ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/8 ojú ìwé 24-27
  • Àwọn Kíndìnrín Rẹ—Asẹ́ Ìgbẹ́mìíró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kíndìnrín Rẹ—Asẹ́ Ìgbẹ́mìíró
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Wà Nínú Àwọn Kíndìnrín Rẹ?
  • Sísẹ́ Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ní Ìpele Méjì
  • Títi Àwọn Èròjà Tí A Kò Nílò Mọ́ Jáde
  • Bójú Tó Àwọn Kíndìnrín Rẹ!
  • ‘Fún Ìwọ̀nba Ìgbà Díẹ̀ Ni!’—Ìgbésí Ayé Mi Pẹ̀lú Àrùn Kíndìnrín
    Jí!—1996
  • Omi Ohun Iyebíye Tó Ń Mú Ká Wà Láàyè
    Jí!—2003
  • Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Jí!—2003
Jí!—1997
g97 8/8 ojú ìwé 24-27

Àwọn Kíndìnrín Rẹ—Asẹ́ Ìgbẹ́mìíró

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ IRELAND

ILẸ̀ ayé àti ara ẹ̀dá ènìyàn ní ohun kan tí ó jọra: Láti gbẹ́mìíró, àwọn méjèèjì nílò asẹ́ kan. Ilẹ̀ ayé nílò ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ ìrọ́lù àwọn ìtànṣán tí ó lè pani lára tí ń wá láti inú oòrùn. Ìpele ozone nínú òfuurufú wa ń sẹ́ ìwọ̀nyí kúrò, tí ó ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ agbẹ́mìíró lè kọjá wá sí ilẹ̀ ayé. Ara rẹ wá ńkọ́? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣiṣẹ́ kẹ́míkà inú ara rẹ ń tú àwọn èròjà olóró àti ìdọ̀tí jáde sínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ. Tí a bá gbà wọ́n láyè láti wà níbẹ̀, ìwọ̀nyí yóò fa àwọn ìṣòro lílekoko fún ọ, ó tilẹ̀ lè pa ọ́. A ní láti máa sẹ́ wọn látìgbàdégbà.

Sísẹ́ wọn yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn lájorí iṣẹ́ àwọn kíndìnrín rẹ. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ẹ̀yà ara kékeré wọ̀nyí ṣe lè mọ àwọn èròjà tí ó lè ṣèpalára, kí wọ́n yà wọ́n sọ́tọ̀, kí wọ́n sì mú wọn kúrò, síbẹ̀ lákòókò kan náà, kí wọ́n sí rí i dájú pé àwọn èròjà ṣiṣekókó ṣẹ́ kù láti bọ́ ara rẹ, kí wọ́n sì ṣe é lóore? Báwo sì ni o ṣe lè ran àwọn kíndìnrín rẹ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí o ní ìlera pípé?

Kí Ló Wà Nínú Àwọn Kíndìnrín Rẹ?

Bí ó ti sábà máa ń rí, àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní kíndìnrín méjì—ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà ní ìhà méjèèjì eegun ẹ̀yìn ní apá ìsàlẹ̀ ẹ̀yìn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 10, wọ́n fẹ̀ ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 5, wọ́n sì nípọn ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 2.5, wọ́n sì tẹ̀wọ̀n láti gíráàmù 110 sí 170. Bí a bá la kíndìnrín lọ́gbọọgba láti òkè wá sí ìsàlẹ̀, ó ní àwọn àbùdá tí a ṣètò dáradára, tí a rí nínú àwòrán tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

Láti fojú inú wo bí kíndìnrín ṣe ń ṣiṣẹ́, finú wòye pápá ìṣiré ńlá kan tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òǹwòran ń wọ́ wá nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn èrò náà gbọ́dọ̀ pínra sí onírúurú ìlà kéékèèké. Lẹ́yìn náà, níkọ̀ọ̀kan ni àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lórí ìlà kọ̀ọ̀kan ń gba ẹnu àwọn géètì ààbò kọjá, níbi tí a ti ń yọ àwọn tí kò ní tíkẹ́ẹ̀tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Àwọn òǹwòran tí wọ́n ní tíkẹ́ẹ̀tì ń kọjá lọ́ sórí ìjókòó tí a fi fún wọn.

Lọ́nà kan náà, gbogbo àwọn èròjà tí ó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ rẹ ní láti lọ káàkiri gbogbo ara rẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa gba inú àwọn kíndìnrín rẹ kọjá léraléra nípasẹ̀ àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ ńlá, àwọn òpójẹ̀ àlọ kíndìnrín, ọ̀kan fún kíndìnrín kọ̀ọ̀kan. (Wo àwòrán tó wà lójú ìwé 24.) Lẹ́yìn wíwọnú kíndìnrín, òpójẹ̀ àlọ kíndìnrín náà yóò tàn wọ́n kálẹ̀ lọ sínú àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ tí ó túbọ̀ kéré nínú àwọn ìpele inú àti ti ìta kíndìnrín náà. Àwọn onírúurú èròjà inú ẹ̀jẹ̀ rẹ ń tipa bẹ́ẹ̀ darí sí “àwọn ìlà” tí ó túbọ̀ kéré, tí ó sì ṣeé ṣàkóso.

Níkẹyìn, ẹ̀jẹ̀ náà dé ní ìṣùjọ tín-tìn-tín, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní nǹkan bí 40 iṣan ẹ̀jẹ̀ kíkéré jọjọ, tí ó so mọ́ra pinpin. Ìṣùjọ kọ̀ọ̀kan, tí a ń pè ní glomerulus, ni awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ oníṣẹ̀ẹ́po méjì kan tí a mọ̀ sí àpò Bowman yí ká rẹ̀.a Lápapọ̀, ìṣùjọ glomerulus náà àti àpò Bowman di apá àkọ́kọ́ ‘géètì ààbò’ kíndìnrín rẹ náà, nephron—lájorí ẹ̀ka ìṣẹ́ǹkan kíndìnrín rẹ. Ó lé ní mílíọ̀nù kan ẹ̀yà ara nephron tó wà nínú kíndìnrín kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n wọ́n kéré gan-an débi pé ìwọ yóò nílò awò asọhun kékeré di ńlá kan láti wo ọ̀kan!—Wo àwòrán ẹ̀yà ara nephron kan, tí a sọ di ńlá gan-an, lójú ìwé 25.

Sísẹ́ Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ní Ìpele Méjì

Àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ àti èròjà protein inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Wọ́n ń pèsè àwọn ohun pàtàkì fún ara rẹ bí afẹ́fẹ́ oxygen, ìgbèjà, àti àtúnṣe ìpalára. Láti ṣèdíwọ́ fún ìpàdánù àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ àti èròjà protein, ìpele àkọ́kọ́ nínú ìṣẹ́ǹkan náà ń yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo àwọn èròjà míràn. Àpò Bowman ní ń ṣe iṣẹ́ àkànṣe yìí. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe ń ṣe é?

Àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ tí ń wọnú ìṣùjọ glomerulus ń pín sí òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ tín-tìn-tín tí àwọn awọ rẹ̀ fẹ́lẹ́ gan-an. Nípa bẹ́ẹ̀, agbára ìlọkiri ẹ̀jẹ̀ lè fipá mú omi díẹ̀ àti àwọn èérún kéékèèké mìíràn jáde gba inú àwọn awọ wọn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, jáde kúrò nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ, kí ó sì wọnú àpò Bowman àti túùbù lílọ́ tí ó so mọ́ ọn. Ihò tóóró yìí ni a ń pè ní ihò tóóró títẹ̀ kolobo. Àwọn molecule èròjà protein tí ó tóbi jù lọ àti gbogbo àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ náà sì wà nínú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì ń ṣàn lọ gba inú àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́.

Ní báyìí, sísẹ́ǹkan wá túbọ̀ di àṣàyàn. Àwọn kíndìnrín rẹ gbọ́dọ̀ rí i dájú láìsí tàbítàbí pé kò sí ohunkóhun tí ó lè ṣàǹfààní fún ara rẹ tí ó dà nù! Omi tí ń ṣàn gbà inú ihò tóóró ní àsìkò yí jẹ́ àpòpọ̀ olómi, tí ó ní àwọn molecule wíwúlò tí ó ti yòrò nínú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìdọ̀tí àti àwọn èròjà tí a kò fẹ́. Àwọn sẹ́ẹ̀lì àkànṣe pa pọ̀ pẹ̀lú awọ inú ihò tóóró náà dá àwọn molecule wíwúlò mọ̀, bí omi, iyọ̀, ṣúgà, èròjà mineral, fítámì, omi ìsúnniṣe, àti ásíìdì amino. Àwọn wọ̀nyí ni a ń tú jáde lọ́nà gbígbéṣẹ́ nípa ṣíṣàtúngbà rẹ̀ sínú awọ ihò tóóró náà, kí a tún dá a pa dà sínú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra tí ó yí àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ náà ká láti tún wọ inú ìṣàn ẹ̀jẹ̀ rẹ. Àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ náà yóò tún pa dà wá bí òpójẹ̀ àbọ̀ wẹ́wẹ́ tí yóò wá pa pọ̀ di iṣan ẹ̀jẹ̀ tí ń jẹ́ òpójẹ̀ àbọ̀ kíndìnrín. Nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ, tí a ti sẹ́, tí ó sì ti mọ́ báyìí, yóò wá kúrò nínú kíndìnrín, yóò sì máa lọ láti gbé ẹ̀mí ró nínú ara rẹ.

Títi Àwọn Èròjà Tí A Kò Nílò Mọ́ Jáde

Ṣùgbọ́n omi tí ó ṣẹ́ kù sínú ihò tóóró náà ńkọ́? Ó hàn gbangba pé àwọn èròjà tí ara rẹ kò nílò ló wà nínú rẹ̀. Bí omi náà ti ń ṣàn lọ gba inú ihò tóóró síhà ihò ìgbaǹkansí, àwọn sẹ́ẹ̀lì míràn nínú awọ ihò tóóró náà ń da àwọn mìíràn tí ó sẹ̀ sínú rẹ̀, títí kan gáàsì ammonia, potassium, urea, ásíìdì uric, àti àpọ̀jù omi. Àmújáde tí ó kẹ́yìn ni ìtọ̀.

Àwọn àpò ìgbaǹkansí wọ̀nyí láti inú onírúurú ẹ̀yà ara nephron para pọ̀, wọ́n sì ń tú ìtọ̀ jáde gba àwọn ihò ṣíṣísílẹ̀ lórí àwọn pyramid. Ìtọ̀ náà ń kọjá wọnú agbada kíndìnrín náà, yóò wá gba inú okùn ìtọ̀, ihò tóóró tí ó so kíndìnrín àti àpòòtọ̀ pọ̀, jáde. Inú àpòòtọ̀ rẹ ní ìtọ̀ máa ń kóra jọ sí kí o tó tọ̀ ọ́ kúrò nínú ara rẹ.

Láìka ti pé wọ́n kéré jọjọ sí, àwọn ẹ̀yà ara nephron tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù méjì tí ó wà nínú àwọn kíndìnrín rẹ ń ṣe iṣẹ́ ribiribi kan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn ẹ̀yà ara nephron . . . ń sẹ́ gbogbo omi ìwọ̀n quart márùn-ún [lítà 4.7] tí ó wà nínú ẹ̀jẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú 45.” Nígbà tí a bá fi máa ṣàtúngbà àwọn onírúurú èròjà sára, tí àwọn ìgbésẹ̀ púpọ̀ náà yóò fi parí, ara tí ó wà déédéé, tí ìlera rẹ̀ pé lè máa tọ nǹkan bíi lítà méjì ìdọ̀tí jáde láàárín wákàtí 24 kọ̀ọ̀kan. Ẹ wo irú ìgbékalẹ̀ aṣiṣẹ́kára, tí ó sì wà létòlétò tí èyí jẹ́!

Bójú Tó Àwọn Kíndìnrín Rẹ!

Àwọn kíndìnrín rẹ máa ń fọ ara wọn, wọ́n sì máa ń ṣàbójútó ara wọn, wọ́n ní agbára láti máa bá a lọ fún àkókò pípẹ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ní ipa kan láti kó nínú ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi gbọ́dọ̀ gba inú àwọn kíndìnrín rẹ kọjá kí ara rẹ lè máa le. Ní gidi, mímu omi tí ó pọ̀ tó ni a kà sí lájorí ọ̀nà tí a lè gbà dènà àwọn àrùn inú kíndìnrín àti ìkórajọ òkúta nínú kíndìnrín.b Dókítà C. Godec, alága Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Ìtọ̀ ní Long Island College Hospital, New York, sọ pé, mímu omi tún ń ṣèrànwọ́ fún bí oúnjẹ ṣe ń dà àti bí a ṣe ń gbé ẹ̀jẹ̀ wọnú ọkàn àyà.

Báwo ni omi náà yóò ṣe pọ̀ tó? Dókítà Godec àti ọ̀pọ̀ àwọn dókítà míràn dámọ̀ràn pé ní àfikún sí jíjẹ àwọn oúnjẹ àti ohun mímu mìíràn, ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa mu, ó kéré tán, omi lítà méjì lójoojúmọ́. Dókítà Godec sọ fún Jí! pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn ni omi ti gbẹ lára wọn.” Ó sọ pé, bí àwọn kíndìnrín rẹ tàbí ọkàn àyà rẹ kò bá ti ní àrùn, omi dára fún wọn. Dókítà Godec sọ pé: “Ṣùgbọ́n o ní láti mu omi tí ó pọ̀ tó. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kì í ṣe bẹ́ẹ̀.”

Omi máa ń dùn mọ́ àwọn kan lẹ́nu gan-an bí wọ́n bá da èròjà aládùn, bí ọsàn wẹ́wẹ́, sínú rẹ̀. Àwọn mìíràn nífẹ̀ẹ́ sí bí omi ṣẹ́lẹ̀rú tàbí omi tí a ti fi èédú sẹ́ ṣe rí lẹ́nu. Bí ó ti wù kí ó rí, yálà omi wà láìládàlú tàbí a da èròjà aládùn díẹ̀ sí i, ó dára jù fún àwọn kíndìnrín rẹ ju ohun mímu èyíkéyìí mìíràn lọ. Ní gidi, ṣúgà tí ó wà nínú àwọn omi èso àti ohun mímu aládùn ń mú kí ara túbọ̀ nílò omi sí i ni. Àwọn ohun mímu tí ó ní ọtí líle tàbí káféènì nínú ń mú kí ara pàdánù omi.

Kíkówọnú àṣà mímu omi lítà méjì lójúmọ́ lè jẹ́ ìpèníjà lótìítọ́. Fún ohun kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn rí i bí èyí tí kò báradé tàbí tí ń mára tini láti máa lọ tọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà ju bí ó ti yẹ lọ. Ṣùgbọ́n ara rẹ yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún sísapá díẹ̀ sí i. Yàtọ̀ sí ṣíṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìlera rẹ, mímu omi tí ó pọ̀ tó tilẹ̀ lè mú kí ìrísí rẹ sunwọ̀n sí i. Àwọn dókítà sọ pé, jíjẹunre kánú àti mímu ohun olómi tí ó pọ̀ túbọ̀ gbéṣẹ́ fún mímú kí ẹran ara rẹ jojú ní gbèsè ju lílo àwọn èròjà ìpara èyíkéyìí lọ.

Ó dunni pé ètò ìmọ̀lára òǹgbẹ wa kò pé pérépéré, ìṣiṣẹ́ rẹ̀ tilẹ̀ ń relẹ̀ sí i bí a ti ń dàgbà sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, a kò lè gbẹ́kẹ̀ lé òǹgbẹ nìkan láti sọ bí omi tí a nílò yóò ṣe pọ̀ tó. Báwo ni o ṣe lè ní ìdánilójú pé o ń mu omi tí ó pọ̀ tó? Àwọn kan máa ń bẹ̀rẹ̀ òòjọ́ wọn nípa mímu ife omi méjì, lẹ́yìn náà, léraléra ní àkókò tí ó dọ́gba, wọn ń mu ife mìíràn. Àwọn mìíràn máa ń gbé ohun ìbomisí tí a lè rí inú rẹ̀ síbi tí ojú àti ọwọ́ wọn yóò ti tó o—ìránnilétí láti máa mu ún díẹ̀díẹ̀ látìgbàdégbà jálẹ̀ ọjọ́ náà. Ọ̀nàkọnà tó wù kí o lò, mímu ọ̀pọ̀ omi tí kò lẹ́gbin, tí ó mọ́ tónítóní jẹ́ ọ̀nà dídára láti fi ìmoore hàn fún àwọn kíndìnrín rẹ—asẹ́ àgbàyanu tí ó mú ọ wà láàyè.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1840, oníṣẹ́ abẹ, ọmọ ilẹ̀ England, tí ó tún jẹ́ onímọ̀ nípa ìgbékalẹ̀ àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ kíkéré jọjọ náà, William Bowman, ṣàpèjúwe awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kékeré yìí àti bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́. A wá fi orúkọ rẹ̀ pè é.

b Wo Jí!, ìtẹ̀jáde August 22, 1993, ojú ìwé 20 sí 22, àti August 8, 1987, ojú ìwé 14.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ẹ̀yà Ara Nephron—Ẹ̀ka Ìsẹ́dọ̀tí Ṣíṣekókó

Ó LÉ ní mílíọ̀nù kan ẹ̀yà nephron tí ó wà nínú kíndìnrín kọ̀ọ̀kan. Ìṣètò ihò tóóró tí ó wà nínú ẹ̀yà ara nephron kọ̀ọ̀kan gùn tó nǹkan bí ìpíndọ́gba sẹ̀ǹtímítà 3, ó sì fẹ̀ ní nǹkan bí 0.05 mìlímítà péré. Síbẹ̀, bí ó bá ṣeé ṣe láti tú gbogbo ìṣètò ihò tóóró inú kíndìnrín kan palẹ̀, wọn óò gùn tó 30 kìlómítà!

Àpò Bowman ni apá ìkangun tí ó tẹ̀ sínú ní ti gidi lára ihò tóóró títẹ̀ kolobo inú ẹ̀yà ara nephron. Ìsokọ́ra àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ kéékèèké tí ń jẹ́ òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ wà yí po ihò tóóró yìí. Ihò tóóró náà lọ sínú ihò ìgbaǹkansí kan tí ó túbọ̀ tóbi, tí ń gbé ìdọ̀tí àti àwọn èròjà onímájèlé tí ẹ̀yà ara nephron sẹ́ jáde dà nù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Òpójẹ̀ àbọ̀ kíndìnrín ń gbé ẹ̀jẹ̀ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ sẹ́ jáde sínú ara

Òpójẹ̀ àlọ kíndìnrín ń gbé ẹ̀jẹ̀ tí a kò sẹ́ lọ sínú kíndìnrín

Àwọn “pyramid” kíndìnrín tí ń gbé ìtọ̀ lọ sínú agbada kíndìnrín dà bí àrọ

Awọ náà ní ìṣùjọ “glomerulus” ti ẹ̀yà ara “nephron” kọ̀ọ̀kan nínú

Agbada kíndìnrín jẹ́ àrọ kan tí ń gba ìtọ̀ sínú, tí ó sì ń darí rẹ̀ lọ sínú okùn ìtọ̀

Okùn ìtọ̀ ń gbé ìtọ̀ lọ sínú àpòòtọ̀ láti inú kíndìnrín

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ẹ̀yà ara “nephron,” tí ó jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì asẹ́ oníhò tóóró kíkéré jọjọ, máa ń fọ ẹ̀jẹ̀

Àpò “Bowman”

Ìṣùjọ “glomerulus”

Ihò tóóró títẹ̀ kolobo náà ń gba ìtọ̀ sínú, lẹ́yìn náà, yóò lọ sínú àpòòtọ̀

Àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́