ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 8/22 ojú ìwé 12-14
  • Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kì í Ṣe Gbogbo Eré Àṣedárayá Ló Rí Bákan Náà!
  • Ohun Tó Burú Nínu Wọn
  • Bárakú!
  • Fí Ọgbọ́n Ṣe Yíyàn Rẹ
  • Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?
    Jí!—2008
  • Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Àwọn Géèmù orí Kọ̀ǹpútà?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 8/22 ojú ìwé 12-14

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Ó Ha Yẹ Kí N Máa Ṣe Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Kọ̀m̀pútà Tàbí Fídíò Bí?

Wọ́n yí ọ ká! Àmọ́, ìrànlọ́wọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ. O bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò ọta bò wọ́n láti inú ìbọn rẹ ràgàjì, o sì ń pa àwọn ọ̀tá rẹ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Ìṣòro ibẹ̀ ni pé, bí o ti ń rọ̀jò ọta tó ni àwọn ọ̀tá ń pọ̀ sí i tó. O wáá ní yíyàn kan ṣoṣo tí o bá fẹ́ẹ́ là á já—pa ohunkóhun tí o bá fojú gán-ánní. Bí o ti ń rọ̀jò ọta ni àwọn ọ̀tá náà ń pòórá pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tó bò wọ́n jìngbìnnì . . .

“ÌMÓRÍYÁ ti kíkán eegun ẹ̀yìn, bíba ẹran ara jẹ́, fífọ́ orí yángá”! Báyìí ni òǹkọ̀wé ìwé ìròyìn kan ṣe fi tọyàyàtọyàyà ṣàpèjúwe ẹ̀da eré àṣedárayá lílókìkí kan tí ó dé kẹ́yìn. Ní tòótọ́, èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀wọ́ eré àṣedárayá orí kọ̀m̀pútà àti fídíò tí ń jẹ́ kí àwọn òṣèré kópa nínú gbígbé àwọn ìfọkànyàwòrán arúmọ̀lára sókè jáde. Ó jọ pé a ti tẹ àwọn ọ̀wọ́ tí ó jáde ṣáájú rì ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn eré àṣedárayá onítàjẹ̀sílẹ̀, tí ó máa ń ní ìwà ipá bíbàjẹ́ bàlùmọ̀ nínú wọ̀nyí.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn eré àṣedárayá oníwà ipá orí fídíò àti kọ̀m̀pútà lókìkí gidi gan-an láàárín àwọn ọ̀dọ́. Níwọ̀n bí ìfojúdíwọ̀n ìdá kan nínú agbo ilé mẹ́ta ní United States ti ní irú àwọn ìgbékalẹ̀ eré àṣedárayá orí ohun èèlò abánáṣiṣẹ́, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èwe ní a ń yọ̀ǹda fún láti lò wọ́n. Fún àwọn èwe tí wọn kò ní irú ohun èèlò bẹ́ẹ̀ nílé, ó lè jẹ́ kíki rírìn òpó díẹ̀ dé ilé ọ̀rẹ́ kan tàbí ibi ìṣiré gbogbogbòò kan ní yóò gbà láti ṣe eré àṣedárayá yìí.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé ó ti wá sí ọ lọ́kàn láti rà—tàbí ó kéré tán láti gbìyànjú—àwọn kan nínú àwọn eré àṣedárayá tuntun yìí? Ó dára, lẹ́yìn tí o bá gbé gbogbo òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ yẹ̀ wò, o lè tún da ọ̀ran ṣíṣe bẹ́ẹ̀ rò.

Kì í Ṣe Gbogbo Eré Àṣedárayá Ló Rí Bákan Náà!

Lákọ̀ọ́kọ́, jẹ́ kí ọ̀rọ wa yé ọ pé kì í ṣe gbogbo eré àṣedárayá orí fídíò tàbí kọ̀m̀pútà ni kò yẹ ní fífẹ́ tàbí ló níwà ipá nínú. Àwọn eré àṣedárayá púpọ̀ ló ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìwé; wọ́n ń kọ́ni ní àwọn kókó ẹ̀kọ́ bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti ìwàláàyè inú rẹ̀, ìṣirò, àti títẹ̀wé lọ́nà tó gbádùn mọ́ni, tí ó sì ń dáni lára yá. Àwọn eré àṣedárayá mìíràn máa ń ru agbára ìrònú sókè nípa gbígbé àpẹẹrẹ irú eré ìdíje kan bíi bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ àti bọ́ọ̀lù aláfigigbá jáde. Àwọn àdìtú ọlọ́gbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga tí ń fa ọkàn mọ́ra tí ó sì ń ru ú sókè wà pẹ̀lú.

Òtítọ́ ni pé àwọn eré àṣedárayá dídára jù lọ pàápàá lè gba ọ̀pọ̀ àkókò. Bíbélì sì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti ‘ra àkókò pada,’ ìyẹn ni pé, lo àkókò lọ́nà ọgbọ́n ní lílépa àwọn ohun tẹ̀mí. (Éfésù 5:16) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì kò béèrè pé kí a máa lo gbogbo wákàtí ayé yìí fún iṣẹ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, ó rán wa létí pé “ìgba rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgba jíjó” ń bẹ́. (Oníwàásù 3:4) Bí a bá ṣeré ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó lè jẹ́ atura, kí ó sì gbámúṣé.

Ámọ́ ṣá o, ó yẹ kí a mọ̀ pé ó jọ pé wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ lára àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyí láti jẹ́ kí àwọn òṣèré máa lo àkókò púpọ̀ jọjọ dà nù ni. Nínú àwọn kan lára wọn, a máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti kọ́ eré náà ní ìpele dídíjú kan, kí òṣèré tóó wáá rí i pé àwọn ìpele bíi mélòó kan—alápá líle koko, tí ó sì díjú pọ̀ gan-an, tí kò sì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀—ni a gbọ́dọ̀ ṣe kí ó tóó parí! Àwọn eré àṣedárayá kan tún wà tí ó jọ pé kì í kọ́ni ní ohun púpọ̀ tó ọ̀pọ̀ ipá ti a sà. Dan àti Sam, àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, fi takuntakun ṣe eré àṣedárayá kan tí wọ́n rò pé ó lè ṣèrànwọ́ fún wọn láti mọ ẹ̀kọ́ ìṣiro wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, kíá ni wọ́n rí i pé àwọ́n tètè ṣe ìṣirò náà tán lórí pépà ju lórí kọ̀m̀pútà lọ!

Nítorí náà, kódà pẹ̀lú eré àṣedárayá orí kọ̀m̀pútà àti fídíò tí ó gbámúṣé, ìdí wà láti ṣàṣàyàn. Dan àti Sam sọ pé: “Bí o bá wá ọjà dáadáa, o lè rí eré àṣedárayá tí ó dára.” Bí ó ti wù kí ó rí, ní tòótọ́ ni ó bọ́gbọ́n mú láti yẹra fún nínáwó púpọ̀ lórí àwọn eré àṣedárayá tí ó wulẹ̀ ń yọrí sí kí ẹnì kan tètè káàárẹ̀. Òbí kan gba àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin níyànjú láti máa ṣe kìkì àwọn eré àṣedárayá tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú àwọn kókó ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́.

Ohun Tó Burú Nínu Wọn

Ó dunni pé kì í ṣe gbogbo eré àṣedárayá orí kọ̀m̀pútà àti fídíò ló jẹ́ eré amóríyà tí kò lè pani lára—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìwé. Púpọ̀ lára àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀m̀pútà nípa eré ìnàjú lóde òní, darí àfiyèsí sí ohun tí Bíbélì pè ní “awọn iṣẹ́ ti ẹran ara”—àwọn ìwà àìmọ́ tí Ọlọ́run dẹ́bi fún. Lára “àwọn iṣẹ́” tí a dẹ́bi fún náà ni “bíbá ẹ̀mí lò.” (Gálátíà 5:19-21) Ní ti gidi, Jèhófà Ọlọ́run “kórìíra” idán pípa.—Diutarónómì 18:10-12.

Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ lára àwọn eré àṣedárayá òde òní ló kún fún ìbẹ́mìílò àti idán! Nínú eré àṣedárayá kan, a ní láti lo “ọfọ̀” kí a baà lè borí. A fún àwọn òṣèré ní ìtọ́ni pé: “Tí o bá ti ṣe tán láti pe ọfọ̀ náà, tẹ àmi mànàmáná tí ó wà nísàlẹ̀ ọwọ́ ọ̀tún ìtòjọ ohun àgbéṣe, lẹ́yìn náà, tẹ ìṣẹ̀dá tí o fẹ́ẹ́ pa.” Ṣé irú àwọn eré àṣedárayá báwọ̀nyí kò lè ru ìfẹ́ ìtọpinpin tí kò tọ̀nà nípa àwọn agbára ẹ̀mí èṣù sókè?

Ti jíjọ̀wọ́ ara ẹni fún ìwọ̀n púpọ̀ jọjọ ti ìwà ipá fífara sin ńkọ́? Ìwé ìròyin U.S.News & World Report sọ nípa eré àṣedárayá lílókìkí méjì tí ń ṣàfihan “títú ọkàn-àyà alábàádíje kan” àti “àwọn àkúdàáyà tí ń dá ihò sí ara àwọn ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba tí aṣọ kò bò lára tán.” Nígbà tí àwọn kan lè fọwọ́ rọ́ ìfọkànyàwòrán ìtàjẹ̀sílẹ̀ yìí sẹ́yìn bí èyí tí kò lè ṣepalára, Bíbélì kìlọ̀ nínú Orin Dáfídì 11:5 pé: “Olúwa ń dán olódodo wò: ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti ẹni tí ń fẹ́ ìwà agbára, ọkàn rẹ̀ kórìíra.”—Fi wé Áísáyà 2:4.

Ó tún ṣeé ṣe láti gbé pàrùpárù àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè jáde lójú kọ̀m̀pútà. Àwòrán ìhòhò goloto àti ìbálòpọ̀ tí a kò fi bò ti di ìran wíwọ́pọ̀ gan-an débi tí àwọn aṣèmújáde eré àṣedárayá ní United States fi gbé ètò ìpele kan jáde láti kìlọ̀ fún àwọn òǹrajà nípa àwọn eré àṣedárayá tó léwu. Síbẹ̀síbẹ̀, ó jọ pé àwọn aláròóbọ̀ bíi mélòó kan ń fẹ́ láti fawọ́ títà á fún àwọn ògowẹẹrẹ sẹ́yìn. Akọ̀wé ilé ìtajà kan sọ pé: “Iṣẹ́ àìgbọdọ̀ má ṣe kan ṣoṣo tí a ní ni láti fún àwọn oníbàárà ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.” Síbẹ̀, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ jíjọ̀wọ́ ara mi fún àwọn àwòrán tí ń ru ìbálòpọ̀ sókè yóò ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ọkàn mi sórí àwọn ohun tí ó jẹ́ “òdodo, mímọ́níwà, tí ó dára ní fífẹ́, àti ìwà funfun”?’—Àwọn ará Fílípì 4:8.

Bárakú!

Lótìítọ́, àwọn ògbógi ń jiyàn nípa bí àwọn eré tí a fi sórí kọ̀m̀pútà ṣe lè nípa lórí àwọn èwe. Ìwádìí kan, tí a ròyin rẹ̀ nínú ìwé ìròyin New Scientist, fi ìfojúsọ́nà fún rere parí ọ̀rọ̀ pé irú àwọn eré àṣedárayá bẹ́ẹ̀ “kì í ṣe gbòǹgbò okùnfà ìwà búburú.” Síbẹ̀síbẹ̀, ìpín 97 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ògowẹẹrẹ tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìwádìí yẹn “rò pé ó ṣeé ṣe láti sọ àwọn eré àṣedárayá náà di bárakú.” Àwọn èwe náà sọ pé àwọn eré àṣedárayá ní ibi ìṣeré gbogbogbòò máa ń kún fún ìpalára gan-an nítorí pé “wọ́n ń fún àwọn òṣèré níṣìírí láti ná owó púpọ̀ sí i.”

Àwọn eré àṣedárayá yìí ha lè di bárakú ní tòótọ́ bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti àwọn òṣèré kan. Èwe kan wí fún Jí! pé: “Gbogbo ohun tí o lè ronú nípa rẹ̀ ni ṣíṣe eré náà parí, kí o sì borí.” Bákan náà, ọ̀dọ́kùnrin kan rántí pé: “Mo máa ń lo ọ̀pọ wákàtí ní gbígbìyànjú láti mọ bí n óò ṣe pa gbogbo àwọn tó wà nínú eré náà, kí n sì kọjá sí ìpele tí ó tẹ̀ lé e nínú eré àṣedárayá náà.”

O lè ronú pé o kò lè kira bọ eré àṣedárayá tó báyẹn. Ṣùgbọ́n ronú ná nípa ọ̀nà tí tẹlifíṣọ̀n àti sinimá ń gba darí èrò ìmọ̀lára àwọn ènìyàn—tí ó ń sún wọn sọkún, bínú, tàbí yọ ayọ̀ amóríyá. Nígbà náà, finú wòye ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀m̀pútà kan tí kì í ṣe pé ó ní ọgbọ́n ìwéwèé ìmóríyá, àwọn ẹ̀dá ṣíṣàrà ọ̀tọ̀, àti àwòrán òun ìró ohùn tí ń ru ìfẹ́ sókè nìkan ni, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ kí o jẹ́ akọni alágbára. Yóò ha rọrùn láti dènà kíkira bọ̀ ọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ bí? Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn òṣèré kan ń ní ìṣòro fífi ìyàtọ̀ sáàárín ìfọkànyàwòrán àti ohun tí ó jẹ́ òtítọ́. Èwe kan rántí pé: “Ipa ṣíṣe eré àṣedárayá oníwà ipá burú gan-an débi pé mo tilẹ̀ ń finú wòye pé ọwọ́ mi jẹ́ ìbọn, tí mo sì ń nàán sí àwọn ènìyàn.”

Fí Ọgbọ́n Ṣe Yíyàn Rẹ

Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí kò pààlà sí ṣíṣe eré àṣedárayá orí kọ̀m̀pútà tàbí fídíò, ó yẹ kí àwọn èwe ronú lórí ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Oníwàásù 2:14 pé: “Ojú ọlọgbọ́n ń bẹ ní orí rẹ̀.” Ìyẹ́n túmọ̀ sí pé ọlọgbọ́n máa ń ṣọ́ ibi tí ó ń lọ, ó sì ń rí ohun tí ó wà níwájú. Ní gidi, ayé eré ìnàjú orí kọ̀m̀pútà ní ohun púpọ̀ tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọ́run nínú. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 10:5.) Ta ló sì mọ ohun tí àwọn olùṣètò ìṣiṣẹ́ kọ̀m̀pútà yóò gbé jáde tẹ̀ lé e? Nítorí náà, kí èwe èyíkéyìí tóó rà, ṣe eré, tàbí háyà eré àṣedárayá kan, ó yẹ kí ó bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Orí kí ni a gbé e kà? Orúkọ rẹ̀ ha dábàá ìtẹ̀sí ẹgbẹ́ awo bí? Àwòrán ara pááli rẹ̀ ha ṣàgbéyọ ìwà ipá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ bí?’

Lábẹ́ ipò dídára jù lọ, àwọn eré àṣedárayá orí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ lè pèsè àwọn ìgbádùn gbígbámúṣé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ kan. Àmọ́, ó ha bójú mu pé kí wọ́n gba gbogbo àkókò ṣíṣeyebíye rẹ bí? Sam, ọmọ ọdún 14 tí a mẹ́nu kàn níṣàájú, sọ pé: “Dádì wa kò tí ì sọ fún wa ní pàtó rí pé a kò gbọdọ̀ ra àwọn eré àṣedárayá orí fídíò. Ṣùgbọ́n ó ti béèrè rí pé, ‘Kí ló ń fa ọkàn mọ́ra tó bẹ́ẹ̀ nípa títẹ bọ́tìnì kan kí o sì rí i tí ẹnì kan ń sáré tàbí fò kọjá lójú kọ̀m̀pútà?’” Arákùnrin rẹ̀, Dan, fi kún un pé: “Bí a sì ṣe ń ronú nísinsìnyí nìyẹn.”

Bẹ́ẹ̀ ni, má ṣe gbàgbé pé àwọn ọ̀nà mìíràn wà—bóyá tí wọ́n túbọ̀ ń mésò wá—láti gbádùn ara rẹ, irú bíi kíkàwé, ṣíṣe iṣẹ́ ọnà àti iṣẹ́ ọwọ́, kíkópa nínú àwọn eré ìdíje sísunwọ̀n, kíkọrin, tàbí kíkọ́ bí a ṣe ń tẹ ohun èèlò ìkọrin. Ó ṣàǹfààní púpọ̀ púpọ̀ láti lo àkókò láti “máa kọ́ ara rẹ pẹlu ìfọkànsin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ.” (Tìmótì Kíní 4:7) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ní àǹfààní púpọ̀ gan-an ju kíkópa nínú eré àṣedárayá orí ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ kan lọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Ìpín 97 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ògowẹẹrẹ tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìwádìí kan “rò pé ó ṣeé ṣe láti sọ àwọn eré àṣedárayá náà di bárakú”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ǹjẹ́ ṣíṣe eré àṣedárayá oníwà ipá orí fídíò lè pa ọ́ lára ní ti gidi bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́