Fèrèsé Kan Ṣí Ilé Ọlẹ̀ Payá
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ AUSTRALIA
ÀWỌN àyẹ̀wò jíjinlẹ̀ tí a ń ṣe ṣáájú ìbímọ lóde òní ń mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn dókítà láti ṣàwárí ọ̀pọ̀ àbùkù ara tàbí ti ọpọlọ, tí ọmọ tí a kò tí ì bí lè ní, lọ́nà pípéye púpọ̀ sí i. Ìgbì ìró ohùn àti fífami ọlẹ̀ wà lára àwọn ọ̀nà ṣíṣètẹ́wọ́gbà jù tí a ń lò.
Ìgbì ìró ohùn jẹ́ ìlànà tí kò kan iṣẹ́ abẹ tàbí abẹ́rẹ́, tí ń lo ìgbì ohùn gíga tí a kò lè gbọ́ láti yàwòrán ọmọ inú ilé ọlẹ̀ sórí kọ̀m̀pútà. Fífami ọlẹ̀ ní nínú, fífi abẹ́rẹ́ fa omi díẹ̀ láti ilé ọmọ, omi tí ó gbé ọmọ náà dúró nínú ilé ọlẹ̀, kí a sì ṣàyẹ̀wo rẹ̀ láti rí ipa oníkẹ́míkà tí ń fi àbùkù tí ọmọ inú ń ní, bíi Down’s syndrome, hàn.
Bí a ti mú irú ìmọ̀ ẹ̀rọ ìṣègùn yìí wọnú àwùjọ bí ìgbà tí a ju òkúta kan sínú omi adágún kan, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àṣàyàn ìṣẹ́yún, ó ń fa ìrúkèrúdò ńlá nínú àwọn ipò dídíjú kan nínú ìlànà ìmọ̀ ìṣègùn.a Ó dunni pé ètò ìgbékalẹ̀ ìníyelórí ayé yìí kì í ṣe ìlànà fífẹsẹ̀ múlẹ̀ lórí èyí tí a ti lè yanjú àwọn ọ̀ràn ìwà híhù àti ìlànà iṣẹ́, ó sì jọ èyí tí ó túbọ̀ dà bí ìtí igi tí kò ní ìdarí, tí ó léfòó lórí ìgbì omi tí ń jà gùdù.
Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn ènìyàn ń ṣe àṣàyàn ìṣẹ́yún, tí ìmọ̀ ẹ̀rọ kín lẹ́yìn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kò tí ì fàṣẹ sí i. Nínú ìwádìí 13 tí a ṣe ní United States láàárín ọdún 15 tí kò tí ì pẹ́, ìpín 75 sí 78 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fèsì gbà gbọ́ lọ́nà bíbára mu délẹ̀ pé ó yẹ kí aboyún kan ní ẹ̀tọ́ òfin láti ṣẹ́yún ọmọ tí a bá ní àmì dídájú pé yóò ní àbùkù ara líle koko. Ní àwọn ilẹ̀ kan, “àbùkù ara tí a sọ tẹ́lẹ̀” fúnra rẹ̀ ti tó láti fàyè gba ìṣẹ́yún.
Láìpẹ́ yìí, ní Australia, ìyá kan kẹ́sẹ járí ní pípe dókítà rẹ̀ lẹ́jọ́ fún ìpalára nítorí pé ó kùnà láti ṣàwárí àrun rubella (èéyi ilẹ̀ Germany) nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lóyún. Bí ènìyàn bá ní àrùn yìí nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lóyún, ó lè ṣamọ̀nà sí àbùkù líle koko lára ọmọ tí a kò tí ì bí náà. Ìyá náà sọ pé ìkùnà dókítà òún fi àǹfààní ṣíṣẹ́yún ọmọ òun du òun.
Nígbà tí olùṣèwádìí nípa ọ̀ràn òfin, Jennifer Fitzgerald, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn apá ẹjọ́ yìí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òfin àti ìlànà iṣẹ́, ó sọ nínú àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyin Queensland Law Society Journal ti April 1995 pé: “Kì í ṣe kìkì pé ó [aboyún náà] ní láti pinnu pé, ‘Ǹjẹ́ mo fẹ́ láti bí ọmọ bí?’, ó tún ní láti pinnu pé, ‘Irú ọmọ wo ni mo fẹ́?’” Fitzgerald béèrè pé, irú àbùkù wo ló wá pèsè ìpìlẹ̀ tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fún ìṣẹ́yún tí ó bófin mu? “Ètè lílà bíi ti ehoro, ihò òkè ẹnu, ojú dídà, Down’s syndrome, ògóró ẹ̀yìn lílà ni bí?” Ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé, irú ẹ̀yà ọmọ náà ni, ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ obìnrin!
“Àwọn Aláìṣeéfọwọ́kàn” Nínú Ilé Ọlẹ̀ Kẹ̀?
Bí ìtòpọ̀ apilẹ̀ àbùdá ẹ̀dá ènìyán ti ń ṣí payá sí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, tí ohun èèlò ìṣèwádìí àrùn ṣáájú ìbímọ sì ń mú kí a lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ inú ilé ọlẹ̀ lọ́nà kan ṣáá, kí ni yóò máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí? A óò ha máa ṣàṣàyàn àwọn tí wọ́n ní ìwọ̀nba àbùkù sọ́tọ̀ fún ìṣẹ́yún bí? Ní tòótọ́, ńṣe ni àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́ ń tẹ̀ síhà ìṣẹ́yún púpọ̀ sí i, kò kéré sí i. Bí iye ìṣẹ́yún ti ń pọ̀ sí i, tí iye ìpẹ̀jọ́ sì ń pọ̀ sí i yìí—bíi ti ọ̀ràn ẹjọ́ tí a mẹ́nu kàn lókè—àwọn dókítà ń ṣàníyàn. A lóye pé èyí lè fipá mú wọn dórí ọ̀nà ìṣe tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ìgbèjà ara ẹni nínú ìmọ̀ ìṣègùn, irú bíi bíbéèrè fún àwọn àyẹ̀wò kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nítori ti ìyá àti ọmọ ṣùgbọ́n láti dáàbò bo ara wọn. Fitzgerald kọ̀wé pé gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, “ó ṣeé ṣe kí iye àyẹ̀wò ṣáájú ìbímọ pọ̀ sí i, èyí sì lè mú kí iye àṣàyàn ìṣẹ́yún pẹ̀lú pọ̀ sí i.” Ó fi kún un pé èyí yóò mú “èto kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú èyí tí ‘àwọn aláìṣeéfọwọ́kàn’ ti di ‘aṣeéyọdànù’” wá.
Bí ìyá kan bá bí ọmọ tí ó lábùkù lára nígbà tí wọ́n fún un ní gbogbo àǹfààní—bóyá tí wọ́n sì fún un níṣìírí—láti ṣẹ́ ẹ ńkọ́? Fitzgerald sọ pé: “Bóyá àkókò kan yóò dé tí a óò máa sọ fún àwọn òbí pé wọn kò lè retí ìrànlọ́wọ́ láti kojú àìní àwọn ọmọ wọn tí ó lábùkù nítorí pé wọ́n yàn láti bí ọmọ náà nígbà tí ó jẹ́ pé wọn ì bá ti ṣẹ́ ẹ.”
A kò níí gbójú fo ohun tí àṣàyàn ìṣẹ́yún tẹ̀ mọ́ àwọn aláàbọ̀ ara nínú àwùjọ wa lọ́kàn. Bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan bá ń pa àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí nítorí àwọn àbùkù ara, yóò ha mú kí àwọn aláàbọ̀ ara nímọ̀lára jíjẹ́ ẹrù ìnira fún àwọn mìíràn bí? Yóò ha mú kí ó túbọ̀ le koko fún wọn láti kojú àìní iyì ara ẹni tí wọ́n ti lè ní nípa ara wọn tẹ́lẹ̀ rí bí?
Òtítọ́ náà pé ẹgbẹ́ àwùjọ òde òní yóò gbé àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí sọnù lọ́nà tí àwọn òṣìṣẹ́ ń gbà gbé ẹ̀yà tí ó lábùkù nínú ìlà ìṣèmújáde kan sọnù bá àpẹẹrẹ àkópọ̀ ìwà tí Bíbélì ṣàpèjúwe nípa àwọn ènìyàn tí ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí mu. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé lọ́nà gbígbòòrò, àwọn ènìyàn kì yóò ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Ọ̀rọ Gíríìkì náà, aʹstor·goi, tí a túmọ̀ sí “aláìní ìfẹ́ni àdánidá,” tọ́ka sí ìsopọ̀ àdánidá tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ń ní fún ẹnì kíní kejì wọn, bí irú ìfẹ́ tí ìyá kan ń ní fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Dájúdájú, àwọn ènìyàn ayé yìí tí wọn kò lákòóso “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bíi nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́,” yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé òdodo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Éfésù 4:14) Gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró kan fún ọkàn, Bíbélì mú kí a fìdí múlẹ̀ gbọn-in ní ti ìwà rere, àti láìyẹsẹ̀ nínú òkun onípákáǹleke. (Fi wé Hébérù 6:19.) Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni mọ̀ pé obìnrin kan lè yọ ọmọ inú tí ó lábùkù ara líle koko dànù látọkànwá, èrò yíyọjú wo inú ilé ọlẹ̀ gan-an láti mọ̀ bóyá ọmọ kan lera tó láti pa mọ́ kó wọn nírìíra.b—Fi wé Ẹ́kísódù 21:22, 23.
Ohun tí ń fún ìpinnu Kristẹni kan láti pa ìwà títọ́ mọ́ lókun ni ìlérí Ọlọ́run nípa àkókò kan tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Bẹ́ẹ̀ ni, láìka àwọn ìṣòro lọ́ọ́lọ́ọ́ tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn aláàbọ̀ ara àti àwọn ìrúbọ tí àwọn tí ń tọ́jú wọn ń ṣe sí, “yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀ru Ọlọ́run.”—Oníwàásù 8:12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àṣàyàn ìṣẹ́yún ni àṣa ṣíṣẹ́yún ọmọ kan nítorí pé kò ní àwọn àmì ànímọ́ tí òbí (tàbí àwọn òbí) ń fẹ́.
b Dájúdájú, èyí kò túmọ̀ sí pé kò tọ̀nà fún Kristẹni kan láti ṣe àyẹ̀wò láti mọ̀ nípa ìlera ọmọ tí a kò tí ì bí. Àwọn ète ìṣègùn bíi mélòó kan tí Ìwé Mímọ́ fọwọ́ sí lè wà, tí ó lè mú kí oníṣègùn kan dámọ̀ràn irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àyẹ̀wò kan lè kan wíwu ọmọ náà léwu, nítorí náà, yóò bọ́gbọ́n mu láti bá dókítà náà sọ̀rọ̀ nípa ìwọ̀nyí. Lẹ́yìn irú àwọn àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀, bí a bá rí i pé ọmọ náà ní àwọn àbùkù líle koko, ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn òbí Kristẹni lè wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ṣẹ́yún ọmọ náà. Yóò bọ́gbọ́n mu láti wà ní ìmúrasílẹ̀ láti rọ̀ mọ́ ìlàna Bíbélì.