Ìwọ́ Ha Ti Ṣe Kàyéfì Rí Bí?
KÍ NI ohun náà gan-an tí Bibeli sọ nípa Maria, ìyá Jesu? Ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ nínú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù fi tọkàntọkàn gbà gbọ́ nínú ẹ̀kọ́ náà pé Baba jẹ́ Ọlọrun, Ọmọ jẹ́ Ọlọrun, tí Ẹ̀mí Mímọ́ náà sì jẹ́ Ọlọrun, àti síbẹ̀ wọn kì í ṣe ọlọrun mẹ́ta, ṣùgbọ́n mẹ́ta nínú ọ̀kan. Ní èdè míràn, Mẹ́talọ́kan. Fún apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù (Kátólíìkì, Áńgílíkà, àti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì), ẹ̀kọ́ yìí ló fi ọgbọ́n ṣamọ̀nà wọn sínú ìgbàgbọ́ pé Maria, ìyá Jesu, ló tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ “Ìyá Ọlọrun.” Bí ọ̀rọ̀ ti rí ha nìyẹn bí? Ojú wo ni Jesu fi wo ìyá rẹ̀? Ojú wo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi wò ó? Jẹ́ kí a wo bí Bibeli ṣe dáhùn:
1. Ìgbà wo ni a kọ́kọ́ dárúkọ Maria nínú Bibeli?—Matteu 1:16.
2. Ìsìn wo ni Maria ń ṣe nígbà tí ó bí Jesu?—Luku 2:39, 41.
3. Ǹjẹ́ Maria ṣe ìrúbọ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ bí?—Luku 2:21-24; fi wé Lefitiku 12:6, 8.
4. Ǹjẹ́ wúńdíá ni Maria nígbà tí ó lóyún Jesu? Èé ṣe tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?—Matteu 1:22, 23, 25; Luku 1:34; Isaiah 7:14; Heberu 4:15.
5. Báwo ni Maria ṣe lóyún?—Luku 1:26-38.
6. Báwo ni Maria ṣe hùwà padà sí ipò rẹ̀ tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀?—Luku 1:46-55.
7. Báwo ni Maria ṣe fi hàn pé òún jẹ́ ìyá tí ó máa ń ṣàníyàn?—Luku 2:41-51.
8. Ǹjẹ́ Maria bí àwọn ọmọ mìíràn nígbà tí ó yá?—Matteu 13:55, 56; Marku 6:3; Luku 8:19-21; Johannu 2:12; 7:5; Ìṣe 1:14; 1 Korinti 9:5.
9. Báwo ni a ṣe mọ̀ ní ti gidi pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin Jesu kì í ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀?—Fi wé Marku 6:3; Luku 14:12; àti Kolosse 4:10.
10. Jesu ha wo Maria gẹ́gẹ́ bí “Ìyá Ọlọrun” bí?—Johannu 2:3, 4; 19:26.
11. Maria ha wo ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ìyá Ọlọrun” bí?—Luku 1:35; Johannu 2:4, 5.
12. Ǹjẹ́ Jesu fún ìyá rẹ̀ ní àyẹ́sí tàbí ọ̀wọ̀ àrà ọ̀tọ̀ kíkàmàmà kankan bí?—Marku 3:31-35; Luku 11:27, 28; Johannu 19:26.
13. Ojú wo ni Maria fi wo ipò rẹ̀ nínú àwọn ète Jehofa?—Luku 1:46-49.
14. Maria ha jẹ́ onílàjà láàárín Ọlọrun àti àwọn ènìyàn bí?—1 Timoteu 2:5.
15. Níbi mélòó lára àwọn ìwé 66 inú Bibeli ni a ti dárúkọ Maria?
16. Àwọn Kristian òǹkọ̀wé ha gbé Maria lékè nínú àwọn ìwé àti lẹ́tà wọn bí?—Johannu 2:4; 2 Korinti 1:1, 2; 2 Peteru 1:1.
17. Ìgbà mélòó ni a dárúkọ Maria nínú àwọn lẹ́tà 21 tí Paulu, Peteru, Jakọbu, Johannu, àti Juda kọ?
18. Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jesu, ìrètí wo ni Maria ní?—1 Peteru 2:5; Ìṣípayá 14:1, 3.
19. Maria ha ni obìnrin náà tí a tọ́ka sí nínú Genesisi 3:15 àti Ìṣípayá 12:3-6?—Isaiah 54:1, 5, 6; Galatia 4:26.
20. Kí ni ipò tí Maria wà nísinsìnyí?—2 Timoteu 2:11, 12.
Àwọn Ìdáhùn Bibeli
1. “Jekọbu di baba Josefu ọkọ Maria, nípasẹ̀ ẹni tí a bí Jesu, ẹni tí à ń pè ní Kristi.”—Matteu 1:16.
2. “Nígbà tí wọ́n ti ṣe ohun gbogbo tán ní ìbámu pẹlu òfin Jehofa, wọ́n padà lọ sí Galili sí Nasareti ìlú-ńlá tiwọn. Wàyí o ó ti di àṣà awọn òbí rẹ̀ lati máa lọ sí Jerusalemu lati ọdún dé ọdún fún àjọyọ̀ ìrékọjá.” (Luku 2:39, 41) Gẹ́gẹ́ bíi Júù, wọ́n tẹ̀ lé Òfin Mose.
3. “Nígbà tí ọjọ́ wíwẹ̀ wọ́n mọ́ gaara ní ìbámu pẹlu òfin Mose pé, wọ́n gbé e gòkè wá sí Jerusalemu lati fi í fún Jehofa, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ ninu òfin Jehofa pé: ‘Gbogbo akọ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ pè ní mímọ́ fún Jehofa.’” (Luku 2:22, 23) “Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ bá pé, fún ọmọkùnrin, tàbí fún ọmọbìnrin, kí ó mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ sísun, àti ẹyẹlé, tàbí àdàbà, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tọ àlùfáà wá, sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ: Bí kò bá sì lè mú ọ̀dọ́ àgùntàn wá, ǹjẹ́ kí ó mú àdàbà méjì, tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá; ọ̀kan fún ẹbọ sísun, àti èkejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀: àlùfáà yóò sì ṣètùtù fún un, òun óò sì di mímọ́.”—Lefitiku 12:6, 8.
4. “Oun [Josefu] kò ní ìbádàpọ̀ kankan pẹlu rẹ̀ títí ó fi bí ọmọkùnrin kan; ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu.” (Matteu 1:25) “Maria wí fún áńgẹ́lì naa pé: ‘Bawo ni èyí yoo ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí emi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹlu ọkùnrin?’” (Luku 1:34) “Oluwa tìkála rẹ̀ yóò fún yín ní àmì kan, Kíyèsí i, Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Immanueli.” (Isaiah 7:14) “Awa ní gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, kì í ṣe ẹni kan tí kò lè bánikẹ́dùn fún awọn àìlera wa, bíkòṣe ẹni kan tí a ti dánwò ní gbogbo ọ̀nà bí awa fúnra wa, ṣugbọn tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.”—Heberu 4:15.
5. “Áńgẹ́lì naa wí fún un pé: ‘Ẹ̀mí mímọ́ yoo bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jùlọ yoo sì ṣíjibò ọ́. Nitori ìdí èyí pẹlu ohun tí a bí ni a óò pè ní mímọ́, Ọmọkùnrin Ọlọrun. . . . Lọ́dọ̀ Ọlọrun kò sí ìpolongo kankan tí yoo jẹ́ aláìṣeéṣe.’”—Luku 1:35, 37.
6. “Maria sì wí pé: ‘Ọkàn mi gbé Jehofa galọ́lá, ẹ̀mí mi kò sì lè dẹ́kun yíyọ ayọ̀ púpọ̀ sí Ọlọrun Olùgbàlà mi . . . Ẹni tí í ṣe alágbára ti ṣe awọn ìṣe ńláǹlà fún mi, mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.’”—Luku 1:46, 47, 49.
7. “Wàyí o nígbà tí wọ́n rí i háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì wí fún un pé: ‘Ọmọ, èéṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yii? Wò ó bayii baba rẹ ati emi ti ń wá ọ ninu wàhálà èrò-orí.’ Ṣugbọn ó wí fún wọn pé: ‘Èéṣe tí ẹ fi níláti máa wá mi? Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé emi gbọ́dọ̀ wà ninu ilé Baba mi ni?’”—Luku 2:48, 49.
8. “Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà naa? Kì í ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ń pè ní Maria, ati awọn arákùnrin rẹ̀ Jakọbu ati Josefu ati Simoni ati Judasi? Ati awọn arábìnrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹlu wa?” (Matteu 13:55, 56) “Oun ati ìyá ati awọn arákùnrin rẹ̀ [Gíríìkì, a·del·phoiʹ] ati awọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ [Gíríìkì, ma·the·taiʹ] sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kapernaumu, ṣugbọn wọn kò dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀.”—Johannu 2:12.
9. Ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà ní èdè Gíríìkì fún arákùnrin àti mọ̀lẹ́bí. “‘Èyí ni káfíńtà naa ọmọkùnrin Maria ati arákùnrin [Gíríìkì, a·del·phosʹ] Jakọbu ati Josefu ati Judasi ati Simoni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Awọn arábìnrin [Gíríìkì, a·del·phaiʹ] rẹ̀ sì wà pẹlu wa níhìn-ín, àbí wọn kò sí?’ Nitori naa wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ lára rẹ̀.” (Marku 6:3) “Máṣe pe . . . awọn ẹbí [Gíríìkì, syg·ge·neisʹ] rẹ.” (Luku 14:12) “Marku mọ̀lẹ́bí [Gíríìkì, a·ne·psi·osʹ] Barnaba . . .” (Kolosse 4:10)—Wo The Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures.
10. “Jesu wí fún un pé: ‘Kí ni pa tèmi tìrẹ pọ̀, obìnrin? Wákàtí mi kò tí ì dé síbẹ̀.’” “Ní rírí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn naa tí oun nífẹ̀ẹ́ tí ó dúró nítòsí, Jesu wí fún ìyá rẹ̀ pé: ‘Obìnrin, wò ó! Ọmọkùnrin rẹ!’” (Johannu 2:4; 19:26) Lílò tí Jesu lo “obìnrin” gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń lò ó nígbà náà lọ́hùn-ún kì í ṣe ọ̀rọ̀ àrífín.
11. Kò sí ibì kankan nínú Bibeli tí a ti lo ọ̀rọ̀ náà “Ìyá Ọlọrun.”
12. “Obìnrin kan bayii lati inú ogunlọ́gọ̀ naa gbé ohùn rẹ̀ sókè ó sì wí fún un pé: ‘Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ naa tí ó gbé ọ ati ọmú tí iwọ mu!’ Ṣugbọn ó wí pé: ‘Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, Aláyọ̀ ni awọn wọnnì tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí wọ́n sì ń pa á mọ́!’”—Luku 11:27, 28.
13. “Maria sì wí pé: ‘Ọkàn mi gbé Jehofa galọ́lá . . . nitori tí oun ti bojúwo ipò rírẹlẹ̀ ẹrúbìnrin rẹ̀. Nitori, wò ó! lati ìsinsìnyí lọ gbogbo ìran ni yoo máa pè mí ní aláyọ̀.’”—Luku 1:46, 48.
14. “Nitori Ọlọrun kan ni ó wà, ati alárinà kan láàárín Ọlọrun ati awọn ènìyàn, ọkùnrin kan, Kristi Jesu.”—1 Timoteu 2:5.
15. Márùn-ún—Matteu, Marku, Luku, Johannu, àti Ìṣe. Ó fara hàn gẹ́gẹ́ bíi “Maria” ní ìgbà 19, gẹ́gẹ́ bí “ìyá” Jesu ní ìgbà 24, àti gẹ́gẹ́ bí “obìnrin” nígbà 2.
16. Yàtọ̀ sí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere mẹ́rin náà, kò sí ibì kankan tí a ti mẹ́nu kan orúkọ Maria—a kò tilẹ̀ mẹ́nu kàn án nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìfáárà lẹ́tà àwọn aposteli pàápàá. “Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́-inú Ọlọrun . . . Kí ẹ ní inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ati àlàáfíà lati ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọrun ati Jesu Kristi Oluwa.” (2 Korinti 1:1, 2) “Simoni Peteru, ẹrú ati aposteli Jesu Kristi, . . . nipa òdodo Ọlọrun wa ati Jesu Kristi Olùgbàlà.”—2 Peteru 1:1.
17. A kò tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré.
18. “Ẹ̀yin fúnra yín pẹlu gẹ́gẹ́ bí awọn òkúta ààyè ni a ń gbéró gẹ́gẹ́ bí ilé ti ẹ̀mí fún ète iṣẹ́ àlùfáà mímọ́, lati máa rú awọn ẹbọ ti ẹ̀mí tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi.” (1 Peteru 2:5) “Mo sì rí, sì wò ó! Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa dúró lórí Òkè-Ńlá Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n ní orúkọ rẹ̀ ati orúkọ Baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. Wọ́n sì ń kọrin bí ẹni pé orin titun kan níwájú ìtẹ́ . . . , kò sì sí ẹni kankan tí ó lè dọ̀gá ninu orin yẹn bíkòṣe ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì naa, tí a ti rà lati ilẹ̀-ayé wá.”—Ìṣípayá 14:1, 3.
19. “Kọrin, ìwọ àgàn, tí kò bí rí; bú sí orin, sì ké rara, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ ẹni aláhoro pọ̀ ju àwọn ọmọ ẹni tí a gbé ní ìyàwó: ni Oluwa wí. Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ní ọkọ rẹ; Oluwa àwọn ọmọ ogun ní orúkọ rẹ̀; àti Olùràpadà rẹ Ẹni Mímọ́ Israeli; Ọlọrun àgbáyé ni a óò máa pè é.” (Isaiah 54:1, 5) “Jerusalemu ti òkè jẹ́ òmìnira, oun sì ni ìyá wa.” (Galatia 4:26) Obìnrin ìṣàpẹẹrẹ Ọlọrun, Sioni ti ọ̀run, ètò Jehofa ti ọ̀run, ni a fi wé ìyàwó àti ìyá kan, òun sì ni “obìnrin” tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí.
20. “Àsọjáde naa ṣe é gbíyèlé: Dájúdájú bí a bá kú papọ̀, a óò wà láàyè papọ̀ pẹlu; bí a bá ń bá a lọ ní fífaradà, a óò ṣàkóso papọ̀ pẹlu gẹ́gẹ́ bí ọba; bí a bá sẹ́, oun pẹlu yoo sẹ́ wa.” (2 Timoteu 2:11, 12) Bí ó bá jẹ́ pé Maria ṣe olóòótọ́ dé ojú ikú, òun yóò máa sàkóso nísinsìnyí ní ọ̀run papọ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù lára 144,000 tí ń jọba pẹ̀lú Kristi.—Ìṣípayá 14:1, 3.