Ìlàkàkà Mi Láti Kojú Àrùn RSD
MO TI lé díẹ̀ ní ẹni 40 ọdún, mo sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni alákòókò kíkún ní ibi iṣẹ́ ọ́fíìsì kan tí mo ti ń fi kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún mi ní eegun ẹ̀yìn lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, mo sì lérò pé mo mọ bí ìrora ṣe rí lára. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi ní January 1994 nítorí iṣan kan tí ó yọ kókó ní ọrùn ọwọ́ òsì mi, mo retí níní ìrora àti àìfararọ díẹ̀—àmọ́ tí kò ní ju èyí tí mo lè kojú lọ.
Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà, tí ó kẹ́sẹ járí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára ìrora lílekoko nínú apá mi ọ̀tún. Ó tún ń wú, ó sì ń pàwọ̀ dà. Àwọn èékánná mi yọ ṣọ̀bọ̀lọ̀, wọ́n sì ń sán, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì lè gé wọn nítorí ìrora. Oorun fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé sùn. Lákọ̀ọ́kọ́, ó dọwọ́ àwọn dókítà àti àwọn olùṣètọ́jú láìlo egbòogi délẹ̀, àmọ́ bí àwọn àmì tí ó ń fi hàn ṣe ń le sí i, oníṣẹ́ abẹ náà wá mọ̀ pé ohun tí ń ṣe mí ni àrùn RSD (Àrùn Ìṣiṣẹ́gbòdì Iṣan Amúnimọ̀rora), tí a tún mọ̀ sí Àrùn Ìrora Lílekoko ní Àpá Kan Ara. Nígbà yẹn, ó ti lé ní oṣù mẹ́ta tí mo ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
Bí Àrùn RSD Ṣe Ń Ṣeni
N kò gbọ́ nípa àrùn RSD rí, àmọ́ mo mọ ohun tó jẹ́ nínú ara tèmi fúnra mi—ÌRORA. Irú ìrora tí ó burú jù lọ. Ìrora tí kò lópin nínú ọwọ́ àti apá mi. Mo ń jẹ̀rora bí ọwọ́ mi ti ń wú tó ìlọ́po mẹ́ta rẹ̀. Ìrora tí ń jóni bí iná láìdábọ̀. Ńṣe ló dà bíi wíwà nínú ilé kan tí ń jóná, n kò sì lè sá àsálà. Kì í ṣe àsọdùn ni mo ń sọ! Fún mi, ó jẹ́ ìrora tí ó burú jù lọ, tí kì í sì í dáwọ́ dúró jù lọ tí a lè finú rò. Ìrora náà ń wá lóríṣiríṣi ní ìpele yíyàtọ̀síra. Ní àwọn ìgbà kan, ìrora náà dà bí ogunlọ́gọ̀ kòkòrò oyin tí ń ta mí. Ní àwọn ìgbà míràn, ó dà bí ìgbà tí ohun èlò afúnǹkanpọ̀ kan ń fún mi pọ̀ àti bíi pé àwọn abẹfẹ́lẹ́ ń ya mí lára. N kò tilẹ̀ lè pa á mọ́ra láti jẹ́ kí irun mi tí ó gùn kan awọ ara mi—tí ó bá kàn án, ń ṣe ló máa ń dà bíi pé àwọn ẹ̀gún ń gún mi lára. Mo nílò ìdẹ̀ra díẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrora gógó náà lọ́nàkọnà.
Ní ìgbà kan, ìrora lílekoko tí kò dábọ̀ náà ń jẹ mí níyà gan-an débi pé mo tilẹ̀ ronú gígé apá mi nínú ilé ìwẹ̀. Mo ṣe kàyéfì nípa iye ibi tí ń óò gé láti mú ìdálóró yìí kúrò. (Lẹ́yìn náà, àwọn dókítà wí fún mi pé gígé e kò lè yanjú ìṣòro náà.) Mo nímọ̀lára bíi ti kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan tí pańpẹ́ mú tí ó ń wá ìtura nípa fífi eyín gé ẹsẹ̀ rẹ̀ tí pańpẹ́ mú dà nù.
Ìtura Díẹ̀ Níkẹyìn!
Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbájáde ìkẹyìn, wọ́n gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn ìtọ́jú ìrora kan láti gbàtọ́jú. Mo pàdé Dókítà Mathew Lefkowitz níbẹ̀, ògbóǹtagí olùtọ́jú ìrora tí ó tún jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn oògùn apàrora, tí ń ṣiṣẹ́ ní New York, ní Brooklyn Heights. Ó jẹ́ agbatẹnirò tí ó sì lóye ẹni gan-an. Ilé ìwòsàn ìtọ́jú ìrora náà wá di ibi ìsádi fún mi, pàápàá bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lóye àrùn tí ń ṣe mí àti ọ̀nà tí a ń gbà tọ́jú rẹ̀.
Dókítà Lefkowitz fi ìtọ́jú pípa ìmọ̀lára ìrora kan bẹ̀rẹ̀—gígún iṣan kan ní ọrùn mi lábẹ́rẹ́ déédéé, èyí yóò sé ìgbéra ìmọ̀lára inú iṣan tí ń fa ìrora náà mọ́ fún ìgbà díẹ̀. Bí ó ṣe ṣàlàyé rẹ̀, ìgbékalẹ̀ iṣan amúnimọ̀rora ló ń tanná ran ìrora náà. Èyí ni ìhùwàpadà aláàbò tí ọpọlọ sábà máa ń ṣe sí àpá tàbí iṣẹ́ abẹ. Àlàyé náà ni pé ó yẹ kí ìgbékalẹ̀ yí máa ṣiṣẹ́ bí ẹnu ọ̀nà. Àwọn ìmọ̀lára iṣan náà ń gba ibẹ̀ kọjá kìkì bí àpá náà ṣe ń jinná. Ní àárín kan, nígbà tí ọpọlọ kò bá fi àwọn ìmọ̀lára kankan ránṣẹ́ nínú iṣan mọ́, ẹnu ọ̀nà náà yóò pa dé, ìrora náà yóò sì pòórá. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn RSD, ẹnu ọ̀nà náà kì í pa dé. Iṣan amúnimọ̀rora kì í dẹra. Ńṣe ló máa ń ṣiṣẹ́ lọ bíi pé àpá kan ṣì wà ní àyíká náà. Dókítà náà ní kí ń máa wá sí ilé ìwòsàn lọ́gán nígbàkigbà tí ìrora náà bá ń le sí i. Nípa bẹ́ẹ̀, mo ti ń gba àwọn abẹ́rẹ́ tí ń sé ìrora mọ́ déédéé fún ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.
Àwọn abẹ́rẹ́ náà ràn mí lọ́wọ́ láti forí ti ìtọ́jú láìlo egbòogi, tí ó jẹ́ kí ń lè máa gbé ọwọ́ tí nǹkan ń ṣe náà, ó sì wúlò gan-an nínú ipò yí. Bí àkókò ti ń lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ní lílo apá méjèèjì àti àwọn ọwọ́ mi. Ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ tí ń múni fojú sọ́nà fún rere.
Kí Ló Lè Jẹ́ Ìyọrísí Rẹ̀?
Ìrora tí kò dábọ̀ náà ní ipa lórí mi ní onírúurú ọ̀nà. Mo fẹ́ láti dá wà, kí n máà sí ní sàkání àwọn ènìyàn; àmọ́ ibikíbi tí mo bá lọ, ìrora náà yóò ṣe mí níbẹ̀. Nítorí náà, ìyẹn kọ́ ni ojútùú rẹ̀ rárá. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára bíi pé apá náà jẹ́ ohun kan tí ó dá wà, tí ń pọ́n ìwàláàyè mi àti ìgbéyàwó mi lójú. Ọkọ mi kò tilẹ̀ tó láti sún mọ́ mi láti fi ìfẹ́ni hàn. Dájúdájú, ó ní sùúrù, ó sì ní ìgbatẹnirò. Mo ti di ìyàwó alápá kan, tí kò lè ṣe ohunkóhun. Ńṣe ni ara máa ń ro mí gógó bí mo bá gbìyànjú láti fi ọwọ́ òsì mi mú abala bébà kan lásán.
Títí di báyìí, kò tí ì sí ìwòsàn kankan fún àrùn RSD, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dẹwọ́ fúnra rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní àwọn ìpele tí ó kẹ́yìn, àrùn àìlágbára egungun lè wọ̀ ọ́, ọwọ́ náà yóò sì joro. Ìdí nìyẹn tí títẹramọ́ ìtọ́jú ara láìlo egbòogi fi wúlò. Lọ́nà àrìnnàkore, tèmi kò tí ì dé ìpele yẹn.
Bí Mo Ṣe Kojú Rẹ̀
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń ní ìrora, kò le tó bí ó ṣe rí ní àwọn àkókò tí ó ti burú jù lọ fún mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láìsí àwọn abẹ́rẹ́ náà, n kò ní lè forí tì í. Kí ló ràn mí lọ́wọ́ láti forí tì í? Ẹ̀mí ìrònú títọ̀nà tí àwọn dókítà, àwọn olùtọ́jú láìlo egbòogi, àti àwọn ọ̀rẹ́ ní ni. Mo tún ti kọ́ nípa àwọn ọ̀nà ti mo lè gbà kojú rẹ̀. Fún ìjámọ́ǹkan àti iyì ara ẹni mi, mo ní láti máa wà ní àwọn ipò bíbójúmu nínú ìgbésí ayé mi, láìka ipò àìgúnrégé tí mo wà sí. Wíwà láàárín àwọn alájọṣiṣẹ́ tí wọ́n ń fún mi níṣìírí, láìfìtínà mi, fi dá mi lójú pé mo ṣì lè ṣe nǹkan tó ní láárí. Mo tún mọ̀ tẹ́lẹ̀, mo sì mọ̀ síbẹ̀, pé orin atunilára àti eré ìmárale mímí tí ń mára ṣe wọ̀ọ̀ ràn mí lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí mo gbádùn láti máa ṣe ni fífẹ̀yìnlélẹ̀ ní ipò títunilára kan, kí n sì máa wo òfuurufú àti àwọn ìkùukùu tí ń yí pa dà láìdúró. Bákan náà, mo ń ṣàṣàrò, mo sì ń finú wòye àwọn ibi gbígbádùnmọ́ni. Ẹ̀rín sábà máa ń jẹ́ egbòogi tí ó dára, bí ẹ̀mí ìrònú títọ̀nà ti jẹ́—àti pàápàá jù lọ nígbà tí o bá mọ̀ pé ó ní ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́. Ó pọn dandan láti mọ̀ pé àrùn RSD kò ní láti borí rẹ. Àwọn oníṣègùn amọṣẹ́dunjú lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ìjà náà.
Ìrírí náà ti mú kí n túbọ̀ ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò fún ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ̀rora, mo sì ti ní ìṣúnniṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí n sì tù wọ́n nínú. Àwọn èrò ìgbàgbọ́ mi ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá. Mo mọ ìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀. N kì í ṣe òjìyà ìpalára kan tí a ṣà yàn. Ọlọ́run kọ́ ló lẹ̀bi. Ìrora jẹ́ ọ̀kan lára ipò ìbànújẹ́ nínú ìgbésí ayé tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Àdúrà aláápọn ti ṣàǹfààní fún mi. Mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ìrora kì yóò sí mọ́. Mo ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípa ṣíṣàjọpín èrò yẹn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn tí mo ti bá pàdé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àrùn RSD ṣì jẹ́ ìṣòro kan fún mi, mo dúpẹ́ pé ó ti sàn díẹ̀. (Ìṣípayá 21:1-4)—Bí Karen Orf ṣe sọ ọ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Èrò Dókítà Kan
Jí! fọ̀rọ̀ wá Dókítà Lefkowitz lẹ́nu wò nípa àpèjúwe tí ó lè ṣe nípa ìtọ́jú náà. Ó ṣàlàyé pé: “A máa ń bójú tó oríṣiríṣi ìrora, kì í ṣe àrùn RSD nìkan. Irú ìrora tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni ìbàdí ríro, tí ó sábà máa ń yọrí sí àrùn latanlatan aronigógó. Nígbà tí ó dájú pé ipò èrò orí máa ń jẹ́ ìpìlẹ̀ ìrora, ipò èrò orí sábà máa ń ní ipa pẹ̀lú.”
Jí!: Ṣé tọmọdétàgbà àti tọkùnrintobìnrin ni àrùn RSD lè ṣe láìdá ọ̀kan sí?
Dókítà Lefkowitz: Bẹ́ẹ̀ ni, àrùn yí kò yọ ẹ̀yà èyíkéyìí sílẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò lè sọ tẹ́lẹ̀ ẹni tí ó ṣeé ṣe jù pé kí ó ṣe. Ohun tí mo mọ̀ ni pé àwọn obìnrin sábà máa ń mú ìrora mọ́ra ju àwọn ọkùnrin lọ. Ó jọ pé wọ́n ní ipò èrò orí òun ìṣe tí ó ga láti fara da ìrora.
Jí!: Ọ̀nà wo ni o lè dámọ̀ràn pé kí a gbà ṣètọ́jú ìrora?
Dókítà Lefkowitz: Oríṣiríṣi ọ̀nà ni a lè lò, ó sinmi lórí orísun ìrora náà àti bí ó ṣe le tó. Ó ṣe tán, ìrora túmọ̀ sí ìjìyà, a sì ní láti dín ìjìyà yẹn kù. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a máa ń lo àwọn egbòogi oníhóró tí kì í mú iṣan le, bí aspirin, àti àwọn tí ó fara pẹ́ wọn. Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, bíi ti Karen, a máa ń lo àwọn egbòogi tí ń sé iṣan àgbègbè ara tí ń roni mọ́. Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó le jù, a lè lo egbòogi akunnilóorun. Ìṣòro tí ó wà nínú èyí ni pé a ní láti wà lójúfò nípa ìṣeéṣe sísọ nǹkan di bárakú.
Jí!: Ó ha jẹ́ àìṣeéyẹ̀sílẹ̀ pé kí àrùn RSD ṣeni dé gbogbo ìpele rẹ̀ bí?
Dókítà Lefkowitz: Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀. Bí a bá lè rí àrùn náà nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a lè ṣẹ́pá lílọ rẹ̀ kọjá ibi tí ó dé. Ẹ wo àpẹẹrẹ ti Karen. Ìpele àárín ni tirẹ̀ ṣì dé, kò sì di dandan pé ó lè dé ìpele tí ó kẹ́yìn, ti ọwọ́ jíjoro.
Jí!: Kí ni o lè dámọ̀ràn pé yóò ran aláìsàn kan lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro náà?
Dókítà Lefkowitz: Ní pàtó, ohun tí Karen ṣe ni. Ó ti fi ipò èrò orí gbógun ti ìrora rẹ̀ nípa ríronú àwọn ohun atunilára àti fífi ọkàn yàwòrán wọn. Ó tún ń gba ìtọ́jú láìlo egbòogi. Ó sì dá mi lójú pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ti ṣèrànlọ́wọ́ ńláǹlà. Ó ti ràn án lọ́wọ́ láti fi ojú títọ̀nà wo ìṣòro náà. Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ kó ipa pàtàkì kan.
Jí!: O ṣeun púpọ̀ fún yíyọ̀ǹda àkókò rẹ̀, o sì kúu sùúrù.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Pẹ̀lú Dókítà Lefkowitz ní ilé ìwòsàn rẹ̀