Àádọ́jọ Ọdún Àwọn Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ HUNGARY
ÀWỌN agbẹ́nà abẹ́lẹ̀ náà kọ háà nígbà tí wọ́n rí ohun tí wọ́n gbẹ́lẹ̀ kàn. Ní ọdún 1912 ni. Nísàlẹ̀ lọ́hùn-ún lábẹ́ àwọn títì Ìlú Ńlá New York, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìmúgbòòrò ọ̀nà ọkọ̀ abẹ́lẹ̀ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, wọ́n já sínú iyàrá ńlá kan tí ó fara sin. Wọ́n ṣe iyàrá náà lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà kíkàmàmà—bí ààfin! Àwọn dígí, ọ̀pá fìtílà alásorọ̀ tí a ń fi ṣe ọ̀ṣọ́, àti àwọn àwòrán àlẹ̀mógiri wà lára rẹ̀ jálẹ̀jálẹ̀. Àwọn ògbólógbòó igi tí pípẹ́ tí wọ́n pẹ́ ti ń wó wọn lulẹ̀, ṣì ń ṣe ògiri náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ní àárín iyàrá náà ni orísun omi àfiṣọ̀ṣọ́ kan wà, kò tú omi jáde mọ́ láti ọjọ́ gbọọrọ.
Iyàrá náà lu já ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kan. Sí ìyàlẹ́nu àwọn òṣìṣẹ́ náà, ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ elérò 22 kan, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ gẹnrẹnmẹjẹn wà lórí ọ̀nà onírin rẹ̀. Ṣé ọ̀nà abẹ́lẹ̀ míràn ti wà lábẹ́ New York ṣáájú èyí tí wọ́n ń gbẹ́ ni? Ta ni ó lè ti kọ́ ibí yìí?
Àwọn Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ àti Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀
A ti ń lo àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ fún ìwakùsà, ìpèsè omi, àti ìlò àwọn ológun fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, kò ì pẹ́ tí a bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọkọ̀ ẹlẹ́rọ kó èrò gba abẹ́lẹ̀. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1800, àwọn òpópó ọ̀nà ìlú London, England, kún fọ́fọ́ fún onírúurú ọkọ̀ ìrìnnà ìgbàlódé tí ó ṣeé ronú kàn, ní àfikún sí àwọn ènìyàn tí ń rinsẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń sọdá Odò Thames lójoojúmọ́, yálà nípa wíwọ ọkọ̀ ojú omi, tàbí nípa gbígba orí Afárá London. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìrìn náà kì í yá débi tí àwọn oníṣòwò kò fi ń rí ohun ṣe sí àwọn ọjà tí wọ́n ń fẹ́ lọ tà lọ́jà bí oòrùn ṣe ń pa wọ́n, tí wọ́n ń rọ.
Marc Isambard Brunel, onímọ̀ ẹ̀rọ ará Faransé kan, tí ń gbé England, ronú ohun kan tí yóò mú kí díẹ̀ lára àwọn ìṣòro ètò ìrìnlọrìnbọ̀ ní London dẹ́rọ́ níkẹyìn. Nígbà kan rí, Brunel ti ṣàkíyèsí kòkòrò mùkúlú kan tí ń jìjàdù nínú ègé igi apá kan. Ó ṣàkíyèsí pé kìkì orí ẹran oníkarawun kékeré náà ni ìkarawun bò. Kòkòrò mùkúlú náà ń fi eteetí ìkarawun rẹ̀ tí ó mú gbẹ́ ọ̀nà la igi náà já. Bí ó ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó ń fi ẹfun tí ń dán bo ihò rẹ̀. Ní lílo ìlànà yí, Brunel ṣàgbékalẹ̀ irin ìgbẹ́hò ńlá kan, tó dà bí apata, tí a óò máa fi jáàkì tì síwájú nínú ilẹ̀. Bí àwọn òṣìṣẹ́ bá ṣe ń kó ilẹ̀ kúrò nínú irin ìgbẹ́hò náà ni irin ìgbẹ́hò ọ̀hún yóò máa dènà ìwólulẹ̀. Bí apata náà bá ṣe ń gbẹ́ ilẹ̀ náà lọ níwájú ni àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn yóò máa to bíríkì sí ojú ilẹ̀ ihò abẹ́lẹ̀ tuntun náà láti fi gbé e ró.
Nípa lílo irin ìgbẹ́hò yìí, Brunel ṣàṣeyọrí iṣẹ́ ọ̀nà abẹ́ omi àkọ́kọ́ lágbàáyé la ilẹ̀ rírọ̀ kọjá, lábẹ́ Odò Thames, ní 1843. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé ó ṣeé ṣe láti la àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀, ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún gbígbẹ́ àwọn ọ̀nà ọkọ̀ abẹ́lẹ̀ òde òní. Ní 1863, ìgbékalẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kíní ṣí sílẹ̀ láàárín àwọn ibùdó òpin ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin pàtàkì méjì ní London, nígbà tí ó sì di 1865, wọ́n ra ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ti Brunel, kí wọ́n lè mú ìgbékalẹ̀ náà gbòòrò sí i. Ọ̀nà abẹ́lẹ̀ yẹn ṣì jẹ́ apá kan Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ti London.
Ìbẹ̀rù—Àfinúrò àti Ojúlówó
Kò sí ìgbà kankan tí ètò ìrìnnà abẹ́lẹ̀ kò ní alátakò. Ní àwọn ọdún 1800, ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rù lílọ sí abẹ́lẹ̀ nítorí pé wọ́n gbà gbọ́ pé hẹ́ẹ̀lì oníná kan wà níbì kan ní abẹ́lẹ̀. Láfikún sí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn ka àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ṣíṣókùnkùn, tí ó lọ́rinrin, sí afẹ́fẹ́ onímájèlé, tí ó ń fa àrùn.
Nídà kejì, àwọn elétò ìlú ti di onítara nínú ìfẹ́ ọkàn wọn láti ṣe nǹkan kan sí àwọn ọ̀nà àárín ìlú tí ń lọ́jú pọ̀. Àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ di kókó ìjiyàn pàtàkì ti ìṣèlú. Ìdí wà láti dàníyàn nípa bí afẹ́fẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ṣe dára sí. Wọ́n dán oríṣiríṣi ọ̀nà ìfẹ́lọfẹ́bọ̀ afẹ́fẹ́ wò, gbogbo rẹ̀ kọ́ ló kẹ́sẹ járí. Àwọn kan lo àǹfààní afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ lọ fẹ́ bọ̀ bí àwọn ọkọ̀ ojú irin náà ṣe ń lọ; àwọn mìíràn ní ihò tí wọ́n gbẹ́ sóòró gangan, tí ó sì ní ìdérí tí ó bá ìtẹ́jú títì dọ́gba, pẹ̀lú àwọn àlàfo láàárín ihò kan sí òmíràn, àwọn abẹ̀bẹ̀ lílágbára, tàbí àwọn ìgbékalẹ̀ tí ń ṣe àkànpọ̀ àwọn ọ̀nà ìgbékalẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Láti kojú àwọn ìdènà ti ìrònú òun ìhùwà láti wọnú àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ṣíṣókùnkùn, wọ́n gbé àwọn iná onígáàsì sí àwọn ibùdó abẹ́lẹ̀. Irú àyíká ipò bẹ́ẹ̀ ló gbòde nígbà tí wọ́n kọ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ New York, tí a ti gbàgbé, tí àwọn òṣìṣẹ́ tún kọsẹ̀ bá náà, ní 1912.
Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Kíní ní New York
Ní ìhà kejì Àtìláńtíìkì lọ́hùn-ún, láti London, ìdààmú bá oníhùmọ̀ míràn kan, tí ó ní ẹ̀bùn àbínibí, Alfred Ely Beach, lórí ipò àìrọgbọ tí ètò ìrìnnà wà ní New York. Gẹ́gẹ́ bí olùtẹ̀jáde ìwé Scientific American, Beach jẹ́ agbátẹrù àwọn ojútùú ìgbàlódé sí àwọn ìṣòro àtọdúnmọ́dún, bíi ti títì tí ọkọ̀ ń dí. Ní 1849, ó pèsè ìwéwèé aláṣerégèé kan pé: “Ẹ gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ sí Broadway,” ọ̀kan lára àwọn títì tí ọkọ̀ ń dí jù, “kí ẹ sì ṣe ibi àbájáde àti àkàsọ̀ sí gbogbo orígun rẹ̀. Ọ̀nà abẹ́lẹ̀ yí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀nà ojú irin méjì, kí ó sì ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì.”
Láàárín àwọn ẹ̀wádún méjì tó tẹ̀ lé e, àwọn aṣàgbékalẹ̀ ètò ìrìnlọrìnbọ̀ míràn pẹ̀lú gbé ìwéwèé ìyáralọkiri kalẹ̀ fún New York. Wọ́n kò fara mọ́ ọ̀kankan wọn níkẹyìn. Alágbára òṣèlú oníwà ìbàjẹ́ náà, Boss Tweed, kò fẹ́ ìbánidíje kankan fún àwọn ilé iṣẹ́ òwò ọkọ̀ orí ilẹ̀, láti ibi tí ó ti ń rí púpọ̀ lára àwọn owó àìbófinmu tí ń wọlé fún un. Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni Beach, tó mọ bí a ti ń kojú ipò, tí kò sì tí ì jáwọ́ lára èròǹgbà rẹ̀, fọgbọ́n pa Boss, arinkinkin náà, láyò.
Beach gba ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti gbẹ́ ihò abẹ́lẹ̀ méjì, tí wọ́n kéré jù fún kíkó èrò, sábẹ́ títì Broadway nífẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Ìwọ̀nyí wà “fún kíkó lẹ́tà, àwọn páálí àti àwọn ẹrù ìṣòwò” lọ sí ilé ìfìwéránṣẹ́ ńlá. Lẹ́yìn náà, ó béèrè fún àtúnṣe kan tí yóò gbà á láyè láti wulẹ̀ kọ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ńlá kan ṣoṣo tí ó sọ pé yóò dín ìnáwó kù. Lọ́nà kan ṣáá, kò sí ẹni tó fura sí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń lò, wọ́n sì fọwọ́ sí àtúnṣe náà. Beach bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́gán, ṣùgbọ́n láìjẹ́ kí wọ́n fiyè sí i. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́lẹ̀ láti abẹ́ ilé ìtaṣọ kan, ó sì ń fi àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tí wọ́n ti wá nǹkan ṣe sí àgbá kẹ̀kẹ́ wọn, kí wọ́n má baà pariwo, kó ìdọ̀tí náà dà nù lóròòru. Ó parí ọ̀nà tí ó gùn ní mítà 95 náà láàárín òru 58.
“Okùn Afẹ́fẹ́” Kan
Beach mọ̀ nípa ìbafẹ́fẹ́jẹ́ tí ń háni lọ́fun, tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ti London, nítorí àwọn ẹ̀rọ tí a ń fi èédúulẹ̀ mú ṣiṣẹ́. Ó ń fi “okùn afẹ́fẹ́” kan—ipá tí ń wá láti inú abẹ̀bẹ̀ ńlá kan tí ó fi sínú ihò ara ògiri ní ìkángun kan ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà—mú ọkọ̀ tirẹ̀ ṣiṣẹ́. Afẹ́fẹ́ náà rọra ń ti ọkọ̀ náà lọ ní ìwọ̀n ìyára kìlómítà mẹ́wàá ní wákàtí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lè máa yára lọ ní ìlọ́po mẹ́wàá ìwọ̀n yẹn. Nígbà tí ọkọ̀ náà bá dé ìkángun kejì ọ̀nà náà, wọn yóò yí abẹ̀bẹ̀ náà sódì, yóò sì fa ọkọ̀ náà pa dà sẹ́yìn! Láti ṣẹ́pá bí àwọn ènìyàn ṣe ń lọ́ra láti wọ abẹ́lẹ̀ síbẹ̀, Beach rí i dájú pé wọ́n fi àwọn àtùpà zircon rẹpẹtẹ, lára àwọn tí ó mọ́lẹ̀ kedere jù lọ nígbà náà, tanná sí iyàrá ìgbàlejò ńlá náà. Ó sì fi àwọn àga olówó ńlá, àwọn ère, àwọn àtọwọ́dá fèrèsé tí a fi aṣọ ìkélé bò, àti dùùrù ńlá òun agbada ẹja goldfish kan pàápàá ṣe iyàrá náà lọ́ṣọ̀ọ́! Wọ́n ṣí ọ̀nà náà fún ìlò àwọn ará ìlú tí kò fura ní February, 1870, ó sì ṣàṣeyọrí lọ́nà àgbàyanu, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Lọ́dún kan ṣoṣo, 400,000 ènìyàn ló ṣèbẹ̀wò sí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà.
Inú bí Boss Tweed gidigidi! Ìdọ́gbọ́nsí lọ́nà ìṣèlú ṣẹlẹ̀, Tweed sì rọ gómìnà láti fọwọ́ sí ìwéwèé ìlòdìsí kan tí ń ṣàgbéga ọkọ̀ ojú irin kan tí yóò náni ní ìlọ́po 16 iye tí ìgbékalẹ̀ abẹ́lẹ̀ tí afẹ́fẹ́ ń sún ṣiṣẹ́, tí Beach dábàá, yóò náni. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, wọ́n fẹ̀sùn kan Tweed, tí ó yọrí sí fífi í sẹ́wọ̀n gbére. Ṣùgbọ́n jìnnìjìnnì nítorí ọjà ìṣúra okòwò ní 1873 darí àfiyèsí àwọn olùdókòwò àti àwọn aláṣẹ kúrò lórí ọ̀ràn ọ̀nà abẹ́lẹ̀, Beach sì ti ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà pa níkẹyìn. Nítorí náà, kò sí ẹni tí ó rántí nípa rẹ̀ mọ́ títí tí wọ́n fi ṣèèṣì wúlẹ̀ kàn án ní 1912, ní èyí tí ó lé ní ọdún méje lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ ti New York ní 1904. Apá kan lára ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti Beach wá di apá kan Ibùdókọ̀ City Hall òde òní, ní agbègbè ìṣòwò ìlú Manhattan.
Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún
Ní èyí tí ó lé díẹ̀ ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, ìfojúsọ́nà kan wáyé ní Hungary. Hungary yóò ṣayẹyẹ ẹgbẹ̀rúndún ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní 1896. Nígbà tí yóò bá fi di òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Budapest, yóò ti wà lára àwọn ìlú ńlá títóbi jù lọ ní Europe. Àwọn títì rẹ̀ ti dí jù ná. Wọ́n dábàá ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin orílẹ̀ tí ń báná ṣiṣẹ́ kan láti dín ìṣòro náà kù nígbà ayẹyẹ ẹgbẹ̀rúndún náà. Ṣùgbọ́n èrò yẹn kọ́ ni ohun tí àwọn aláṣẹ ìlú ń wá, wọ́n kò sì fara mọ́ àbá náà. Láàárín àkókò náà, Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ti London ti fa agbára ìwòye àwọn elétò ìrìnlọrìnbọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn mọ́ra. Ọ̀kan lára irú àwọn ògbógi bẹ́ẹ̀ ní Hungary, Ọ̀gbẹ́ni Mór Balázs, dábàá ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ń lo iná mànàmáná. Wọ́n fọwọ́ sí èyí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀ ní August 1894.
Wọ́n lo ọgbọ́n àgbẹ́bò láti ṣe ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà—wọ́n gbẹ́ ojú ọ̀nà kan tó ti wà tẹ́lẹ̀, wọ́n to ọ̀nà ojú irin sí abẹ́lẹ̀. Wọ́n kọ́ òrùlé títẹ́jú pẹrẹsẹ kan sórí ihò tí wọ́n gbẹ́ náà, wọ́n sì dá ojú ọ̀nà náà pa dà sípò. Wọ́n ṣe àfilọ́lẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ó gùn ní kìlómítà 3.7 náà ní May 2, 1896. Wíwọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkọ̀ rẹ̀ tí iná mànàmáná ń sún ṣiṣẹ́ jẹ́ ìmúsunwọ̀n ńláǹlà kan, bí a bá fi wé ìrírí èéfín onísúfúrù tí àwọn tí wọ́n wọ Ọkọ̀ Abẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ ti London fara dà! Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, Ọba Francis Joseph Kíní bẹ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà wò, ó sì fọwọ́ sí i pé kí a sọ ọ́ lórúkọ òun. Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín àkókò onípákáǹleke ti ìṣèlú tí ó tẹ̀ lé e, wọ́n tún ọ̀nà náà sọ ní Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún. Òun ni ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kíní ní àgbáálá ilẹ̀ Europe. Láìpẹ́, àwọn mìíràn tẹ̀ lé e. Ní 1900, Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ ti Paris bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, Berlin sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ní 1902.
Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ Lẹ́yìn 100 Ọdún
Fún ayẹyẹ ẹgbẹ̀rúndún lé ọgọ́rùn-ún ti Hungary, ní 1996, wọ́n ṣàtúnṣe ọ̀nà ojú irin abẹ́lẹ̀ náà, tí ó tún fi ní ẹwà àti ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́. Àwọn ègé amọ̀ funfun pẹlẹbẹ kéékèèké, tí eteetí wọn tí a ṣọnà sí pọ́n bíi wáìnì, ni a fi ṣe àwọn ògiri ibùdókọ̀ náà lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn orúkọ ibùdókọ̀ hàn yàtọ̀—a fi àwọn ègé amọ̀ pẹlẹbẹ kọ wọ́n sára ògiri. Wọ́n tún àwọn òpó onírin náà gbé ró, wọ́n sì kùn wọ́n láwọ̀ ewé, kí wọ́n lè fi ipò ọ̀rúndún tó kọjá náà hàn. Ibùdókọ̀ àárín gbùngbùn ti Budapest ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti ọ̀nà ojú irin kan, níbi tí o ti lè rí ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́—ó ti lé ní 100 ọdún! A pàtẹ àwọn àfihàn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú bí a ṣe ṣe Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún àti Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ ti Budapest tí ó túbọ̀ bágbà mu síbẹ̀ pẹ̀lú.
Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Hungary bá ń ṣèbẹ̀wò síbi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí náà, wọ́n máa ń rántí dáradára pé láìpẹ́ sẹ́yìn, ọ̀nà ojú irin abẹ́lẹ̀ náà ní ìwúlò yíyàtọ̀ kan fún àwọn Kristẹni tí ń gbé ìhín yìí. Ní gbogbo àkókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìsìn wọn ní Hungary, Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fọgbọ́n inú lo àwọn ibùdókọ̀ ọ̀nà ojú irin lílókìkí yìí láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Láti 1989 wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ń gbádùn òmìnira láti wàásù ní Hungary. Ṣùgbọ́n, o ṣì lè rí wọn ní Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún náà, bí wọ́n ti ń ṣàjọpín ìgbàgbọ́ wọn pé, Ẹgbẹ̀rúndún tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì—ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rúndún ti Kristi—yóò dé láìpẹ́.
Ogún tí Àwọn Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ Fi Sílẹ̀
Lónìí, àwọn èrò ń gba àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ láti ibì kan dé òmíràn ní àwọn ìlú ńláńlá pàtàkì kárí ayé. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ìṣòro àtijọ́, ti ariwo àti ìbafẹ́fẹ́jẹ́, ni kíkọ ìkọkíkọ sára ògiri àti ìwà ọ̀daràn ti mú peléke sí i. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbékalẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ní ń fi àwọn èròǹgbà ẹlẹ́wà. tí ó lógo, tí ó sì gbéṣẹ́, ti àwọn olùṣàgbékalẹ̀ àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ hàn. Ó pète ọ̀nà abẹ́lẹ̀ kúkúrú náà láti ṣàṣefihàn kíkẹ́sẹjárí kan tí yóò mú àtakò èyíkéyìí láti mú kí ó gùn sí i kúrò. Ìfẹ́ ọkàn láti mú kí ètò ìtibìkan-débòmíràn ọlọ́pọ̀ èrò sunwọ̀n sí i, kí ó sì gbòòrò sí i ṣì lágbára gan-an. A ṣẹ̀ṣẹ̀ ń parí àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí pé a ń kọ́ wọn lọ́wọ́ ní àwọn ìlú ńlá kan bíi Bangkok, Medellín, Seoul, Shanghai, Taipei, àti Warsaw. Gbogbo ìwọ̀nyí ha lè ya àwọn olùṣàgbékalẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́nu bí? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀—irú ìlò tí ó gbòòrò bẹ́ẹ̀ ni ohun tí wọ́n rí tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ní ọ̀rúndún kan àti ààbọ̀ sẹ́yìn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
1. Ọ̀kan lára àwọn ibùdókọ̀ Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún ní Budapest, tí a tún ṣe—1996
2-4. Ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ ti 1896, tí ń lo iná mànàmáná, ní Ọ̀nà Ojú Irin Abẹ́lẹ̀ fún Ayẹyẹ Ẹgbẹ̀rúndún