ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 11-12
  • Ọ̀nà Mẹ́fà Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Mẹ́fà Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà 6 Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ
    Jí!—2003
  • Ohun Méje Tí Ò Ní Jẹ́ Kí Oúnjẹ Léwu Táá sì Ṣara Lóore
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
    Jí!—2015
  • 2. Jẹ́ Onímọ̀ọ́tótó
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 11-12

Ọ̀nà Mẹ́fà Tí O Lè Gbà Dáàbò Bo Ìlera Rẹ

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ

GẸ́GẸ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, nǹkan bí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni kò ní omi tí ó dára. Ó lé ní ìpín 66 nínú ọgọ́rùn-ún—ó kéré tán bílíọ̀nù 2.5 ènìyàn—tí kò ní ètò ìdàdọ̀tínù tó dára tó. Ó máa ń yọrí sí àrùn àti ikú fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, wíwà ní ipò ìmọ́tótó tí ó bójú mu máa ń jẹ́ ìpèníjà. Síbẹ̀, bí o bá fi ìmọ́tótó kọ́ra, ìwọ yóò dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àrùn púpọ̀. Àwọn ohun mẹ́fà tí o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn tí wọ́n lè kó wọ ara rẹ, kí wọ́n sì fa àìsàn nìwọ̀nyí.

1. Fi ọṣẹ àti omi fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn fífọwọ́kan ìgbẹ́ àti kí o tó fọwọ́ kan oúnjẹ.

Ọ̀nà pàtàkì kan tí a lè gbà dènà àìsàn jẹ́ láti rí i dájú pé ọṣẹ àti omi ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo, kí olúkúlùkù nínú ìdílé rẹ lè máa fi fọ ọwọ́ wọn. Ọṣẹ àti omi máa ń fọ kòkòrò àrùn kúrò ní ọwọ́—àwọn kòkòrò àrùn tí ó lè wọnú oúnjẹ tàbí ẹnu bí a kò bá fọ̀ wọ́n kúrò. Níwọ̀n bí àwọn ọmọdé ti sábà máa ń ki ìka bọ ẹnu, ó ṣe pàtàkì láti máa fọ ọwọ́ wọn nígbà púpọ̀, ní pàtàkì, kí a tó fún wọn lóúnjẹ.

Ó ṣe pàtàkì gan-an láti máa fọ ọwọ́ rẹ lẹ́yìn tí o bá yàgbẹ́ tán, kí o tó fọwọ́ kan oúnjẹ, àti lẹ́yìn tí o bá ṣàndí fún ọmọ ọwọ́ tàbí ọmọdé kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yàgbẹ́ tán.

2. Máa lo ṣáláńgá.

Láti má ṣe jẹ́ kí àwọn kòkòrò àrùn gbèèràn, ó ṣe pàtàkì láti da ìgbẹ́ nù síbi tí ó tọ́. Ọ̀pọ̀ àìsàn, ní pàtàkì ìgbẹ́ gbuuru, ló ń ti inú àwọn kòkòrò àrùn tí ó wà nínú ìgbẹ́ ènìyàn wá. Àwọn kòkòrò àrùn wọ̀nyí lè dé inú omi mímu tàbí oúnjẹ, ọwọ́, tàbí inú àwọn abọ́ tí a fi ń bu oúnjẹ àti orí ibi tí a ti ń gbọ́únjẹ tàbí tí a ti ń bù ú. Nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, àwọn ènìyàn lè gbé àwọn kòkòrò àrùn náà mì, kí wọ́n sì ṣàìsàn.

Láti lè dènà èyí, máa lo ṣáláńgá. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbẹ́ àwọn ẹranko jìnnà sí ilé àti orísun omi. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ìgbẹ́ àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọ kéékèèké léwu ju ti àwọn àgbàlagbà lọ. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ pẹ̀lú bí a ṣe ń lo ṣáláńgá. Tí àwọn ọmọdé bá yàgbẹ́ síbòmíràn, a gbọ́dọ̀ kó ìgbẹ́ wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí a sì jù ú sínú ṣáláńgá tàbí kí a rì í mọ́lẹ̀.

A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ṣáláńgá máa wà ní mímọ́tónítóní, kí a sì máa bò ó.

3. Máa lo omi mímọ́tónítóní.

Àwọn ìdílé tí omi ẹ̀rọ mímọ́tónítóní ń yọ gan-an nílé wọn kì í sábà ṣàìsàn tó bí àwọn tí wọn kò ní in ti ń ṣàìsàn. Àwọn tí wọn kò ní omi ẹ̀rọ lè dáàbò bo ìlera wọn nípa bíbo kànga àti nípa ṣíṣàìgbé omi ìdọ̀tí sún mọ́ omi mímu, omi ìwẹ̀, tàbí omi ìfọǹkan. Ó tún ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn ẹranko máa wà níta, kí wọ́n sì jìnnà sídìí omi mímu.

Ọ̀nà míràn tí o lè gbà dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrùn jẹ́ láti jẹ́ kí àwọn korobá, okùn tí a fi ń fami, àti àwọn ìkòkò tí a ń pọnmi sí máa wà ní mímọ́tónítóní bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Fún àpẹẹrẹ, ó sàn láti gbé korobá kọ́ sókè ju kí a fi sílẹ̀ẹ́lẹ̀ lọ.

A gbọ́dọ̀ gbé omi mímu tí a pọn sílé sínú ohun ìpọnmisí tí ó mọ́ tónítóní, tí a sì bò. A gbọ́dọ̀ máa fi ìkéèmù tàbí kọ́ọ̀pù bu omi láti inú ohun ìpọnmisí náà. Má ṣe gba àwọn ènìyàn láyè láti ki ọwọ́ bọ omi mímu náà tàbí láti tẹnu bọ ohun ìpọnmisí náà.

4. Máa se omi mímu àyàfi bí ó bá jẹ́ omi ẹ̀rọ tí ó dára ni.

Omi tí ó dára jù lọ fún mímu sábà máa ń jẹ́ omi ẹ̀rọ. Ó ṣeé ṣe kí omi tí a pọn láti orísun mìíràn ní àwọn kòkòrò àrùn nínú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè mọ́ lójú.

Síse omi máa ń pa àwọn kòkòrò àrùn. Nítorí náà, bí o bá lọ pọn omi láti ibi adágún omi, odò, tàbí láti inú àgbá omi, ó bọ́gbọ́n mu láti sè é, kí o sì jẹ́ kí ó tutù kí o tó mu ún. Omi mímu tí kò ní kòkòrò àrùn ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé gan-an, nítorí pé ara wọn kò lágbára láti dènà kòkòrò àrùn tó àwọn àgbàlagbà.

Bí kò bá ṣeé ṣe láti se omi mímu, pọn ọ́n sínú ohun ìpọnmisí ọlọ́mọrí tí wọ́n fi ike tàbí ìgò tí ń fi inú hàn ṣe. Lẹ́yìn náà, gbé ohun ìpọnmisí náà sí gbangba nínú oòrùn fún ọjọ́ méjì kí o tó lo omi náà.

5. Jẹ́ kí oúnjẹ rẹ wà ní mímọ́.

Kí a tó jẹ oúnjẹ tí a kò ní sè, a gbọ́dọ̀ fọ̀ ọ́ dáradára. A gbọ́dọ̀ se àwọn oúnjẹ mìíràn jinná dáradára, ní pàtàkì ẹran àti adìyẹ.

Ó dára jù lọ láti máa jẹ oúnjẹ láìpẹ́ lẹ́yìn tí a bá ti sè é tán; tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní lè bà jẹ́. Bí o bá ní láti gbé oúnjẹ tí o ti sè kalẹ̀ fún àkókò tí ó ju wákàtí márùn-ún lọ, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó wà ní gbígbóná tàbí kí o gbé e sínú fìríìjì. Kí o tó jẹ ẹ́, o gbọ́dọ̀ tún gbé e gbóná dáradára.

Ẹran tútù sábà máa ń ní àwọn kòkòrò tí a kò lè fojú rí nínú, nítorí náà, o kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó kan oúnjẹ tí o ti sè. Lẹ́yìn tí o bá ṣètò ẹran tútù tán, fọ àwọn abọ́ àti àwọn orí ibi tí ó kàn ní ilé ìgbọ́únjẹ.

Àwọn orí ibi tí a ti ń gbọ́únjẹ gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́tónítóní nígbà gbogbo. A gbọ́dọ̀ máa bo oúnjẹ, kí a sì gbé e síbi tí eṣinṣin, èkúté, eku, àti àwọn ẹranko mìíràn kò ní lè dé.

6. Máa sun àwọn ìdọ̀tí tàbí kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀.

Àwọn eṣinṣin tí ń tan kòkòrò àrùn kálẹ̀ máa ń fẹ́ràn láti pamọ nínú ìdọ̀tí oúnjẹ. Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ da àwọn ìdọ̀tí sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. A gbọ́dọ̀ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀, kí a sun wọ́n, tàbí kí a wá ọ̀nà míràn láti palẹ̀ wọn mọ́ lójoojúmọ́.

Nípa ṣíṣàmúlò àwọn ìlànà wọ̀nyí, o lè dáàbò bo ara rẹ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ ìgbẹ́ gbuuru, kọ́lẹ́rà, ibà jẹ̀funjẹ̀fun, kòkòrò àkóràn, májèlé oúnjẹ, àti ọ̀pọ̀ àwọn àìsàn míràn.

[Credit Line]

Orísun: Ìwé Facts for Life, tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé, Àjọ Èto Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, àti àjọ WHO pawọ́ pọ̀ ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́