ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 15-18
  • Ẹlẹgẹ́ Arìnrìn Àjò tí Kì Í Káàárẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹlẹgẹ́ Arìnrìn Àjò tí Kì Í Káàárẹ̀
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àràmàǹdà Ohun Ẹlẹgẹ́ Ìṣẹ̀dá
  • Fífò Lọ́nà Tí Ń Wúni Lórí
  • Ìṣíkiri Lọ́pọ̀ Rẹpẹtẹ
  • Àwọn Ibi Tí Wọ́n Ń Forí Lé
  • Bí Labalábá Monarch Ṣe Ń Ṣí Kiri
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àwọn Igbó Àìro Di Pápá Ìṣekúpa Àwọn Labalábá Monarch
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1999
  • Ìyẹ́ Labalábá Cabbage White
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 15-18

Ẹlẹgẹ́ Arìnrìn Àjò tí Kì Í Káàárẹ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ

Àwọn ayàwòrán ń yà wọn, àwọn akéwì sì ń kọ nípa wọn. Àìmọye wọn lónírúurú ń gbé inú igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru. Ọ̀pọ̀ ń gbé inú igbó, inú pápá, àti inú àwọn pápá ewéko. Àwọn kan ń fara da òtútù orí àwọn òkè ńlá; àwọn mìíràn ń fara da ooru àwọn aṣálẹ̀. A ti ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn arẹwà jù lọ láwùjọ kòkòrò.

LÁÌṢIYÈ méjì, o mọ ẹ̀dá wíwuni, tí ó sì fani mọ́ra yìí—labalábá—dunjú. Bí ó ti wù kí ó rí, oríṣi labalábá kan ti lókìkí kárí ayé, nítorí agbára rẹ̀ kíkàmàmà láti rìnrìn àjò. Ẹlẹgẹ́ arìnrìn àjò tí kì í káàárẹ̀ yìí ní ń jẹ́ monarch (ọba). Ẹ jẹ́ kí á wo àràmàǹdà ìṣẹ̀dá yìí àti ìṣíkiri rẹ̀ tí ó ṣòroó gbà gbọ́ láwòfín.

Àràmàǹdà Ohun Ẹlẹgẹ́ Ìṣẹ̀dá

Finú wòye ara rẹ ní ilẹ̀ eléwéko tútù kan, ní ọjọ́ kan tí oòrùn mú, tí ooru sì mú. Tẹjú rẹ mọ́ àwọn ohun àràmàǹdà abìyẹ́ tí ń fò kiri láàárín àwọn òdòdó ìgbẹ́, bí wọ́n ṣe ń wá oúnjẹ àti ohun mímu kiri ṣáá. Dúró láìmira, kí o sì na apá rẹ jáde. Ọ̀kan ń sún mọ́ ọ bọ̀. Óò, ó fẹ́ẹ́ bà lé ọ lápá! Kíyè sí bí ó ṣe balẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó.

Fara balẹ̀ wò ó fín nísinsìnyí. Ṣàkíyèsí àwọn ìyẹ́ rẹ̀ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, tí ó ní lẹ́búlẹ́bú lára, tí ó sì ní àwọ̀ omi ọsàn, pẹ̀lú àwọ̀ dúdú, tí ààlà wọn kò yanjú. A ti sọ pé àwọn abulẹ̀dó ará England tí ń gbé America, tí wọ́n rí ìjọra láàárín òun àti ọba wọn, William ti Orange, ni wọ́n sọ ọ́ ní monarch. Ká sọ tòótọ́, “ọba” ni labalábá yìí. Ṣùgbọ́n ẹlẹgẹ́ arẹwà yìí, tí ó wọn kìkì 0.5 gíráàmù, tí ìyẹ́ rẹ̀ sì gbòòrò tó sẹ̀ǹtímítà 8 sí 10 lágbára láti rin ìrìn àjò gígùn, tí ń tánni lókun.

Fífò Lọ́nà Tí Ń Wúni Lórí

Nígbà tí a ti sọ pé àwọn labalábá kan ń ṣí kiri lọ sí ọ̀nà jíjìn nígbà tí ìgbà òtútù bá bẹ̀rẹ̀, monarch nìkan ní ń rin irú ìrìn àjò jíjìn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ibì kan pàtó lọ́kàn, àti ní ògìdìgbó bẹ́ẹ̀. Ìṣíkiri monarch jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ agbàfiyèsí kan nípa labalábá. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun wíwọni lọ́kàn díẹ̀ tí àwọn arìnrìn àjò tí kì í káàárẹ̀ wọ̀nyí ń gbé ṣe.

Ìfòkiri wọn láti Kánádà nígbà ìwọ́wé sí ibi tí wọ́n ti ń lo ìgbà òtútù ní California tàbí Mexico lé ní 3,200 kìlómítà. Wọ́n ń kọjá àwọn adágún omi, odò, pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti òkè ńláńlá. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn máa ń kẹ́sẹ járí láti parí ìṣíkiri wọn sí ibi gíga kan lórí òkè ńlá Sierra Madre ní àárín gbùngbùn Mexico.

Irú ìfòkiri bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ń ṣeni ní kàyéfì nígbà tí a bá tàrò ti pé àwọn labalábá kéékèèké náà kò fo ìfò yìí rí, tí wọn kò sì rí àwọn ibi ìsinmi ìgba òtútù náà rí. Ṣùgbọ́n láìṣìnà, wọ́n ń mọ ìhà ibi tí wọ́n ní láti fò lọ, wọ́n sì ń mọ̀ bí wọ́n bá ti dé ilé wọn ìgbà òtútù. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?

Ìwé ìròyìn Canadian Geographic sọ pé: “Ní kedere, ìṣètò apilẹ̀ àbùdá dídíjú kan ń bẹ nínú ọpọlọ wọn kóńkóló, bóyá ọ̀nà kan tí wọ́n ń gbà ṣàkíyèsí igun ìtànṣán oòrùn, bí àwọn oyin ṣe ń ṣe, tàbí ọ̀nà kan tí wọ́n fi ń kíyè sí agbègbè mágínẹ́ẹ̀tì ilẹ̀ ayé, tí ó jọ pé ó ń ṣamọ̀nà àwọn ẹyẹ. Agbára kan láti mọ ìdíwọ̀n ìgbóná òun ìtutù àti ipò ọ̀rinrin lè ṣèrànwọ́ nígbà tí ìrìn àjò náà bá ń parí lọ. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tí ì rí ìdáhùn náà.” Bíi ti àwọn ẹ̀dá tí Bíbélì mẹ́nu bà nínú ìwé Òwe, “wọ́n gbọ́n.”—Òwe 30:24.

Àwọn monarch tún jẹ́ ògbógi níbi ká fò. Wọ́n máa ń fò láìlu apá ní nǹkan bíi kìlómítà 12 ní wákàtí kan, wọ́n ń fò lọ sókè láìlo ìyẹ́ ní nǹkan bíi kìlómítà 18 ní wákàtí kan, àti—bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbìyànjú láti mú wọn rí ṣe mọ̀—wọ́n túbọ̀ ń yára láti mẹ̀yẹ̀, ní nǹkan bíi kìlómítà 35 ní wákàtí kan. Wọ́n já fáfá jù lọ ní lílo ẹ̀fúùfù—àní wọ́n tilẹ̀ ń fò dojú kọ ẹ̀fúùfù tí ń fẹ́ sí ìhà ìlà oòrùn, lọ́nà tí kò fi níí gbé wọn, nígbà tí wọ́n bá forí lé ìhà ìwọ̀ oòrùn gúúsù, síhà ibi tí wọ́n ń lọ. Ní lílo àwọn ọgbọ́n dídíjú láti fò, wọ́n ń kojú àwọn ìyàtọ̀ nínú ìyára ẹ̀fúùfù àti ibi tí ẹ̀fúùfù bá dorí kọ. Ni irú ọ̀nà kan náà pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ òfuurufú abẹ́fùúùfù ṣiṣẹ́ láìlo ẹ̀rọ àti àwọn àwòdì, wọ́n máa ń fi ìmóoru (afẹ́fẹ́ gbígbóná tí ń lọ sókè) fò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìtọ́kasí kan ṣe sọ, àwọn monarch sábà máa ń rin ìrìn àjò 200 kìlómítà lóòjọ́. Ọ̀sán nìkan ni wọ́n fi ń fò. Wọ́n ń sinmi lálẹ́, ó sì sábà máa ń jẹ́ níbì kan náà lọ́dọọdún.

Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì David Gibo ti Yunifásítì Toronto ti mọ̀ pé monarch kì í fò lọ sókè láìlo ìyẹ́ tàbí fò láìlu apá nìkan. Ó sọ pé: “Àwọn labalábá náà ní láti lo ẹ̀fúùfù ní àwọn ọ̀nà tí mo rò pé ó gba òye iṣẹ́ gidigidi ju ti àwọn pẹ́pẹ́yẹ ńlá tí ń ṣí kiri lọ.” Ọ̀nà ìgbàṣe ti lílu ìyẹ́, lílọ sókè láìlo ìyẹ́, àti jíjẹun, mú kí àwọn monarch lè máa dé Mexico pẹ̀lú ìwọ̀n ọ̀rá tí wọ́n nílò fún gbogbo ìgbà òtútù àti ìbẹ̀rẹ̀ ìfòpadà wọn sí àríwá nígbà ìrúwé. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gibo tún sọ pẹ̀lú pé: “Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà rin ìrìn àjò gígùn náà, kí wọ́n má sì ṣàárẹ̀, kí ara wọn sì le ni nípa fífò láìlu apá.”

Ìṣíkiri Lọ́pọ̀ Rẹpẹtẹ

Ó pẹ́ tí a ti mọ̀ pé àwọn monarch tí ó wà níhà ìwọ̀ oòrùn àwọn Òkè Ńlá Alápàáta ń ṣí lọ sí ìhà Gúúsù, wọ́n sì ń lo ìgbà òtútù ní California. A lè rí wọn bí wọ́n ṣe ń ṣùùrù mọ́ àwọn igi ahóyaya àti eucalyptus ní àwọn àdúgbò ìhà etíkun gúúsù California. Ṣùgbọ́n, fún àkókò kan, ibi tí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn monarch ìhà ìlà oòrùn Kánádà ń ṣí lọ kò yéni.

Ní 1976, a rídìí àdììtú yìí. A ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń lo ìgbà òtútù wọn níkẹyìn—orí òkè gíga fíofío kan tí igbó kún bò ní àwọn òkè ńlá Sierra Madre ní Mexico. A bá àìmọye àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn labalábá tí wọ́n há ara wọn mọ́ orí àwọn ẹ̀ka àti igi ahóyaya gíga fíofío, tí wọ́n ní àdàlú àwọ̀ ewé òun eérú. Ìrísí wíwúni lórí yìí ń bá a lọ láti máa fa àwọn olùṣèbẹ̀wò lọ́kàn mọ́ra.

Ọ̀kan lára àwọn ibi tí ó dára jù lọ láti rí àwọn monarch lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ ní Kánádà ni Ọgbà Ìtura Orílẹ̀-Èdè ti Point Pelee, Ontario, níbi tí wọ́n ń kóra jọ sí ní ìmúra sílẹ̀ fún ìṣíkiri wọn lọ sí ìhà gúúsù. Tí ìgbà òtútù bá ń parí lọ, wọ́n máa ń kóra jọ sí ìhà gúúsù yìí ní Kánádà, wọ́n ń dúró sí etíkun ìhà àríwá Adágún Erie, títí di ìgbà tí ẹ̀fúùfù àti ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù yóò fi bára dé, kí wọ́n tóó gbéra ìrìn àjò wọn lọ sí ìhà gúúsù, sí ibi tí wọ́n ti ń lo ìgbà òtútù wọn ní Mexico.

Àwọn Ibi Tí Wọ́n Ń Forí Lé

Bẹ̀rẹ̀ láti Point Pelee, wọ́n ń ti erékùṣù dé erékùṣù la Adágún Erie kọjá láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò gígùn náà la kọ́ńtínẹ́ǹtì United States já. Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àwùjọ monarch mìíràn ń dara pọ̀ mọ́ wọn lọ́nà nínú ìṣíkiri náà. A fojú díwọ̀n pé nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ọ̀kẹ́ wọn ní ń kóra jọ pọ̀ láti lo ìgbà òtútù lórí àwọn òkè ńlá ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Ìlú Ńlá Mexico.

Àwọn ìṣíkiri mìíràn ń ṣẹlẹ̀ la Florida já, àti jákèjádò òkun Caribbean, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn wọ̀nyí máa parí sí ibì kan tí a kò tí ì mọ̀ ní ilẹ̀ Yucatán tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí ká tàbí ní Guatemala. Yálà ní Mexico, tàbí ní àwọn ibòmíràn tí wọ́n ti ń lo ìgbà òtútù wọn, àwọn monarch ń kóra jọ lógìdìgbó ní àwọn ibi igbó orí òkè ńlá kéékèèké mélòó kan.

Ẹnì kan lè rò pé fífò tí wọ́n fò jìnnà lọ sí ibi tí wọ́n ti ń lo ìgbà òtútù yóò mú wọn dé ilẹ̀ ìsinmi olóoru, ilẹ̀ eléwéko tútù tí oòrùn ti ń mú. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ kọ́. Ibi tí wọ́n ń lọ, ní Àwọn Ìsokọ́ra Òkè Ayọnáyèéfín ti Mexico, tutù nini. Bí ó ti wù kí ó rí, ojú ọjọ́ tí ó wà ní àwọn ṣóńṣó orí òkè ńlá wọ̀nyẹn bá a mu gẹ́lẹ́ fún wọn láti lo ìgbà òtútù. Ó tutù tó láti mú kí wọ́n lo gbogbo àkókò wọn láìṣe nǹkan kan—kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sún ọjọ́ ayé wọn sí oṣù mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá, tí yóò mú kí wọ́n lè fò lọ sí Mexico, kí wọ́n lo ìgbà òtútù níbẹ̀, kí wọ́n sì padà kúrò níbẹ̀. O kúkú lè pe ìyẹn ní àkókò ìsinmi kan.

Ìgbà ìrúwé dé, àwọn monarch sì tún bẹ̀rẹ̀ àwọn ìgbòkègbodò wọn lẹ́ẹ̀kan sí i. Bí ọjọ́ ṣe ń gùn sí i, àwọn labalábá náà ń yára ju ìyẹ́ fò nínú ìmọ́lẹ̀ oòrùn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gùn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fò padà sí àríwá. Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé, ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára wọn parí ìrìn àjò náà, ṣùgbọ́n ó sábà máa ń jẹ́ kìkì àwọn ọmọ wọn ní ń dé ibi àwọn òkè tí wọ́n ti ń lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ní Kánádà àti ní ìhà àríwá United States. Ìran mẹ́ta tàbí mẹ́rin tí ó la àwọn ìpele ẹyin, ìdin labalábá, káwọ́bojú àti labalábá kọjá ní ń ṣe pẹ̀lẹ́ pada sí kọ́ńtínẹ́ǹtì náà. Abo—tí ó kó ẹyìn tí ó ti gbàlejò bí ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sínú—ń yára ju ìyẹ́ fò láàárín àwọn òdòdó ìgbẹ́, ó sì ń yé ẹyin rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan nígbà kọ̀ọ̀kan sí ẹ̀yìn ọ̀mùnú ewé àwọn igi olóje tí kò ì gbó. Bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ń yí lọ, ìrìn àjò náà sì ń bá a lọ sí ibùgbé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn monarch.

Ní tòótọ́, ẹ̀dá fífani lọ́kàn mọ́ra ni monarch. Ẹ wo irú àǹfààní tí ẹ̀dá ènìyàn ní láti ṣàkíyèsí àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn. Ko yani lẹ́nu ṣáá pé àwọn ìgbòkègbodò ọrọ̀ ajé ẹ̀dá ènìyàn ti ń fewu wu àwọn ibi ìlògbà òtútù monarch ní Mexico, àti ní California, tí ó ti jẹ́ àṣírí fún ìgbà pípẹ́. Láti wulẹ̀ rò pé àwọn ẹwà ìṣẹ̀dá tí ó wu ojúú rí wọ̀nyí ní ibòmíràn tí wọ́n lè lọ, lè yọrí sí àkúrun wọn. Lọ́nà tó gboríyìn, a ti ń gbìyànjú láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ẹ wo bí yóò ti kọyọyọ tó nígbà tí àwọn ẹlẹgẹ́ arìnrìn àjò tí kì í káàárẹ̀ wọ̀nyí bá ní ibùgbé aláàbò nínú Párádísè tí Ẹlẹ́dàá ṣèlérí, tí ó sì sún mọ́lé nísinsìnyí!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

Labalábá: Parks Canada/J. N. Flynn

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]

Ojú ìwé 16 lókè àti nísàlẹ̀: Parks Canada/J. N. Flynn; láàárín: Parks Canada/D. A. Wilkes; ojú ìwé 17 lókè: Parks Canada/J. N. Flynn; láàárín àti nísàlẹ̀: Parks Canada/J. R. Graham

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́