Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Takora Kẹ̀?
“BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbọ́dọ̀ ta èrò pé sáyẹ́ǹsì jẹ́ wíwá òtítọ́ nípa àgbáyé kiri nù, a gbọ́dọ̀ gbé àwọn kókó ti ìrònú òun ìhùwà àti ti àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, tí ó sábà máa ń lòdì sí ìwákiri yìí, yẹ̀ wò.” Báyìí ni Tony Morton ṣe kọ ọ́ nínú ìwé àpilẹ̀kọ tí ó pè ní “Àwọn Èrò Tí Ń Forí Gbárí: Ète àti Ọ̀nà Ìṣeǹkan Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì.” Lóòótọ́, ó jọ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, òkìkí, èrè owó, tàbí ìtẹ̀sí ti ìṣèlú ti nípa lórí àwọn àwárí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe.
Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1873, Alàgbà Jessel fi àníyàn rẹ̀ lórí irú ipa bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn ilé ẹjọ́ hàn nígbà tó wí pé: “Àwọn ẹ̀rí tí àwọn ògbógi gbé kalẹ̀ . . . ń fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ènìyàn ń fi gbígbé ẹ̀rí kalẹ̀ ṣe iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ṣùgbọ́n nínú gbogbo ọ̀ràn, a ń sanwó fún wọn nítorí ẹ̀rí wọn. . . . Ní báyìí, ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé, bí ó ti wù kí ó jẹ́ aláìlábòsí tó, èrò inú rẹ̀ gbọ́dọ̀ tẹ̀ síhà gbígbè sẹ́yìn ẹni tó gbéṣẹ́ fún un, a sì ń rí irú ìtẹ̀sí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.”
Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ kí a wo ẹ̀ka sáyẹ́ǹsì tí ń pèsè ìsọfúnni nípa ìwà ọ̀daràn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ọ̀ràn náà kàn. Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan sọ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń pèsè ìsọfúnni nípa ìwà ọ̀daràn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ọ̀ràn náà kàn lè ṣègbè. Ìwé ìròyìn náà, Search, sọ pé: “Òtítọ́ náà pé àwọn ọlọ́pàá ń wá ìrànlọ́wọ́ wọn lè mú kí ipò ìbátan kan wá láàárín àwọn ọlọ́pàá àti àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń pèsè ìsọfúnni nípa ìwà ọ̀daràn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ọ̀ràn náà kàn. . . . Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń pèsè ìsọfúnni nípa ìwà ọ̀daràn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ọ̀ràn náà kàn, tí ìjọba gbà síṣẹ́, lè wá rí iṣẹ́ wọn bíi ríran ọlọ́pàá lọ́wọ́.” Ìwé ìròyìn yìí tún fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn ẹjọ́ bọ́ǹbù tí IRA (Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ilẹ̀ Olómìnira Ireland) jù ba Maguire (1989) àti Ward (1974) ní Britain gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀rí lílágbára kan sí bí àwọn ìjìmì onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a ń gbé gẹ̀gẹ̀ mìíràn ṣe múra tán láti pa àìdásí-tọ̀tún-tòsì tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu tì, kí wọ́n sì wo ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi ríran olùpẹ̀jọ́ lọ́wọ́.”
Àpẹẹrẹ títayọ mìíràn ni ẹjọ́ Lindy Chamberlain ní Australia (1981 sí 1982), tó wá di ìpìlẹ̀ sinimá A Cry in the Dark. Ní kedere, ẹ̀rí tí àwọn ògbógi olùpèsè ìsọfúnni nípa ìwà ọ̀daràn nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ọ̀ràn náà kàn gbé kalẹ̀ ló mú kí aya Chamberlain, tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó pa ọmọ ọwọ́ rẹ̀, Azaria, jẹ̀bi ẹjọ́ náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé ajá dingo (ajá igbó) kan ló pa ọmọ náà, wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí a wá rí jákẹ́ẹ̀tì ọmọ náà tó dọ̀tí, tí ẹ̀jẹ̀ sì rin gbindingbindin, ẹ̀rí ìṣáájú kò tó láti fi ẹni tó pa ọmọ náà hàn mọ́. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n dá Lindy sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n fagi lé ìdálẹ́bi rẹ̀, wọ́n sì sanwó ìtanràn fún un nítorí ìdálẹ́bi láìtọ́.
Nígbà tí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá ń bá onímọ̀ sáyẹ́ǹsì jiyàn, fàákájáa náà lè le gan-an. Ní ẹ̀wádún mélòó kan sẹ́yìn, bí Dókítà William McBride ṣe pe àwọn tó ṣe egbòogi thalidomide níjà di kókó pàtàkì nínú ìròyìn àgbáyé. Nígbà tí ó sọ pé egbòogi yìí, tí a ń tà láti ṣèwòsàn ìrìndọ̀ àti èébì àárọ̀ nígbà tí a bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lóyún, ń fa ìpalára gidigidi fún àwọn ọmọ tí a kò ì bí, ó di ẹni àpéwò ní ọ̀sán-kan-òru-kan. Síbẹ̀, ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, nígbà tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ìdáwọ́lé mìíràn, dókítà kan tó di akọ̀ròyìn fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣe màgòmágó nípa àwọn ìsọfúnni. Wọ́n dá McBride lẹ́bi ṣíṣe ẹ̀tàn nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àti ṣíṣe ohun tí kò bá ìlànà iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe rẹ̀ mu. Wọ́n yọ orúkọ rẹ̀ kúrò lára orúkọ àwọn oníṣègùn ilẹ̀ Australia.
Àwọn Àìfohùnṣọ̀kan Inú Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì
Àìfohùnṣọ̀kan títayọ kan ní lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́ ní ti yálà àgbègbè agbára mágínẹ́ẹ̀tì oníná lè ṣèjàǹbá fún ìlera ènìyàn àti ẹranko tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn ẹ̀rí kan fi hàn pé agbára ìṣiṣẹ́ tó kan ìbátan àárín iná mànàmáná àti mágínẹ́ẹ̀tì, tí orísun rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn wáyà iná lílágbára gan-an dé orí kọ̀ǹpútà kéékèèké àti ohun ìdáná tí ìgbì mànàmáná rẹ̀ kéré gan-an tí a ń lò nínú ilé, ń ba àyíká wa jẹ́ gan-an. Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé lílo tẹlifóònù alágbèérìn fún ọdún mélòó kan lè ba ọpọlọ jẹ́. Àwọn mìíràn tún ń tọ́ka sí àwọn ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń fi hàn pé ìrànyòò ìgbì ìtànṣán lè fa àrùn jẹjẹrẹ, ó sì lè pani. Àpẹẹrẹ kan nípa èyí ni ìròyìn tí ìwé agbéròyìnjáde The Australian ṣe pé: “Wọ́n ti pe ilé iṣẹ́ mànàmáná kan nílẹ̀ Britain lẹ́jọ́ nítorí ikú ọmọkùnrin kan tí a gbọ́ pé ó ní àrùn jẹjẹrẹ nítorí pé ó ń sùn nítòsí wáyà iná lílágbára gan-an.” Oníṣègùn àwọn àrùn tí iṣẹ́ ẹni ń fà kan ní Melbourne, Dókítà Bruce Hocking, ṣàwárí pé, “àwọn ọmọdé tí ń gbé ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rin sí àwọn ọ̀pá gíga ti ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n ti Sydney ń ní ju ìlọ́po méjì ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn leukaemia tí ń ṣe àwọn ọmọdé tí ń gbé ní ìkọjá ìwọ̀n kìlómítà mẹ́rin náà lọ.”
Nígbà tí àwọn onímọ̀ nípa àyíká ń ṣagbátẹrù irú èrò bẹ́ẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ ìṣòwò aládàá-ńlá àti àwọn ilé iṣẹ́ ìṣòwò wà ní ipò láti pàdánù ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là láti inú ohun tí wọ́n pè ní “ìpolongo apániláyà tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n ṣàgbékalẹ̀ àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn, wọ́n sì gba ìtìlẹ́yìn wọn.
Àìfohùnṣọ̀kan nípa ìbàjẹ́ tí àwọn kẹ́míkà ń ṣe tún wà níbẹ̀. Àwọn kan ti ṣàpèjúwe kẹ́míkà dioxin gẹ́gẹ́ bí “kẹ́míkà onímájèlé jù lọ tí ènìyàn ṣe.” Kẹ́míkà tí Michael Fumento júwe bí “èròjà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ láti ara àwọn tí a fi ṣe oògùn pagipagi lásán” yìí (Science Under Siege), ni àwọn kan pè ní “èròjà pàtàkì jù lọ nínú oògùn Agent Orange.”a Ó dé orí góńgó òkìkí rẹ̀ lẹ́yìn ogun Vietnam. Àríyànjiyàn ńláńlá nílé ẹjọ́ bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn àbọ̀dé ológun àti àwọn ilé iṣẹ́ aṣekẹ́míkà, tí àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì ní àwọn ògbógi onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tirẹ̀ tí ń forí gbárí.
Bákan náà, àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ àyíká bíi mímóoru ilẹ̀ ayé, ìmáyégbóná, àti ìparun ìpele ozone ń gba àfiyèsí aráàlú lọ́pọ̀lọpọ̀. Nípa ìbẹ̀rù nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àyíká ní Antarctica, ìwé agbéròyìnjáde The Canberra Times wí pé: “Ìwádìí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe ní Ibùdó Palmer, ibùdó iṣẹ́ sáyẹ́ǹsì ti United States ní Erékùṣù Anvers, fi hàn pé ìtànṣán ultraviolet lílágbára gan-an ń ṣèpalára fún àwọn ohun alààyè rírẹlẹ̀ bí àwọn ohun alààyè ojú omi àti àwọn ẹran oníkarawun, ó sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í nípa lórí àwọn ẹranko mìíràn nínú ìsokọ́ra ìṣètò oúnjẹ.” Ṣùgbọ́n ó jọ pé ọ̀pọ̀ ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mìíràn ń tako irú èrò bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ń tú ìbẹ̀rù nípa ìparun ìpele ozone àti mímóoru ilẹ̀ ayé ká.
Ta ló wá tọ̀nà? Ó jọ pé èrò tàbí iyàn kọ̀ọ̀kan ni àwọn ògbógi onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè tì lẹ́yìn tàbí kí wọ́n tì lulẹ̀. Ìwé Paradigms Lost sọ pé: “Ó kéré tán, a lè pinnu òtítọ́ tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu dé àyè kan nípa ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tó yí i ká nígbà náà, bí a ṣe lè pinnu rẹ̀ nípa ìlànà àfiṣèpinnu ti ìrònú àti ìbọ́gbọ́nmu nìkan.” Michael Fumento ṣàkópọ̀ ọ̀ràn ti kẹ́míkà dioxin nípa sísọ pé: “Ní sísinmi lórí èrò ẹni tí a ń fetí sí, gbogbo wa ló ṣeé ṣe ká fara gbá májèlé tàbí ká fara gbá ìmọ̀ọ́mọ̀-ṣèsọfúnni-èké lọ́nà lílékenkà.”
Síbẹ̀, àwọn ìjábá sáyẹ́ǹsì kan tí a mọ̀ dunjú kò ṣeé fojú kéré. Sáyẹ́ǹsì gbọ́dọ̀ jíhìn fún wọn.
“Ìjábá Tó Dunni Wọra Gan-an”
Nínú “Ìsọfúnni Kan fún Àwọn Onílàákàyè,” tí a gbé jáde ní August 29, 1948, Albert Einstein tànmọ́lẹ̀ sórí àwọn apá tí kò fani mọ́ra nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nígbà tó wí pé: “Ìrírí tí kò bára dé ti kọ́ wa pé èrò àrògún kò tó láti yanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé àwùjọ wa. Ìwádìí alátojúbọ̀ àti iṣẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a ṣe tọkàntara ti sábà ń ní ìyọrísí alájàálù fún aráyé, . . . nípa ṣíṣẹ̀dá àwọn ohun tí ń pa òun fúnra rẹ̀ run láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Ní tòótọ́, èyí jẹ́ ìjábá tó dunni wọra gan-an!”
Àgbéjáde kan láti ọwọ́ àjọ akóròyìnjọ Associated Press sọ láìpẹ́ yìí pé: “Britain Jẹ́wọ́ Dídán Ìtànṣán Wò Lára Ènìyàn.” Ilé Iṣẹ́ Ààbò Ilẹ̀ Britain fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 ọdún tí ìjọba ti ń dán ìtànṣán wò lára ènìyàn. Ọ̀kan lára irú àṣedánrawò bẹ́ẹ̀ ni lílo bọ́ǹbù átọ́míìkì kan wò ní Maralinga, Gúúsù Australia, ní agbedeméjì àwọn ọdún 1950.
A fa orúkọ Maralinga yọ láti inú ọ̀rọ̀ àwọn Ọmọ Onílẹ̀ tó túmọ̀ sí “àrá,” ibi tí ó dá dó yìí ló sì wá jẹ́ ibi tó dára jù fún ilẹ̀ Britain láti ṣe àwọn àfidánrawò ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì rẹ̀. Lẹ́yìn ìbúgbàù kíní, ayọ̀ pé wọ́n ṣàṣeyọrí gbòdekan. Ìròyìn tí ìwé agbéròyìnjáde kan ṣe ní Melbourne kà pé: “Bí eruku [tí ìtànṣán olóró fà] náà ti ń rọlẹ̀, àwọn ọkọ̀ akẹ́rù àti ọkọ̀ ológun tí ó gbémú lémú kó àwọn ọmọ ogun ará Britain, Kánádà, Australia, àti New Zealand tí wọ́n ti dojú kọ ìbúgbàù náà láti inú àwọn ihò ẹ̀bá òkè ní kìlómítà mẹ́jọ péré láti ibi tí ìbúgbàù náà ti ṣẹlẹ̀ dé. Gbogbo wọn ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń bọ̀ láti òde fàájì kan.”
Chapman Pincher, tí ń kọ̀ròyìn lórí sáyẹ́ǹsì fún ìwé agbéròyìnjáde ti ilẹ̀ Britain náà, Daily Express, tilẹ̀ ṣàkójọ orin kan tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní “Yíyánhànhàn fún Eruku Tí Ìbúgbàù Ohun Ìjà Átọ́míìkì Fà.” Tún fi ìdánilójú tí mínísítà kan lábẹ́ ìjọba fúnni kún un, tó sọ pé ìdánrawò náà ti ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ bí wọ́n ṣe wéwèé rẹ̀ àti pé ewu ìtànṣán kankan kì yóò wu ẹnikẹ́ni ní Australia. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ̀rín músẹ́ náà pòórá lójú àwọn tí ìtànṣán ń pa, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè fún owó ìtanràn sì tẹ̀ lé e. Kò sí “Yíyánhànhàn fún Eruku Tí Ìbúgbàù Ohun Ìjà Átọ́míìkì Fà” mọ́ ní báyìí! Nítorí ìbàjẹ́ tí ìtànṣán fà, a kò tíì gba àwọn ènìyàn láyè láti lọ sí Maralinga di báyìí.
Ó jọ pé ìdánrawò tí United States lọ ṣe ní Nevada rí bákan náà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé ọ̀ràn ìṣèlú ló wà nídìí rẹ̀, pé kì í ṣe àṣìṣe ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Robert Oppenheimer, tó wà nídìí àbójútó ṣíṣe bọ́ǹbù átọ́míìkì kìíní fún Amẹ́ríkà, ní Los Alamos, New Mexico, sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti pinnu bóyá kí a lo bọ́ǹbù eléròjà hydrogen. Ìpinnu yẹn wà lọ́wọ́ àwọn ará Amẹ́ríkà àti àwọn aṣojú tí wọ́n yàn.”
Oríṣi Àjálù Mìíràn
Lílo ẹ̀jẹ̀ nínú ìṣègùn di ìlànà iṣẹ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Sáyẹ́ǹsì gbé e lárugẹ bí ohun tí ń gba ẹ̀mí là, ó sì kéde pé lílò ó kò léwu. Ṣùgbọ́n bí àrùn AIDS ṣe yọjú mú iṣẹ́ ìṣègùn ta kìjí sí àìfura rẹ̀ sí àwọn ewu àti àìkúnjú-òṣùwọ̀n rẹ̀. Lójijì ohun olómi tí a retí pé yóò máa gba ẹ̀mí là di ohun tí ń pani fún àwọn kan. Ọ̀gá alábòójútó kan ní ilé ìwòsàn ńlá kan ní Sydney, Australia, sọ fún Jí! pé: “Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, a ti fa èròjà kan tí a kò mọ púpọ̀ nípa rẹ̀ sí àwọn ènìyàn lára. A kò tilẹ̀ mọ àwọn kan lára àwọn àrùn tó wà nínú rẹ̀. A kò tí ì mọ ohun tó wà nínú èyí tí a ń fà síni lára lọ́wọ́lọ́wọ́ nítorí a kò lè ṣèwádìí lórí ohun tí a kò mọ̀.”
Ọ̀ràn kan tó mú ìbànújẹ́ lọ́wọ́ ní pàtàkì ni ti omi ìsúnniṣe tó ń darí ìdàgbà ara tí a ń fi ṣètọ́jú àwọn obìnrin tó bá yàgàn. Nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ń fẹ́ ayọ̀ púpọ̀ sí i nínú ìgbésí ayé nípa bíbímọ, wọ́n rí ọ̀nà ìtọ́jú yìí bí ìbùkún kan. Ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, àrùn Creutzfeldt-Jakob (CDJ) tí ń dín ìṣiṣẹ́ ọpọlọ kù pa àwọn kan lára wọn lọ́nà tó rúni lójú. Àwọn ọmọdé tí a fi omi ìsúnniṣe kan náà tọ́jú nítorí ìdàgbà wọn tí kò dára tó bẹ̀rẹ̀ sí kú. Àwọn olùwádìí rí i pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mú omi ìsúnniṣe náà láti inú àwọn ẹṣẹ́ pituitary lára àwọn òkú ènìyàn. Ó dájú pé àwọn kan lára àwọn òkú náà ti ní fáírọ́ọ̀sì CJD náà lára, àwọn ọ̀wọ́ omi ìsúnniṣe náà sì kó àkóràn rẹ̀. Èyí tó túbọ̀ bani nínú jẹ́ jù ni pé àwọn kan nínú àwọn obìnrin tí wọ́n fi omi ìsúnniṣe náà ṣètọ́jú fún tún fi ẹ̀jẹ̀ tọrọ kí àmì pé wọ́n ní àrùn CJD náà tó yọjú. Ìbẹ̀rù tí a ní báyìí ni pé fáírọ́ọ̀sì náà lè wà nínú àwọn àkójọ ẹ̀jẹ̀ tí a óò fà síni lára, nítorí pé kò sí ọ̀nà tí a lè fi ṣàyẹ̀wò láti dá a mọ̀.
Gbogbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ní ìwọ̀n ewu kan nínú. Abájọ nígbà náà tí ó fi jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé The Unnatural Nature of Science ṣe wí, sáyẹ́ǹsì “ni a ń fi ojú àdàlù ìgbóríyìn àti ìbẹ̀rù, ìrètí àti àìnírètí, wò, a rí i bí ohun tó ń fa ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro àwùjọ oníṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní àti bí ibi tí ìwòsàn àwọn ìṣòro wọ̀nyí yóò ti wá.”
Àmọ́ báwo ni a ṣe lè dín ewu ara ẹni kù? Báwo ni a ṣe lè ní ojú ìwòye wíwàdéédéé nípa sáyẹ́ǹsì? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣèrànwọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Oògùn Agent Orange ni oògùn pagipagi tí wọ́n fi mú kí ewé igi rẹ̀ ní àwọn àgbègbè tí igbó wà nígbà ogun Vietnam.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Mínísítà kan lábẹ́ ìjọba sọ pé ewu ìtànṣán kankan kì yóò wu ẹnikẹ́ni
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Ìtànṣán ti ba ibi ìdánrawò Maralinga jẹ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Kì í ṣe iṣẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti pinnu bóyá kí a lo bọ́ǹbù eléròjà hydrogen.”
—Robert Oppenheimer, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa átọ̀mù
[Credit Line]
Hulton-Deutsch Collection/Corbis
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
“Ìrírí tí kò bára dé ti kọ́ wa pé èrò àrògún kò tó láti yanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé àwùjọ wa.”—Albert Einstein, onímọ̀ físíìsì.
[Credit Line]
Fọ́tò U.S. National Archives
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Richard T. Nowitz/Corbis
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Fọ́tò USAF