ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 13-17
  • Ẹwà Àwọn Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Níbi Òkè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹwà Àwọn Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Níbi Òkè
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Wọ́n Wà Fún
  • Onírúurú Ẹ̀dá Gbígbàfiyèsí
  • Àwọn Ohun Ọ̀gbìn Orí Òkè
  • Mìmì Ti Ń Mi Àwọn Òkè Báyìí O
    Jí!—2005
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 13-17

Ẹwà Àwọn Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Níbi Òkè

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

OMI mímọ́ gaara tí ń ṣàn nínú ìyalulẹ̀ kan, àwọn ewé tí ń rọra fẹ́ lẹ́lẹ́ nínú afẹ́fẹ́, òfuurufú tí kò ní ìkuukùu tó wà lókè, ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí ń tàn gba àárín àwọn igi. Àwọn ìran àti ìró amọ́kànyọ̀ tí a kọ́kọ́ bá pàdé nìwọ̀nyí, ó sì dá wa lójú pé, wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ìtọ́wò ìṣáájú nínú ọjọ́ títayọ kan ni. Ibo la wà? Inú Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Écrins, ní Ilẹ̀ Olókè Dauphiné, ilẹ̀ Faransé.

Ní ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà àbáwọlé ọgbà ohun alààyè náà ní Ailefroide, ní ibi àbáwọgbó náà, wọ́n gbé àwọn àmì ìsọfúnni tí ń fi hàn pé wọ́n ka àwọn ìgbòkègbodò kan, bíi pípàgọ́ tàbí dídáná nínú ọgbà ohun alààyè náà, léèwọ̀. Wọ́n rọ̀ wá láti mú pàǹtírí èyíkéyìí pa dà lọ sílé, a sì kíyè sí i pé wọ́n fòfin de mímú ajá wọ ibẹ̀, nítorí pé wọ́n sábà máa ń dẹ́rù ba àwọn ẹranko ibẹ̀, wọ́n sì ń dí wọn lọ́wọ́.

Ohun Tí Wọ́n Wà Fún

Ṣùgbọ́n kí ni ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-èdè jẹ́ gan-an, kí ni wọ́n sì wà fún? A dá Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Yellowstone, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀, sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Wyoming, ní United States, ní 1872. Láti ìgbà náà wá, a ti ṣí ọ̀pọ̀ rẹ̀ ní gbogbo kọ́ńtínẹ́ǹtì. Ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-èdè tó wà ní ilẹ̀ Faransé jẹ́ méje, mẹ́ta lára wọn wà níbi olókè tí ó dà bí àṣẹ̀ṣẹ̀lé-oṣù, tí ó lọ láti ilẹ̀ Faransé sí ilẹ̀ Austria. A dá ọgbà ohun alààyè àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Yúróòpù sílẹ̀ ní 1914, ní ẹkùn ilẹ̀ Graubünden (Grisons), Switzerland. Lẹ́yìn náà, ní 1922, a ṣí Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Gran Paradiso, ní Ítálì. Àwọn ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-èdè míràn tí ó tún wà níbi òkè tí ó dà bí àṣẹ̀ṣẹ̀lé-oṣù ni ti Berchtesgaden, ní Germany; ti Hohe Tauern, ní Austria; ti Stelvio, ní Ítálì; àti ti Triglav, ní Slovenia. Àkọ́kọ́ ọgbà ohun alààyè ti orílẹ̀ èdè ní ilẹ̀ Faransé ni ti Vanoise, tí a dá sílẹ̀ ní 1963.

Olórí ète tí a fi ń dá àwọn ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-èdè sílẹ̀ ni láti dáàbò bo àwọn ewéko àti ẹranko ní àgbègbè àdánidá. Ó yẹ kí a pàfiyèsí sí i pé àwọn ọgbà ohun alààyè púpọ̀ ló wà tí kì í ṣe ti orílẹ̀-èdè, tí wọ́n ní góńgó kan náà. Lára ìwọ̀nyí ni Ọgbà Ohun Alààyè ti Ẹkùn Ilẹ̀ ti Vercors, ní ilẹ̀ Faransé, àti Igbó Àìro ti Karwendel, ní ilẹ̀ Austria. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọgbà ohun alààyè orílẹ̀-èdè ní ipò àrà ọ̀tọ̀ kan tó fún àwọn olùṣọ́ wọn ní àṣẹ pàtó kan. A fún wọn láṣẹ láti bu owó ìtanràn lé àwọn ènìyàn tí kò bá pa àwọn òfin ọgbà ohun alààyè mọ́. Bí àpẹẹrẹ, mímú ajá wọnú ọgbà ohun alààyè kan ní Switzerland lè yọrí sí sísan owó ìtanràn tó pọ̀ tó 500 owó francs ti ilẹ̀ Switzerland (350 dọ́là ti United States).

Bóyá àwọn kan rò pé ìyẹn ti pọ̀ jù. Ṣùgbọ́n ìdí máa ń wà fún àwọn ìkàléèwọ̀ àti owó ìtanràn. Ronú lórí èyí. Nígbà kan tí a wà ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Mercantour ní Òkè Etíkun ní ìhà gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé, a bá agódóńgbó ẹtu chamois kan pàdé. Ó jọ pé ó dá wà, kò sì lólùrànlọ́wọ́ rárá. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò fọwọ́ kàn án, nítorí pé a rò pé òórùn ọwọ́ wa lè mú kí ìyá rẹ̀ má gbà á pa dà. Ṣùgbọ́n ronú nípa ohun tí ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní a mú ajá kan lọ́wọ́! Ẹtu chamois tí kò lólùrànlọ́wọ́ náà ì bá ti páyà, ní pàtàkì, bí ajá náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbó.

Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn olùṣọ́ náà wulẹ̀ jẹ́ ọlọ́pàá ọgbà ohun alààyè lásán ni bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́. Olùṣọ́ kan tí a bá pàdé nínú Ọgbà Ohun Alààyè ti Mercantour fi ibi tí agbo àwọn ẹtu chamois kan ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà kọjá hàn wá, tí ipa ẹsẹ̀ wọn sì wà lórí òjò dídì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ náà. Ó tọ́ka sí bí ipasẹ̀ náà ṣe hàn. Èyí mú kí a mọ̀ pé, ní àfikún sí dídáàbòbo ìmúwàdéédéé lọ́nà àdánidá inú ọgbà ohun alààyè náà, iṣẹ́ àwọn olùṣọ́ náà ni láti fúnni ní ìsọfúnni àti láti kọ́ni.

Onírúurú Ẹ̀dá Gbígbàfiyèsí

Bí a tún ti rìn síwájú, níbi ẹ̀bá òkè jíjìnnà kan, a rí àwọn ẹtu chamois tí ń bẹ́ kiri lórí èérún òjò dídì. A tún rí àwọn eku marmot méjì ti ń bẹ́ kiri lórí taàrá ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ náà. Ó ṣe kedere pé àwọn kan lára àwọn eku marmot wọ̀nyí ti dà bí àmúsìn, tí wọ́n ń sún mọ́ àwọn tí ń gun òkè náà, ní ríretí pé a óò fún àwọn lóúnjẹ.

Àwọn agbo ewúrẹ́ orí òkè kan ń gbé inú àwọn ọgbà ohun alààyè níbi òkè. Ibi tí wọ́n pọ̀ sí jù lọ ni Ọgbà Ohun Alààyè ti Gran Paradiso, ní Ítálì. Ó dùn mọ́ wa láti rí àwọn díẹ̀ kan ní Mercantour. Ọgbà ohun alààyè ìhà gúúsù ibi òkè yí ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹranko nínú. Àwọn àgùntàn mouflon, oríṣi àgùntàn inú ìgbẹ́ kan, ń rìn káàkiri fàlàlà, a sì tún ti ń rí àwọn ìkookò ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olùbẹ̀wò kò ní láti dààmú, nítorí àwọn ìkookò náà kì í sábà rìn nítòsí ojú ọ̀nà, wọ́n sì máa ń yẹra fún ẹ̀dá ènìyàn. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn béárì máa ń yan fanda níbi Òkè Ilẹ̀ Switzerland, ṣùgbọ́n wọ́n pa èyí tí a rí kẹ́yìn níbẹ̀ lára wọn ní 1904. Nísinsìnyí ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù, a lè rí àwọn béárì aláwọ̀ ilẹ̀ ní Pyrenees, tó wà ní ààlà ilẹ̀ Faransé àti Sípéènì; a tún lè rí wọn ní Òkè Ńlá Cantabrian, tó wà ní ìhà àríwá Sípéènì; àti ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Abruzzi, tó wà ní ẹkùn àárín Ítálì. Yàtọ̀ sí ìyẹn, o lè gbọ́ igbe akọ àgbọ̀nrín kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Switzerland, níbi tí wọ́n ti pọ̀ yanturu.

Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí àwọn ẹranko ńláńlá, ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko kéékèèké tó lè mú inú olùbẹ̀wò dùn, bí àwọn ẹranko ermine àti onírúurú ehoro, tí ń pa àwọ̀ dà di funfun nígbà òtútù, àti àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, àwọn eku marmot, àti àwọn ọ̀kẹ́rẹ́, ló wà. Láfikún sí i, ogunlọ́gọ̀ àwọn kòkòrò, títí kan àwọn labalábá aláwọ̀ mèremère àti àwọn ikán alákitiyan, ní ń gbé àwọn ẹkùn ilẹ̀ wọ̀nyí. Dájúdájú, àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹyẹ pẹ̀lú yóò rí oúnjẹ fún ojú wọn. O lè rí ẹyẹ idì tí ń fò sókè láìlo ìyẹ́ lókè fíofío, kódà ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Switzerland àti ní àwọn ọgbà ohun alààyè ti Vanoise àti ti Mercantour, o lè rí igún lammergeier, tàbí igún onírùngbọ̀n. Ó tún wọ́pọ̀ kí o máa gbọ́ ìró ìdánimọ̀ àgógó ẹyẹ àkókó tí ń sọgi bí ó ti ń wá kòkòrò kiri. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń wádìí nípa bí àwọn olùgbé orí òkè ńlá wọ̀nyí ṣe ń lè la ìgbà òtútù já lórí àwọn Òkè náà. Ara àwọn ẹranko wọ̀nyí bá àyíká yìí mu púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ipò ojú ọjọ́ búburú máa ń pa àwọn tí ara wọn kò dá àti àwọn tó ti darúgbó.

Àwọn Ohun Ọ̀gbìn Orí Òkè

A ń dáàbò bo àwọn ohun ọ̀gbìn pàápàá ní àwọn ọgbà ohun alààyè náà. Nítorí náà, èèwọ̀ ni láti já àwọn òdòdó, títí kan òdòdó lílì ọsàn aláwọ̀ mèremère, tó wà lẹ́bàá ọ̀nà tí a ń gbà. Bóyá o ń ṣe kàyéfì nípa èrèdí rẹ̀. Àwọn irúgbìn kan—bí irúgbìn edelweiss lílókìkí, irúgbìn anemone orí òkè, irúgbìn rose orí òkè, irúgbìn bluet orí òkè, àti àwọn irú ọ̀wọ́ irúgbìn gentian mélòó kan—ṣọ̀wọ́n, ó sì ṣe pàtàkì pé kí a dáàbò bò wọn kí wọ́n má baà run. Ìjónírúurú àwọn òdòdó náà jojú ní gbèsè ní tòótọ́.

Ẹwà ìṣẹ̀dá tún fara hàn kedere nínú àwọn igi tí ó wà nínú àwọn ọgbà ohun alààyè náà. Ní ìgbà ìwọ́wé, àwọn àwọ̀ olómiwúrà ti irú ọ̀wọ́ igi ahóyaya larch máa ń ṣe igbó náà lọ́ṣọ̀ọ́. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó jọ pé ipò àìbáradé ìgbà òtútù kì í rí igi arolla, tàbí igi ahóyaya ilẹ̀ Switzerland gbé ṣe, bí ó ti ń pèsè oúnjẹ láìdáwọ́dúró fún ẹyẹ tí a mọ̀ sí afọ́kóró-èso. Ẹyẹ yìí máa ń fi àpò ọ̀fun rẹ̀ kó hóró èso ahóyaya tó bá ká jọ lọ, ó sì ń rì wọ́n mọ́lẹ̀ de ìgbà tí yóò jẹ́ wọ́n lọ́jọ́ iwájú. Ó ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí igi ahóyaya náà tàn kálẹ̀ dé àwọn ibi tí kì bá tí dé bí kò bá rí bẹ́ẹ̀. Láìsí iyè méjì, a lè máa wo àwọn ohun rírẹwà tó yí wa ká látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá ní láti dé ibùgbé orí òkè náà, a gbọ́dọ̀ máa pọ́nkè wa lọ.

A ń lọ síwájú, a sì dé ipa ọ̀nà kan tí ó túbọ̀ ṣòro láìpẹ́. Ó jọ pé àwọn ẹtu chamois ń dúró dè wá nínú igbó náà, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti ya fọ́tò mélòó kan. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ti sún mọ́ wọn sí i, àwọn ẹ̀dá rírẹwà wọ̀nyí sá, ó ṣe kedere pé bí a ṣe sún mọ́ wọn ló já wọn láyà. A ronú lórí ìlérí Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀ nínú Aísáyà 11:6-9 pé: “Ìkookò yóò máa bá ọ̀dọ́ àgùntàn gbé pọ̀, kìnnìún yóò sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́; àti ọmọ màlúù àti ọmọ kìnnìún àti ẹgbọrọ ẹran àbọ́pa yóò máa gbé pọ̀; ọmọ kékeré yóò sì máa dà wọ́n. Màlúù àti béárì yóò sì máa jẹ pọ̀; ọmọ wọn yóò sì dùbúlẹ̀ pọ̀. . . . Wọn kì yóò pani lára, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò pani run ní gbogbo òkè mímọ́ mi.” A láyọ̀ pé a ní ìfojúsọ́nà pé láìpẹ́, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di párádísè kíkàmàmà kan tí ó dà bí ọgbà ohun alààyè, níbi tí ènìyàn àti ẹranko yóò ti máa gbé pọ̀ láìsí ìbẹ̀rù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹtu “chamois” kan ní ibùgbé àdánidá rẹ̀ ní àwọn Òkè ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Eku “marmot” oníṣọ̀ọ́ra kan ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Vanoise, ní ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Ẹyẹ idì kan ní Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè ti Mercantour, ní ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹtu “chamois” ń pọ́nkè ní àwọn Òkè ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ọmọ ẹtu “chamois”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Òdòdó “rose” orí òkè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Òdòdó “artichoke” inú ìgbẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ancolie des Alpes

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ewúrẹ́ orí òkè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Òdòdó lílì ọsàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Òdòdó lílì fìlà ará Turkey

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Panicaut des Alpes

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Eku “marmot”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́