ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 4/8 ojú ìwé 18-19
  • Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ha Wà Ní Tòótọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ha Wà Ní Tòótọ́ Bí?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣarasíhùwà Ìdẹ̀rùn
  • Àìgbàgbọ́ Ń Fa Ìṣòro Lílekoko Kan
  • Àwọn Olubi Ẹlẹ́tàn
  • Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Àwọn Wo Ni Ẹ̀mí Èṣù?
    Jí!—2010
  • Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 4/8 ojú ìwé 18-19

Ojú Ìwòye Bíbélì

Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ha Wà Ní Tòótọ́ Bí?

LÁÀÁRÍN ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, ìgbétáásì inúnibíni gbígbónájanjan kan lòdì sí àwọn àjẹ́ wáyé káàkiri ibi púpọ̀ jù lọ ní Yúróòpù. Wọ́n dá ọ̀pọ̀ àwọn tí a pè ní àjẹ́ lóró gan-an. Àwọn kan tí a fẹ̀sùn èké kàn sọ pé àwọn jẹ́ àjẹ́ kí wọ́n baà lè bọ́ nínú ìdálóró náà. Àìníye ènìyàn ni wọ́n pa látàrí àhesọ tàbí ìfura.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé lòdì sí iṣẹ́ àjẹ́, irú ìbẹ́mìílò kan, karí Ìwé Mímọ́, dájúdájú àṣejù ni. A kò gbé iṣẹ́ ìdálóró tàbí pípa àwọn àjẹ́ tàbí àwọn abẹ́mìílò mìíràn lé àwọn Kristẹni lọ́wọ́. (Róòmù 12:19) Ìṣarasíhùwà wo ló wọ́pọ̀ lónìí?

Ìṣarasíhùwà Ìdẹ̀rùn

Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ka irú àṣà ìbẹ́mìílò bẹ́ẹ̀ sí bàbàrà. Nítorí ojúmìító, àwọn kan lè máa ṣe iṣẹ́ ìwòràwọ̀, idán pípa, iṣẹ́ wíwò, àti iṣẹ́ àjẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò ka àwọn àṣà ẹgbẹ́ awo wọ̀nyí sí bíbá ẹ̀mí èṣù lò. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn òṣèré, àwọn eléré ìdárayá, àti àwọn òṣèlú ń jẹ́wọ́ ní gbangba pé àwọn wà nínú ẹgbẹ́ awo. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé, àwọn ìwé àti sinimá kan ṣàgbéyọ àwọn àjẹ́ àti àwọn oṣó bí “ẹni tí ó jojú ní gbèsè, tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ díẹ̀, tí àwọn ìgbòkègbodò agbára títayọ wọn kì í pa ẹnikẹ́ni lára.” Àwọn ìwé tí a pète láti dá àwọn ọmọdé lára yá, kí wọ́n sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, lè gbé àwọn àkọlé ẹlẹ́gbẹ́-òkùnkùn jáde.

Irú ìṣarasíhùwà ìdẹ̀rùn àti ìfọwọ́-dẹngbẹrẹ-múǹkan bẹ́ẹ̀ nípa ẹ̀mí èṣù lè yọrí sí àìgbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà. Ìwọ ha gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà àti pé wọ́n ń gbìyànjú láti pa wá lára bí? Bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí ni yóò sọ pé àwọn kò tíì ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù rí tàbí pé àwọn kò tíì rí iṣẹ́ wọn rí. Àwọn ẹ̀mí èṣù ha wà ní tòótọ́ bí?

Àìgbàgbọ́ Ń Fa Ìṣòro Lílekoko Kan

Àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn tẹ́wọ́ gba Bíbélì, àmọ́ tí wọn ṣiyèméjì nípa pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà ní tòótọ́ dojú kọ ìṣòro lílekoko kan. Bí wọn kò bá gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà ní tòótọ́, wọ́n ń fi ìwọ̀n àìnígbàgbọ́ kan hàn nínú Bíbélì. Èé ṣe? Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, kọ́ni pé àwọn ẹ̀mí búburú ní agbára tí ó ré kọjá ti ẹ̀dá.

Ìwé àkọ́kọ́ nínú rẹ̀, Jẹ́nẹ́sísì, sọ bí ẹ̀dá onílàákàyè kan ṣe lo ejò kan láti tan Éfà jẹ, tí ó sì fà á sínú ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì, Ìṣípayá, tọ́ka sí atannijẹ búburú yìí, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” bí “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Sátánì ṣàṣeyọrí nínú fífa àwọn áńgẹ́lì mìíràn sínú ìṣọ̀tẹ̀. (Júdà 6) Nínú Bíbélì, a pe àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ṣubú wọ̀nyí ní ẹ̀mí èṣù. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní sàkáání ilẹ̀ ayé, inú sì ń bí wọn gidigidi sí Ọlọ́run àti sí àwọn tí ń sìn ín.—Ìṣípayá 12:12.

Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ní agbára láti darí àwọn ẹ̀dá ènìyàn, láti pa wọ́n lára, kí wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀. (Lúùkù 8:27-33) Wọ́n ti fara balẹ̀ wo àbùdá ẹ̀dá ènìyàn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Wọ́n mọ bí àwọn ṣe lè lo àwọn àìlera ẹ̀dá ènìyàn láti fi mú wọn. Bíbélì ròyìn àwọn ọ̀ràn kan tí wọ́n ti gbé àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé dè, tàbí tí wọ́n ti lò wọ́n pátápátá. (Mátíù 15:22; Máàkù 5:2) Wọ́n lè fa àrùn tàbí àbùkù ara bí ìfọ́jú. (Jóòbù 2:6, 7; Mátíù 9:32, 33; 12:22; 17:14-18) Wọ́n tún lè fọ́ èrò inú àwọn ènìyàn lójú. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Àwọn ẹ̀mí èṣù ń bá iṣẹ́ lọ láìdáwọ́dúró, bí aṣáájú wọn, Sátánì, tí ó dà bí “kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Bíbélì ní ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ nípa wíwà àwọn ẹ̀mí èṣù nínú. Bí o bá gba Bíbélì gbọ́, nígbà náà o gbà pé àwọn ẹ̀dá búburú tí a kò lè fojú rí wà ní tòótọ́.

Àwọn Olubi Ẹlẹ́tàn

Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ẹ̀mí èṣù lílágbára ṣe lè wà lónìí láìsí pé wọ́n ń dá ìpayà tí kò lópin sílẹ̀ lágbàáyé? Kí ló dé tí wíwà níhìn-ín wọn àti àwọn iṣẹ́ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ hàn ní gbangba? Bíbélì dáhùn pé: “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ẹlẹ́tàn ni Èṣù. Ó sábà máa ń díbọ́n yí ìgbòkègbodò ẹ̀mí èṣù padà bí ohun tí kò lè pani lára tàbí tí ó tilẹ̀ ṣàǹfààní. Nítorí náà, ó ṣòro láti mọ̀.

Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń bá a lọ ní pípọ́n àwọn ènìyàn lójú lónírúurú ọ̀nà, bí wọ́n ti ṣe ní àkókò tí a ń kọ Bíbélì. Àwọn kan tí wọ́n ti di ojúlówó Kristẹni nísinsìnyí ti lọ́wọ́ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn nígbà kan; wọ́n lè jẹ́rìí sí àwọn ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí ó wà nínú ìkọlù ẹ̀mí èṣù. Bóyá lọ́nà tí ó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn ẹ̀mí èṣù ń lo agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ tí wọ́n ní lónìí láti fa àwọn ènìyàn sínú àwọn iṣẹ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní tààrà. A kò gbọ́dọ̀ fojú kéré agbára wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ń ṣàṣeparí ohun púpọ̀ nípa títan àwọn ènìyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ju pípa-wọn-láyà lọ. Bíbélì sọ pé, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Èrò wọn jẹ́ láti máa fi ọgbọ́n àti ẹ̀tàn sọ ipò tẹ̀mí di aláìlágbára.

Àwọn ẹ̀mí èṣù wà ní tòótọ́. Báwo ni à bá ṣe ṣàlàyé òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ àti ìparun tí a kò lè paná rẹ̀ tí a rí ẹ̀rí rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn? Lọ́nà àdánidá, àwọn ẹ̀dá ènìyàn fẹ́ láti máa gbé lálàáfíà àti ayọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé ìwà ibi lárugẹ, wọ́n sì ní agbára láti darí èrò inú ẹ̀dá, kí wọ́n sì bà á jẹ́.

Síbẹ̀, Jèhófà ni Ọlọ́run alágbára ńlá gbogbo—tí ó lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ. Ó ń pèsè okun àti ààbò rẹ̀ lòdì sí “àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11-18) Kò sí ìdí fún wa láti ní ìbẹ̀rùbojo fún àwọn ẹ̀mí èṣù, nítorí pé Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]

Sipa Icono

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́