Mo La Ìjàǹbá Ọkọ̀ Òfuurufú Nọnba 801 Já
MO YỌJÚ lójú fèrèsé bí a ti ń lọ sílẹ̀ láti balẹ̀ ní Guam. Mo ronú pé, ‘ìyẹn ṣàjèjì. Ó jọ pé òkùnkùn ṣú jù.’ Lóòótọ́, ó ti kọjá ọ̀gànjọ́ òru, òjò ńlá tí ń rọ̀ sì mú kí ó ṣòro láti ríran. Àmọ́, àwọn iná tí a sábà ń rí ní erékùṣù náà àti àwọn ọ̀nà dídángbinrin tí ọkọ̀ òfuurufú ti ń balẹ̀ ní pápákọ̀ òfuurufú náà dà? Gbogbo ohun tí mo lè rí ni àwọn iná tí kò mọ́lẹ̀ dáadáa láti àwọn apá ọkọ̀ òfuurufú ayára-bí-àṣá wa.
Ọ̀kan nínú àwọn alábòójútó èrò inú ọkọ̀ wa ti ṣe ìkéde tí a ń gbọ́ nígbà gbogbo ní ìmúrasílẹ̀ fún bíbalẹ̀, mo sì gbọ́ tí àwọn táyà ẹ̀yìn ọkọ̀ òfuurufú náà ń yọ sí àyè wọn. Lójijì, a gbọ́ ariwo ńlá kan bí ọkọ̀ òfuurufú wa ṣe fẹsẹ̀ balẹ̀. Ọkọ̀ òfuurufú náà ṣe jàgàjàgà láìṣeé-ṣàkóso, àwọn èrò ọkọ̀ sì gbá àwọn ìgbápálé wọn mú, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ló ń ṣẹlẹ̀?”
Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ọkọ̀ Boeing 747 tí a wọ̀ forí sọ ẹ̀gbẹ́ òkè kan, ó ku kìlómítà márùn-ún ká dé pápákọ̀ òfuurufú náà, ó ṣe kedere pé awakọ̀ wa ṣi ìṣirò ṣe. Nítorí ìjàǹbá ọkọ̀ òfuurufú yẹn ní August 6, 1997, àpapọ̀ èrò àti òṣìṣẹ́ ọkọ̀ 228 ló kú. Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹni 26 péré tó là á já.
Kí n tó wọ ọkọ̀ náà ní Seoul, Korea, aṣojú ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú kan ṣàgbéga ipò tó yẹ kí n jókòó, ó sì fún mi ní ìjókòó kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù níbi ìjókòó ọlọ́lá. Ó dùn mọ́ mi nínú gan-an tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi tẹ ìyàwó mi, Soon Duck, tó yẹ kó wá pàdé mi ní pápákọ̀ òfuurufú Guam, láago. Ìyípadà àyè ìjókòó yẹn ṣàǹfààní fún mi ju bí mo ṣe lè finú rò lọ.
Ìjàǹbá Náà àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Tẹ̀ Lé E
Nítorí àìlèríran-jìnnà, àwọn agbo òṣìṣẹ́ ọkọ̀ náà lè ṣàìmọ̀ pé ewu kankan wà níwájú. Gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní wàràǹṣeṣà! Níṣẹ̀ẹ́jú kan, mo ń múra sílẹ̀ de ohunkóhun tó wù kó ṣẹlẹ̀, ohun tí mo mọ̀ tẹ̀ lé e ni pé mo bá ara mi nílẹ̀ẹ́lẹ̀, ní dídè mọ́ ìjókòó mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú ọkọ̀ òfuurufú náà. Kò dá mi lójú bóyá mo mọ ohun tí ń lọ tàbí n kò mọ̀ ọ́n.
Mo ṣe kàyéfì pé, ‘Àbí mo ń lálàá ni?’ Nígbà tí mo wá mọ̀ pé àlá kọ́, ohun tí mo kọ́kọ́ ronú lé ni bí ìyàwó mi yóò ṣe ṣe nígbà tó bá gbọ́ nípa ìjàǹbá náà. Níkẹyìn, ó sọ fún mi pé òun kò fìgbà kankan sọ̀rètí nù. Kódà, nígbà tí ó gbọ́ tí ẹnì kan sọ pé èrò ọkọ̀ méje péré ló là á já, ó gbà gbọ́ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn méje náà.
Ọkọ̀ òfuurufú wa ti fọ́ sí mẹ́rin, tó fọ́n ká sí orí ilẹ̀ inú igbó tí kò tẹ́jú. Òkú wà nílẹ̀ lọ kítikìti. Àwọn apá kan ọkọ̀ náà ń jóná, mo sì ń gbọ́ ìró ìbúgbàù àti igbe ìrora òun ẹkún bíbanilẹ́rù. A ń gbọ́ ohùn àwọn tí ń bẹ̀bẹ̀ pé: “Ẹ gbà mí o! Ẹ gbà mí o!” Ìjókòó mi ti balẹ̀ sáàárín koríko ìfèèféé tó ga ní ìwọ̀n mítà 1.8, nínú ìmọ́lẹ̀ bíbanilẹ́rù tí iná tí ń jó náà mú wá, mo lè rí òkè gogoro kan nítòsí. Ó jẹ́ nǹkan bí agogo méjì òru, òjò sì ń rọ̀.
Ó bá mi lábo tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tilẹ̀ ronú pé mo lè ti fara pa, títí di ìgbà tí mo rí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí awọ orí rẹ̀ ṣí sí ìpàkọ́ rẹ̀. Lọ́gán ni mo mọ́wọ́ lọ sórí mi, mo sì rí i pé ojú ọgbẹ́ kan lókè ojú mi òsì ń ṣẹ̀jẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò gbogbo ara mi, mo sì rí ọ̀pọ̀ ojú ọgbẹ́ kéékèèké sí i. Ṣùgbọ́n, ọpẹ́ ni pé, kò sí èyí tó jọ pé ó burú. Bí ó ti wù kí ó rí, mo ní ìrora amúniṣàárẹ̀ ní ẹsẹ̀ mi, tó mú kí n má lè yíra padà. Ẹsẹ̀ méjèèjì ti dá.
Níkẹyìn, nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, àwọn dókítà pe ìfarapa mi ní “kékeré.” Lóòótọ́, wọ́n kéré, bí a bá fi wé ti àwọn mìíràn tó là á já. Wọ́n fa ọkùnrin kan jáde nínú àfọ́kù ọkọ̀ náà láìsí ẹsẹ̀ kankan. Àwọn mìíràn jóná gan-an, títí kan àwọn mẹ́ta tí wọn kò kú síbi ìjàǹbá náà, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá kú lẹ́yìn náà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tí wọ́n fi jẹ̀rora gidigidi.
Iná Náà Mú Kí N Dààmú
Kàkà kí n jẹ́ kí àwọn ìpalára mi gbà mí lọ́kàn, mo wulẹ̀ dààmú nípa bóyá àwọn ayọni-nínú-ewu yóò lè dé ọ̀dọ̀ mi lásìkò. Apá àárín ọkọ̀ òfuurufú náà tí ǹ bá ti jókòó fẹ́rẹ̀ẹ́ rún jégé tán. Èyí tó ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ti gbiná, àwọn èrò tí iná sì ká mọ́ inú rẹ̀ kú ikú onírora. N kò lè gbàgbé bí wọ́n ṣe ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láé.
Ìjókòó mi wà níbi imú ọkọ̀ òfuurufú náà. Mo sún mọ́ ibi ìfọ́yángá náà púpọ̀. Bí mo bá wulẹ̀ tẹ ọrùn sẹ́yìn, mo lè rí ọwọ́ iná náà. Ẹ̀rù bà mí pé bí àkókò ti ń lọ, kò ní pẹ́ tí iná yóò fi jó dé ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ pé kò jó débẹ̀.
Wọ́n Yọ Mí Níkẹyìn!
Ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan rọra ń kọjá. Ó lé ní wákàtí kan. Níkẹyìn, àwọn ayọni-nínú-ewu díẹ̀ ṣàwárí ibi tí ìjàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí agogo mẹ́ta òru. Mo gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lórí òkè, tí wọ́n ń fìyanu hàn nípa ohun tí wọ́n rí. Ọ̀kan lára wọn kígbe pé: “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wà níbẹ̀?”
Mo kígbe padà tìroratìrora pé: “Ibí ni mo wà. Ẹ ràn mí lọ́wọ́!” Àwọn èrò ọkọ̀ mìíràn dáhùn pẹ̀lú. Ayọni-nínú-ewu kan pe òmíràn ní “Ted.” Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Jọ̀wọ́, Ted, ìhín ni mo wà!” àti, “Ted, wá ràn wá lọ́wọ́!”
Ìdáhùn náà ni pé: “A ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀! Ẹ wulẹ̀ dúró.”
Òjò tí ń rọ̀, tó ṣeé ṣe kó ti gba ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ iná náà, wá ṣèdíwọ́ láti sọ̀ lórí òkè gogoro náà. Nítorí náà, wákàtí kan mìíràn kọjá kí àwọn ayọni-nínú-ewu náà tó dé ọ̀dọ̀ àwọn olùlàájá. Àkókò tó gbà wọ́n láti wá mi kàn dà bí ayérayé lójú mi.
Àwọn ayọni-nínú-ewu méjì tó gbé iná tọ́ọ̀ṣì lọ́wọ́ sọ pé: “A ti déhìn-ín. Má dààmú.” Láìpẹ́, àwọn ayọni-nínú-ewu méjì mìíràn dara pọ̀ mọ́ wọn, lápapọ̀, wọ́n gbìyànjú láti gbé mi. Àwọn méjì gbé mi lápá, àwọn méjì tó kù sì gbé mi lẹ́sẹ̀. Gbígbé tí wọ́n gbé mi bẹ́ẹ̀ fa ìrora fún mi jù, ní pàtàkì, nítorí pé ẹrẹ̀ náà ń yọ̀ wọ́n. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ síwájú díẹ̀, wọ́n gbé mi kalẹ̀. Ọ̀kan lára wọn lọ gbé bẹ́ẹ̀dì tí wọ́n fi ń gbáláìsàn, wọ́n sì gbé mi lọ síbi tí hẹlikópítà ológun kan ti lè gbé mi lọ síbi ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbáláìsàn kan lórí òkè náà.
Rírí Ìyàwó Mi, Níkẹyìn!
Agogo márùn-ún ààbọ̀ òwúrọ̀ ti lù kí n tó dé iyàrá ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn. Àwọn dókítà kò gbà mí láyè láti lo tẹlifóònù nítorí bí mo ṣe fara pa púpọ̀ tó. Nítorí náà, ìyàwó mi kò mọ̀ pé mo la ìjábá náà já títí di agogo mẹ́wàá ààbọ̀ òwúrọ̀, nǹkan bí wákàtí mẹ́sàn-án lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfuurufú náà ti já bọ́. Ọ̀rẹ́ kan tó rí orúkọ mi lára orúkọ àwọn tó là á já ló sọ fún un.
Nígbà tí wọ́n wá gba ìyàwó mi láyè láti rí mi níkẹyìn ní nǹkan bí agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, n kò tètè dá a mọ̀. Àwọn egbòogi apàrora ti sọ agbára ìmọ̀lára mi daláìlágbára. Àwọn ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ ni pé: “O ṣeun tí o wà láàyè.” N kò rántí ìjíròrò náà, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún mi lẹ́yìn náà pé mo dáhùn pé: “Máà dúpẹ́ lọ́wọ́ mi. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”
Fífi Àwọn Ohun Àkọ́múṣe sí Àyè Tó Yẹ Wọ́n
Bí ara mi ṣe ń yá bọ̀ nílé ìwòsàn, ìrora tí mo ń ní kò ṣàjèjì sí mi. Ní 1987, tí kò pé ọdún kan lẹ́yìn tí mo kó kúrò ní Korea wá sí Guam, mo ṣubú láti orí pákó tí a ń dúró lé nígbà tí a bá ń kọ́lé, tó wà ní àjà kẹta, ẹsẹ̀ mi méjèèjì sì dá. Ìyẹn ti jẹ́ ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé mi. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, tó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ti ń rọ̀ mí tẹ́lẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mẹ́fà tí mo lò nílé ìwòsàn fún mi láǹfààní láti ṣe èyí. Ní ìyọrísí rẹ̀, ní ọdún yẹn kan náà, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, mo sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ìrìbọmi.
Láti ìgbà ìjàǹbá ọkọ̀ òfuurufú náà ni mo ti ń ronú nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí mo yàn láàyò, tó wí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba [Ọlọ́run] àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Nígbà tí mo ń kọ́fẹ padà lẹ́yìn ìjàǹbá ọkọ̀ òfuurufú náà, mo ní àǹfààní láti tún díye lé ìgbésí ayé mi.
Lọ́nà lílágbára kan, ìjàǹbá ọkọ̀ òfuurufú nọnba 801 tẹ bí ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó mọ́ mi lọ́kàn. Mo ti lè kú wẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ yẹn! (Oníwàásù 9:11) Bí ipò náà ti rí, mo nílò iṣẹ́ abẹ mélòó kan láti ṣàtúnṣe ara mi, mo sì lò ju oṣù kan lọ ní kíkọ́fẹpadà ní ilé ìwòsàn.
Nígbà yìí ni mo fẹ́ fi han Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa pé mo mọrírì ẹ̀bùn àgbàyanu ti ìwàláàyè gidigidi, títí kan àwọn ìpèsè tí ó ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Mo mọ̀ pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ hàn jẹ́ nípa fífi ire Ìjọba sípò kìíní nìṣó nínú ìgbésí ayé mi.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
US Navy/Sipa Press