Iṣẹ́ Rẹ Ń Sú Ọ Bí?
BÓYÁ nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ lo fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́. Àkókò àti ìgbésí ayé yẹn ti pọ̀ ju ohun tí a jẹ́ fi ṣe ohun tí ń súni lọ! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí a ń ṣe ní ọ̀rúndún ogún wà bákan náà ṣáá láìsí ìyípadà, kò sì fún òṣìṣẹ́ ní ohun púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti fi ṣògo.
Nítorí náà, o lè jàǹfààní púpọ̀ nípa mímú kí iṣẹ́ rẹ gbádùn mọ́ ọ. Ayọ̀ rẹ ń pọ̀ sí i nípa ṣíṣiṣẹ́, o sì ń mọ àṣírí mímú kí iṣẹ́ yòó wù kí o ṣe lọ́jọ́ iwájú gbádùn mọ́ ọ. Jẹ́ kí a wá ṣàwárí àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí o lè gbà ṣàṣeyọrí èyí.
Máa Túra Ká
Àwọn orísun ìsọfúnni kan dámọ̀ràn pé kí o máa ṣe iṣẹ́ bíi pé o ń gbádùn rẹ̀. Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn rẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kí o dáhùn pé, ‘Ṣùgbọ́n n kò lè túra ká nípa iṣẹ́ mi láé!’ Iṣẹ́ rẹ lè rọ̀ mọ́ ìlànà tí kò gba gbẹ̀rẹ́, bíi ṣíṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ tí ń gbé iṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan lọ sọ́dọ̀ ẹnì kejì títí iṣẹ́ yóò fi parí. Tàbí ó lè jẹ́ pé o ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ rẹ tó bẹ́ẹ̀ tí o fi rò pé kò ṣeé ṣe láti sọ ọkàn ìfẹ́ rẹ nínú rẹ̀ dọ̀tun. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọgbọ́n rírọrùn bíi rírẹ́rìn-ín músẹ́ àti híhùwà àìlábòsí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ túra ká nípa iṣẹ́ rẹ.
Pípọkànpọ̀ pátápátá sórí ohun tí o ń ṣe tún lè gbéṣẹ́. Má wulẹ̀ máa ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rọ lásán, má sì máa ṣiṣẹ́ lákòókò kan náà tí o ń ronú lórí àkókò oúnjẹ, òpin ọ̀sẹ̀, tàbí iṣẹ́ mìíràn tí ó wà láti ṣe pàápàá. Ó bọ́gbọ́n mu lọ́pọ̀ ìgbà láti pọkàn pọ̀ pátápátá sórí iṣẹ́ tí o ń ṣe lọ́wọ́. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? O lè wá gbádùn iṣẹ́ náà, yóò sì wá dà bíi pé àkókò ń sáré tete.
Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nìyí bí o bá ń ṣe ohun kan tí o fẹ́ràn gidigidi. O lè ṣàṣeyọrí ohun kan náà nípa fífipá mú ara rẹ láti pọkàn pọ̀ pátápátá sórí iṣẹ́ tí kì í fìgbà gbogbo dùn mọ́ ọ.
Ṣe Gbogbo Ohun Tí O Lè Ṣe
Ṣíṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe lè mú kí o ní ìtẹ́lọ́rùn lẹ́nu iṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí èrò lílókìkí náà pé bí iṣẹ́ kan kò bá dùn mọ́ ọ, má ṣe lo ara sí i púpọ̀. Ṣùgbọ́n, ó ṣeé ṣe kí àìnáání, ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la, àti ìkẹ́ralò tán ọ lókun, kí ó sì fi kún hílàhílo àti àárẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ńṣe ni ẹni tó sábà máa ń tibi iṣẹ́ dé, tí ó ń ṣàìlókun, tí ó ń ní hílàhílo, tí ó sì ń ṣàárẹ̀, ti kùnà láti ṣiṣẹ́ taápọntaápọn.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, fífi tọkàntara ṣe iṣẹ́ kan ń mú kí àkókò ìsinmi túbọ̀ gbádùn mọ́ni. “Kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju kí ó jẹ, kí ó sì mu àti kí ó mú ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere nínú làálàá rẹ̀.” (Oníwàásù 2:24) Èyí lè jọ àkọmọ̀nà tí kò bágbà mu lójú àwọn kan, ṣùgbọ́n àwọn kan ṣì ń tẹ̀ lé ìlànà tí kò mọ sí sáà kan yìí. Wọ́n gbà pé, ní tòótọ́, ‘kò sí ohun tí ó dára ju’ kí wọ́n jadùn èso làálàá wọn lọ. Ìwé náà, The Joy of Working, sọ pé: “Iṣẹ́ tí a ṣe yanjú dáradára ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn inú lọ́hùn-ún.”
Nítorí náà, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe, ó sì ṣeé ṣe kí o nímọ̀lára níní okun. Ṣe ju ìwọ̀n kékeré kan lọ, ìwọ sì lè láyọ̀ sí i. Kọ́kọ́ ṣe àwọn iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù, ìwọ yóò sì gbádùn àwọn àkókò ìsinmi oúnjẹ àti àwọn òpin ọ̀sẹ̀ rẹ ju ẹni náà tí ń fi ìfònídónìí-fọ̀ladọ́la tán ara rẹ̀ lókun lọ.—Fi wé Ẹ́sítérì 10:2; Róòmù 12:11; Tímótì Kejì 2:15.
Dípò bíbá àwọn ẹlòmíràn díje, gbìyànjú láti lo ara rẹ dé góńgó. (Gálátíà 6:4) Gbé ọ̀pá ìdíwọ̀n tuntun, góńgó ìlépa tuntun kalẹ̀. Gbìyànjú láti túbọ̀ ṣe dáradára sí i. Obìnrin kan, ti iṣẹ́ rẹ̀ wé mọ́ ríránṣọ ní gbogbo ìgbà, tí àwọn ẹlòmíràn yóò kà sí ohun tí ń súni ṣáá, sọ dídá àkókò fúnra rẹ̀ di eré àṣedárayá kan. Ó ṣàkọsílẹ̀ bí ó ti ń ṣiṣẹ́ tó ní wákàtí kọ̀ọ̀kan, ó sì wá gbìyànjú láti ṣàfikún rẹ̀. Ní gidi, ó ń gbádùn iṣẹ́ rẹ̀ nítorí pé ó ń gbìyànjú láti lo ara rẹ̀ dé góńgó.—Òwe 31:31.
“Gbé” Iṣẹ́ Rẹ “Lárugẹ”
Àwọn Ọ̀mọ̀wé Dennis T. Jaffe àti Cynthia D. Scott dámọ̀ràn pé: “Máa ronú iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ilé kan tó ṣófo. O kó sínú rẹ̀, o sì wo ìrísí àti ìgbékalẹ̀ rẹ̀. Ó wá ru agbára ìhùmọ̀ rẹ sókè. O ṣàgbékalẹ̀ bí o ṣe fẹ́ lo àyè náà, o ṣe ilé náà lọ́ṣọ̀ọ́, o sì sọ ọ́ di ibùgbé rẹ. O sọ ọ́ di tìrẹ nípa fífún un ní ìrísí tó wù ọ́.”
A sábà máa ń gbéṣẹ́ fúnni pẹ̀lú àpèjúwe àwọn òfin àti ìlànà. Wíwulẹ̀ ṣe ohun tí a retí kí o ṣe dà bíi gbígbé inú òfìfo ilé. Kò sí ohun tí ń fi bí o ti jẹ́ hàn. Ṣùgbọ́n bí o bá fi ọ̀nà ti ara rẹ kún un, iṣẹ́ rẹ lè di èyí tí ń gbádùn mọ́ ọ gan-an. Ènìyàn méjì kò jẹ́ “gbé” iṣẹ́ kan “lárugẹ” lọ́nà kan náà. Agbáwo kan yóò máa kọ́ ohun tí àwọn oníbàárà ń béèrè sórí. Òmíràn yóò ní inúure, yóò sì bọ̀wọ̀ fúnni lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Àwọn méjèèjì ń gbádùn iṣẹ́ wọn nítorí pé wọ́n ń fi tọkàntara ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó
Ọ̀nà míràn láti láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ni kíkẹ́kọ̀ọ́. Ìwé náà, Tension Turnaround, sọ pé, bí a ti ń dàgbà, ọpọlọ wa ń mú kí agbára rẹ̀ láti ṣàtúpalẹ̀ ìsọfúnni pọ̀ sí i. Èyí ṣàlàyé ìdí tí àwọn ohun tó dùn mọ́ wa tẹ́lẹ̀ rí fi lè máa sú wa nísinsìnyí. Ojútùú tó wà ni pé kí a máa tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ọpọlọ náà láti gba ìsọfúnni tuntun lọ́rùn nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun tuntun.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa iṣẹ́ rẹ lè mú kí a fún ọ ní iṣẹ́ tó túbọ̀ fà ọ́ lọ́kàn mọ́ra láìpẹ́. Ká ní ìyẹn kò tilẹ̀ ṣẹlẹ̀, ìgbésẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fúnra rẹ̀ yóò túbọ̀ mú kí iṣẹ́ rẹ gbádùn mọ́ ọ, kí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn. Àwọn òǹkọ̀wé Charles Cameron àti Suzanne Elusorr tọ́ka sí i pé: “Yàtọ̀ sí pé kíkẹ́kọ̀ọ́ ń mú ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ pọ̀ sí i nípa ṣíṣàlékún agbára ìlèṣeǹkan rẹ, ó tún ń nípa lórí àpapọ̀ ìṣarasíhùwà rẹ sí ìgbésí ayé: pé o lè rí ojútùú sí àwọn ìṣòro, o lè borí àwọn ìṣòro, o lè dín ìbẹ̀rù kù, àti pé ọ̀pọ̀ nǹkan tí o kò lè ronú kàn ló ṣeé ṣe.”
O lè ṣàtakò pé, ‘Ṣùgbọ́n, mo ti kọ́ gbogbo ohun tó yẹ kí n mọ̀ nípa iṣẹ́ mi nígbà kan rí!’ Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ o lè kọ́ àwọn ohun tí kò bá iṣẹ́ rẹ tan ní tààràtà bí? Bí àpẹẹrẹ, o lè pinnu láti túbọ̀ kọ́ nípa àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn tàbí nípa ohun èlò iṣẹ́ rẹ. Bóyá o lè kọ́ nípa bí o ṣe lè kọ ìwé ìsọfúnni níbi iṣẹ́ lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i tàbí bí o ṣe lè darí ìpàdé lọ́nà tó sunwọ̀n sí i. O lè kọ́ àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ láti bá àwọn alábòójútó iṣẹ́ rẹ ṣiṣẹ́.
Báwo ni o ṣe lè kọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ó lè jẹ́ pé ilé iṣẹ́ tí o ń bá ṣiṣẹ́ ń pèsè àwọn ètò ẹ̀kọ́ tí o wà nípò láti gbà. Tàbí ibi ìkówèésí kan lè ní àwọn ìwé tí o nílò gẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n má ṣe gbójú fo àwọn orísun ìsọfúnni tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn gbangba. Wíwo àwọn ènìyàn lẹ́nu iṣẹ́ ní kíkíyèsí bí wọ́n ṣe gbéṣẹ́ àti bí wọ́n ṣe ṣàìgbéṣẹ́ tó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ kan. O lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àṣìṣe rẹ, o sì lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àṣeyọrí rẹ pẹ̀lú, nípa ṣíṣàtúpalẹ̀ àwọn ohun tí o ṣe bó ti yẹ. Ohun tí o kọ́ láti inú ìrírí ara rẹ àti láti inú kíkíyèsí àwọn ẹlòmíràn lè kọ́ ọ ní ohun tí o lè máà rí kà nínú ìwé tàbí gbọ́ ní kíláàsì.
Àwọn Ìdámọ̀ràn Ìkẹyìn
Ọ̀nà míràn kan wà tí o lè gbà ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ rẹ. O lè pinnu pé ohun tí o lẹ́tọ̀ọ́ sí pọ̀ ju ohun tí o rí gbà lọ—pé àwọn mìíràn ní ń jẹ gbogbo àǹfààní náà, àti pé a kò fún ọ láǹfààní rí láti ṣe iṣẹ́ tí o ń fẹ́ láti ṣe gan-an. O lè lo àkókò púpọ̀ ní bíbá àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n fara mọ́ ọ jíròrò, ó sì lè wá dá ọ lójú pé gbogbo èyí jẹ́ òtítọ́.
Ṣùgbọ́n ó lè ṣàìjóòótọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń gbádùn iṣẹ́ wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹnì kan tí ń gbádùn kíkun ilé tún lè wá gbádùn wíwa bọ́ọ̀sì. Èé ṣe? Nítorí pé ọ̀nà ìṣeǹkan oníhùmọ̀ tí ó ń gbà ṣiṣẹ́ ń fún un ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.
Nítorí náà, já ara rẹ gbà lọ́wọ́ ìrònú òdì tí ń mú kí àkókò iṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ má ṣe máyọ̀ wá bí òpin ọ̀sẹ̀. Má fi àkókò ṣòfò ní ríronú lórí àwọn ìkùnà rẹ àtijọ́, ní ríronú lórí àṣìṣe tí yóò tún ṣẹlẹ̀ àti ní dídààmú nípa ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń rò nípa rẹ. Wo iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ. Pa gbogbo ọkàn rẹ pọ̀ sórí rẹ̀. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ó gbà ọ́ lọ́kàn lọ́nà kan náà tí ohun àṣepawọ́dà tí o fẹ́ràn jù lọ yóò fi gbà ọ́ lọ́kàn. Sa gbogbo ipá rẹ lórí rẹ̀, síbẹ̀, máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ tí o bá ṣe yọrí.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Má Ṣàìnáání Iṣẹ́ Rẹ
Nínú Òwe 27:23, 24, Bíbélì wí pé: “Ìwọ máa ṣàníyàn àtimọ ìwà agbo ẹran rẹ, kí ìwọ kí ó sì bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ. Nítorí pé ọrọ̀ kì í wà títí láé: adé a ha sì máa wà dé ìrandíran?” Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?
Ó túmọ̀ sí pé ọrọ̀ (ìṣúra) àti ipò ọlá (adé), bí a bá tilẹ̀ ní in, sábà máa ń wà fún ìgbà díẹ̀. Nítorí náà, ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì, olùṣọ́ àgùntàn kan tó bá pọkàn pọ̀ dáradára sórí bíbójútó agbo ẹran rẹ̀ taápọntaápọn, ìyẹn ni pe, tó ń ‘bójú tó àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀,’ fi ọgbọ́n hàn. Bí àwọn ẹsẹ mẹ́ta tó tẹ̀ lé e ti fi hàn, ìyọrísí rẹ̀ yóò jẹ́ ànító ohun ìní fún òṣìṣẹ́ náà àti àwọn ará ilé rẹ̀.—Òwe 27:25-27
Lónìí ńkọ́? Àwọn ènìyàn sábà ń gbọ́kàn wọn lé níní ọrọ̀ jaburata tàbí ipò ọlá, tí wọ́n retí pé, yóò mú kí wọ́n lè fi iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ sílẹ̀. Àwọn kan ní ìwéwèé tó lè dòótọ́; àlá lásán làwọn mìíràn ń lá. Ìyówù kó jẹ́, kò bọ́gbọ́n mu láti pẹ̀gàn iṣẹ́ tí ẹnì kan ní lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí láti ṣàìnáání rẹ̀. Òun ni ọ̀nà ìpawówọlé tó ṣeé gbára lé jù lọ, ó sì lè máa jẹ́ bẹ́ẹ̀ nìṣó. Ó túbọ̀ lọ́gbọ́n nínú jù fún ẹnì kan láti máa bójú tó “àwọn ọ̀wọ́ ẹran” rẹ̀, ní dídarí gbogbo àfiyèsí sórí ọ̀nà iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ tó ṣeé gbára lé. Ó ṣeé ṣe kí ṣíṣe tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ mú ànító ohun ìní wá nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.