A Rí Àṣírí Bí Kòkòrò Ṣe Ń Fò
TIPẸ́TIPẸ́ ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣe kàyéfì nípa bí àwọn kòkòrò ṣe ń fò pẹ̀lú ara wọn títóbi àti àwọn ìyẹ́ wọn fífẹ́lẹ́ gan-an. Ó jọ pé àwọn ẹ̀dá tín-tìn-tín wọ̀nyí kò ka àwọn ìlànà wíwọ́pọ̀ ti ipá ìgbérasọ ohun èlò lófuurufú sí. Nísinsìnyí, àwọn olùṣèwádìí ní Yunifásítì Cambridge, England, ti rídìí bí àwọn kòkòrò ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí ó dà bíi pé kò ṣeé ṣe yìí.
Láti kọ́ nípa bí kòkòrò ṣe ń fò, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì so òwú fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan mọ́ àfòpiná kan lára, wọ́n sì fi í sínú ihò afẹ́fẹ́ kan. Wọ́n tú èéfín tí kò ní májèlé gba inú ihò náà, wọ́n sì ṣàkíyèsí bí èéfín náà ṣe ń lọ bí àfòpiná náà ti ń ju ìyẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá ṣe àgbílẹ̀rọ ẹ̀yà kan tí ó tóbi ní ìlọ́po 10, tí ń ju ìyẹ́ rẹ̀ ní ìwọ̀n tí ó fi ìgbà 100 falẹ̀ sí i, wọ́n sì wo àwọn ipa rẹ̀ tí ó ṣeé tètè fòye mọ̀ nísinsìnyí. Wọ́n ṣàwárí pé nígbà tí ìyẹ́ àfòpiná náà bẹ̀rẹ̀ sí í jù sísàlẹ̀, ó mú kí ìyíbírí, tàbí ìyípo afẹ́fẹ́, ṣẹlẹ̀ níbi tí ìyẹ́ náà ti so mọ́ ara rẹ̀. Ìyọrísí ìwọ̀n ipá rírelẹ̀ tí ó wà lókè ìyẹ́ náà mú kí kòkòrò náà lè gbéra nílẹ̀, ó sì ń fà á sókè. Bí ìyíbírí afẹ́fẹ́ náà bá kúrò níbẹ̀, àfòpiná náà yóò pàdánù agbára ìgbérasókè, yóò sì já bọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyípo afẹ́fẹ́ náà ń gba etí ìyẹ́ náà lọ sí ìhà ṣóńṣó ìyẹ́ náà, gbígbérasókè tí jíju ìyẹ́ sísàlẹ̀ náà ń mú wá, tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n kan ààbọ̀ ìwúwo àfòpiná náà, sì ń jẹ́ kí kòkòrò náà lè fò tìrọ̀rùntìrọ̀rùn.
Àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ọkọ̀ òfuurufú ti mọ̀ pé ọkọ̀ òfuurufú tí apá rẹ̀ ní ìrísí delta (tí a pè bẹ́ẹ̀ nítorí pé apá rẹ̀ jọ lẹ́tà Δ nínú èdè Gíríìkì) ń pèsè ìyíbírí afẹ́fẹ́ létí apá wọn, tí ń mú kí wọ́n gbéra nílẹ̀. Àmọ́ nísinsìnyí tí wọ́n ti mọ bí ìyíbírí afẹ́fẹ́ ṣe ń mú kí àwọn kòkòrò tí ń ju apá wọn lè gbéra nílẹ̀, wọ́n fẹ́ ṣèwádìí nípa bí wọ́n ṣe lè ṣàmúlò ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ yí nínú ṣíṣe àwọn abẹ̀bẹ̀ ayíbírí àti hẹlikópítà.