ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/22 ojú ìwé 19-23
  • Wíwá Tí A Wá Àìṣègbè Kiri

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwá Tí A Wá Àìṣègbè Kiri
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì
  • Iṣẹ́ Ológun àti Ìgbéyàwó
  • Àtakò Olóríkunkun Tí Mo Ṣe
  • A Tẹ́ Wíwá Tí Mo Ń Wá Àìṣègbè Lọ́rùn
  • Ó Wọ̀ Mí Lọ́kàn Níkẹyìn
  • Lílépa Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún
  • Ìgbà Tí Ọwọ́ Tẹ Àìṣègbè ní Kíkún
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Jí!—1997
g97 6/22 ojú ìwé 19-23

Wíwá Tí A Wá Àìṣègbè Kiri

BÍ ANTONIO VILLA ṢE SỌ Ọ́

Ní 1836, gbogbo ará Texas tí ń jà fún Alamo—tí iye wọn dín sí 200—ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mexico kan, tí ó tó 4,000 ọkùnrin, pa. Lẹ́yìn ìgbà náà, igbe ogun náà, “Ẹ rántí Alamo,” ni a lò láti tanná ran ìjà òmìnira tí a gbà lẹ́yìn náà lọ́dún yẹn. Ní 1845, ohun tí ó jẹ́ apá kan Mexico tẹ́lẹ̀ di apá kan United States, àwọn ará Mexico sì bá ara wọn ní àgbègbè ilẹ̀ tí kò níwà bí ọ̀rẹ́. A ṣì ń rántí ìyàtọ̀ àárín ẹ̀yà ìran.

A BÍ mi ní 1937, nítòsí San Antonio, Texas, níbi tí Alamo fìdí sọlẹ̀ sí. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, wọ́n ń kọ ọ̀rọ̀ náà “Aláwọ̀ Funfun Nìkan” àti “Àwọn Mìíràn” sára ilé ìwẹ̀, ẹ̀rọ omi, àti àwọn ìpèsè amáyédẹrùn míràn fún ará ìlú. Kò pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé àwa tí a jẹ́ àtìrandíran Mexico náà wà lára “Àwọn Mìíràn” náà.

Nígbà tí mo ń wòran kan ní ibi ìwòran sinimá, wọ́n gba àwọn ará Mexico àti àwọn adúláwọ̀ láyè láti jókòó ní àkọ́yọ ilé náà nìkan, kì í ṣe nínú gbọ̀ngàn ìwòran gan-an. Ọ̀pọ̀ ilé àrójẹ àti ilé ìtajà kì í ta nǹkan fún àwọn ará Mexico. Nígbà kan tí ìyàwó mi, Velia, àti àbúrò rẹ̀ obìnrin wọ ṣọ́ọ̀bù ìṣaralóge kan, àwọn tí ó ni ṣọ́ọ̀bù náà kò tilẹ̀ ní ọ̀wọ̀ láti sọ pé: “A kì í dá àwọn ará Mexico lóhùn níbí.” Wọ́n wulẹ̀ ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín ni, títí Velia àti àbúrò rẹ̀ fi fìtìjú kúrò níbẹ̀.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọkùnrin aláwọ̀ funfun—lọ́pọ̀ ìgbà, tí wọ́n bá ti mutí yó—máa ń wá àwọn obìnrin ará Mexico, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn kà sí oníwà-pálapàla lọ́nà àdánidá, kiri. Mo ronú pé, ‘Wọn kò lè bá wa ṣàjọlò ilé ìwẹ̀ tàbí ẹ̀rọ omi, àmọ́ wọ́n lè bá àwọn obìnrin ará Mexico sùn.’ Ìṣègbè wọ̀nyí mú kí n wà láìláàbò lákọ̀ọ́kọ́, níkẹyìn, mo di aṣàyàgbàǹgbà-peniníjà.

Ìṣòro Pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì

Àgàbàgebè ìsìn ló túbọ̀ bí mi nínú. Ṣọ́ọ̀ṣì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà fún àwọn aláwọ̀ funfun, àwọn adúláwọ̀, àti àwọn ará Mexico. Nígbà tí mo ń múra láti gba Ara Olúwa fún ìgbà kíní gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì, àlùfáà náà kó àwọn àpò ìwé tí a kọ déètì ọjọ́ iwájú sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lára, pé kí n kó wọn fún bàbá mi. A gbọ́dọ̀ máa dá àpò ìwé kọ̀ọ̀kan pa dà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ kan. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àlùfáà náà sọ fún mi pé: “O jẹ́ sọ fún bàbá rẹ pé a kò rí àwọn àpò ìwé wọ̀nyẹn gbà.” Ọ̀rọ̀ ìbínú tí bàbá mi sọ mú kí n nímọ̀lára kan pé: “Nǹkan kan ṣoṣo tó jẹ wọ́n lógún nìyẹn—owó!”

Lemọ́lemọ́, ìwà ìdójútini ń ṣẹlẹ̀, nínú èyí tí àwọn oníwàásù ti ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ jí obìnrin gbé sá lọ nínú ìjọ wọn. Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ mú kí n máa sọ léraléra pé: “Ète méjì ni ìsìn ní—yálà láti gba owó rẹ tàbí láti gbà ọ́ lóbìnrin.” Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣèbẹ̀wò, mo máa ń lé wọn lọ, ní sísọ pé: “Bí mo bá fẹ́ ìsìn, mo máa wá a fúnra mi.”

Iṣẹ́ Ológun àti Ìgbéyàwó

Ní 1955, mo wọ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Òfuurufú ti United States, níbi tí mo retí pé, bí mo bá ta yọ nídìí iṣẹ́ mi, mo lè jèrè ọ̀wọ̀ tí a fi dù mí nítorí pé mo jẹ́ ará Mexico. Nípa lílo ara mi dé góńgó, wọ́n mọ̀ mí dunjú, níkẹyìn, wọ́n fi mí sí ìdí àbójútó ìdíyelé ìjójúlówó iṣẹ́. Èyí kan dídíyelé àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ológun mìíràn.

Ni 1959, mo gbé Velia níyàwó. Velia ti fìgbà gbogbo nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn. Síbẹ̀, onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì tí ó ti lọ rí ti já a kulẹ̀. Lọ́jọ́ kan ní 1960, nígbà tí ó ní ìsoríkọ́, ó gbàdúrà pé: “Ìwọ Ọlọ́run, bí o bá wà lóòótọ́, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n mọ̀. Mo fẹ́ láti mọ̀ ọ́.” Lọ́jọ́ yẹn kan náà, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sí ilé wa ní Petaluma, California.

Bí ó ti wù kí ó rí, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Velia kò fi rí Àwọn Ẹlẹ́rìí náà mọ́ nítorí ìyípadà tí ó dé bá iṣẹ́ àyànfúnni ológun mi. Ó tún di ọdún 1966, nígbà tí mo wà ní Vietnam, kí ó tó tún bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn lọ́tun ní Seminole, Texas. Nígbà tí mo pa dà dé láti Vietnam níbẹ̀rẹ̀ ọdún tí ó tẹ̀ lé e, kò dùn mọ́ mi nínú láti rí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àtakò Olóríkunkun Tí Mo Ṣe

Mo rò pé ìsìn yóò tan Velia jẹ, yóò sì já a kulẹ̀. Nítorí náà, mo bá wọn jókòó níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì tẹ́tí sí i kí n lè rí àǹfààní kan láti tú àgàbàgebè èyíkéyìí fó, bí o ti wù kí ó kéré mọ. Nígbà tí obìnrin náà sọ pé, Àwọn Ẹlẹ́rìí wà láìdásí-tọ̀túntòsí nínú ìṣèlú, mo já lù ú pé: “Iṣẹ́ kí ni ọkọ rẹ ń ṣe?”

Ó dáhùn pé: “Ó ń gbin òwú.”

Mo fìgbéraga fèsì pé: “Ha! Òwú ni wọ́n fi ń ṣe aṣọ ológun. Nítorí náà, ẹ ń ti ìsapá ogun lẹ́yìn!” Mo ń pariwo sókè, n kò sì gba tirẹ̀ rò.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní June 1967, iṣẹ́ àyànfúnni ológun tún gbé wa lọ jìnnà, sí Minot, Àríwá Dakota, Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó wà níbẹ̀ kàn sí Velia, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtakò bí ọmọdé. N ó mọ̀ọ́mọ̀ dé lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, n ó sì máa tilẹ̀kùn gbàà-gbòò, n óò máa fẹsẹ̀ kilẹ̀ lórí àtẹ̀gùn ilé, n óò sọ bàtà mi lulẹ̀ kó lè pariwo, n óò sì máa yí omi tí ń gbé ìyàgbẹ́ dà nù lọ́pọ̀ ìgbà.

Velia jẹ́ ìyàwó onítẹríba tí ó máa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, kò sì ṣe ohunkóhun láìgba ìyọ̀ǹda mi rí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo gbà á láyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé yóò jẹ́ ìṣòro púpọ̀ láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí. Nígbà tí wọ́n bá rọ̀ ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sábà ń wí pé: “Ó sàn kí n má ṣe bẹ́ẹ̀. N kò fẹ́ láti mú Tony bínú.”

Bí o ti wù kí ó rí, lọ́jọ́ kan, Velia kà á nínú Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.” (Éfésù 4:30) Ó béèrè pé: “Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?” Ẹlẹ́rìí tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàlàyé pé: “Tóò, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló mí sí kíkọ Bíbélì. Nítorí náà, bí a kò bá ṣe ohun tí Bíbélì sọ, a ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan kì í lọ sí ìpàdé, bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀.” (Hébérù 10:24, 25) Ìyẹn ti tó láti sún ọkàn àyà onírẹ̀lẹ̀ tí Velia ni ṣiṣẹ́. Láti ìgbà náà lọ, ó ń lọ sí gbogbo ìpàdé láìka àtakò tí mo ń ṣe sí.

Mo ń jágbe mọ́ ọn pé: “Báwo lo ṣe lè jáde nílé láìse oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀?” Velia yára kọ́ láti máa gbé oúnjẹ alẹ́ mi gbóná, kí ó sì pèsè rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí náà, mo lo àwọn àwáwí mìíràn pé: “O kò fẹ́ràn èmi tàbí àwọn ọmọ wa. O pa wá tì nítorí àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn.” Tàbí nígbà tí mo bá ṣàtakò sí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí Velia sì gbìyànjú láti gbèjà wọn ní pẹ̀lẹ́tù, mo máa ń lo kókó ọ̀rọ̀ bocona—“ẹnu ńlá”—ní pípè é ní bocona aláìlọ́wọ̀, aláìní-ìtẹríba.

Síbẹ̀, Velia ń lọ sí àwọn ìpàdé, ó máa ń ṣomi lójú nígbà tí ó bá ń kúrò nílé lọ́pọ̀ ìgbà, nítorí èébú tí mo ń bú u. Bí ó ti wù kí ó rí, mo rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà kan. N kò lu ìyàwó mi rí, tàbí kí n ronú láti pa á tì nítorí ìsìn rẹ̀ tuntun. Ṣùgbọ́n mo dààmú pé arẹwà ọkùnrin kan lè nífẹ̀ẹ́ sí i ní àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn. Mo ṣì lérò pé, ní ti ìsìn, ‘Yálà owó tàbí obìnrin ni.’ Mo sábà máa ń ṣàròyé bí Velia bá ń múra láti lọ sí ìpàdé pé: “O máa ń múra pàpàrẹrẹ nítorí ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n o kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí tèmi láé.” Nítorí náà, nígbà tí mo kọ́kọ́ pinnu láti lọ sí ìpàdé, mo wí pé: “N ó lọ—àmọ́ kí n kàn lọ ṣọ́ ọ lásán ni!”

Bí ó ti wù kí ó rí, ète ìsúnniṣe mi jẹ́ láti rí nǹkan kan lòdì sí Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ní ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé tí mo kọ́kọ́ lọ, wọ́n sọ̀rọ̀ nípa gbígbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (Kọ́ríńtì Kíní 7:39) Nígbà tí a pa dà délé, mo ṣàròyé gidigidi pé: “O ò rí nǹkan! Bákan náà ni wọ́n rí pẹ̀lú àwọn yòó kù—wọ́n ní ẹ̀tanú lòdì sí ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe onísìn wọn.” Velia fọkàn tútù ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun tí wọ́n wí, ohun tí Bíbélì wí ni.” Mo yára ṣàtakò nípa gbígbá ògiri lẹ́ṣẹ̀ẹ́ àti kíkígbe sókè pé: “Bocona tún ti bẹ̀rẹ̀ o!” Ní gidi, mo ti tẹ́, nítorí mo mọ̀ pé ohun tí ó sọ tọ̀nà.

Mo ń lọ sípàdé, mo sì ń ka àwọn ìwé Àwọn Ẹlẹ́rìí nìṣó, ṣùgbọ́n ète ìsúnniṣe mi jẹ́ láti rí àṣìṣe kan nínú rẹ̀. Mo tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lóhùn sí ìpàdé pàápàá—ṣùgbọ́n ó jẹ́ kìkì láti fi han àwọn ènìyàn pé n kì í ṣe “olúńdù ará Mexico.”

A Tẹ́ Wíwá Tí Mo Ń Wá Àìṣègbè Lọ́rùn

Nígbà tí ó di ọdún 1971, iṣẹ́ ológun tí mo ń ṣe ti gbé wa lọ sí Arkansas. Mo ṣì ń bá Velia, tí ó ti ṣèrìbọmi ní ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà ní December 1969, lọ sí àwọn ìpàdé. N kò ta kò ó mọ́, ṣùgbọ́n n kò ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìmọ̀ tí mo ní nípa kíka àwọn ìwé tí a gbé karí Bíbélì ti pọ̀ sí i lọ́nà gígadabú. Síbẹ̀, mímọ kókó ọ̀rọ̀ nìkan ni—àbájáde ìfẹ́ ọkàn mi láti ṣe dáradára jù lọ nínú ohunkóhun tí mo bá ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí ọkàn àyà mi.

Bí àpẹẹrẹ, mo kíyè sí i pé àwọn aláwọ̀ dúdú ń nípìn-ín nínú ìkọ́ni nínú ìpàdé ìjọ. Ṣùgbọ́n lákọ̀ọ́kọ́, mo sọ fún ara mi pé, ‘Hẹ́n-ẹn, wọ́n wulẹ̀ ń ṣe ìyẹn níkọ̀kọ̀ níhìn-ín ni.’ Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí a lọ sí àpéjọpọ̀ kan ní ibi ìṣeré ìdárayá baseball ńlá kan, ó yà mí lẹ́nu láti rí i pé àwọn aláwọ̀ dúdú nípa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pẹ̀lú. Ó di dandan fún mi láti gbà pé kò sí ìyanisọ́tọ̀ láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí. Wọ́n ń ṣe àìṣègbè tòótọ́.

Mo tún wá mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ojúlówó ìfẹ́ fún ara wọn lẹ́nìkíní kejì. (Jòhánù 13:34, 35) Nígbà tí mo sì bá wọn ṣiṣẹ́ níbi kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, mo lè rí i pé wọn kì í ṣe ènìyàn àrà ọ̀tọ̀. Mo rí i tí ó ń rẹ̀ wọ́n, tí wọ́n ń ṣe àṣìṣe, kódà, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ líle sí ara wọn nígbà tí nǹkan kò bá lọ déédéé. Kàkà kí àwọn àìpé wọ̀nyí mú kí n dàjèjì sí wọn, mo túbọ̀ wá nímọ̀lára ààbò láàárín wọn. Bóyá, mo mọ̀ pé mo nírètí láìka àwọn ọ̀pọ̀ àṣìṣe mi sí.

Ó Wọ̀ Mí Lọ́kàn Níkẹyìn

Nígbà tí Ilé-Ìṣọ́ Na ṣàlàyé ní 1973 pé mímu sìgá jẹ́ ‘ẹ̀gbin ti ẹran ara,’ àti ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń torí rẹ̀ yọni lẹ́gbẹ́, ni mo kọ́kọ́ mọ̀ pé mo ti ń gbé ipò ìbátan kan ró pẹ̀lú Jèhófà. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Nígbà yẹn, mo ń mu sìgá páálí kan sí méjì lóòjọ́. Mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti ṣíwọ́, àmọ́ n kò ṣàṣeyọrí. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà yí, gbogbo ìgbà tí mo bá ti ní ìsúnni láti mu sìgá ni mo ń gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, kí n lè ṣíwọ́ àṣà ẹlẹ́gbin náà. Ó ya gbogbo ènìyàn lẹ́nu pé n kò mu sìgá mọ́.

Ó yẹ kí n fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ológun ní July 1, 1975. Mo lóye rẹ̀ pé bí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, mo gbọ́dọ̀ ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà. N kò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ara ẹni rí, nítorí náà, ó ya àwọn alàgbà ìjọ lẹ́nu gidigidi nígbà tí mo sọ fún wọn ní June 1975, pé mo fẹ́ ṣe ìrìbọmi ní gbàrà tí iṣẹ́ ológun mi bá ti parí. Wọ́n ṣàlàyé pé, mo kọ́kọ́ ní láti mú àṣẹ Jésù ṣẹ, láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Mátíù 28:19, 20) Mo ṣe èyí ní Saturday àkọ́kọ́ ní oṣù July. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, mo bá alàgbà kan pàdé, mo sì dáhùn àwọn ìbéèrè lórí Bíbélì tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Mo ṣe ìrìbọmi lọ́sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà.

Bí àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—Vito, Venelda, àti Veronica—ṣe rí i pé mo ṣèrìbọmi, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yára tẹ̀ síwájú kíákíá nípa tẹ̀mí. Láàárín ọdún méjì tí ó tẹ̀ lé e, àwọn méjì tó dàgbà jù ṣe ìrìbọmi, èyí tó kéré jù sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún mẹ́rin lẹ́yìn náà. Nígbà tí mo bá ń bá àwọn ọkùnrin tí wọ́n mọ òtítọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ sọ̀rọ̀, mo sábà máa ń sọ fún wọn nípa ìyọrísí tí ìkùnà wọn láti gbégbèésẹ̀ lè ní. Mo ń sọ fún wọn pé, bí àwọn ọmọ wọn kò tilẹ̀ sọ ọ́ jáde, wọ́n ń ronú pé, ‘Bí òtítọ́ kò bá ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ fún Dádì, a jẹ́ pé kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ fún mi.’

Lílépa Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ìdílé wa lápapọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní Marshall, Arkansas. Èmi àti Velia bẹ̀rẹ̀ ní 1979, àwọn ọmọ sì dara pọ̀ mọ́ wa ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e bí wọ́n ṣe ń jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, a gbọ́ ìròyìn nípa bí òùngbẹ òtítọ́ Bíbélì ṣe ń gbẹ àwọn ènìyàn ní Ecuador, Gúúsù America, a sì fi ṣe góńgó wa láti kó lọ síbẹ̀. Nígbà tí ó fi di 1989, àwọn ọmọ wa ti dàgbà, wọ́n sì ti tó láti bójú tó ara wọn. Nítorí náà, ní ọdún yẹn, a ṣe ìbẹ̀wò ráńpẹ́ kan sí Ecuador láti “ṣe amí ilẹ̀” náà.—Númérì 13:1, 2.

Ní April 1990 ni a kó dé Ecuador, ilé wa tuntun. Níwọ̀n bí owó kò ti pọ̀ lọ́wọ́ wa—owó ìfẹ̀yìntì mi lẹ́nu iṣẹ́ ológun ni gbogbo ohun tí a ní—a fìṣọ́ra wéwèé ìnáwó wa. Ṣùgbọ́n ayọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní àgbègbè ìpínlẹ̀ eléso tẹ̀mí yìí ti ta ìrúbọ ètò ìṣúnná èyíkéyìí yọ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ. A kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní ìlú èbúté ti Manta, níbi tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 10 sí 12 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn náà ní 1992, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò kan, tí aya mi ń bá mi ṣiṣẹ́. A ń bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ìgbà Tí Ọwọ́ Tẹ Àìṣègbè ní Kíkún

Ní bíbojúwẹ̀yìn, èmi àti Velia lè rí i pé àwọn ìṣègbè tí a fojú winá nígbà tí a ń dàgbà ń ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A ń wà lójúfò, ní pàtàkì, láti má fojú tín-ínrín ẹnikẹ́ni tí ó lè ṣàìní tó wa tàbí tí kò kàwé tó wa tàbí tí ẹ̀yà ìran rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwa. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a rí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ń fojú winá ìṣègbè láàárín àwùjọ ju èyí tí a fojú winá lọ. Síbẹ̀, wọn kò ráhùn. Wọ́n tẹjú mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ wá, ìyẹn ni a sì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe. A ti pa wíwá àìṣègbè nínú ètò àwọn nǹkan yìí tì tipẹ́tipẹ́; kàkà bẹ́ẹ̀, a ń lo ìgbésí ayé wa ní títọ́ka àwọn ènìyàn sí ojútùú tòótọ́ kan ṣoṣo tí ó wà sí ìṣègbè, Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 24:14.

A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwa tí ìṣègbè ti mú bínú gidigidi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí a má retí àìṣègbè ní pípé láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Èyí jẹ́ nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, a sì ní ìtẹ̀sí láti ṣe ohun tí ó burú. (Róòmù 7:18-20) Síbẹ̀, láìṣàbòsí, a lè sọ pé a ti rí ẹgbẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, ti àwọn arákùnrin tí ń tiraka láti ṣe ohun tí ó tọ́, títí dé ibi tí wọ́n lè ṣe é dé. Ìrètí wa ni pé, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run níbi gbogbo, a óò wọ inú ayé tuntun Ọlọ́run, nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé.—Pétérù Kejì 3:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Mo yára ṣàtakò nípa gbígbá ògiri lẹ́ṣẹ̀ẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Pẹ̀lú Velia, nígbà tí mo wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun òfuurufú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pẹ̀lú Velia, ní 1996

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́