ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/22 ojú ìwé 31
  • Àwọn Oyin Mi Bá Adìyẹ Pamọ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Oyin Mi Bá Adìyẹ Pamọ!
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́
    Jí!—2009
  • Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Malle Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Jí!—1998
g98 5/22 ojú ìwé 31

Àwọn Oyin Mi Bá Adìyẹ Pamọ!

OKO kékeré kan ní àríwá Sweden ni mo ń gbé. Láìpẹ́ yìí, nígbà tí méjì lára àwọn àgbébọ̀ adìyẹ mi bẹ̀rẹ̀ sí í sàba, mo ṣàkíyèsí bí wọ́n ṣe ń ṣe. Ni ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí ọ̀kan pamọ àkọ́kọ́, díẹ̀ lára àwọn òròmọdìyẹ náà jẹ̀ lọ, wọ́n sì kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgbébọ̀ adìyẹ kejì. Bí ó ti rò pé tòun ni àwọn òròmọdìyẹ náà, ó fò fẹ̀rẹ̀ dìde, ó fi àwọn ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì kó àwọn òròmọdìyẹ náà sábẹ́. Ó jọ pé àwọn òròmọdìyẹ náà kò bìkítà nípa àgbébọ̀ adìyẹ yòówù kí ó ṣètọ́jú wọn.

Mo gbìyànjú láti jẹ́ kí àgbébọ̀ adìyẹ náà dá àwọn òròmọdìyẹ tí ó “jí kó” padà, kí ó sì padà lọ máa sàba lórí àwọn ẹyin tirẹ̀, àmọ́ pàbó ni ìsapá mi já sí. Bí mo ti fẹ́ da àwọn ẹyin tí ó kọ̀ sílẹ̀ náà nù ni kinní kan bá sọ sí mi lọ́kàn pé, ‘Ẹ̀mí kan mà ṣì lè wà nínú wọn!’ Èrò kan sì wá sí mi lọ́kàn.

Àwùjọ àwọn kòkòrò oyin títóbi kan máa ń ní ìwọ̀n ooru ara tí ó jẹ́ nǹkan bí 34 lórí òṣùwọ̀n Celsius nínú ilé wọn. Nítorí náà, mo kó àwọn ẹyin náà sínú òwú, mo sì gbé e sórí ibi tí ó wà fún pípamọ nínú ọ̀kan lára àwọn ilé oyin mi. Lẹ́yìn náà, mo gbé ife omi méjì sítòsí wọn, kí “ìtẹ́” náà lè lọ́rinrin. Mo ń yí ẹyin náà padà lójoojúmọ́, èyí sì ń jẹ́ kí ó dà bí ìgbà tí àgbébọ̀ adìyẹ kan ń sàba.

Lẹ́yìn ọjọ́ bí mélòó kan, mo ń gbọ́ tí àwọn ohùn kan ń dún kúlúkúlú lọ́nà tí ó ṣe ketekete ní inú mélòó kan lára àwọn ẹyin náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni òròmọdìyẹ kékeré kan tí ara rẹ̀ tutù yọ jáde nínú èèpo rẹ̀! Mo mú un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo sì fi sí abẹ́ àgbébọ̀ adìyẹ tí ó fi àwọn ẹyin rẹ̀ sílẹ̀. Inú mi dùn pé ó gbà á. Ó wá ní òròmọ abìyẹ́múlọ́múlọ́ 12 láti bójú tó, ọpẹ́ ni fún àwọn oyin tí ń ṣiṣẹ́ kára.—A kọ ọ́ ráńṣẹ́.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbogbo àwòrán: Foto, Roland Berggren, Västerbottens-Kuriren, Sverige

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́