ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 18-20
  • Ọ̀nà Márùn-ún Láti Mú Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Sunwọ̀n sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Márùn-ún Láti Mú Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Sunwọ̀n sí I
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èkíní: Dá Oko
  • Èkejì: Máa Rajà Lọ́pọ̀
  • Ẹ̀kẹta: Kọ́ Bí A Ṣe Ń Tọ́jú Oúnjẹ Kó Má Bàjẹ́
  • Ẹ̀kẹrin: Gbìyànjú Sísin Ohun Ọ̀sìn Níwọ̀nba
  • Ẹ̀karùn-ún: Máa Ṣèmọ́tótó Bó Ṣe Yẹ
  • Kí Nìdí Tí Ìmọ́tótó Fi Ṣe Pàtàkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Pípèsè Oúnjẹ Látinú Oko Rẹ
    Jí!—2003
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Bójú Tó Agbo Ilé?
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ohun Tó Máa Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 18-20

Ọ̀nà Márùn-ún Láti Mú Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Sunwọ̀n sí I

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ORÍLẸ̀-ÈDÈ OLÓMÌNIRA ÀÁRÍNGBÙNGBÙN ÁFÍRÍKÀ

Ọ̀WỌ́NGÓGÓ ọjà, àìsàn, àìjẹunrekánú, ipò òṣì—àwọn ìṣòro wọ̀nyí tàn kálẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Ó kéré tán, bí ènìyàn ṣe ń wò ó, kò sí ojútùú kankan tí ń bọ̀ láìpẹ́. Bí o bá ń gbé orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí o lè ṣe láti mú kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà! Àwọn àbá márùn-ún tí o lè rí i pé ó wúlò, ó sì gbéṣẹ́, nìyí.

Èkíní: Dá Oko

Nínú Òwe 28:19, Bíbélì wí pé: “Ẹni tí ó bá ń ro ilẹ̀ tirẹ̀ yóò ní oúnjẹ tí ó pọ̀ tó.” Ní tòótọ́, ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí bí irè tí o lè kó lórí ilẹ̀ kan tó mọ níwọ̀n ṣe pọ̀ tó. Nínú ìwé rẹ̀, Le jardin potager sous les tropiques (Oko Ẹ̀fọ́ Nílẹ̀ Olóoru), òǹkọ̀wé Henk Waayenberg sọ pé, ilẹ̀ tó bá wọn 50 sí 100 mítà níbùú lóròó lè mú ẹ̀fọ́ tó pọ̀ tó láti bọ́ ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́fà jáde!

Kí ló dé tí o ó fi máa fowó ra àwọn nǹkan tí o lè gbìn fúnra rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ àti ipò ojú ọjọ́ bá ṣe pinnu rẹ̀, o lè gbin àwọn irè bí ilá, ata, ẹ̀fọ́, ewé tíì, àlùbọ́sà eléwé, pákí, elégédé, ọ̀dùnkún, ìrèké, tòmátì, apálá, àti àgbàdo sí ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ gan-an. Ó wá kéré pin, irú ọgbà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ àfikún oúnjẹ fún ìdílé rẹ, o sì tilẹ̀ lè ní àjẹṣẹ́kù tí o lè tà.

Bí o bá ní ilẹ̀ tó pọ̀ tó, o tún lè ronú kan gbígbin onírúurú igi eléso. Nígbà mìíràn, igi eléso kan ṣoṣo lè so èso tó pọ̀ ju èyí tí ìwọ àti ìdílé rẹ lè jẹ lọ. Mímọ̀ nípa bí a ṣe ń sọ àwọn ohun ìṣẹ̀fọ́-ìṣẹran di èròjà ajílẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí o pèsè oúnjẹ lọ́nà tó dára sí i. Àwọn igi lè ṣe ju wíwulẹ̀ pèsè oúnjẹ àti mímú àfikún owó wọlé fún ìdílé rẹ lọ. Àwọn igi tí a gbìn síbi tó yẹ tún lè pèsè ìbòòji, kí wọ́n sọ afẹ́fẹ́ di mímọ́, kí wọ́n sì mú kí àyíká rẹ túbọ̀ lẹ́wà, kó sì gbádùn mọ́ni.

Àmọ́, bí o kò bá mọ nǹkan púpọ̀ nípa oko dídá ńkọ́? Ǹjẹ́ o ní àwọn ọ̀rẹ́, aládùúgbò, tàbí ojúlùmọ̀ tó ní ìrírí nípa èyí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o kò ṣe ní kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n gbà ọ́ nímọ̀ràn? Ó tún lè ṣeé ṣe fún ọ láti ra àwọn ìwé kan lórí gbígbin ọgbà, tàbí kí o tọrọ wọn.—Wo àpilẹ̀kọ náà, “Èé Ṣe Tí O Kò Dá Oko Ẹ̀fọ́ Kan?,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! (Gẹ̀ẹ́sì), May 22, 1974.

Èkejì: Máa Rajà Lọ́pọ̀

Ǹjẹ́ o máa ń ra àwọn ọjà kòṣeémánìí bí ìyẹ̀fun, ìrẹsì, àti òróró níwọ̀n díẹ̀díẹ̀? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ pé o ń fi ọ̀pọ̀ owó ìná tí o wéwèé ṣòfò ni. Dípò ìyẹn, bí ó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú kí o máa ra irú àwọn èlò oúnjẹ bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀, kí ìwọ àti àwọn ìdílé méjì, mẹ́ta, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ máa pín owó rẹ̀ san. Ríra ọjà lọ́pọ̀ tún lè dín ìnáwó rẹ kù nígbà tí àwọn èso tàbí ẹ̀fọ́ kan bá wà ní àkókò tí wọ́n dára jù lọ láti jẹ. Nígbà mìíràn, o tilẹ̀ lè ra àwọn nǹkan ní àràtúntà.

Ẹ̀kẹta: Kọ́ Bí A Ṣe Ń Tọ́jú Oúnjẹ Kó Má Bàjẹ́

Ríra nǹkan lọ́pọ̀ fa ìbéèrè nípa bí a ó ṣe máa tọ́jú àwọn ohun tó lè bàjẹ́. Ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́, tó sì wọ́pọ̀ ni sísá oúnjẹ. Ọ̀pọ̀ obìnrin ní Áfíríkà ń gbọ́ bùkátà wọn nípa sísá àwọn èso, ilá, ẹ̀wà, gbọ̀rọ̀, hóró elégédé, àti àwọn irúgbìn amóúnjẹ-tasánsán. Sísá nǹkan gbẹ kò nílò ohun èlò àrà ọ̀tọ̀ kankan. A lè na ohun tí a fẹ́ sá sórí ilẹ̀ títẹ́jú tó mọ́, tàbí kí a gbé e kọ́, bóyá kí a fi aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bò ó nítorí eṣinṣin. Afẹ́fẹ́ àti oòrùn ni yóò ṣe èyí tó bá kù.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Ǹjẹ́ O Lè Gbọ́ Bùkátà Yọrí Nípa Lílo Ohun Àmúṣọrọ̀ Kékeré?,” nínú ìtẹ̀jáde Jí! (Gẹ̀ẹ́sì), August 8, 1975.

Ẹ̀kẹrin: Gbìyànjú Sísin Ohun Ọ̀sìn Níwọ̀nba

Ǹjẹ́ o lè máa sin adìyẹ, ewúrẹ́, ẹyẹlé, tàbí àwọn ẹran mìíràn fúnra rẹ? Ẹran ti di oúnjẹ olówó níbi púpọ̀. Ṣùgbọ́n bí o bá rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, o lè kọ́ bí a ṣe ń sin ẹran díẹ̀. Ṣé o máa ń gbádùn ẹja jíjẹ? Ó dára, o lè gbìyànjú láti kọ́ bí a ṣe ń ṣe odò ẹja kékeré kan. Ẹran, ẹyin, àti ẹja ní àwọn èròjà iron, calcium, fítámì, mineral, protein—àwọn ohun tó ṣe pàtàkì fún ìlera ìdílé rẹ.

Ẹ̀karùn-ún: Máa Ṣèmọ́tótó Bó Ṣe Yẹ

Ìmọ́tótó tún ṣe pàtàkì fún ìlera ìdílé rẹ. Àìsí ìmọ́tótó ń fa àwọn eku, eṣinṣin, àti aáyán—àwọn ohun tí ń fa onírúurú àrùn. Ṣíṣe ìmọ́tótó bó ṣe yẹ yóò gbà ọ́ lákòókò àti ìsapá. Ṣùgbọ́n ohun tí ìmọ́tótó yóò ná ọ kò tó owó egbòogi àti owó iṣẹ́ dókítà. Ìlànà ìmọ́tótó ń yàtọ̀ síra láàárín àwọn ènìyàn àti láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìlànà kan wà tó jẹ́ ti gbogbogbòò níbi gbogbo.

Bí àpẹẹrẹ, mú ọ̀ràn àwọn ibi ìtura. Ní àwọn àrọko, àwọn ènìyàn sábà máa ń jẹ́ kí wọ́n dọ̀tí, kí wọ́n di ẹgẹrẹmìtì, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ dí ibi tí a ti ń kó àwọn àìsàn àti àrùn. Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ládùúgbò lè fún ọ ní àwọn ìtọ́ni lórí bí o ṣe lè kọ́ ilé ìyàgbẹ́ mímọ́tónítóní lówó pọ́ọ́kú.

Ilé rẹ gan-an ńkọ́? Ṣé ó mọ́, o sì tò ó nigínnigín? Ǹjẹ́ òórùn rẹ̀ dára? Ilé ìdáná oúnjẹ rẹ ńkọ́? Ǹjẹ́ ó wà létòlétò, ó sì mọ́? Oúnjẹ gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́, kí a sì sè é dáradára, kí ara ẹni lè le. Àwọn kòkòrò àrùn àti kòkòrò àfòmọ́ ń pọ̀ nínú omi tó bá lẹ́gbin. Nítorí náà, sẹ́ omi, tàbí kí o sè é kí o tó lò ó. Máa fi omi gbígbóná ṣan àwọn ohun tí o fi ń jẹun, kí o sì máa fọwọ́ rẹ dáadáa kí o tó fọwọ́ kan oúnjẹ. Máa pọn omi sínú àwọn ohun ìpọnmisí tó mọ́, tó sì wà ní bíbò.

Kò yẹ kí o gba àwọn ajá, ológbò, adìyẹ, àti ewúrẹ́ láyè láti máa rìn kiri nílé ìdáná oúnjẹ—bí o bá ń fẹ́ àyíká tó mọ́ tónítóní. Bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí o gba àwọn èkúté àti eku láyè láti kọjá nínú àwọn ìkòkò àti abọ́, kí wọ́n ba oúnjẹ rẹ jẹ́. Àjànpa kan lásán lè yanjú ìṣòro náà.—Wo “Kíkojú Ìpèníjà Ìmọ́fínnífínní,” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, March 22, 1989.

Níkẹyìn pátápátá, Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni yóò tán gbogbo ìṣòro aráyé láìkùsíbìkan. (Mátíù 6:9, 10) Bí ó ti wù kí ó rí, kí àsìkò yẹn tó dé, àwọn ìmọ̀ràn rírọrùn wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Dá oko

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Máa rajà lọ́pọ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kọ́ bí a ṣe ń tọ́jú oúnjẹ kó má bàjẹ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Gbìyànjú sísin ohun ọ̀sìn níwọ̀nba

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Máa ṣèmọ́tótó bó ṣe yẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́