ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/22 ojú ìwé 16-18
  • Via Egnatia—Òpópó Kan Tó Ṣèrànwọ́ fún Ìmúgbòòrò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Via Egnatia—Òpópó Kan Tó Ṣèrànwọ́ fún Ìmúgbòòrò
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí A Fi Nílò Rẹ̀
  • Ojú Ilẹ̀ Tí Kò Rọrùn Láti Fi Lànà
  • Kíkúnjú Ète Rẹ̀
  • Ipa Tí Ó Kó Nínú Ìtànkálẹ̀ Ìsìn Kristẹni
  • Ìjàkadì Nítorí Ìhìn Rere Ní Ìlú Tẹsalóníkà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọ̀nà Àwọn Ará Róòmù Ohun Tó Ń ránni Létí Iṣẹ́ Àwọn Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ayé Àtijọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Sọdá Wá sí Makedóníà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
Jí!—1997
g97 8/22 ojú ìwé 16-18

Via Egnatia—Òpópó Kan Tó Ṣèrànwọ́ fún Ìmúgbòòrò

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ GÍRÍÌSÌ

NÍ ỌDÚN 50 Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn míṣọ́nnárì Kristẹni kan gúnlẹ̀ sí Europe fún ìgbà àkọ́kọ́. Ohun tó mú wọn wá ni ìkésíni kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí gbà nínú ìran kan pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” (Ìṣe 16:9) Ìsọfúnni tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mú wá nípa Jésù Kristi ní ipa gbígbàfiyèsí lórí Europe.

Ohun kan tí ó ṣèrànwọ́ ní pàtàkì fún ìtànkálẹ̀ ìsìn Kristẹni ní Makedóníà ni Via Egnatia, òpópó kan tí àwọn ará Róòmù da ọ̀dà sí. Lẹ́yìn tí àwọn míṣọ́nnárì náà gúnlẹ̀ sí etíkun Neapólísì (Kaválla, Gíríìsì, nísinsìnyí) ní igun àríwá Òkun Aegean, ó ṣe kedere pé wọ́n rìnrìn àjò gba òpópó yẹn lọ sí Fílípì, ìlú ńlá pàtàkì ní àgbègbè Makedóníà. Ọ̀nà náà lọ sí Ámífípólì, Apolóníà, àti Tẹsalóníkà, àwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ tún ti dúró lẹ́yìn náà.—Ìṣe 16:11–17:1.

Àwọn apá kan lára òpópó ìgbàanì yí ṣì wà di báyìí, a sì ń lò wọ́n lójoojúmọ́. Ní báyìí, ìwéwèé wà láti la òpópó ìgbàlódé kan tí yóò gba ojú òpó ọ̀nà ìgbàanì náà, tí yóò sì máa jẹ́ orúkọ kan náà.

Ta ló la òpópó àkọ́kọ́ náà? Nígbà wo ni wọ́n là á, fún ète wo sì ni?

Ìdí Tí A Fi Nílò Rẹ̀

Bí Ilẹ̀ Ọba Róòmù ti ń bá ìṣẹ́gun rẹ̀ nìṣó sí ìhà ìlà oòrùn, Makedóníà wá di ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù ní ọdún 146 ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí ó ti wù kí ó rí, gbígbà tí wọ́n gba ilẹ̀ yí dá àìní tuntun kan sílẹ̀ fún ilẹ̀ ọba náà—agbára láti kó àwọn ọmọ ogun lọ sí àwọn àgbègbè tuntun náà ní kíákíá. Via Appia, tàbí Ọ̀nà Appian, níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Italian ti so Róòmù pọ̀ mọ́ Etíkun Adriatic tí ó wà ní ìhà gúúsù ìlà oòrùn ná. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ilẹ̀ ọba náà nílò irú òpópó kan náà lórí Ìyawọlẹ̀ Omi Balkan, nítorí náà, èrò nípa Via Egnatia wáyé. Wọ́n sọ ọ́ ní orúkọ ọ̀gá àgbà onímọ̀ ẹ̀rọ tó bójú tó iṣẹ́ náà, aṣojú àgbà fún ọba ilẹ̀ Róòmù, Gnaius Egnatius.

Via Egnatia bẹ̀rẹ̀ láti ìlú èbúté òkun Dyrrachium ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Ílíríkónì (Durres, Albania), ó sì lọ títí dé ìlú ńlá ìgbàanì ti Byzantium (Istanbul, Turkey), tí ó lé ní 800 kìlómítà ní gígùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í là á ní ọdún 145 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì gba nǹkan bí ọdún 44 kó tó parí. Bí a ti pète rẹ̀, Via Egnatia wá di ohun èlò wíwúlò gidigidi kan fún ìlànà ìmúgbòòrò ilẹ̀ Róòmù ní ìhà Ìlà Oòrùn láìpẹ́.

Ojú Ilẹ̀ Tí Kò Rọrùn Láti Fi Lànà

Bí ó ti wù kí ó rí, ojú ilẹ̀ náà mú kí líla òpópó náà jẹ́ ìpèníjà. Bí àpẹẹrẹ, níbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ojú ọ̀nà náà já Adágún Ohrid, tí ó wà ní ààlà ìhà àríwá. Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí ó ti lọ́ kọ́lọkọ̀lọ gba ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ àárín àwọn òkè ńláńlá, tí ó sì ń lọ síhà ìlà oòrùn la ojú ilẹ̀ kan tí kò bára dé, tí ó ní àwọn ihò bí ife ní àgbègbè olókè, àwọn òkè ńláńlá tí ilẹ̀ ti wọ́ lọ kúrò lórí wọn, àti àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì tí ó ní àwọn adágún lápá kan kọjá, ọ̀nà náà jálẹ̀ sí àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ Makedóníà nígbẹ̀yìngbẹ́yín.

Bí òpópó náà ti ń sún mọ́ ìlú ńlá Tẹsalóníkà, ó bọ́ sí ilẹ̀ títẹ́jú gbalasa kan. Ṣùgbọ́n ojú ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn ìlú ńlá náà jẹ́ olókè. Bí Via Egnatia ti ń darí gba àárín àwọn òkè wọ̀nyí, ó sọ̀ lọ sínú àfonífojì kan tí ó ní àwọn adágún tí a kò lè sọ ibi tí etí wọn dé, tí ó sì jẹ́ irà. Bí ó ti ń bá a nìṣó, ó ń la àárín àwọn àfonífojì àti irà kọjá títí ó fi dé ìlú Neapólísì ìgbàanì.

Láti ibẹ̀, ọ̀nà náà gba etíkun Aegean lọ síhà ìlà oòrùn, ó sì sọ dá sí ẹkùn ilẹ̀ Thrace. Ní apá ìkẹyìn rẹ̀, òpópó náà gba ọ̀nà títọ́ gbọnrangandan kan, tí ó sì tẹ́jú pẹrẹsẹ dé ibi tó ń lọ gan-an, Byzantium.

Kíkúnjú Ète Rẹ̀

Via Egnatia di ọ̀nà tààrà jù lọ tí ó sì rọrùn jù lọ láàárín Róòmù àti àwọn ibi tí Róòmù ṣẹ́gun ní ìhà ìlà oòrùn Òkun Adriatic. Ó mú kí ìdásílẹ̀ àwọn àgbègbè ìgbókèèrè-ṣàkóso ilẹ̀ ọba Róòmù rọrùn ní àwọn ìlú ńlá Makedóníà, ó sì nípa gidigidi lórí ìdàgbàsókè àgbègbè náà ní ti ọrọ̀ ajé, iye ènìyàn àti ìpínkiri wọn, àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀. Òpópó náà mú kí kíkó bàbà, èròjà asphalt, fàdákà, ẹja, epo, wáìnì, wàràkàṣì, àti àwọn ohun mìíràn láti ibì kan dé òmíràn lọ́nà rírọrùn ṣeé ṣe.

Ìníláárí tí irú òwò bẹ́ẹ̀ mú wá ló sọ àwọn ìlú kan lójú ọ̀nà náà, bíi Tẹsalóníkà àti Ámífípólì, di díẹ̀ lára àwọn ìlú ńlá títóbilọ́lá tó wà ní àgbègbè Balkan. Ní pàtàkì, Tẹsalóníkà gbèrú di ìlú ńlá ìṣòwò pàtàkì kan, tí ó kún fún àwọn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ọnà àti ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Lóòótọ́, àwọn ìlú tí ọ̀nà yí gbà kọjá ń gbé apá kan nínú ìnáwó ìgbọ́bùkátà lórí rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní àbárèbábọ̀, àwọn ìlú wọ̀nyí gbádùn àwọn àǹfààní rẹpẹtẹ tí òwò ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè ń mú wá.

Ipa Tí Ó Kó Nínú Ìtànkálẹ̀ Ìsìn Kristẹni

Bí ó ti wù kí ó rí, Via Egnatia mú àǹfààní kan tí ó lọ́lá ju ìníláárí ti ara lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àgbègbè náà. Bí àpẹẹrẹ, wo ti gbajúmọ̀ obìnrin oníṣòwò náà, Lìdíà. Ó ń gbé ní ìlú Fílípì—ìlú àkọ́kọ́ tí a ti gbọ́ tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù ìhìn rere ní Europe. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ gúnlẹ̀ sí Neapólísì ní ọdún 50 Sànmánì Tiwa, wọ́n rin ìrìn àjò kìlómítà 16 síhà àríwá ìwọ̀ oòrùn ní òpópó Via Egnatia lọ sí ìlú Fílípì.

Lúùkù kọ̀wé pé: “Ní ọjọ́ sábáàtì a sì jáde lọ sẹ́yìn òde ibodè lẹ́bàá odò kan, níbi tí a ń ronú pé ibi àdúrà wà; a sì jókòó a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn obìnrin tí wọ́n ti pé jọ sọ̀rọ̀.” Lìdíà wà lára àwọn obìnrin tí ó fetí sí Pọ́ọ̀lù. Lọ́jọ́ yẹn gan-an, òun àti agboolé rẹ̀ di onígbàgbọ́.—Ìṣe 16:13, 14.

Láti ìlú Fílípì, Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ gba òpópó Via Egnatia la Ámífípólì àti Apolóníà kọjá lọ sí Tẹsalóníkà, àpapọ̀ nǹkan bí 120 kìlómítà. (Ìṣe 17:1) Kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù ní Tẹsalóníkà, ó lo àwọn ìpéjọpọ̀ àwọn Júù ní ọjọọjọ́ Sábáàtì ní sínágọ́gù àdúgbò. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Júù mélòó kan, àti ògìdìgbó àwọn Gíríìkì di onígbàgbọ́.—Ìṣe 17:2-4.

Bákan náà lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Albania àti Gíríìsì ń lo àwọn apá kan òpópó yìí láti dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ wọ̀nyí. Ohun tí wọ́n ń lépa ni láti tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀, lọ́nà kan náà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ gbà ṣe é. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8) Ní gidi, Via Egnatia jẹ́ òpópó àwọn ará Róòmù tí ó ti ṣèrànwọ́ fún ìmúgbòòrò tẹ̀mí, ní ọ̀rúndún kìíní títí wọnú ọ̀rúndún ogún yìí!

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

BRITAIN

EUROPE

ÁFÍRÍKÀ

BALKAN ÌYAWỌLẸ̀ OMI

MAKEDÓNÍÀ

GÍRÍÌSÌ

Dyrrachium, Ílíríkónì (Durres, Albania)

Tẹsalóníkà

Apolóníà

Ámífípólì

Ffílípì

Neapólísì (Kaválla)

Byzantium (Istanbul)

ÒKUN DÚDÚ

ÒKUN MARMARA

THRACE

ÒKUN AEGEAN

Tíróásì

TURKEY

[Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lójú ọ̀nà tí ó lọ sí Neapólísì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Lójú ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú Fílípì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́