ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/22 ojú ìwé 4-9
  • Àwọn Ibi Tí Ìṣòro Náà Ti Le Jù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ibi Tí Ìṣòro Náà Ti Le Jù
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Kan Ní, Àwọn Kan Kò Ní
  • Ẹ̀wádún Tí Ó Kún fún Ìrètí
  • Ènìyàn Tí Ń Pọ̀ Sí I, Àìní Tí Ń Pọ̀ Sí I
  • Ìsọdìbàjẹ́
  • Omi Tí Kò Dára, Ìlera Tí Kò Pé
  • Pípín Omi Odò
  • Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
    Jí!—2001
  • Ibo Ni Gbogbo Omi Ọ̀hún lọ?
    Jí!—2001
  • A Ń fẹ́ Omi Ìyè
    Jí!—2001
  • Omi Tó Ń Tú Yàà Sókè Láti Fúnni Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 8/22 ojú ìwé 4-9

Àwọn Ibi Tí Ìṣòro Náà Ti Le Jù

MARY, tí ń gbé United States, ń bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nípa wíwẹ̀, ó ń lo omi tí ń jáde lẹ́nu ẹ̀rọ láti fọyín rẹ̀, ó ń tẹ omi tí ń gbé ìgbẹ́ rẹ̀ lọ, ó sì ń fọ ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn náà. Kódà kí ó tó jókòó jẹ oúnjẹ àárọ̀, ó lè lo omi tó lè kún agbada ìwẹ̀ alábọ́ọ́dé. Nígbà tí ilẹ̀ bá fi máa ṣú, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí ń gbé United States, Mary ti lo omi tí ó ju 350 lítà lọ, omi tó lè kún agbada ìwẹ̀ kan nígbà méjì àti ààbọ̀. Ní tirẹ̀, ó lè tètè rí omi tí ó mọ́ tónítóní, tí ó sì pọ̀ tó lẹ́nu ẹ̀rọ tí ó sún mọ́ ìtòsí jù lọ. Ó sábà máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó; kò kà á sí.

Ní ti Dede, tí ń gbé Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ọ̀ràn náà yàtọ̀ pátápátá. Ó máa ń jí kí ilẹ̀ tó mọ́, yóò wọṣọ, yóò gbé abọ́ ìpọnmi ńlá kan rù, yóò sì rin ìrìn kìlómítà mẹ́jọ dé odò tó sún mọ́ jù lọ. Ibẹ̀ ni yóò ti wẹ̀, yóò pọnmi kún abọ́ náà, yóò sì darí sílé. Ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ yìí ń gba nǹkan bíi wákàtí mẹ́rin. Ní wákàtí kan tó tẹ̀ lé e, yóò sẹ́ omi náà láti yọ àwọn kòkòrò àfòmọ́ kúrò nínú rẹ̀, yóò wá pín in sínú ohun ìpọnmisí mẹ́ta—ọ̀kan fún mímu, ọ̀kan fún lílò nílé, àti ọ̀kan fún ìwẹ̀ rẹ̀ nírọ̀lẹ́. Ó gbọ́dọ̀ fọ aṣọ èyíkéyìí tó bá fẹ́ fọ̀ lódò.

Dede sọ pé: “Ọ̀wọ́n omi ń pa wá níbí. Nígbà tí a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo gbogbo apá ìdajì òwúrọ̀ tán ní pípọnmi, wákàtí mélòó ló kù lọ́jọ́ kan láti fi ṣiṣẹ́ oko tàbí àwọn ìgbòkègbodò míràn?”

Ó dájú pé kì í ṣe Dede nìkan ló wà nínú ipò náà. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, àròpọ̀ àkókò tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ń lò lọ́dọọdún ní pípọnmi àti ríru omi tí wọ́n máa ń pọn ní àwọn ibi jíjìnnà, tí ó máa ń jẹ́ ìsun omi dídọ̀tí lọ́pọ̀ ìgbà, lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá ọdún!

Àwọn Kan Ní, Àwọn Kan Kò Ní

Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé omi aláìníyọ̀ pọ̀ jákèjádò ayé, kò kárí lọ́gbọọgba. Lájorí ìṣòro àkọ́kọ́ nìyẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú díwọ̀n pé níwọ̀n bí Éṣíà ti ní ìpín 36 nínú ọgọ́rùn-ún lára omi tó kún inú gbogbo adágún omi àti ti odò àgbáyé, kọ́ńtínẹ́ǹtì yẹn ni ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn tí ń gbé ayé fi ṣelé. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, Odò Amazon ní ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo omi odò àgbáyé, àmọ́ kìkì ìpín 0.4 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn tí ń gbé ayé ní ń gbé ibi tó sún mọ́ ọn dáradára tó tí wọ́n fi lè rí i lò. Òjò pẹ̀lú kò kárí lọ́gbọọgba. Àwọn ẹkùn ilẹ̀ kan lórí ilẹ̀ ayé fẹ́rẹ̀ẹ́ di èyí tí kò lómi títí lọ fáàbàdà; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn kì í sábà wà láìlómi, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n ń jìyà sáà ọ̀gbẹlẹ̀.

Àwọn ògbóǹkangí bíi mélòó kan gbà gbọ́ pé àwọn ènìyàn lè fa àwọn ìyípadà kan tí ó kan òjò nínú ojú ọjọ́. Ìpagbórun, ilẹ̀ àrojù, àti ìfẹranjẹkojù ń sọ ilẹ̀ di kodoro. Àwọn kan ronú pé tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ojú ilẹ̀ ń dá oòrùn púpọ̀ sí i pa dà sínú afẹ́fẹ́. Àbájáde rẹ̀ ni pé: Afẹ́fẹ́ yóò túbọ̀ gbóná, kùrukùru yóò pòórá, òjò tí ń rọ̀ yóò sì dín kù.

Ilẹ̀ ṣíṣá pẹ̀lú lè mú kí rírọ̀ òjò dín kù, nítorí pé òjò púpọ̀ gan-an tí ń rọ̀ sí igbó jẹ́ omi tí ó kọ́kọ́ jáde wá láti inú igbó náà fúnra rẹ̀—láti ara ewé àwọn igi àti irúgbìn tí ó hù níbàǹbalẹ̀. Ní ọ̀rọ̀ míràn, igbó ń ṣiṣẹ́ bí kànrìnkàn ràgàjì kan tí ń fa omi òjò sára, tí ó sì ń gbà á dúró sára. Bí a bá kó àwọn igi àti irúgbìn tí ó hù níbàǹbalẹ̀ náà kúrò, omi tí yóò wà kò ní pọ̀ tó láti di kùrukùru òjò.

Bí ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn ṣe ń nípa lórí òjò gẹ́lẹ́ lọ́nà gbígbàfiyèsí ṣì jẹ́ ọ̀ràn tí a ń jiyàn lé lórí; ìwádìí ṣì pọ̀ tí a óò ṣe. Àmọ́ èyí tí ó dájú ni pé: Àìtó omi wà káàkiri. Báńkì Àgbáyé kìlọ̀ pé, ní báyìí ná, àìtó rẹ̀ ń wu ètò ọrọ̀ ajé àti ìlera 80 orílẹ̀-èdè léwu. Àti ní báyìí ná, ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ayé—ó lé ní bílíọ̀nù méjì ènìyàn—kò ní omi tí ó mọ́ tónítóní tàbí ìmọ́tótó.

Nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ bá ní ìṣòro omi, wọ́n sábà máa ń ná owó wọn láti yẹ ìṣòro tí ìyọrísí rẹ̀ lè le koko sílẹ̀. Wọ́n mọ àwọn ìsédò, wọ́n ń lo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ anánilówó láti ṣàtúnṣe omi wọn fún lílò, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ yọ iyọ̀ kúrò nínú omi òkun. Àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ kò ní irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó di ọ̀ràn-anyàn fún wọn láti yàn yálà kí wọ́n ṣọ́ omi aláìníyọ̀ lò, èyí lè ṣèdíwọ́ fún ìlọsíwájú, kí ó sì dín ìṣèmújáde oúnjẹ kù, tàbí láti ṣàtúnlò omi ẹlẹ́gbin, tí ń yọrí sí títan àrùn kálẹ̀. Bí ìlò omi ti ń pọ̀ sí i níbi gbogbo, ó jọ pé àìtó omi yóò gbilẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la.

Ẹ̀wádún Tí Ó Kún fún Ìrètí

Ní November 10, 1980, Àpéjọ Gbogbogbòò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ̀rọ̀ tìgboyàtìgboyà nípa “Ẹ̀wádún Ìpèsè Omi Mímu àti Ìmọ́tótó Omi Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-Èdè” tí ń bọ̀. Ẹgbẹ́ náà polongo pé, góńgó ìlépa náà ni pé, tí ó bá máa di ọdún 1990, kí a ti pèsè omi tí ó mọ́ tónítóní àti ìmọ́tótó lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ní òpin ẹ̀wádún náà, wọ́n ti ná iye tí ó tó bílíọ̀nù 134 dọ́là láti fa omi tí ó mọ́ tónítóní dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní bílíọ̀nù kan, wọ́n sì ti pèsè àwọn ohun èlò ìdàdọ̀tínù fún àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní 750 mílíọ̀nù—àṣeyọ́rí kan tó wúni lórí.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lílọ tí iye ènìyàn lọ sókè sí 800 mílíọ̀nù ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà sọ ìwọ̀n àṣeyọrí wọ̀nyí di aláìgbéṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí ó fi di ọdún 1990, ó lé ní bílíọ̀nù kan àwọn ènìyàn tí wọn kò ní omi tí kò léwu àti ìmọ́tótó tí ó pọ̀ tó. Ó jọ pé ìṣòro náà ń ṣàtúnwí ohun tí ayaba sọ fún Alice nínú ìtàn àwọn ọmọdé náà, Through the Looking-Glass, pé: “Ṣé o rí i, o ní láti sáré bí o bá ṣe lè yára tó kí o baà lè wà ní ipò rẹ. Bí o bá fẹ́ ya ẹnì kan sílẹ̀, o gbọ́dọ̀ yára sáré tó ìlọ́po méjì ìyẹn, ó kéré tán!”

Gẹ́gẹ́ bí àjọ WHO ti sọ, láti 1990, àpapọ̀ ìlọsíwájú nínú mímú kí ipò àwọn tí wọn kò ní omi àti ìmọ́tótó sunwọ̀n sí i ti “dín kù.” Nígbà tí Sandra Postel, jẹ́ igbákejì ààrẹ ẹ̀ka ìṣèwádìí ní Ibùdó Worldwatch, ó kọ̀wé pé: “Pé 1.2 bílíọ̀nù ènìyàn kò lè mu omi láìsí ewu àrùn tàbí ikú ṣì jẹ́ àbùkù nínú ìhùwà ẹ̀dá. Kì í ṣe àìtó omi gangan tàbí àìní ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ló fà á, àmọ́ àìsí ìfarajìn ní ti ìfẹ́dàáfẹ́re àti ti ètò ìṣèlú láti yanjú àwọn àìní ṣíṣekókó tí àwọn òtòṣì ní. Yóò náni ní iye tí a fojú díwọ̀n sí bílíọ̀nù 36 dọ́là sí i lọ́dún kọ̀ọ̀kan, nǹkan bí ìpín 4 nínú ọgọ́rùn-ún iye tí a ń ná sórí ìgbòkègbodò ológun lágbàáyé, láti mú ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa kò kà sí nísinsìnyí—omi mímọ́ tónítóní àti dída ìdọ̀tí nù lọ́nà ìmọ́tótó—wá fún gbogbo ìran aráyé.”

Ènìyàn Tí Ń Pọ̀ Sí I, Àìní Tí Ń Pọ̀ Sí I

Ìṣòro kan tí ó ṣìkejì mú kí pípín tí a ń pín omi lọ́nà tí kò dọ́gba díjú: Bí àwọn ènìyàn ti ń pọ̀ sí i ni àìní fún omi ń pọ̀ sí i. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ló wà nínú ìwọ̀n tí òjò fi ń rọ̀ jákèjádò ayé, àmọ́ ènìyàn ń pọ̀ jaburata. Ìwọ̀n omi tí a ń mu ti ga ní ìlọ́po méjì, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀mejì láàárín ọ̀rúndún yìí, àwọn kan sì fojú díwọ̀n pé ó tún lè ga ní ìlọ́po méjì lẹ́ẹ̀kan sí i láàárín 20 ọdún tí ń bọ̀.

Dájúdájú, kì í ṣe omi mímu púpọ̀ sí i nìkan ni iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i náà ń béèrè fún, wọ́n tún ń béèrè fún oúnjẹ púpọ̀ sí i pẹ̀lú. Bí ó ti yẹ, ìpèsè oúnjẹ ń béèrè fún ìwọ̀n omi tí ó pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ àgbẹ̀ gbọ́dọ̀ figagbága pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n nílò omi. Bí àwọn ìlú ńlá àti àwọn àgbègbè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ti ń fẹ̀ sí i, iṣẹ́ àgbẹ̀ ló sábà ń pàdánù. Olùṣèwádìí kan béèrè pé: “Ibo ni oúnjẹ náà yóò ti wá? Báwo ni a ṣe lè tẹ́ àìní bílíọ̀nù 10 ènìyàn lọ́rùn nígbà tí ó jẹ́ pé agbára káká lá fi lè tẹ́ àìní bílíọ̀nù 5 lọ́rùn, tí a sì ń mú omi kúrò níhà iṣẹ́ àgbẹ̀?”

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìlọsókè nínú iye ènìyàn náà ní ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, níbi tí omi tí sábà máa ń wọ́n tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn kò ní owó àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí wọ́n lè fi yanjú àwọn ìṣòro omi.

Ìsọdìbàjẹ́

Ní àfikún sí àwọn ìṣòro àìtó omi àti àìní àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i, ìṣòro kẹta tí ó tan mọ́ ọn ni: ìsọdìbàjẹ́. Bíbélì sọ nípa “odò omi ìyè kan,” àmọ́ lónìí, púpọ̀ àwọn odò ló jẹ́ odò ikú. (Ìṣípayá 22:1) Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n kan ti fi hàn, ìwọ̀n omi dídọ̀tí—láti ilé àti àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ—tí ń ṣàn sínú àwọn odò àgbáyé lọ́dọọdún pọ̀ tó 450 kìlómítà ní ìwọ̀n òró, ìbú, àti gíga. Ọ̀pọ̀ odò ńlá àti odò kéékèèké ni a ti bà jẹ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin wọn.

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lágbàáyé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn odò ńláńlá ni a ti fi ògidì ẹ̀gbin bà jẹ́. Ìwádìí kan tí a ṣe nípa 200 odò ńláńlá ní Rọ́ṣíà fi hàn pé, àwọn 8 nínú 10 ni bakitéríà àti àwọn fáírọ́ọ̀sì pọ̀ nínú wọn lọ́nà líléwu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò da ẹ̀gbin sí ìpele òkè àwọn odò àti omi ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà gan-an, a sábà máa ń fi àwọn kẹ́míkà eléròjà májèlé, títí kan àwọn tí ó wá láti inú ajílẹ̀ tí a ń lò nínú iṣẹ́ àgbẹ̀, bà wọ́n jẹ́. Ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ apá ibi gbogbo lágbàáyé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní etí òkun ń da ògidì ẹ̀gbin sínú àwọn omi tí kò jinlẹ̀ nítòsí àwọn etíkun wọn, wọ́n sì ń ba àwọn èbúté òkun jẹ́ lọ́nà bíburú jáì.

Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣòro tí ó kárí ayé ni bíba omi jẹ́. Ní ṣíṣàkópọ̀ ipò náà, ìwé pẹlẹbẹ tí Ẹgbẹ́ Audubon ṣe náà, Water: The Essential Resource, sọ pé: “Ìdámẹ́ta ìran aráyé ń ṣe làálàá nínú ipò àìsàn tàbí àìlera títí lọ kánrin gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí omi tí kò mọ́ tónítóní; dídà tí a da àwọn èròjà oníkẹ́míkà tí a kò mọ ìpalára ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí ó lè ṣe ń wu ìdámẹ́ta mìíràn léwu.”

Omi Tí Kò Dára, Ìlera Tí Kò Pé

Nígbà tí Dede, tí a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀, sọ pé, “ọ̀wọ́n omi ń pa wá,” ó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà àfiṣàpèjúwe ni. Dájúdájú, lọ́nà olówuuru àìsí omi mímọ́ tónítóní, tí kò níyọ̀ máa ń pani. Ní ti òun àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹni bíi tirẹ̀, wọn kò ní yíyàn èyíkéyìí mìíràn àyàfi kí wọ́n máa lo omi tí wọ́n pọn láti àwọn odò kéékèèké àti odò ńláńlá, tí wọ́n sábà máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ ibi tí a ń da ẹ̀gbin sí tí ó wà ní gbayawu. Abájọ tí àjọ WHO fi sọ pé, àrùn tí ó tan mọ́ omi ń pa ìpíndọ́gba ọmọdé kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá mẹ́jọ!

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn World Watch ti sọ, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àrùn ni mímu omi tí ó léwu ń tàn kálẹ̀. Àwọn ohun tí ń ṣokùnfà àrùn tí omi ń fà àti bíba omi jẹ́ ń pa mílíọ̀nù 25 ènìyàn lọ́dọọdún.

Àwọn àrùn panipani tí ń bá omi rìn—títí kan àrùn ìgbẹ́ gbuuru, onígbáméjì, àti typhoid—ń pa ọ̀pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n ń pa ní àwọn Ilẹ̀ Olóoru. Síbẹ̀, àwọn àrùn tí ń bá omi rìn kò mọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan. Láàárín 1993, ní United States, 400,000 ènìyàn ni àìsàn kọ lù ní Milwaukee, Wisconsin, lẹ́yìn tí wọ́n mu omi ẹ̀rọ tí ó ní kòkòrò àrùn kan tí èròjà chlorine kò ràn. Ní ọdún kan náà, àwọn kòkòrò àrùn eléwu wọ inú ọ̀nà ìpèsè omi àwọn ìlú ńlá mìíràn ní United States—Washington, D.C.; New York City; àti Cabool, Missouri—tí èyí fipá mú àwọn olùgbé ibẹ̀ láti máa se omi tó jáde lẹ́nu ẹ̀rọ wọn.

Pípín Omi Odò

Àwọn ìṣòro bíbáratan nípa àìtó omi, àìní àwọn ènìyàn tí iye wọn ń pọ̀ sí i, àti bíba omi jẹ́ tí ń ṣamọ̀nà sí àìlera jẹ́ àwọn kókó abájọ tí ó lè yọrí sí pákáǹleke àti ìforígbárí. Ó ṣe tán, ó dájú pé omi kì í ṣe ohun afẹ́. Òṣèlú kan tí ń bá ìṣòro omi wọ̀dìmú ní Sípéènì sọ pé: “Kì í tún ṣe ìjàkadì ètò ọrọ̀ ajé là ń jà, ìjà fún wíwà nìṣó ni.”

Ìhà títóbi kan tí pákáǹleke ti ń wá ni pípín omi tí ń wá láti inú àwọn odò. Gẹ́gẹ́ bí Peter Gleick, olùṣèwádìí kan ní United States, ti sọ, ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ayé ní ń gbé àwọn 250 àgbègbè ilẹ̀ odò, tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jà lé omi wọn lórí ju ọ̀kan lọ. Àwọn odò Brahmaputra, Indus, Mekong, Ọya, Náílì, àti Tígírísì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń ṣàn gba àárín orílẹ̀-èdè púpọ̀—àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n fẹ́ láti fa omi láti inú àwọn odò wọ̀nyẹn bí ó bá ṣe lè pọ̀ tó. Ní báyìí ná, awuyewuye ti wà.

Bí àìní fún omi ti ń pọ̀ sí i, irú pákáǹleke bẹ́ẹ̀ yóò pọ̀ sí i. Igbákejì ààrẹ Báńkì Àgbáyé tí ń bójú tó Ìdàgbàsókè Tí Kò Lè Ba Àyíká Jẹ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ogun tí ń jà ní ọ̀rúndún yìí ló jẹ́ nítorí epo, àmọ́ àwọn ogun tí yóò jà ní ọ̀rúndún tí ń bọ̀ yóò jẹ́ lórí omi.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Molecule Kan Ń Rìnrìn Àjò

Jẹ́ kí a bá molecule omi kan ṣoṣo lọ nínú ìrìn àjò rẹ̀ tí kò lópin. Ọ̀wọ́ àwọn àwòrán tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, tí a kọ nọ́ńbà sí kí ó lè bá ohun tí a kọ sílẹ̀ mu, ṣàlàyé ọ̀kan ṣoṣo lára àìmọye ọ̀nà tí molecule omi kan ṣoṣo lè tọ̀ pa dà sí ibi tí ó ti wá. —Jóòbù 36:27; Oníwàásù 1:7.

A óò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú molecule kan lójú òkun.(1) Bí agbára oòrùn ti ń fa omi gbẹ, molecule náà ń lọ sókè títí ti yóò fi tó ẹgbẹ̀rún mítà bíi mélòó kan sókè ilẹ̀ ayé.(2) Nísinsìnyí, ó dà pọ̀ mọ́ àwọn molecule omi mìíràn láti di ẹ̀kán omi tínńtín kan. Ẹ̀kán omi náà ń bá ẹ̀fúùfù rìn fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà. Bí àkókò ti ń lọ, ẹ̀kán omi náà gbẹ, molecule náà sì tún gbéra lẹ́ẹ̀kan sí i títí tí ó fi dà pọ̀ mọ́ ẹ̀kán òjò kan tí ó tóbi tó láti kán sórí ilẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín.(3) Ẹ̀kán òjò náà kán sí ẹ̀bá òkè kan pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn; omi náà ṣàn lọ sínú odò kékeré kan nísàlẹ̀.(4)

Lẹ́yìn náà, ìgalà kan mu nínú omi odò kékeré náà, ó sì mu molecule wa náà.(5) Ní wákàtí mélòó kan lẹ́yìn náà, ìgalà náà tọ̀, molecule náà sì bọ́ sórí ilẹ̀ níbi tí àwọn gbòǹgbò igi kan ti gbé e.(6) Láti ibẹ̀, molecule náà gbéra lọ sókè lára igi náà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, afẹ́fẹ́ sì fà á gbẹ láti inú ewé kan.(7) Bí ó ti ṣe tẹ́lẹ̀, ó sú lọ sókè láti di ẹ̀kán omi tínńtín mìíràn. Ẹ̀kán omi náà bá ẹ̀fúùfù lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ títí tí ó fi dà pọ̀ mọ́ kùrukùru òjò ńlá, ṣíṣú kan.(8) Molecule wa náà tún bá òjò rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, àmọ́, lọ́tẹ̀ yí, ó dé inú odò kan tí ó gbé e lọ sínú òkun.(9) Ó lè lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún níbẹ̀ kí ó tó tún wá sókè, tí oòrùn yóò fà á gbẹ, tí afẹ́fẹ́ yóò sì tún gbé e lẹ́ẹ̀kan sí i.(10)

Àyípoyípo náà kò dópin rí: Oòrùn ń fa omi láti inú òkun, ó ń káàkiri lórí ilẹ̀, ó ń rọ̀ sílẹ̀ bí òjò, ó sì ń ṣàn pa dà sínú àwọn òkun. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, omi ń gbé ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè orí ilẹ̀ ayé ró.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ohun Tí A Ti Dámọ̀ràn

Ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ tí ń yọ iyọ̀. Ìwọ̀nyí ń yọ iyọ̀ kúrò nínú omi òkun. Wọ́n sábà máa ń ṣe èyí nípa fífa omi sínú àwọn àlàfo oníwọ̀n ipá kékeré, níbi tí a óò ti sè é títí yóò fi hó. Omi náà yóò gbẹ, wọ́n óò sì darí eruku rẹ̀ síbòmíràn, yóò wá ṣẹ́ ku iyọ̀ dídì níbẹ̀. Ìgbésẹ̀ tó gbówó lórí ni, èyí tí ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà kò lè ṣe.

Yíyọ́ àwọn òkìtì yìnyín. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan gbà gbọ́ pé a lè fi àwọn ọkọ̀ ojú omi ńláńlá tí a fi ń fa nǹkan fa àwọn òkìtì yìnyín títóbi, tí ó ní omi aláìníyọ̀, tí ó mọ́ tónítóní láti àgbègbè Antarctic, kí a sì yọ́ wọn láti pèsè omi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ wọn gbẹ táútáú ní ìhà Gúúsù Ìlàjì Ayé. Ìṣòro kan ni pé: Nǹkan bí ìdajì òkìtì yìnyín kọ̀ọ̀kan yóò yọ́ nínú òkun kí ó tó dé ibi tí wọ́n ń gbé e lọ.

Fífa omi láti ìpele ilẹ̀ agbomidúró. Àwọn ìpele ilẹ̀ agbomidúró ni àwọn àpáta tí ó ní omi níbi jíjìn nísàlẹ̀ ilẹ̀. Láti àwọn ibi wọ̀nyí, a lè fa omi sókè, kódà ní aṣálẹ̀ tí ó gbẹ jù lọ. Ṣùgbọ́n fífa omi yìí ń náni lówó, ó sì ń mú kí ìpele apá òkè ibi tí omi wà nínú ilẹ̀ dín kù. Ìpalára mìíràn ni pé: Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìpele ilẹ̀ agbomidúró ń ṣàtúnṣe ara wọn lọ́nà ti kò yára rárá—àwọn kan kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Fọ́tò: Mora, Godo-Foto

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Omi pípọn lè gba wákàtí mẹ́rin lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Omi dídọ̀tí tó pọ̀ tó 450 kìlómítà ní ìwọ̀n òró, ìbú, àti gíga ń ṣàn sínú àwọn odò lọ́dọọdún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́