Oúnjẹ fún Gbogbo Ènìyàn—Àlá Lásán Ni Bí?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ
NÍGBÀ náà lọ́hùn-ún ní 1974, Ìpàdé Àpérò Àgbáyé Lórí Oúnjẹ tí Àjọ Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ Lábẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (FAO) ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ polongo pé: “Gbogbo ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé ní ẹ̀tọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ebi àti àìjẹunre-kánú.” Wọ́n ké gbàjarè kan nígbà náà láti fòpin sí ebi lágbàáyé “láàárín ẹ̀wádún kan.”
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè 173 pàdé pọ̀ ní orílé iṣẹ́ Àjọ FAO ní Róòmù ní apá ìparí ọdún tó kọjá fún Àpérò Àgbáyé Lórí Oúnjẹ tí wọ́n fi ọjọ́ márùn-ún ṣe, ète wọn ni láti béèrè pé: “Kí ló fà á tí wọ́n fi kùnà?” Kì í ṣe kìkì pé wọ́n ti kùnà láti pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn ni ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ní èyí tí ó lé ní ẹ̀wádún méjì lẹ́yìn náà, ipò náà ti burú sí i ni.
Àwọn ọ̀ràn pàtàkì ti oúnjẹ, iye ènìyàn, àti ipò òṣì ṣe kánjúkánjú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tí wọ́n gbé jáde níbi àpérò náà ṣe sọ, bí a kò bá yanjú àwọn ìṣòro wọ̀nyí, “wọ́n lè nípa búburú lórí ìdúródéédéé ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti ẹkùn ilẹ̀, bóyá, kí wọ́n tilẹ̀ ṣèpalára fún àlàáfíà àgbáyé pàápàá.” Alákìíyèsí kan túbọ̀ sọ ojú abẹ níkòó pé: “A óò fojú wa rí ìparun ọ̀làjú àti àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè.”
Gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Àgbà àjọ FAO, Jacques Diouf, ṣe sọ, “àwọn ènìyàn tí kò ní oúnjẹ tí ó pọ̀ tó lárọ̀ọ́wọ́tó lónìí lé ní 800 mílíọ̀nù; 200 mílíọ̀nù ọmọdé wà lára wọn.” A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé nígbà tí ó bá fi di ọdún 2025, iye ènìyàn lágbàáyé tí ó jẹ́ bílíọ̀nù 5.8 lónìí yóò ti pọ̀ tó bílíọ̀nù 8.3, tí ọ̀pọ̀ jù lọ ìbísí náà yóò sì jẹ́ láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Diouf dárò pé: “Kìkìdá iye àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí a fi ẹ̀tọ́ ìwàláàyè àti iyì wọn tí kò ṣeé gbé sọ nù dù ti ga ju ìwọ̀n tó ṣeé tẹ́wọ́ gbà lọ. Ìkérora àwọn tí ebi ń pa dà pọ̀ mọ́ làásìgbò tí a kò sọ jáde ní ti ilẹ̀ tí a bà jẹ́, àwọn igbó tí a bó borokoto àti àwọn ibi ìpẹja tí a ti kó ẹja wọn tán.”
Ojútùú wo ni a dábàá? Diouf sọ pé ojútùú náà wà nínú “ìgbésẹ̀ onígboyà,” pípèsè “ìdánilójú oúnjẹ” fún àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ní oúnjẹ tó, pa pọ̀ pẹ̀lú pípèsè agbára ìṣeǹkan, ìdókòwò, àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, tí yóò mú kí wọ́n lè pèsè oúnjẹ púpọ̀ tó fúnra wọn.
“Ìdánilójú Oúnjẹ” —Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣòro Tó Bẹ́ẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ kan tí àpérò náà gbé jáde ṣe sọ, “ìdánilójú oúnjẹ wà nígbà tí gbogbo ènìyàn, ní gbogbo ìgbà, bá ní àǹfààní ti ara àti ti ọrọ̀ ajé láti rọ́wọ́ tó oúnjẹ aṣaralóore, tí kò lábùkù, tí ó sì pọ̀ tó láti kápá àìní wọn fún oúnjẹ àti oúnjẹ tí wọ́n yàn láàyò fún ìgbésí ayé gbígbéṣẹ́ tí ó sì gbámúṣé.”
Bí a ṣe lè wu ìdánilójú oúnjẹ léwu ni a ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ nínú yánpọnyánrin àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Zaire. Nígbà tí ebi ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ará Rwanda, àwọn aṣojú àjọ UN ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ nípamọ́ láti fi bọ́ wọn. Àmọ́ ìṣètò láti kó oúnjẹ láti ibì kan sí òmíràn, kí a sì pín in, ń béèrè àṣẹ ìṣèlú àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn aláṣẹ àdúgbò—tàbí àwọn aláṣẹ ológun tí ń fipá ṣàkóso bí ó bá jẹ́ pé àwọn ló ń pàṣẹ lórí àwọn ibùdó àwọn olùwá-ibi-ìsádi. Ọ̀ràn ìṣòro ti Zaire fi bí ó ti ṣòro tó fún àwùjọ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti bọ́ àwọn arebipa, kódà nígbà tí oúnjẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó, hàn lẹ́ẹ̀kan sí i. Alákìíyèsí kan sọ pé: “A ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kàn sí àwọn àwùjọ àti ẹgbẹ́ mélòó kan, kí a sì jírẹ̀ẹ́bẹ̀ lọ́dọ̀ wọn kí a tó lè ṣe ohunkóhun.”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan láti ọwọ́ Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ilẹ̀ United States ṣe tọ́ka sí i, àwọn okùnfà mélòó kan lè bẹ́gi dínà ìdánilójú oúnjẹ lọ́nà lílekoko. Yàtọ̀ sí àwọn ìjábá àdánidá, ìwọ̀nyí kan ogun àti ìjà abẹ́lé, àwọn ìlànà orílẹ̀-èdè tí kò yẹ, ìwádìí àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí kò kúnjú ìwọ̀n, ìbàjẹ́ àyíká, ipò òṣì, iye ènìyàn tí ń pọ̀ sí i, àìdọ́gba tí ó wà láàárín akọ àti abo, àti àìlera.
A ti ṣe àwọn àṣeyọrí díẹ̀. Láti àwọn ọdún 1970, ìpíndọ́gba ìpèsè agbára oúnjẹ, ohun kan tí ń tọ́ka sí bí a ṣe ń jẹun tó, ti lọ sókè láti ìwọ̀n èròjà afáralókun 2,140 sí 2,520 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lóòjọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àjọ FAO ti wí, bí a ti ń fojú sọ́nà pé iye ènìyàn yóò pọ̀ dé bílíọ̀nù mélòó kan nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2030, “láti wulẹ̀ jẹ́ kí oúnjẹ máa wà ní ìpele ti lọ́ọ́lọ́ọ́ yóò béèrè fún pé kí a ṣe àfikún ìmújáde ní kánmọ́kánmọ́ láti mú kí iye tí a ń pèsè lọ sókè ju ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún lọ láìsí bíba àwọn orísun àdánidá tí gbogbo wa gbára lé jẹ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìpèsè oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa kò fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀lé.
‘A Nílò Ìgbéṣẹ́ṣe, Kì Í Ṣe Àfikún Àpérò’
Wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ àríwísí sí àwọn ohun tí wọ́n ṣe ní ibi Àpérò Àgbáyé Lórí Oúnjẹ náà àti àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe níbẹ̀. Aṣojú kan láti Latin America pe “ìmọníwọ̀n” ìpinnu tí wọ́n ṣe láti dín iye àwọn ènìyàn tí kò róúnjẹ jẹ kánú kù sí ìdajì iye ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ní “ọ̀ràn ìtìjú.” Àwọn orílẹ̀-èdè 15 sọ pé àwọn kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn àbá tí àpérò náà fọwọ́ sí. Kódà, ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ti Ítálì sọ pé, láti dé orí ìpolongo àti ìwéwèé ìgbésẹ̀ mímọníwọ̀n kan, “ó gba ìfojúkojú àti ìdúnàádúrà ọlọ́dún méjì. A gbé ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, àmì ìdánudúró díẹ̀ kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò dáradára kí ó má baà mú kí àwọn ọgbẹ́ àtijọ́ . . . tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ̀jẹ̀.”
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ṣètò àwọn àkọsílẹ̀ àpérò náà kò láyọ̀ látàrí àwọn àbájáde náà. Ọ̀kan sọ pé: “A ń ṣiyè méjì gidigidi nípa bóyá àwọn àbá rere tí wọ́n kéde náà yóò dòótọ́.” Ọ̀ràn àríyànjiyàn kan ni bóyá ó yẹ kí a ṣàpèjúwe níní oúnjẹ lárọ̀ọ́wọ́tó gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀tọ́ tí a mọ̀ kárí ayé,” níwọ̀n bí a ti lè ṣẹjọ́ lórí “ẹ̀tọ́” kan. Ọmọ ilẹ̀ Kánádà kan ṣàlàyé pé: “Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó lọ́lá ń bẹ̀rù pé a lè fipá mú àwọn láti pèsè ìrànwọ́. Ìdí nìyí tí wọ́n fi fàáké kọ́rí pé kí a lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò wúwo tó bẹ́ẹ̀ nínú ìpolongo náà.”
Nítorí àsọọ̀sọtán ọ̀rọ̀ tí ń wáyé ní àwọn ibi àpérò tí àjọ UN ń ṣonígbọ̀wọ́ wọn, mínísítà kan fún ìjọba ilẹ̀ Europe sọ pé: “Lẹ́yìn tí a ti fẹnu ọ̀rọ̀ jóná tó bẹ́ẹ̀ níbi àpérò ti Cairo [lórí iye ènìyàn àti ìdàgbàsókè, tí wọ́n ṣe ní 1994], a ti bá ara wa níbi tí a ti tún ń pa dà jíròrò àwọn ohun kan náà nínú àwọn àpérò tí ó tẹ̀ lé e.” Ó dámọ̀ràn pé: “Ohun tí ó gbọ́dọ̀ máa jẹ́ àkọ́múṣe wa nígbà gbogbo ni sísọ àwọn ìwéwèé di òótọ́ fún àǹfààní àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, kì í ṣe ṣíṣe àwọn Àpérò sí i.”
Àwọn alákìíyèsí tún tọ́ka sí i pé, lílọ síbi àpérò náà pàápàá jẹ́ ìnáwó gígadabú fún àwọn orílẹ̀-èdè kan tí ó ṣòro fún láti lọ. Orílẹ̀-èdè kékeré kan láti ilẹ̀ Áfíríkà fi aṣojú 14 àti mínísítà 2, tí gbogbo wọn wà ní Róòmù fún àkókò tí ó ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ, ránṣẹ́. Ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ti Ítálì ròyìn pé ìyàwó ààrẹ kan nílẹ̀ Áfíríkà, ní orílẹ̀-èdè tí ìpíndọ́gba owó tí ń wọlé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́dún kò ju 3,300 dọ́là lọ, ti lọ ná 23,000 dọ́là ní àgbègbè ìtajà tó ta yọ jù lọ ní Róòmù.
A ha ní ìdí láti gbà gbọ́ pé Ìwéwèé Ìṣiṣẹ́ tí a fọwọ́ sí níbi àpérò náà yóò kẹ́sẹ járí bí? Akọ̀ròyìn kan dáhùn pé: “Gbogbo ohun tí a ń retí ní báyìí ni pé kí àwọn ìjọba fọwọ́ gidi mú un, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti rí i pé a óò mú àwọn àbá rẹ̀ ṣẹ. Wọn yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? . . . Ìtàn kò fúnni ní ìfojúsọ́nà rere.” Oníròyìn kan náà tọ́ka sí kókó ajánikulẹ̀ náà pé, láìka ìfohùnṣọ̀kan wọn níbi Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé ní Rio de Janeiro ní 1992 sí, láti ṣàfikún owó ìtìlẹ́yìn fún ìdàgbàsókè sí ìpín 0.7 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ owó tí ń wọlé fún orílẹ̀-èdè, “ìwọ̀nba orílẹ̀-èdè mélòó kan péré ló ti dójú ìlà góńgó tí kì í ṣe ọ̀ràn-anyàn yẹn.”
Ta Ni Yóò Bọ́ Àwọn Arebipa?
Ìtàn ti fi hàn lọ́nà púpọ̀ tó pé láìka gbogbo ìpinnu rere tí ẹ̀dá ènìyàn lè ní sí, “ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23, NW) Nítorí náà, kò jọ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn yóò fúnra wọn pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn láé. Ìwọra, àṣìlò, àti ìgbéra-ẹni-lárugẹ ti ṣamọ̀nà aráyé sí ipò eléwu. Olùdarí Àgbà àjọ FAO, Diouf, sọ pé: “Ohun tí a nílò ní àbárèbábọ̀ ni àyípadà nínú ọkàn àyà, èrò inú àti ìfẹ́ inú.”
Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe ìyẹn. Ní gidi, ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Èmi yóò fi òfin mi sínú wọn, inú ọkàn àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí. Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.”—Jeremáyà 31:33, NW.
Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run ṣètò ilé ọlọ́gbà àkọ́kọ́ fún aráyé, ó fún ènìyàn ní ‘gbogbo ewéko tí ń mú irúgbìn jáde, èyí tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti gbogbo igi lórí èyí tí èso igi tí ń mú irúgbìn jáde wà,’ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:29) Ìpèsè yẹn pọ̀ yanturu, ó dọ́ṣọ̀, ó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Gbogbo ohun tí aráyé nílò láti tẹ́ àìní wọn fún oúnjẹ lọ́rùn nìyẹn.
Ète Ọlọ́run kò tí ì yí pa dà. (Aísáyà 55:10, 11) Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, ó fúnni ní ìdánilójú pé òun nìkan yóò tẹ́ gbogbo àìní aráyé lọ́rùn nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ní ọwọ́ Kristi, ní pípèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, mímú ipò òṣì kúrò, kíkápá àwọn ìjábá àdánidá, àti fífòpin sí gbogbo ìforígbárí. (Orin Dáfídì 46:8, 9; Aísáyà 11:9; fi wé Máàkù 4:37-41; 6:37-44.) Nígbà yẹn, “ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.” “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Orin Dáfídì 67:6; 72:16, NW.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Dorothea Lange, FSA Collection, Library of Congress