ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Póòpù Tún Fìdí Ẹ̀rí Ẹfolúṣọ̀n Múlẹ̀
  • Ìwọ̀n Ìgbéyàwó Ń Jó Rẹ̀yìn
  • Àwọn Ọ̀dọ́langba Tí A Fi Oorun Dù
  • Oúnjẹ Ń Dín Ewu Àrùn Jẹjẹrẹ Kù
  • Iye Àwọn Olùgbé Ayé Kò Kúrò Lójú Kan Kẹ̀?
  • Rédíò Tí Kì Í Lo Bátìrì
  • Òjò Panipani
  • Dídá Àwọn Erin Áfíríkà Lẹ́kọ̀ọ́
  • Àwọn Èròjà Àfikún Tí A Fi Ẹ̀jẹ̀ Ṣe
  • Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Àwọn Ọmọdé
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Eyín Erin—Báwo Ló Ṣe Níye Lórí Tó?
    Jí!—1998
  • Oorun—Ṣé Fáwọn Olóòrayè ni Àbí Ohun Àìgbọ́dọ̀máṣe?
    Jí!—2003
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Máa Sùn Dáadáa?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Póòpù Tún Fìdí Ẹ̀rí Ẹfolúṣọ̀n Múlẹ̀

Póòpù John Paul Kejì gbé àkọsílẹ̀ kan jáde láìpẹ́ yìí lórí wíwà ènìyàn nípasẹ̀ ẹfolúṣọ̀n, ní títọ́ka sí “àkójọ́ àbájáde” ìwádìí àdáṣe gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀rí pàtàkì tí ó gbe àbá èrò orí yìí lẹ́yìn.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fọwọ́ sí ẹ̀kọ́ yìí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, John Paul Kejì ṣàtúnwí ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí Póòpù Pius Kejìlá kọ sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù ní 1950, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde L’Osservatore Romano ti sọ, ó “ka ẹ̀kọ́ ‘ìgbàgbọ́ nínú ẹfolúṣọ̀n’ sí àbá ìpìlẹ̀ ṣíṣepàtàkì, tí ó yẹ láti gbé yẹ̀ wò.” Ní gbígbìyànjú láti mú Ọlọ́run wọ inú ọ̀ràn náà, póòpù náà yíjú sí ẹ̀kọ́ Plato pé ènìyàn ní ọkàn àìlèkú. Bákan náà, nígbà tí ó ń fa ọ̀rọ̀ yọ nínú lẹ́tà Pius Kejìlá sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù, ó wí pé: “Bí ara ẹ̀dá ènìyàn bá wá láti inú àwọn ohun alààyè tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá ọkàn tẹ̀mí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Ìwọ̀n Ìgbéyàwó Ń Jó Rẹ̀yìn

Jean Dumas, ọ̀gá níbi ìṣèfọ́síwẹ́wẹ́ ìṣirò iye ẹ̀dá ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní Ibùdó Ìpèsè Ìsọfúnni Oníṣirò ti Kánádà, sọ pé: “A ń rí ìpòórá ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ipò ìbátan kan.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ti sọ, ìwọ̀n ìgbéyàwó ní Kánádà ń dín kù, pàápàá jù lọ ní Quebec. Ìròyìn náà sọ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, lílọ́ra láti kó wọnú ìdè wíwà pẹ́ títí jẹ́ nítorí ohun tí àwọn ènìyàn ti rí nípa ìgbéyàwó ti àwọn òbí wọn. Ìsọfúnni oníṣirò tí a kó jọ láàárín ọdún 25 fi hàn pé ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tọkọtaya tí wọ́n ṣègbéyàwó ní 1969 ni wọn kò gbé pọ̀ mọ́ ní 1993. Ìṣirò tún fi hàn pé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ń kọ ara wọn sílẹ̀. Ìdámẹ́ta lára gbogbo ìkọ̀sílẹ̀ ní Kánádà ní 1993 kan àwọn tọkọtaya tí kò tí ì tó ọdún márùn-ún tí wọ́n ṣègbéyàwó, tí ó ti pọ̀ sí i láti orí ìdámẹ́rin iye irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ ní 1980. Marshall Fine, olùdarí ibùdó ìṣàtúnṣe ìgbéyàwó àti ìdílé ní Yunifásítì Guelph, Ontario, sọ pé: “Kò jọ pé ó jẹ́ ibi tí ó láàbò fún àwọn ọ̀dọ́.”

Àwọn Ọ̀dọ́langba Tí A Fi Oorun Dù

Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé, àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ògbóǹtagí onímọ̀ nípa ìṣòro oorun ní Australia àti ní United States gbà gbọ́ pé àwọn okùnfà míràn lè wà tí ń mú kí àwọn ọ̀dọ́langba fẹ́ láti máa pẹ́ kí wọ́n tó jí lówùúrọ̀ yàtọ̀ sí tẹlifíṣọ̀n wíwò, ẹ̀mí ọ̀tẹ̀, tàbí ọ̀lẹ. Ògbóǹtagí onímọ̀ nípa ìṣòro oorun ní Australia náà, Dókítà Chris Seton, sọ pé, àwọn ìyípadà nínú omi ìsúnniṣe àti ìdàgbà lójijì lè ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́langba fi ń ní ìtẹ̀sí láti sun oorun àsùnjù. Bẹ̀rẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni oorun tí ọ̀dọ́ kan nílò ń pọ̀ sí i. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nínú ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ àwọn 3,000 akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún 17 sí 19 ní United States, ìpín 85 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ni kì í rí oorun tí ó pọ̀ tó sùn. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, àbájáde rẹ̀ jẹ́ àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń bá ìtòògbè jà léraléra, pàápàá jù lọ ní àkókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọwọ́ òwúrọ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n James B. Maas láti Yunifásítì Cornell sọ pé: “A ní àwọn ọmọ tí a ń fi oorun dù gan-an, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ pé a fún wọn ní oògùn apanilọ́bọlọ̀ ni.” Àwọn ògbóǹtagí gbà gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́langba nílò, ó kéré tán, oorun wákàtí mẹ́jọ ààbọ̀ lóru.

Oúnjẹ Ń Dín Ewu Àrùn Jẹjẹrẹ Kù

Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé, jíjẹ èso àti ewébẹ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀marùn-ún lójúmọ́ ń dín ewu kí ẹnì kan ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, ìfun, ikùn, àti irú àwọn àrùn jẹjẹrẹ mìíràn kù. “Ẹ̀rí lílágbára” tí ó wà fún èyí yọjú lẹ́yìn tí a ṣe àwọn àyẹ̀wò tí ó lé ní 200 tí ń jẹ́rìí sí àwọn àǹfààní inú oúnjẹ yìí ní, ó kéré tán, orílẹ̀-èdè 17. Ìwọ̀n rẹ̀ kò ní láti pọ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí Àjọ Abójútó Àrùn Jẹjẹrẹ ní Orílẹ̀-Èdè United States ṣe, sọ pé, ìwọ̀n tí ó wà déédéé ní nínú: “Oríṣi èso kékeré kan, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin ife [180 cc] omi ọsàn, ìlàjì ife [125 cc] ewébẹ̀ tí a sè, ife kan [250 cc] ewébẹ̀ títutù yọ̀yọ̀ nínú sàláàdì tàbí ìlàrin ife [60 cc] èso gbígbẹ.” Àjọ náà ti ń ṣonígbọ̀wọ́ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ fún ọdún márùn-ún tí ó ti kọjá, àmọ́, ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ní United States, àgbàlagbà 1 péré lára àwọn 3 àti ọmọdé 1 lára àwọn 5 ní ń dójú ìwọ̀n ìlapa náà. Ó jọ pé ìyánhànhàn fún oúnjẹ àsúréṣe ń ṣèdíwọ́ fún ìkẹ́sẹjárí. Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé: “Àwọn oúnjẹ dídín tí wọ́n rí wọ́lọwọ̀lọ tí a da tòmátì sí kò dọ́gba pẹ̀lú oúnjẹ ewébẹ̀ ẹ̀ẹ̀mejì.”

Iye Àwọn Olùgbé Ayé Kò Kúrò Lójú Kan Kẹ̀?

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìṣèmúlò Ìṣèfọ́síwẹ́wẹ́ Ìgbékalẹ̀ (IIASA), ní Vienna, ti sọ, iye àwọn olùgbé ayé ní lọ́ọ́lọ́ọ́ kò lè di ìlọ́po méjì. Ìfojúdíwọ̀n wọn ni pé, iye àwọn olùgbé ayé, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ti sọ, “yóò pọ̀ sí i láti orí bílíọ̀nù 5.75 tí ó wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́ sí bílíọ̀nù 10 tí ó bá fi máa di ọdún 2050, yóò pọ̀ tó bílíọ̀nù 11 tí ó bá fi máa di ọdún 2075, yóò sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dúró sójú kan tàbí kí ó dín kù níwọ̀nba tí ó bá ń tó ọdún 2100.” Gẹ́gẹ́ bí àjọ IIASA ti sọ, ìṣeéṣe ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún ló wà pé iye àwọn olùgbé ayé wa kì yóò di ìlọ́po méjì láé. Iye wọ́n fi hàn pé, ó jọ pé ìwọ̀n ìbímọ lọ sílẹ̀ ní gbogbo àgbègbè ayé ní 1995.

Rédíò Tí Kì Í Lo Bátìrì

Láti kojú àìsí iná mànàmáná àti àìtó bátìrì ní ọ̀pọ̀ àwọn ìgbèríko Áfíríkà, ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ kékeré kan nítòsí Cape Town, Gúúsù Áfíríkà, ti ń ṣèmújáde rédíò alágbèéká kan tí ó ní ẹ̀rọ amúnáwá, aláfọwọ́yí, tí a ṣe mọ́ ọn. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Bí o bá fi agbára yí ọwọ́ rẹ̀ fún ìgbà bíi mélòó kan,” yóò “ṣiṣẹ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtóbi rẹ̀ ko ju ike oúnjẹ lọ, tí ó sì tẹ̀wọ̀n kìlógíráàmù mẹ́ta, ó jọ pé ẹ̀yà tuntun náà yóò yọrí sí rere. Gẹ́gẹ́ bí Siyanga Maluma, tí ó jẹ́ olùdarí ọ̀ràn ìtajà ní ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ náà, ṣe sọ, bí a bá tan rédíò náà fún wákàtí márùn-ún sí mẹ́wàá lójúmọ́, yóò pa 500 dọ́là sí 1,000 dọ́là tí a ń ná lórí bátìrì mọ́ láàárín ọdún mẹ́ta. Maluma sọ pé, pa pọ̀ pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ àti alùpùpù, “rédíò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì dídé ipò gíga mẹ́ta ní Áfíríkà.” Ó tẹnu mọ́ ọn pé: “Ó lè dá ọ lójú.” Lórí ìpìlẹ̀ pé o wulẹ̀ ní rédíò kan, “o lè gbéyàwó.”

Òjò Panipani

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sweden náà, Ọ̀mọ̀wé Adrian Frank, ti sọ, òjò ásíìdì ti dá kún ikú ọ̀pọ̀ lára ìgalà ilẹ̀ Scandinavia lọ́nà tí kò ṣe tààrà. Láti sọ ipá òjò oníkẹ́míkà náà di èyí tí kò gbéṣẹ́, wọ́n da ẹfun sórí àwọn pápá àti àwọn adágún. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ewéko tí ń hù lórí ilẹ̀ tí a da ìyẹ̀fún sí fi ìlọsókè nínú ìwọ̀n àwọn èròjà kan hàn, ní pàtàkì jù lọ èròjà molybdenum. Bí ìgalà bá gba èròjà molybdenum tí ó pọ̀ jù sára, ó ń fa àìnító èròjà copper tí ó lè fa ikú, tí ń ṣèpalára lílekoko fún ìgbékalẹ̀ agbára ìdènà àrùn àwọn ẹranko náà. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí mìíràn nítorí òjò ásíìdì, àwọn ẹja kò lè máa wà nìṣó mọ́ nísinsìnyí nínú ohun tí ó lé ní 4,000 adágún tí wọ́n wà ní Sweden, iye àwọn ẹja trout tí wọ́n sì wà ní Norway ti lọ sílẹ̀ dé ìlàjì bí wọ́n ṣe pọ̀ tó tẹ́lẹ̀ rí. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Telegraph ti London sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Britain ń dín ìwọ̀n imí ọjọ́ tí ń tú sáfẹ́fẹ́ láti àwọn ilé iṣẹ́ ìpèsè agbára rẹ̀ kù láti darí orísun ìsọdeléèérí náà, ipá tí èérí òjò ásíìdì náà ń ní lè máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Dídá Àwọn Erin Áfíríkà Lẹ́kọ̀ọ́

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni a ti ń fi àwọn erin Éṣíà ṣiṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n tóbi jù wọ́n lọ láti Áfíríkà ni a ti ronú pé wọ́n jẹ́ oníjàgídí-jàgan jù láti sìn. Àmọ́, ó kéré tán àyẹ̀wò kan ti kẹ́sẹ járí. A ti ń fi àwọn erin Áfíríkà tí wọ́n wà ní igbó àwọn ẹran ìgbẹ́ Imire, tí ó wà ní Zimbabwe, rolẹ̀ àti láti gbé àwọn aṣọ́gbó lọ sí àwọn àgbègbè tí ó ṣòro láti dé. Ìlànà ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń lò ni a ń pè ní “ìfẹ́ àti èrè.” Oníròyìn kan tí ń bá ilé iṣẹ́ aṣèwé agbéròyìnjáde kan ní Áfíríkà ṣiṣẹ́ wòran erin kan tí ń jẹ́ Nyasha níbi tí ó ti ń ro pápá oko, pẹ̀lú lébìrà kan, Muchemwa, tí ó jókòó lé e lẹ́yìn. Oníròyìn náà ṣàlàyé pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń na ọwọ́ ìjà rẹ̀ sẹ́yìn, Muchemwa sì ń ju oúnjẹ tí ó ní ọ̀pọ̀ èròjà protein nínú sínú rẹ̀.” Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Wọn óò lo Nyasha àti àwọn erin mẹ́fà míràn tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Imire láti tún àwọn pápá oko ṣe kí ìgbà òjò tí ń bọ̀ tó de láti gbin àwọn irè bí àgbàdo, tí wọn óò máa lò láti bọ́ àwọn àti àwọn ẹranko mìíràn nínú oko náà.”

Àwọn Èròjà Àfikún Tí A Fi Ẹ̀jẹ̀ Ṣe

Wọ́n ti ń lo èròjà Prothemol, àfikún èròjà protein kan tí a fi ṣàyẹ̀wò, ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Brazil láti yanjú ìṣòro àìjẹunre-kánú ní ẹkùn ilẹ̀ náà. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn àjọ akọ̀ròyìn Associated Press kan ti sọ, ní pàtàkì, a gbé ìmújáde náà karí ẹ̀jẹ̀ màlúù tí a gbà láti àwọn ibùpa ẹran, tí wọ́n sọ pé, ó “tilẹ̀ ń ṣara lóore púpọ̀ ju ẹran lọ.” A ṣe àwọn àyẹ̀wò tí ó jọra ní Guatemala, ní 1990, ní lílo ìmújáde kan tí wọ́n ń pè ní “Harina de Sangre” (ìyẹ̀fun ẹ̀jẹ̀). Ní Brazil, ìjọba ṣètò pé kí wọ́n pín èròjà Prothemol láti ilé dé ilé, “ní fífún àwọn ènìyàn ní èròjà àfikún náà, kí wọ́n sì máa fún àwọn ọmọdé tí wọ́n bá gbà a ní tábúlẹ́ẹ̀tì.” Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ibùpa ẹran ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Brazil wulẹ̀ máa ń da ẹ̀jẹ̀ nù ni, gẹ́gẹ́ bí a ti lànà rẹ̀ sílẹ̀ nínú Bíbélì.—Léfítíkù 17:13, 14.

Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Àwọn Ọmọdé

Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí tí a ṣe ní orílẹ̀-èdè 26, tí a sì ròyìn rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly ti Manchester, England, ti fi hàn, ìlàrin mílíọ̀nù kan àwọn ọmọdé, tí àwọn kan lára wọn jẹ́ ọmọ ọdún méje péré, ń ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun káàkiri ayé. Ìròyìn náà, tí ó jẹ́ apá kan àyẹ̀wò ọlọ́dún méjì tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, fi hàn pé àwọn ọmọdé tí a gbà síṣẹ́ ológun ni a ti hùwà òkú òǹrorò sí àwọn fúnra wọn, lọ́pọ̀ ìgbà, nípa fífipá mú wọn láti wo bí a ṣe ń dá àwọn ẹbí wọn lóró tí a sì ń pa wọ́n. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá ń lò wọ́n bíi aṣekúpani, adìtẹ̀pànìyàn, àti amí. Ní orílẹ̀-èdè kan, “ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ sójà ni a ti pàṣẹ fún láti dá àwọn ọmọdé tàbí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti sá àsálà lóró, kí wọ́n gé wọn lẹ́sẹ̀ tàbí kí wọ́n pa wọ́n.” A ti rí àwọn ọmọdé, tí wọ́n sábà máa ń fún ní oògùn olóró tàbí ọtí líle kí wọ́n tó lọ jà, tí wọ́n ń sá wọnú ogun jíjà “bíi pé a kò lè pa wọ́n tàbí kí a ṣèpalára fún wọn.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́