Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Fífi Ẹ̀yà Ẹni Yangàn Ńkọ́?
Tanya, ọmọ ọdún 17 wí pé: “Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀yà àti àwọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nínú ọ̀pọ̀ ìjíròrò tó ń ṣe, ó ń sọ pé òun ta wọ́n yọ.”
Ó WULẸ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu láti máa fi ìdílé, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, èdè, tàbí ilẹ̀ ìbí ẹni, yangàn ni. Ọmọ ọdún 15 kan tí ń jẹ́ Phung sọ pé: “Ọmọ ilẹ̀ Vietnam ni mí, mo sì ń fi àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ mi yangàn.”
Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, fífi ẹ̀yà ẹni yangàn máa ń bá ẹ̀tanú ẹ̀yà rìn. Ìfiyangàn yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun burúkú kan tó rọra ń ba àwọn ipò ìbátan jẹ́, kódà, nígbà tí a bá fi ìdíbọ́n oníwà ọmọlúwàbí bò ó lójú pàápàá. Jésù Kristi wí pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Àwọn èrò ìlọ́lájù—tàbí ìpẹ̀gàn—tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ sábà máa ń jẹ yọ, tí ó sì ń fà ìpalára tàbí ìrora.
Nígbà mìíràn, fífi ẹ̀yà ẹni yangàn lè yọrí sí ìwà ipá. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti tanná ran àwọn ogun, ìrúkèrúdò, àti “ìpaláparun ẹ̀yà” láìláàánú. Bí ó ti wù kí ó rí, kò di ìgbà tí o bá fojú rí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kí o tó fojú winá ìhà búburú ti fífi ẹ̀yà ẹni yangàn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o ń rí ẹ̀rí rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́, tàbí ní àdúgbò rẹ? Kristẹni ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Melissa sọ pé: “Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn kan nínú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ mi máa ń fi àwọn ọmọ tí ohùn tí wọ́n fi ń pe ọ̀rọ̀ yàtọ̀ ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń sọ pé àwọn sàn jù wọ́n lọ.” Bákan náà ni Tanya sọ pé: “Nílé ẹ̀kọ́, mo ti gbọ́ tí àwọn ọmọ kan ń sọ fún àwọn mìíràn ní gbangba pé: ‘Mo sàn jù ọ́ lọ.’” Nínú ìwádìí kan tí a ṣe ní United States, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì nínú àwọn tí a ṣèwádìí lọ́dọ̀ wọn tó sọ pé àwọn fúnra àwọn ti fojú winá àwọn oríṣi ẹ̀tanú ẹ̀yà kan láàárín ọdún tó ṣáájú. Ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Natasha sọ pé: “Ìṣòro ẹ̀yà náà gbilẹ̀ gan-an nílé ẹ̀kọ́ mi.”
Jẹ́ kí a wá sọ pé o ń gbé ilẹ̀ kan tàbí àgbègbè kan tí àwọn aṣíwọ̀lú pọ̀ rẹpẹtẹ, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ fa ìyípadà nínú oríṣi àwọn ènìyàn tó wà nínú ilé ẹ̀kọ́ rẹ, àdúgbò rẹ, tàbí ìjọ Kristẹni tí o wà. Ǹjẹ́ èyí ń dààmú rẹ lọ́nà kan? Nígbà náà, bóyá fífi ẹ̀yà ẹni yangàn ti jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú èrò rẹ ju bí o ṣe mọ̀ lọ.
Ìyangàn Yíyẹ àti Ìyangàn Tí Kò Yẹ
Ṣé èyí túmọ̀ sí pé ìyangàn kò dára lọ́nàkọnà ni? Kò fi dandan jẹ́ bẹ́ẹ̀. Bíbélì fi hàn pé àyè wà fún oríṣi ìyangàn tí ó yẹ. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà, ó wí pé: “Àwa fúnra wa ń fi yín yangàn láàárín àwọn ìjọ Ọlọ́run.” (2 Tẹsalóníkà 1:4) Lọ́nà kan náà, ó kéré tán, jíjọ ara ẹni lójú dé ìwọ̀n kan dára, ó sì wọ́pọ̀. (Róòmù 12:3) Nítorí náà, kì í ṣe ohun tó burú nínú ara rẹ̀ láti fi ẹ̀yà, ìdílé, èdè, àwọ̀, tàbí ilẹ̀ ìbí ẹni, yangàn níwọ̀nba. Ó dájú pé Ọlọ́run kò jẹ́ béèrè pé kí a tijú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Nígbà tí wọ́n ṣi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú, tí wọ́n sì kà á sí ọ̀daràn ará Íjíbítì kan, kò lọ́ra láti sọ pé: “Ní ti tòótọ́, Júù ni mí, láti Tásù ní Sìlíṣíà, aráàlú ìlú ńlá kan tí kò mù rárá.”—Ìṣe 21:39.
Bí ó ti wù kí ó rí, fífi ẹ̀yà ẹni yangàn ń di ohun búburú nígbà tí ó bá ń bomi rin èrò ìjọra-ẹni-lójú aláṣejù tàbí tí ó ń múni fojú tín-ínrín àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì wí pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà túmọ̀ sí kíkórìíra ohun búburú. Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn àti ọ̀nà búburú àti ẹnu tí ń ṣàyídáyidà.” (Òwe 8:13) Bákan náà, Òwe 16:18 wí pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” Fífọ́nnu pé a jẹ́ ti ẹ̀yà kan tó lọ́lá jù jẹ́ ìríra níwájú Ọlọ́run.—Fi wé Jákọ́bù 4:16.
Orírun Fífi Ẹ̀yà Ẹni Yangàn
Kí ló ń mú kí àwọn ènìyàn máa fi ẹ̀yà wọn yangàn ju bó ṣe yẹ lọ? Ìwé Black, White, Other, láti ọwọ́ Lise Funderburg, sọ pé: “Ní ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, èrò àkọ́kọ́ (tó sì ń wà pẹ́ jù) tí wọ́n ní nípa ẹ̀yà wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn àti ìdílé wọn.” Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà púpọ̀ jù, èrò òdì, tí kò wà déédéé ni àwọn òbí kan ń fi fúnni. A lè ti sọ fún àwọn ọmọ kan ní tààrà pé àwọn ènìyàn ẹ̀yà tiwọn ló lọ́lá jù, tí àwọn ènìyàn àwọn ẹ̀yà mìíràn sì yàtọ̀ tàbí pé wọn kò lọ́lá tó wọn. Àmọ́ nígbà púpọ̀ ju ìyẹn lọ, àwọn ọmọdé wulẹ̀ ń ṣàkíyèsí pé àwọn òbí àwọn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn ènìyàn ẹ̀yà mìíràn ṣe. Èyí pẹ̀lú lè lágbára gidigidi lórí bí wọ́n ṣe ń ronú. Àwọn ìwádìí fi hàn pé nígbà tí àwọn ọ̀dọ́langba lè ṣàìbá àwọn òbí fojú kojú jíròrò lórí ìwọṣọ tàbí orin, ògìdìgbó èwe ló ní èrò kan náà tí àwọn òbí wọn ní nípa ẹ̀yà.
Ìṣarasíhùwà tí kò wà déédéé nípa ẹ̀yà tún ń jẹ yọ bí ìhùwàpadà sí ìnilára àti ìfìyàjẹni. (Oníwàásù 7:7) Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùkọ́ ti ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọ tí ó wá láti inú àwọn ẹ̀yà tí a ń fẹnu lásán pè ní ẹ̀yà kéékèèké sábà máa ń ṣàìní ọ̀wọ̀ ara ẹni. Nínú ìgbìyànjú láti ṣàtúnṣe ipò náà, àwọn olùkọ́ kan ti gbé àwọn ètò ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́, tí ń kọ́ àwọn ọmọ ní ìtàn ẹ̀yà wọn, kalẹ̀. Ó dùn mọ́ni pé, àwọn olùṣelámèyítọ́ ti sọ pé ìtẹnumọ́ fífi ẹ̀yà ẹni yangàn yìí wulẹ̀ ń yọrí sí ẹ̀tanú ẹ̀yà ni.
Ìrírí ara ẹni pẹ̀lú lè kópa nínú mímú ìṣarasíhùwà búburú nípa ẹ̀yà dàgbà. Bíbá ẹnì kan tí ó wá láti inú ẹ̀yà tó yàtọ̀ pàdé lábẹ́ ipò tí kò báni lára mu, lè múni parí èrò sí pé gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti inú ẹ̀yà yẹn ni kò sunwọ̀n tàbí ló lẹ́tanú. Ó tún ṣeé ṣe kí a ní èrò òdì nígbà tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde bá ń tẹnu mọ́ àwọn ìjà láàárín àwọn ẹ̀yà, ìwà ìkà tí àwọn ọlọ́pàá ń hù, àti ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tàbí nígbà tí wọ́n bá ń fi àwọn ẹ̀yà hàn lọ́nà òdì.
Èrò Èké Nípa Ìlọ́lájù Ẹ̀yà
Kí ni a lè sọ nípa ohun tí àwọn kan sọ pé ẹ̀yà àwọn ní ẹ̀tọ́ láti gbà pé àwọn lọ́lá ju àwọn mìíràn lọ? Lákọ̀ọ́kọ́, èrò pé a lè pín àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí ẹ̀yà tó dá dúró ní gidi ṣeni níyè méjì. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ti kọ́ nípa ọ̀ràn ẹ̀yà ṣe rí i, ẹ̀yà jẹ́ èrò tó lókìkí burúkú, tí kò ṣeé gbára lé, tí kò ṣeé ṣàlàyé lọ́nà gbígbéṣẹ́.” Òtítọ́ ni pé, “àwọn ìyàtọ̀ àwọ̀ ara, ìrísí irun, àti ìrísí ojú tàbí imú” lè wà. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé “àwọn ìyàtọ̀ wọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ tòde ara lásán—bí ó sì ti wù kí wọ́n gbìyànjú tó, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ní gbogbogbòò kò tí ì lè tọ́ka pàtó sí àwọn ìyàtọ̀ tó fi ẹ̀yà kan hàn yàtọ̀ sí èkejì. . . . Kókó pàtàkì jù lọ fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń ṣiṣẹ́ lórí ìwọ̀nyí ni pé, ẹ̀yà wulẹ̀ jẹ́ ‘èrò àwùjọ’ lásán—ìdàpọ̀ [tí ń rẹni sílẹ̀] ti ẹ̀tanú, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti èrò èké.”
Kódà, bí sáyẹ́ǹsì bá lè fìyàtọ̀ sáàárín ẹ̀yà, èrò nípa ẹ̀yà “tí kò lábùlà” kan jẹ́ àròsọ lásán. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Kò sí ẹ̀yà tí kò lábùlà; gbogbo ẹ̀yà tó wà nísinsìnyí ló ti dà pọ̀ mọ́ra pátápátá.” Ohun yòó wù kó jẹ́, Bíbélì kọ́ni pé “láti ara ọkùnrin kan ni” Ọlọ́run “ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 17:26) Láìka àwọ̀ ara, ìrísí irun, tàbí ìrísí ojú sí, ẹ̀yà kan ṣoṣo ló wà—ìran ènìyàn. Gbogbo ẹ̀dá ló bára wọn tan nípasẹ̀ baba ńlá wa, Ádámù.
Àwọn Júù ìgbàanì mọ̀ nípa orírun àjùmọ̀ni gbogbo ẹ̀yà. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn kan tilẹ̀ ti di Kristẹni tán, wọ́n ṣì rọ̀ mọ́ èrò pé àwọn lọ́lá ju àwọn tí kì í ṣe Júù lọ—títí kan àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí kì í ṣe Júù! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bi èrò pé ẹ̀yà kan lọ́lá ju òmíràn lọ lulẹ̀ nípa sísọ ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú Róòmù 3:9 pé: “Àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì ni gbogbo wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.” Nítorí náà, kò sí ẹ̀yà kan tó lè yangàn pé òun ní ipò àrà ọ̀tọ̀ kan níwájú Ọlọ́run. Ní gidi, nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi nìkan ni ẹnì kọ̀ọ̀kan fi lè ní ipò ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Ó sì jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.
Mímọ̀ tí o bá mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yà dọ́gba níwájú Ọlọ́run lè nípa gbígbàfiyèsí lórí ojú tí o fi ń wo ara rẹ àti àwọn ẹlòmíràn. Ó lè mú kí o máa bu iyì àti ọlá fún àwọn ẹlòmíràn, kí o mọyì ìyàtọ̀ wọn, kí ó sì jọ ọ́ lójú. Bí àpẹẹrẹ, Melissa ọ̀dọ́, tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, kò dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní fífi àwọn èwe tí ohùn tí wọ́n fi ń pe ọ̀rọ̀ yàtọ̀ rẹ́rìn-ín. Ó wí pé: “Èmi ka àwọn tí ń sọ èdè méjì sí onílàákàyè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó wù mí láti lè sọ èdè mìíràn, èdè kan ṣoṣo ni mo lè sọ.”
Tún rántí pé, nígbà tí àwọn ènìyàn ẹ̀yà rẹ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ ní ohun púpọ̀ láti fi yangàn láìsíyèméjì, àwọn ènìyàn ẹ̀yà mìíràn náà ní in bẹ́ẹ̀. Bí ó sì tilẹ̀ lè lọ́gbọ́n nínú láti lè fi àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ àti àwọn àṣeyọrí tí àwọn baba ńlá rẹ ti ṣe yangàn, ó túbọ̀ ń tẹ́ni lọ́rùn láti fi ohun tí o ṣe yọrí fúnra rẹ̀, nípasẹ̀ ìsapá àti iṣẹ́ àṣekára, yangàn! (Oníwàásù 2:24) Ní gidi, àṣeyọrí kan wà tí Bíbélì rọ̀ ọ́ láti fi yangàn. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú Jeremáyà 9:24, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wí pé: “Kí ẹni tí ń fọ́nnu nípa ara rẹ̀ fọ́nnu nípa ara rẹ̀ nítorí ohun yìí gan-an, níní tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye àti níní tí ó ní ìmọ̀ mi, pé èmi ni Jèhófà.” Ǹjẹ́ ìwọ lè fi ìyẹn yangàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mímọ èrò Ọlọ́run nípa ẹ̀yà ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn àjọṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn ẹ̀yà mìíràn