Wíwo Ayé
“Gbígbé Nínú Ẹ̀ṣẹ̀” Kì í Ṣe Ẹ̀ṣẹ̀ Kẹ̀?
Ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly sọ pé, Ẹgbẹ́ Abójútó Ọ̀ràn Ojúṣe Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà ti Ṣọ́ọ̀ṣì England gba ṣọ́ọ̀ṣì náà níyànjú láìpẹ́ yìí pé “gbígbé nínú ẹ̀ṣẹ̀” kì í tún ṣe ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. Wọ́n ròyìn pé ẹgbẹ́ náà tún gba ṣọ́ọ̀ṣì náà níyànjú pé “àwọn ìjọ lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn tọkọtaya tí wọn kò ṣègbéyàwó, títí kan àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí wọ́n sì dènà àdánwò bíbojú wẹ̀yìn wo ‘sànmánì ìláásìkí ìdílé.’” Ìwé agbéròyìnjáde Guardian náà fa ọ̀rọ̀ àlùfáà Philip Hacking yọ nígbà tí ó ń dáhùn padà pé: “Èyí sọ Ṣọ́ọ̀ṣì yìí di ohun ìyọṣùtì sí, ó sì ń fa wàhálà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn Kristian olùṣòtítọ́.”
Pípàdánù Agbára Láti Kàwé àti Láti Kọ̀wé
Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn míràn ní ilẹ̀ Germany ti pàdánù agbára láti kàwé àti láti kọ̀wé dáradára nítorí àìmáaṣeé déédéé. Johannes Ring, akọ̀wé Àjọ Ìwé Kíkà, ṣàlàyé pé ìlọsíwájú tí àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ ń ní ń mú kí ìṣòro náà pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Frankfurter Allgemeine Zeitung ti sọ, níbi Àpérò Àgbáyé Lórí Ṣíṣẹ́pá Àìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà, Ring sọ pé pípọ̀ tí irú àìmọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà yìí ń pọ̀ sí i, lápá kan, jẹ́ nítorí gbígbalẹ̀ tí tẹlifíṣọ̀n, kọ̀m̀pútà, àti àwọn eré orí fídíò ń gbalẹ̀ kan.
Mu Omi Kí O Lè Ronú Dáadáa
Ìwọ́ ha ní ìṣòro ìpọkànpọ̀ bí? Ìwé ìròyìn Asiaweek dábàá pé, bóyá ó yẹ kí o máa mu omi púpọ̀ sí i. Ìwé ìròyìn náà sọ pé a fún àwọn olùkọ́ àti àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní Hong Kong nímọ̀ràn láìpẹ́ yìí pé mímu omi púpọ̀ yóò ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti gbógun ti ìrẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n wí fún àwọn òbí pé, ó yẹ kí àwọn ọmọ máa mu ife omi 8 sí 15 lójúmọ́. Nígbà tí ìròyìn náà ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ìwé The Learning Brain, ó tọ́ka sí àwọn ìwádìí tí ó fi hàn pé àìlómilára lè ṣamọ̀nà sí àìlèkẹ́kọ̀ọ́ dáradára. Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé, mímu omi dáradára, tí ó mọ́ tónítóní, sàn ju mímu ọtí ẹlẹ́rìndòdò, kọfí, tíì, tàbí omi èso pàápàá lọ, èyí tí ó lè mú kí ara máa ti omi jáde ní ti gidi.
Ìkìlọ̀ Nípa Lílo Oògùn Apakòkòrò
Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì California ní Berkeley ti sọ, àwọn ará America ń jìyà púpọ̀ gan-an lọ́wọ́ ìṣírapayá sí àwọn oògùn apakòkòrò láti ara àwọn ohun èèlò inú ilé ju láti ara àwọn èso àti ewébẹ̀ tí a fi oògùn apakòkòrò fín lọ. Àwọn oògùn fífín tí ń pa aáyán, àwọn ìkẹ́dẹ alálẹ̀mọ́ tí a gbé kọ́, apakòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀, ìṣù káńfọ̀, àti àwọn ohun èèlò jíjọra ní kẹ́míkà èròjà májèlé nínú. Ní àfikún sí fífa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìṣẹ̀lẹ̀ májèlé lọ́dún, ọ̀pọ̀ ń fa àwọn ewu ìlera tí ó wà pẹ́ títí. Lẹ́tà ìròyìn UC Berkeley Wellness Letter dábàá àwọn àfirọ́pò tí kò léwu: Ṣàtúnṣe nẹ́ẹ̀tì tàbí kí o ra tuntun, kí o sì dí àwọn ibi tí ó sán nílẹ̀ àti lára ògiri láti lé àwọn kòkòrò jìnnà; pa oúnjẹ àti ìdọ̀tí mọ́ sínú láílọ́ọ̀nù; sì lo ìhùmọ̀ apakòkòrò tí a fi rọ́bà ṣe; gbá àwọn èérún oúnjẹ kúrò nílẹ̀; fi ooru gbígbóná fọ rọ́ọ̀gì; máa nu àwọn ohun tí a fi òwú ṣe léraléra, kí o sì kó wọn sínú àpò tí a dé pa. Wellness Letter dábàá pé, bí àwọn aáyán kò bá lọ, gbìyànjú lílo ìkẹ́dẹ alálẹ̀mọ́ tàbí wíwọ́n ásíìdì boric sẹ́yìn àwọn kọ́bọ́ọ̀dù, àmọ́ má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ àti àwọn ohun ọ̀sìn ìṣiré dé ibi tí àwọn ohun èèlò wọ̀nyí wà.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tẹlifíṣọ̀n fún Àwọn Ọmọdé—Ó Ti Níwà Ipá Jù
Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórí ìsokọ́ra tẹlifíṣọ̀n ní America ti sọ pé “ìwà ipá ìjà ẹlẹ́mìí èṣù” ti pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ eré tí a ń ṣe fún àwọn ọmọdé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ti sọ, ìwádìí tí wọ́n ṣe ní Yunifásítì California ní Los Angeles náà tọ́ka sí ọ̀wọ́ àwọn àwòrán ẹ̀fẹ̀ bíi mélòó kan bí èyí tí ó ní “ìwà ipá nínú nítorí fífi ìwà ipá hàn.” Wọ́n sábà máa ń gbé àwọn eré náà sáfẹ́fẹ́ ní òwúrọ̀ Saturday, nígbà tí àwọn ọmọdé kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́, tí ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí wọ́n ṣì máa sùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn eré báyìí kì í ṣe tuntun, ìwádìí náà ṣàwárí pé “àwọn ipa ẹlẹ́mìí èṣù àti ìjà tí kò dáwọ́ dúró tí ó wà nínú eré wọ̀nyí para pọ̀ jẹ́ ìtẹ̀sí tuntun tí ó jọ pé ó ń pọ̀ sí i.”
Igi Ìyanu
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ará Britain ti ṣàwárí àwọn hóró èso tí ó lè sọ omi mímu di aláìléèérí láìlo àwọn kẹ́míkà olówó gọbọi. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé àwọn hóró èso tí a fọ́ tí ó wá láti ara igi Moringa oleifera láti ìhà àríwá India maa ń fa bakitéríà àti àwọn fáírọ́ọ̀sì mọ́ra, ó sì máa ń lẹ̀ mọ́ wọn, lẹ́yìn náà, a lè ré e dànù tàbí kí a fi asẹ́ sẹ́ e. A tún lè fi igi gbogboǹṣe náà ṣe epo ìsebẹ̀, ọṣẹ, ohun ìṣaralóge, epo àtùpà, àti ìpara kan fún kòkòrò ara. Igi náà rọrùn láti gbìn, ọ̀gbẹlẹ̀ kì í ṣe é ní nǹkan, ó lè gba atẹ́gùn dúró, kí ó sì pèsè epo àti àpòlùpọ̀ rírọ̀ fún ṣíṣe bébà. Lójú ìwòye èyí, àwọn olùṣèwádìí rọ àwọn ènìyàn pé kí wọ́n máa gbin àwọn igi yìí láti mú àwọn hóró tí yóò báni dènà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ikú tí mímu omi eléèérí ń fà lọ́dọọdún jáde.
Tín-ínrín Jù Kẹ̀?
Nínú àwùjọ tí ọ̀ràn ìrísí jẹ lógún jù, ọ̀pọ̀ ènìyàn ronú pé kò ṣeé ṣe láti tín-ínrín jù. Ó lè jẹ́ pé ìwádìí kan tí a ṣe láìpẹ́ yìí tí ń jẹ́rìí sí àwọn ewu ìlera tí ó wà nínu sísanra jọ̀kọ̀tọ̀ ń fún èrò wíwọ́pọ̀ yìí níṣìírí ni, àmọ́ aṣáájú nínú ìwádìí náà, JoAnn Manson ti Yunifásítì Harvard, fẹ́ kí ó di mímọ̀ pé títín-ínrín jù tún jẹ́ ewu fún ìlera. Wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal níbi tí ó ti sọ pé: “Mo mọ̀ pé o lè di ẹni tí ó tín-ínrín jù nípa àìjẹuntó, eré ìmárale tí ó ré kọjá ààlà, tàbí sìgá mímu.” Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde Journal ń tọ́ka sí àwọn dókítà díẹ̀ tí wọ́n ké gbàjarè nípa àwọn ewu inú ìfebipanú ré kọjá ààlà, ó ṣàkọsílẹ̀ àwọn ewu títín-ínrín lọ́nà àfọwọ́fà, bóyá kí ẹnì kan fi ìwọ̀n ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún kéré sí ìpíndọ́gba ìtẹ̀wọ̀n tí ó yẹ fún gíga rẹ̀. Àwọn ni àìyánnu fún oúnjẹ, àrùn àìlágbára egungun, ìdíwọ́ omi ìsúnniṣe inú ara, ìṣubú, yíyẹ̀ léegun, àti àìtètè kọ́fẹ padà ara.
Ìbuniṣán Ejò —Ohun Tí Kò Yẹ Kí A Ṣe
Bí ó bá di ọ̀ràn títọ́jú àwọn tí ejò ṣán, ohùn àwọn ògbógi kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣọ̀kan. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn FDA Consumer ti sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn amọṣẹ́ ìṣègùn dunjú ní United States ni wọ́n “fẹ́rẹ̀ẹ́ fohùn ṣọ̀kan nínú ojú ìwòye wọn nípa ohun tí kò yẹ kí a ṣe.” Bí o bá wà níbi tí kò ju 30 sí 40 ìṣẹ́jú sí ibi ìtọ́jú aláìsàn, àmọ̀ràn náà ni pé: Má ṣe fi omi dídì sí ojú rẹ̀, má ṣe dì í tàbí fi iná mànàmáná kàn án, má sì ṣe sín in ní gbẹ́rẹ́. Ìdámọ̀ràn tí a tẹ́wọ́ gbà jù lọ ni pé yálà ejò náà jọ olóró tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ kí a tọ́jú gbogbo ìbuniṣán ejò ní pàjáwìrì, a sì gbọ́dọ̀ gbé ẹni tí ó ṣán náà lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ìwé ìròyìn FDA Consumer sọ pé, ìgbésẹ̀ ìṣèdíwọ́ tí ó dára jù lọ ni láti “má ṣe da àwọn ejò láàmú. Ejò ń ṣán ọ̀pọ̀ ènìyàn nítorí pé wọ́n ń gbìyànjú láti pa á tàbí láti wò ó dáadáa.”
Ìkìlọ̀ Kan fún Àwọn Agbábọ́ọ̀lù
Nínú bọ́ọ̀lù gbígbá, eré ìdárayá tí ó gbajúmọ̀ jù lọ lágbàáyé, àwọn agbábọ́ọ̀lù lè fi orí gbá bọ́ọ̀lù. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé agbéròyìnjáde Jornal do Brasil sọ pé, èyí lè ba ọpọlọ jẹ́ bí ó bá di lemọ́lemọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe láìpẹ́ yìí tí sọ, àwọn agbábọ́ọ̀lù lè jìyà ìpàdánù agbára ìrántí àti àìjáfáfá ọpọlọ nítorí fífi orí gbá bọ́ọ̀lù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fi bẹ́ẹ̀ le jù, ìpalára rẹ̀ jọra pẹ̀lú èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn akànṣẹ́ kan tí wọ́n máa ń gba ẹ̀ṣẹ́ lórí lemọ́lemọ́. Onímọ̀ nípa ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ náà, Paulo Niemeyer Filho dábàá pé ó yẹ kí àwọn agbábọ́ọ̀lù yẹra fún títẹ́rí gba bọ́ọ̀lù nígbà tí ó bá ń já bọ̀ lókè tàbí tí ara rẹ̀ bá tutù, èyí tí ń mú kí bọ́ọ̀lù náà wúwo sí i. Àwọn ògbógi kan gbà gbọ́ pé fífi orí gbá bọ́ọ̀lù jù tún lè ba ojú agbábọ́ọ̀lù jẹ́.
Ẹ̀rín Músẹ́ Tí Ó Dénú Máa Ń Ranni
Àwọn olùṣèwádìí ara Finland náà, Dókítà Jari Hietanen ti Yunifásítì Tampere àti Dókítà Veikko Surakka ti Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ìṣègùn Nípa Wíwà Ẹ̀dá ní Yunifásítì Helsinki sọ pé oríṣi ẹ̀rín músẹ́ méjì ló wà. Ìsọ̀wọ́ kan ni àwọn ògbógi mọ̀ sí ẹ̀rín músẹ́ ojúlarí. Kìkì ìmọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe ló máa ń fa èyí, ó sì máa ń lo kìkì àwọn iṣan ẹ̀rẹ̀kẹ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀rín músẹ́ tí ó dénú ń fi ìmọ̀lára ìjadùn gidi hàn, kì í sì í ṣe àwọn iṣan ẹ̀rẹ̀kẹ́ nìkan ló ń mú ṣiṣẹ́ àmọ́ ó máa ń mú àwọn iṣan ojú pẹ̀lú ṣiṣẹ́. Ìwádìí kan tí a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti Finland sọ pé ẹ̀rín músẹ́ tí ó dénú máa ń ranni. Nípa mímọ̀ àti ṣíṣẹ̀dà ìgbékiri iṣan ara kíkéré jọjọ, àwọn olùṣèwádìí rí i pé àwọn tí wọ́n ń lò fún àyẹ̀wò wọn ni a sún láti rẹ́rìn-ín músẹ́ kìkì nípa wíwo fọ́tò ẹnì kan tí ń rẹ́rìn-ín músẹ́ tí ó dénu. Wọn kò rí ìhùwàpadà yìí nígbà tí àwọn tí wọ́n ń lò fún àyẹ̀wò ń wo fọ́tò àwọn ènìyàn tí ń rẹ́rìn-ín ojúlarí.
Àwọn Awòràwọ̀ Kùnà
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany náà Die Zeit ti sọ, láìpẹ́ yìí ni àwọn awòràwọ̀ 44 ní ilẹ̀ Netherlands fínnúfíndọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àyẹ̀wò kan tí Ẹgbẹ́ Àwọn Aṣiyèméjì Ilẹ̀ Netherlands ṣe. Wọ́n fún àwọn awòràwọ̀ náà ní àkọsílẹ̀ méjì. Ọ̀kan ní ọjọ́ ìbí àti ibi tí a bí àwọn ẹni méje sí. Èkejì pèsè ìsọfúnni púpọ̀ yanturu nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn ẹni méje náà. Wọ́n sọ fún àwọn awòràwọ̀ náà láti sọ ẹnì kọ̀ọ̀kan tí àlàyé tí ó wà nínú àkọsílẹ̀ kejì bá dọ́gba nínú àkọsílẹ̀ àkọ́kọ́ nípa lílo agbára tí wọ́n sọ pé àwọ́n ní nínú ìwòràwọ̀. Báwo ni wọ́n ṣe kẹ́sẹ járí tó? Ìdajì lára àwọn awòràwọ̀ náà kò tilẹ̀ gba ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kankan tí ó lè gbà ju mẹ́ta lọ. Àwọn àṣeyẹ̀wò tí ó ṣáájú ti mú irú ìyọrísí kan náà wá, àmọ́ àwọn awòràwọ̀ náà sọ pé ńṣe ni wọ́n fún àwọn ní ìsọfúnni tí kò tọ̀nà. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwọn awòràwọ̀ náà fúnra wọn ni wọ́n gbé ààlà ìpinnu àyẹ̀wò náà kalẹ̀.