àwọn orílẹ̀-èdè tí à ń pè ní Kristian ń ṣe ìgbékèéyíde tí ń fún ìwà ìṣekúṣe, tí ó léwu lókun! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kò ṣe ohun tí ó jọjú láti dáwọ́ ìwà yìí dúró, yálà ní ilẹ̀ tiwọn fúnra wọn tàbí ní ilẹ̀ òkèèrè, àwọn ìjọba ilẹ̀ Áfíríkà kan, irú bíi Chad àti Cameroon, ti gbìyànjú láti ka kíkó àwọn àwòrán oníṣekúṣe wọ orílẹ̀-èdè wọn léèwọ̀, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ dín in kù. Ṣùgbọ́n léraléra ni ìsapá wọn máa ń já sí pàbó.

Ohun tí ó jẹ́ àbáyọrí gbogbo èyí ni ìlọsílẹ̀ ìwà rere tí ń gbalẹ̀ sí i láàárín àwọn “Kristian” ilẹ̀ Áfíríkà. Ipò ọrọ̀ ajé tí kò dára tún ní ipa kan tí ó fara sin. Nítorí pé iṣẹ́ wọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà ni a máa ń fagbára mú àwọn ọkùnrin láti fi ìdílé wọn sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù gbọọrọ kí wọ́n baà lè wáṣẹ́. Ó ṣe kedere pé irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ àfojúsùn fún àwọn aṣẹ́wó àdúgbò. Bí ó ti wù kí ó rí, ipò òṣì ló wọ́pọ̀ jù nínú ohun tí ń sún àwọn aṣẹ́wó fúnra wọn dé ìdí rẹ̀. Àwọn òbí tí wọ́n máa ń bèèrè owó orí tí ó gọntiọ jẹ́ okùnfà míràn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin kò gbéyàwó nítorí pé wọn kò lè kó owó tí wọ́n nílò láti fi san owó orí ìyàwó jọ. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ máa ń parí rẹ̀ sí pé kí wọ́n máa ṣèṣekúṣe kiri. Nínú irú ipò ìwà híhù àti ọrọ̀ ajé bẹ́ẹ̀, àrùn AIDS ti tàn kálẹ̀ lọ́nà yíyára kánkán.

Ojútùú sí Yánpọnyánrin Náà

Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù nìkan ló ni ẹ̀bi yánpọnyánrin àrùn AIDS ní ilẹ̀ Áfíríkà. Àmọ́ pé ó hàn gbangba pé òun ni ó ni èyí tí ó pọ̀ jù nínú rẹ̀ bani nínú jẹ́. Èyí ní ìtumọ̀ tí ó wúwo rinlẹ̀ fún àwọn tí wọ́n bá ń fẹ́ láti wà lára àwọn wọnnì tí Jesu pè ní “olùjọsìn tòótọ́.”—Johannu 4:23.

Kí a fi ọ̀rọ̀ ẹ̀bi tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí ni a lè ṣe láti dáwọ́ àjàkálẹ̀ àrùn AIDS dúró? Àwọn ìjọba ilẹ̀ Áfíríkà tí tọrùn bọ ìkégbàjarè ṣíṣọ́ra fún àrùn AIDS, ní fífún àwọn ènìyàn níṣìírí láti máa lo kọ́ńdọ́ọ̀mù. Ṣùgbọ́n Dókítà Samuel Brew-Graves, tí ó jẹ́ aṣojú fún Ètò-Àjọ Ìlera Àgbáyé fún Nàìjíríà, sọ ojú abẹ níkòó pé: “Olúkúlùkù ló gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbésí ayé lọ́nà tí ó dára . . . , tí ó sì jẹ́ pé àwọn ìdílé gbọ́dọ̀ . . . yẹra fún ìṣekúṣe.”

Tipẹ́tipẹ́ kí àrùn AIDS tóó di ohun tí àwọn ènìyàn mọ̀, Bibeli dẹ́bi fún ìṣekúṣe, ó sì fún ìwà mímọ́, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ìṣòtítọ́ nínú ìgbeyàwó ní ìṣírí. (Owe 5:18-20; 1 Korinti 6:18) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilẹ̀ Áfíríkà lè jẹ́rìí sí i fúnra wọn pé títẹ̀lé àwọn ìlànà yìí pèsè àbò kúrò lọ́wọ́ àrùn AIDS àti àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ takọtabo mìíràn ń ta látaré, dé ìwọ̀n àyè kan. Rírọ̀ tí wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli jẹ́ ẹ̀sùn sí Kirisẹ́ńdọ̀mù lọ́rùn. Àwọn Kristian tòótọ́ wọ̀nyí tún ti gbé ìrètí wọn lórí ayé tuntun kan tí ń bọ̀ tí ‘òdodo yoo máa gbé’ inú rẹ̀. (2 Peteru 3:13) Fún àwọn ènìyàn onígbàgbọ́, èyí ni ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà sí yánpọnyánrin àrùn AIDS.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú sí i, wo àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “AIDS Ní Africa—Ki ni Yoo Gbẹhin Rẹ̀?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 8, 1992.

b Fífa ẹ̀jẹ̀ sára àti lílo abẹ́rẹ́ ìṣègùn tí ẹnì kan tí lò tẹ́lẹ̀ tún lè tan àrùn náà kálẹ̀. Àwọn Kristian tí wọn kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kan ti kó àrùn yìí lára alábàáṣègbeyàwó tí ó ti hùwà ìṣekúṣe tàbí tí ó ti lo òògùn ìlòkulò ṣaájú.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

“Ní apá ibi púpọ̀ ní agbègbè oko, . . . àwọn àlùfáà àti àwọn bíṣọ́ọ̀bù jẹ́ olóbìnrin púpọ̀.”—The New York Times

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àpẹẹrẹ burúkú tí àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù fi lélẹ̀ ti tanná ran ìtànkálẹ̀ ìṣekúṣe ní ilẹ̀ Áfíríkà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Wọ́n ṣí àwọn ògo wẹẹrẹ payá sí eré ìnàjú oníṣekúṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè “Kristian” ń kó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́