“Oníbàárà Ní Ń Tọ̀nà”
GẸ́GẸ́ BÍ WEI TUNG CHIN ṢE SỌ Ọ́
Ọkọ mi máa ń sọ fún mi pé n kò gbọ́dọ̀ fetí sí “àwọn ẹlẹ́sìn tí ń kanlẹ̀kùn ilé kiri wọ̀nyẹn.” Nítorí náà, nígbà tó wù kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sẹ́nu ọ̀nà wa, mo wulẹ̀ ń sọ pé a kò fẹ́ gbọ́. Àmọ́ ó tún sọ fún mi pé “oníbàárà ní ń tọ̀nà,” nítorí náà, nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan wá sílé àrójẹ wa, Red Dragon, tó sì fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ nípa ìsìn rẹ̀, mo rò pé, mo gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí i.
ỌKỌ mi, Tong Y., ló ni Red Dragon, ilé àrójẹ kan tí ń ta oúnjẹ ilẹ̀ China, ní Òpópó St. Clair, ní Cleveland, Ohio. Lẹ́yìn tí a ṣègbéyàwó, níbẹ̀ ló ti kọ́ mi ní àkọmọ̀nà náà, “Oníbàárà ní ń tọ̀nà.”
T.Y. ti wá sí Amẹ́ríkà láti kẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì New York. Nígbà tí ó jáde ní 1927, ó lọ ṣiṣẹ́ ní ilé àrójẹ kan ní àdúgbò Gbàgede Times ní New York. Ó ṣàkíyèsí bí àwọn ènìyàn ṣe ń dúró jẹun lórí tábìlì ìtajà ilé ìtoògùn àti àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn, níbi tí àwọn ìgbékalẹ̀ ìgbọ́únjẹ kò ti tó nǹkan. Nítorí náà, ó ronú láti máa ta ọbẹ̀ chow mein gbígbóná fún wọn.
Láìpẹ́, òwò ilé àrójẹ kékeré tó dá sílẹ̀ ní Abúlé Greenwich bú rẹ́kẹ. Ní 1932, ó gbégbá òwò rẹ̀ lọ sí Cleveland, Ohio, ó sì ṣí Red Dragon, tó lè gba 200 ènìyàn. Ìwé agbéròyìnjáde kan ní Cleveland ròyìn ní September 1932 pé: “Bí Tong Y. Chin ti ń gbégbá òwò rẹ̀ wọ àgbègbè Great Lakes lẹ́yìn tí ó ti tẹ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ènìyàn lọ́rùn jákèjádò ìhà ìlà oòrùn, ó ti dá irú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́, tí ó ti sọ di ńlá láàárín ọdún márùn-ún débi tí ó ń pa mílíọ̀nù dọ́là lọ́dún, sílẹ̀ ní ìhà agbedeméjì ìwọ̀ oòrùn, bí ó ti ń ta ọbẹ̀ chow mein gbígbóná, ní Cleveland.”
Kí n tó ṣàlàyé bí èmi àti T.Y. ṣe pàdé, ẹ jẹ́ kí n sọ bí mo ṣe dàgbà ní China, tó nípa gidigidi lórí ìgbésí ayé mi.
Ìbẹ̀rẹ̀ Ìgbésí Ayé Nípò Àìní
Ohun tí mo lè rántí nípa ìbẹ̀rẹ̀ náà ni bí Màmá ṣe ń jáde ní abúlé wa kékeré ní àárín orílẹ̀-èdè China láti wá oúnjẹ lọ. Àwọn òbí mi ṣaláìní tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ní láti gbé àwọn kan lára àwa ọmọ wọn sílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ nǹkan bí ọdún méjì tàbí mẹ́ta, Bàbá darí wálé, ìrísí ojú rẹ̀ sì rí bákan ṣáá. Mo ronú pé, ‘Ìròyìn búburú kan wà fún mi.’
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, Màmá fà mí lọ́wọ́, a sì rìn gba ọ̀nà ẹsẹ̀-ò-gbèjì, ẹlẹ́rọ̀fọ̀ kan, láàárín ilẹ̀ àbàtà, tí a ń ṣọ́ra kí a má ṣubú sínú omi níhà tọ̀túntòsì. A dúró nílé kan, níbi tí Màmá ti bá ọmọbìnrin kan tí ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sọ̀rọ̀, lẹ́yìn náà, ní ilé mìíràn níbi tí ọ̀dọ́mọbìnrin kan ti rojú koko láìrẹ́rìn-ín. N kò rántí bóyá mo ti rí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí rí. Ẹ̀gbọ́n mi ni wọ́n. Bí wọ́n ti ń dá gbére fún mi, mo nímọ̀lára pé, a kì yóò túnra rí mọ́.
Bí a ti ń lọ, màmá mi fìdájú sọ̀rọ̀, ní sísọ nípa ara rẹ̀, bàbá mi, àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi, fún mi. Mo ṣì lè wòye rí ojú Màmá tó ń fi inúure àti ìkáàánú hàn. Nígbà tí a dé ibi tí a ń lọ, ó jọ pé nǹkan kò rí bí a ti retí. Ó jọ pé ilé náà bani lẹ́rù, ó sì bani nínú jẹ́. Ilé mi tuntun nìyí. N kò fẹ́ sùn, ṣùgbọ́n màmá mi àti àwọn òbí tó gbà mí ṣọmọ rẹ̀ mí tẹ́. Láìpẹ́, mo sùn lọ, nígbà tí mo sì jí, Màmá ti lọ. N kò tún pa dà rí i mọ́.
Ìgbà Ọmọdé Bíbaninínújẹ́
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tí ó tó ti wà nísinsìnyí, ìfẹ́ tí ó tó kò sí, omijé sì kún ọkàn àyà mi. Àràárọ̀ ni mo máa ń jí sunkún. Aáyun Màmá àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ń yun mí. Nígbà púpọ̀ ni mo máa ń ronú láti pa ara mi. Nígbà tí mo dàgbà tó, mo fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n àwọn òbí tó gbà mí ṣọmọ dá mi dúró sílé láti máa ṣiṣẹ́.
Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, a kó lọ sí Shanghai jíjìnnà. Wọ́n sọ fún mi pé: “Ní báyìí, o ti dàgbà tó láti máa lọ rajà kí o sì máa gbọ́únjẹ.” Nítorí náà, wọ́n fi àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí kún iṣẹ́ ojúmọ́ mi. Lójoojúmọ́, àwọn òbí tó gbà mí ṣọmọ yóò fún mi lówó púpọ̀ tó láti ra oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mẹ́ta. Nígbà tí mo bá ń lọ sọ́jà, mo máa ń kọjá lára àwọn oníbáárà, àánú wọn sì máa ń ṣe mí nítorí pé ebi ń pa wọ́n. Nítorí náà, mo máa ń tiraka fún wọn ní owó wẹ́wẹ́ kan tàbí méjì, síbẹ̀, mo ń ní ànító láti fi ra oúnjẹ tí mo nílò.
Ẹ wo bí mo ti fẹ́ láti lọ sílé ẹ̀kọ́ kí n sì kẹ́kọ̀ọ́ tó! Àwọn òbí tó gbà mí ṣọmọ ṣèlérí pé: “Ní oṣù mẹ́fà sí i, a óò forúkọ rẹ sílẹ̀.” Nígbà tí àkókò náà kọjá, wọ́n sọ fún mi pé: “Ní oṣù mẹ́fà sí ìsinsìnyí.” Bí àkókò ti ń lọ, mo wá mọ̀ pé wọn kò ní rán mi lọ sílé ẹ̀kọ́. Ọkàn mí dà rú. ẹ̀ bá mi. Mo wá kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbé inú ilé náà. Nígbà púpọ̀, n ó ti ara mi mọ́ ilé ìwẹ̀, n ó sì gbàdúrà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gba ọ̀pọ̀ ọlọ́run gbọ́, lọ́nà kan ṣáá, mo mọ̀ pé Ọlọ́run pàtàkì kan wà, tó lágbára ju gbogbo àwọn tó kù lọ. Nítorí náà, mo gbàdúrà sí i pé: “Èé ṣe tí ìrora àti ìbànújẹ́ fi pọ̀ tó báyìí?” Àdúrà tí mo ń gbà lọ́pọ̀ ọdún nìyẹn.
Ìgbéyàwó Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà
Àwọn ìgbéyàwó tí a báni ṣètò rẹ̀ wọ́ pọ̀ ní China nígbà yẹn. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ T. Y. ní yunifásítì, tó ti pa dà sí China, kọ̀wé sí i pé: “O ti lé ní ọmọ 30 ọdún, o sì jẹ́ àpọ́n síbẹ̀.” Ó wá sọ̀rọ̀ nípa mi, ó sì fi kún un pé: “Ọmọ ọdún 18 ni; ìrísí ojú rẹ̀ fani mọ́ra, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwà rẹ̀. . . . Tong Y. Chin, ì bá ṣèmi nìwọ ni, ǹ bá ronú nípa rẹ̀ gidigidi.” Ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi fọ́tò kan sí i.
T. Y. kọ̀wé sí àwọn òbí tó gbà mí ṣọmọ pé: “Mo ti rí fọ́tò ọmọbìnrin yín oníwàrere. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí a bá ti pàdé, tí a sì jọ lo àkókò díẹ̀ pọ̀, ìfẹ́ gbèrú nínú ọkàn wa, èmi yóò fẹ́ ẹ.” T. Y. wá sí Shanghai, a sì pàdé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rò pé ó ti dàgbà jù fún mi, mo pinnu pé, ó kéré tán, ṣíṣe ìgbéyàwó yóò mú kí n lè jáde nílé náà. Nítorí náà, a ṣègbéyàwó ní 1935, a sì wọkọ̀ òkun lọ sí Amẹ́ríkà lọ́gán. Bí mo ṣe dé Cleveland nìyẹn.
Àwọn Ìṣòro Lílekoko Láìka Níní Ọrọ̀ Sí
Ní ìbẹ̀rẹ̀, a ní ìṣòro ìbára-ẹni-sọ̀rọ̀. Ọkọ mi ń sọ ẹ̀ka èdè China kan, Cantonese, èmi sì ń sọ òmíràn, Shanghaiese. Ńṣe ló dà bíi pé a ń sọ èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Mo tún ní láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àwọn àṣà ìbílẹ̀ tuntun. Iṣẹ́ mi tuntun ńkọ́? Mo gbọ́dọ̀ jẹ́ obìnrin olùgbàlejò ilé oúnjẹ, tí ń tẹ́ni lọ́rùn, tó sì ń bọ̀wọ̀ fúnni, tó ń fẹ́ láti tẹ́ àwọn oníbàárà lọ́rùn nígbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni, mo ní láti máa rántí pé, “Oníbàárà ní ń tọ̀nà.”
Lójúmọ́, èmi àti ọkọ mi ń ṣiṣẹ́ wákàtí mẹ́rìndínlógún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kárakára, tí oyún sì ń wà nínú mi lọ́pọ̀ ìgbà. A bí Gloria, àkọ́bí wa obìnrin, ní 1936. Lẹ́yìn náà, mo bí ọmọ mẹ́fà láàárín ọdún mẹ́sàn-án—ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin mẹ́ta sí i, tí ọ̀kan nínú wọn kú lọ́mọ ọdún kan péré.
Láàárín àkókò kan náà, T. Y. ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ilé àrójẹ àti ilé ìgbafàájì alaalẹ́. Ọ̀pọ̀ òṣèré tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré ní àwọn ibi wọ̀nyí, bíi Keye Luke, Jack Soo, àti Kaye Ballard, wá di olókìkí òṣèré. Bákan náà ni a ń ta àwọn oúnjẹ China wa káàkiri, wọ́n sì wá lókìkí.
Nígbà tí àwọn ọdún 1930 fi dé ìdajì, a ti mọ T. Y. sí ọ̀gá ọlọ́bẹ̀ chow mein. Ó tún jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Oníṣòwò Ọmọ Ilẹ̀ China àti olùdánilẹ́kọ̀ọ́ kan nípa China. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ọ̀pọ̀ àlámọ̀rí ọrẹ àánú, àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, ìlú ìbílẹ̀, àti ti àwùjọ. Fífarahàn ní gbangba àti yíyan bí ológun aláṣehàn di apá kan ìgbésí ayé mi. Àwòrán wa àti orúkọ wa wá di ohun tó wọ́pọ̀ nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde ní Cleveland; ó jọ pé gbogbo ohun tí a bá ṣe tàbí tí a sọ ni ìròyìn ń gbé—láti orí àwọn ìdáwọ́lé ìṣòwò dé orí àkókò ìsinmi, àti kódà, ìwọ̀n bàtà ẹsẹ̀ mi pàápàá!
Ní 1941, tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun òfuurufú ilẹ̀ Japan fi bọ́ǹbù fọ́ Pearl Harbor, ilẹ̀ United States bá Japan jagun. Nítorí pé a jẹ́ ará Ìlà Oòrùn, a nírìírí ẹ̀tanú. Kódà, ṣáájú ogun náà, a gba àwọn lẹ́tà ìhàlẹ̀ ikú nígbà tí a ń kọ́ ilé wa ńlá sí àgbègbè àdúgbò pàtàkì kan. Ṣùgbọ́n a parí rẹ̀, a sì tọ́ àwọn ọmọ wa dàgbà nínú rẹ̀.
Nítorí náà, mo ní ilé mèremère kan tó láyè gan-an, ọkọ àti ìdílé kan tó lọ́wọ̀, àní, àwọn aṣọ àti ohun ọ̀ṣọ́ rírẹwà. Síbẹ̀, mo ń wà láìláyọ̀ nìṣó. Èé ṣe? Ìdí kan ni pé a kì í ní àkókò púpọ̀ láti wà pọ̀ bí ìdílé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń tiraka láti jí, kí n rí àwọn ọmọ kí wọ́n tó lọ sílé ẹ̀kọ́ láràárọ̀, ẹnu iṣẹ́ la máa ń wà nígbà tí wọ́n bá ń lọ sùn. Olùtọ́jú ilé kan ní ń bójú tó àwọn àìní wọn ojoojúmọ́.
Onísìn Búdà ni wá, síbẹ̀ àwọn ọlọ́run ìsìn wa kò fún mi ní ìtùnú. T.Y. àti ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù yóò lọ káàkiri inú ilé, wọn yóò tan àbẹ́là síwájú àwọn ère, wọn yóò gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, kí àwọn ọlọ́run lè jẹun. Ṣùgbọ́n wọn kò jẹ ẹ́ rí, nítorí náà, àwọn ọmọ ni yóò wá jẹ oúnjẹ náà fúnra wọn níkẹyìn.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, tí gbogbo rẹ̀ sú mi, tí n kò sì rí ojútùú kankan, mo ronú pé ìdílé mi yóò túbọ̀ láyọ̀ láìsí mi níbẹ̀. Ìdààmú bá mi pátápátá, mo sì gbìyànjú láti pa ara mi. Mo dúpẹ́ pé wọ́n sáré gbé mi lọ sílé ìwòsàn, mo sì kọ́fẹ pa dà.
A Dáhùn Àwọn Àdúrà Mi
Lákòókò kan lẹ́yìn náà, ní 1950, obìnrin kan tó ní irun funfun rírẹwà àti ọkọ rẹ̀ wọ ilé àrójẹ náà wá. Bí mo ti ń kí wọn káàbọ̀ tí mo sì ń rí sí i pé wọ́n jókòó lọ́nà tó tẹ́ wọn lọ́rùn, obìnrin náà bá mi sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. N kò fẹ́ gbọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń wá sílé, wọ́n sì ti ń gbìyànjú láti bá mi sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n mo máa ń lé wọn lọ lójú ẹsẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ilé àrójẹ, ipò náà yàtọ̀—“Oníbàárà ní ń tọ̀nà!”
Obìnrin náà, Helen Winters, béèrè bóyá mo gba Bíbélì gbọ́. Mo dáhùn pé: “Bíbélì wo? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀ ló wà!” Nígbà kọ̀ọ̀kan tó bá pa dà wá, mo máa ń rò nínú ara mi pé, ‘Ayọnilẹ́nu yẹn ló tún ń bọ̀ yí!’ Àmọ́ ó ní inúure àti ìforítì. Ó sì jọ pé ohun tí ó sọ nípa párádísè ilẹ̀ ayé kan, níbì tí kò ti ní sí ìrora tàbí ìjìyà mọ́, wọni lọ́kàn.—Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.
Nígbà ìbẹ̀wò kan tó ṣe, ó fi ìwé ìkésíni kan sílẹ̀ pé kí n wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì tọ́ka sí ìsọfúnni kúkúrú tó wà lẹ́yìn ìwé náà, tó ṣàpèjúwe àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. Mo rántí bí mo ti yẹ̀ ẹ́ wò lẹ́yìn náà, tí mo sì ronú pé, ‘Ì bá lè jẹ́ bẹ́ẹ̀!’ Ó ní òun yóò fẹ́ láti máa bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé, mo sì gbà níkẹyìn.
Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni a ń kóra jọ yí tábìlì wa ká fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà—èmi pẹ̀lú àwọn ọmọ mi mẹ́fẹ̀ẹ̀fà, tí ọjọ́ orí wọn nígbà náà jẹ́ ọdún 5 sí 14, àti Helen. Àánú obìnrin náà máa ń ṣe mí lọ́pọ̀ ìgbà nítorí ó máa ń jọ pé àwọn ọmọ kì í lọ́kàn ìfẹ́ nígbà míràn. Ní 1951, a bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Láìpẹ́, mo mọ̀ pé àwọn ohun tí mo ń kọ́ jẹ́ ìdáhùn sí àwọn àdúrà mi. Nítorí náà, mo pinnu pé ní gidi, mo gbọ́dọ̀ kọ́ láti ka èdè Gẹ̀ẹ́sì dáradára, tó jẹ́ ìpèníjà lílekoko kan fún mi.
Rírí Ojúlówó Ayọ̀
Láìpẹ́, ìmọ̀ mi bẹ̀rẹ̀ sí í yára pọ̀ sí i, mo sì ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ní October 13, 1951, ní àpéjọpọ̀ ńlá kan ní Washington, D.C., èmi àti àwọn ọmọ mi méjì tó dàgbà jù, Gloria àti Tom, ṣèrìbọmi. Fún ìgbà àkọ́kọ́, ìgbésí ayé mi ń nítumọ̀. Ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún tí mo ti láyọ̀ jù lọ.
Mo ti fi gbogbo ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá ṣiṣẹ́ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn míràn, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo pinnu láti ṣiṣẹ́ sin Ẹlẹ́dàá wa ṣáájú ohunkóhun! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá gbogbo ẹni tí yóò bá fetí sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ṣàjọpín rẹ̀. Mo tún gbìyànjú láti tẹ ìjẹ́pàtàkì lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ àwọn ọmọ mi lọ́kàn.
Ní 1953, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nínú ilé wa. Ní èyí tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 45 ọdún lẹ́yìn náà, a ṣì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà níbẹ̀. Jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ọdún wọ̀nyí, ó ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí kíkọyọyọ fún ìdílé wa.
Ìpèníjà gidi ni wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí àti bíbójútó òwò ilé àrójẹ wa nígbà kan náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeé ṣe fún mi láti bá ọ̀pọ̀ ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn kan lára àwọn wọ̀nyí gba òtítọ́ Bíbélì, wọ́n sì wá di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Láàárín àwọn ọdún 1950, àwọn ọmọ wa kéékèèké mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì batisí wọn. T. Y. kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì, síbẹ̀, yóò fi ọkọ̀ gbé wa lọ sí ìpàdé, yóò sì wá gbé wa pa dà. A pinnu láti má ṣe wàásù fún un ṣùgbọ́n a óò máa bá ara wa sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀, nípa ohun kan tàbí méjì tí a gbádùn nípàdé, nígbà tí a bá ń ti ìpàdé bọ̀.
Ní àkókò yẹn, T. Y. ń rìnrìn àjò ìṣòwò lemọ́lemọ́ lọ sí àwọn ìlú ńlá jákèjádò United States. Mo tẹ olú ilé iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, New York, láago, mo sì ṣàlàyé ipò wa. Nígbà tí a wà ní New York, Grant Suiter, tó jẹ́ akọ̀wé àti akápò Society nígbà náà, pè wá láti ṣe ìbẹ̀wò kí a sì rìn yí ká àwọn ilé lílò náà. Ó wú T. Y. lórí gidigidi, ní pàtàkì, bí ilé ìgbọ́únjẹ tí ń pèsè oúnjẹ fún nǹkan bí 500 ènìyàn náà ṣe wà ní mímọ́ tónítóní.
Láàárín àkókò ìbẹ̀wò wa, a pàdé Russell Kurzen, tó wá fi Bíbélì kan, tí T.Y. ń kà lálaalẹ́, títí tí ó fi kà á tán ránṣẹ́ sí i. Lẹ́yìn náà, ní àpéjọpọ̀ àgbáyé tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní New York ní 1958, ọkọ mi ṣe batisí! Sí ìyàlẹ́nu wa, ọmọkùnrin wa tó dàgbà jù lọ, tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ìdílé orílé iṣẹ́ náà nígbà náà, bójú tó apá kúkúrú kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
Ó Ṣòtítọ́ Títí Tó Fi Kú
Èmi àti T.Y. sábà máa ń jọ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Nígbà tí ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bàìbàì, a ń kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí òpópónà déédéé. Ìwé agbéròyìnjáde The Cleveland Press gbé àkọlé ìròyìn kan pé, “Ìyílọ́kànpadà ní Red Dragon,” pẹ̀lú àwòrán wa níbi tí a ti ń fi àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ ẹnì kan tí ń kọjá lọ. Ìròyìn náà sọ bí a ṣe di Ẹlẹ́rìí. Lọ́nà kan ṣáá, a pa orúkọ Red Dragon dà sí Ilé Àrójẹ Chin.
Láti àwọn ọdún wọ̀nyẹn wá, èmi àti ọkọ mi máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin láti ibi gbogbo lágbàáyé lálejò nílé àrójẹ wa. A rántí ìmọ̀ràn tí Arákùnrin Fred Franz, tí ó ṣiṣẹ́ bí ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society, fún wa dáadáa. Nígbà tí ó bẹ̀ wá wò, ó rọ̀ wá pé: “Ẹ jẹ́ olùṣòtítọ́, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ ètò Jèhófà tímọ́tímọ́.”
Àrùn ẹ̀gbà kọ lu T.Y. lọ́pọ̀ ìgbà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ó sì kú ní August 20, 1975. Ìwé agbéròyìnjáde kan ní àdúgbò tẹ ìkéde gígùn gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ kan jáde nípa ikú náà, ó sì gbé àwòrán rẹ̀ kan, níbi tí ó ti ń fi Ilé Ìṣọ́ lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, sí i. Àwọn ọdún tí a jọ gbé kẹ́yìn ló gbádùn mọ́ wa jù. Lẹ́yìn tí Ilé Àrójẹ Chin ti ṣiṣẹ́ lé ní 60 ọdún, ó kógbá sílé níkẹyìn ní April 1995. Lójú àwọn kan, ó dà bí òpin sáà kan.
Rírọ̀ Mọ́ Àwọn Ìlépa Tẹ̀mí
Nígbà kan, ìfẹ́ ọkàn wa ni pé kí àwọn ọmọkùnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bẹ̀rẹ̀ gbé igbá òwò ìdílé náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìfẹ́ ọkàn náà yí pa dà; a fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù, kí wọ́n sì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. A béèrè lọ́wọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ náà bí wọn yóò bá fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Hong Kong, kí wọ́n sì ran àwọn ará China míràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí àwa ti mọ̀. A fún wọn ní ìtìlẹ́yìn owó kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí èyí tó lè sọ èdè Chinese dán mọ́rán nínú wọn, Winifred, Victoria, àti Richard yàn láti kó lọ sí Hong Kong.
Ó lé ní ọdún 34 tí ọmọbìnrin wa, Winifred, ti jẹ́ aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀! Victoria fẹ́ Marcus Gum, wọ́n sì pa dà sí United States níkẹyìn. Wọ́n ti tọ́ ọmọ mẹ́ta dàgbà—Stephanie àti Seraiah, tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní Cleveland, àti Symeon, tí òun àti aya rẹ̀, Morfydd, ń ṣiṣẹ́ sìn ní Oko Watchtower, Wallkill, New York. Victoria àti Marcus ń gbé nítòsí nísinsìnyí, níbi tí wọ́n ti lè máa bójú tó mi. Marcus ni alábòójútó olùṣalága Ìjọ Coventry ní Cleveland.
Gloria, ọmọbìnrin wa tó dàgbà jù, kò lè kúrò lórí kẹ̀kẹ́ arọ láti ìgbà tí àrùn rọpárọsẹ̀ ti kọ lù ú ní 1955. Òun àti ọkọ rẹ̀, Ben, ń gbé ní Escondido, California, níbi tí ó ti ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Ó lé ní ọdún 22 tí Tom ti jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Òun àti aya rẹ̀, Esther, ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí ní Ibùdó Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower, ní Patterson, New York. Richard àti Amy, aya rẹ̀, pa dà wá láti Hong Kong kí wọ́n lè tọ́jú T.Y. kó tó kú. Ní báyìí, àwọn pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ sìn ní Patterson. Walden, ọmọ wa tó kéré jù, ti lò ju 30 ọdún lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Fún ọdún 22 tó kọjá, òun àti Mary Lou, aya rẹ̀, ti ṣiṣẹ́ sin àwọn ìjọ ní United States nínú iṣẹ́ àbójútó àyíká àti àbójútó àgbègbè.
Ẹ má rò pé àwọn ọmọ wa kò yọ wá lẹ́nu rí. Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn wà ní ọ̀dọ́langba, ó sá lọ kúrò nílé, a kò sì gbúròó rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta. Fún àkókò kan, òmíràn nínú wọn nífẹ̀ẹ́ sí eré ìdárayá ju àwọn ohun tẹ̀mí lọ, ó sì ń pa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìdílé wa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ láti lọ díje. Wọ́n tilẹ̀ fún un ní àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nítorí eré ìdárayá. Nígbà tí ó pinnu láti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún dípò kí ó gba ọ̀kan lára àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní yunifásítì náà, ńṣe ni mo nímọ̀lára bíi pé a sọ ẹrù wíwúwo bàǹtàbanta kan kúrò léjìká mi!
Mo Dúpẹ́ Pé Mo Tẹ́tí sí I
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní gidi, àwọn ọmọ mi fọ́n yí ká ayé, ó ń fún ọkàn àyà mi láyọ̀ láti mọ̀ pé wọ́n ń sin Jèhófà tòótọ́tòótọ́. Ẹni ọdún 81 ni mí nísinsìnyí, oríkèé ríro àti àwọn àrùn míràn kò sì jẹ́ kí n lè máa ta kébékébé mọ́, ṣùgbọ́n okùn ìtara mi fún Jèhófà kò dẹ̀. Mo ń gbìyànjú láti bójú tó ara mi, kí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ mi lè máà ní láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀ láti máa bójú tó mi.
Mo ń fi ìháragàgà wo ọjọ́ iwájú tí ète Ọlọ́run yóò ṣẹ ní kíkún, tí n óò sì tún pa dà rí àwọn olólùfẹ́ mi tí wọ́n ti kú, títí kan ọkọ mi, àwọn òbí tó bí mi gan-an, àti Helen Winters, tó bá wa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó pé mo tẹ́tí sí obìnrin onírunfunfun, onínúure yẹn, ní èyí tí ó lé ní ọdún 46 sẹ́yìn! Ní tòótọ́, oníbàárà yẹn tọ̀nà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Nígbà tí a ṣègbéyàwó
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìdílé wa ní 1961. Láti apá òsì sí ọ̀tún: Victoria, Wei, Richard, Walden, Tom, T.Y., Winifred, àti Gloria níwájú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Wei Chin lónìí