Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Rántí Ohun Tó Ti Kọjá?
“ǸJẸ́ àwọn Júù lè gbàgbé Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà?” Virgil Elizondo, ààrẹ Ibùdó Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Mexico òun Amẹ́ríkà, ní San Antonio, Texas, ló béèrè ìbéèrè yìí. Ó rán wa létí pé, lápapọ̀, àwọn ènìyàn lè máa rántí àwọn àpá tí kò ṣeé gbàgbé tí àwọn ìwà ìkà tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún yìí dá sí wọn lára. A gbọ́dọ̀ ka ìparun ẹ̀yà àwọn ará Armenia (1915 sí 1923) àti ìpalápalù àwọn ará Cambodia (1975 sí 1979) pẹ̀lú mọ́ àwọn ìwà ìkà ọ̀rúndún ogún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìwà ìkà náà kò ṣeé tò lẹ́sẹẹsẹ tán.
Àwọn aṣáájú onísìn àti òṣèlú ti gbìyànjú láti mú kí àwọn tí a fìyà jẹ àti àwọn tó jẹ wọ́n níyà tún padà rẹ́ nípa rírọ àwọn ènìyàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti gbàgbé àwọn ìwà ìkà tí a ti hù sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, èyí ṣẹlẹ̀ ní Áténì, Gíríìsì, ní ọdún 403 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìlú náà ṣẹ̀ṣẹ̀ rẹ́yìn odì ìṣàkóso afipátẹni-lóríba àwọn Ọgbọ̀n Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ni, ìjọba tí àwọn ènìyàn kéréje kan ṣe, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ yẹ ojú gbogbo àwọn alátakò wọn tán. Àwọn alákòóso tuntun ń wá ọ̀nà láti dá ìṣọ̀kan ará ìlú padà sípò nípa ṣíṣe òfin ìdáríjì (láti inú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí ó túmọ̀ sí “àìmọ̀” tàbí “ìgbàgbé”) fún àwọn alátìlẹ́yìn ìjọba oníkùmọ̀ tó kógbá sílé náà.
Ǹjẹ́ A Lè Gbàgbé Nítorí A Ti Ṣe Òfin Ìdáríjì?
Dé ìwọ̀n kan, ó lè rọrùn láti gbìyànjú láti fi òfin fagi lé rírántí àwọn ìwà ìkà tí a ti hù sí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Àwọn aláṣẹ lè pinnu láti ṣe èyí nítorí àǹfààní ìṣèlú, bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní Gíríìsì ìgbàanì àti ní onírúurú orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Yúróòpù ní ìparí Ogun Àgbáyé Kejì. Bí àpẹẹrẹ, ní Ítálì, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn La Repubblica ṣe sọ, a ṣe òfin kan ní 1946, tó dárí ji àwọn ará ìlú tó lé ní 200,000 tó “jẹ̀bi lílọ́wọ́ sí ìwàkiwà ìṣàkóso Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ lọ́nà kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan ni ìpinnu ìjọba tàbí àwọn àjọ ará ìlú jẹ́. Ohun mìíràn ni ìmọ̀lára ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwùjọ kan jẹ́. Kò ṣeé ṣe pé ká fi òfin tipátipá mú aráàlú kọ̀ọ̀kan—bóyá àwọn tí kò lè gbèjà ara wọn tí a fìyà jẹ nínú àwọn ìforígbárí oníwà ìkà, ìpakúpa, tàbí àwọn ìwà àìṣènìyàn mìíràn—láti gbàgbé ìyà tó ti jẹ wọ́n sẹ́yìn.
Ní ọ̀rúndún yìí nìkan, àwọn tó ti kú nígbà ogun ti lé ní 100 mílíọ̀nù, tí ọ̀pọ̀ wọn kú lẹ́yìn ìjìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ. Bí a bá fi àwọn tí wọ́n pa nígbà àwọn ìpakúpa tí ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí kò sógun kún un, ìwà ìkà náà kò ní ṣeé ṣírò. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń sa gbogbo ipá láti rí i pé a kò gbàgbé èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí.
Àwọn Tí Ì Bá Fẹ́ Pa Ìrántí Náà Rẹ́
Àwọn tí ń rọ àwọn tí a hùwà ìkà sí tàbí àwọn àtìrandíran wọn láti dárí jì, kí wọ́n sì gbàgbé sábà máa ń sọ pé rírántí ohun tó ti kọjá wulẹ̀ ń fa ìyapa ni, ní pàtàkì bí ọjọ́ bá ti gorí ọjọ́. Wọ́n sọ pé gbígbàgbé ń mú ìṣọ̀kan wá, nígbà tí rírántí kò lè tún ohun tó ti bàjẹ́ ṣe, bí ó ti wù kí ìjìyà náà ti pọ̀ tó.
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn kan ń gbìyànjú láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn gbàgbé, wọ́n ṣe é débi pé wọ́n sẹ́, wọ́n sì sọ pé a kò hu ìwà ìkà kankan sí ìran ènìyàn ní gidi. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí ń lo ìròyìn tí àwọn òpìtàn alátùn-únṣe àdábọwọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ìtìlẹ́yìn wọn ti sọ pé, kò sí Ìpakúpa kan nígbà kankan.a Wọ́n tilẹ̀ ń ṣètò fún ìrìn àjò afẹ́ lọ sí àwọn àgọ́ ìparun àtijọ́, irú ti Auschwitz tàbí Treblinka, wọ́n sì ń sọ fún àwọn olùbẹ̀wò pé kò sí àwọn ìyẹ̀wù ìfigáàsìpani kankan níbẹ̀ rí—wọ́n ń sọ èyí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹni tó fojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti àwọn ẹ̀rí pelemọ àti àkọsílẹ̀ wà, tó lòdì sí ohun tí wọ́n ń sọ.
Báwo ló ṣe jẹ́ tí àwọn èrò alátùn-únṣe èké fi kẹ́sẹ járí ní àárín àwùjọ àwọn ènìyàn kan? Ó jẹ́ nítorí pé àwọn kan ń yàn láti gbàgbé ojúṣe tiwọn fúnra wọn àti ti àwọn ènìyàn wọn. Èé ṣe? Nítorí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, èròǹgbà ara wọn, tàbí ìmọ̀lára àìnífẹ̀ẹ́ àwọn Júù tàbí irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ mìíràn. Àwọn alátùn-únṣe rò pé, ní gbàrà tí a bá ti gbàgbé àwọn ìwà ìkà, kò sí ọ̀ràn ojúṣe mọ́. Ṣùgbọ́n, tagbáratagbára ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lòdì sí àwọn alátùn-únṣe tí kò ka ojúṣe sí wọ̀nyí, tí òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé kan pè ní “àwọn amọ̀ọ́mọ̀-pàrántí.”
Wọn Kò Gbàgbé
Ó dájú pé ó ṣòro púpọ̀ fún àwọn olùlàájá láti gbàgbé àwọn olólùfẹ́ wọn tó kú nígbà ogun tàbí àwọn tí a ṣìkà pa. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń fẹ́ ṣèrántí àwọn ìpakúpa àti ìparun ẹ̀yà ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìrètí pé àwọn ẹ̀kọ́ tí a ń fà yọ láti inú àwọn ìyà tó jẹ àwọn àti àwọn olólùfẹ́ àwọn yóò wúlò láti mú kí a má ṣe tún hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀.
Nípa bẹ́ẹ̀, ìjọba ilẹ̀ Germany ti pinnu láti ṣèrántí ṣíṣàwárí àwọn ìwàkiwà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí àwọn Nazi hù ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Auschwitz. Gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ilẹ̀ Germany ṣe wí, ète rẹ̀ ni pé, “rírántí yóò jẹ́ ìkìlọ̀ kan fún àwọn ìran tí ń bọ̀.”
Bákan náà, nígbà ìrántí àádọ́ta ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, Póòpù John Paul Kejì sọ pé: “Bí ọdún ti ń gorí ọdún, a kò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà Ogun náà; kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n di ẹ̀kọ́ aláìgbagbẹ̀rẹ́ fún ìran wa àti àwọn ìran tí ń bọ̀.” Síbẹ̀, ó yẹ kí a sọ pé Ìjọ Kátólíìkì kò dúró sójú kan ní rírántí àwọn ìwà ìkà tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn àti àwọn tí ìyà jẹ.
Kí àwọn ìran ènìyàn tuntun lè kọ́ ẹ̀kọ́, kí wọ́n sì gba ìkìlọ̀ lára àwọn ìparun ẹ̀yà nínú ọ̀rúndún yìí àti àwọn mìíràn, a ti dá àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí kan sílẹ̀—irú ti Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ní Ìrántí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tó wà ní Washington, D.C., àti Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Ìráragbaǹkan ní Los Angeles. Nítorí ìdí kan náà, a ti ṣe àwọn ìwé tí ń ru ìmọ̀lára sókè àti àwọn fíìmù mìíràn lórí ọ̀ràn yìí. A ṣe gbogbo èyí ní gbígbìyànjú láti máà jẹ́ kí ìran ènìyàn gbàgbé àwọn tí àwọn ènìyàn mìíràn jẹ níyà.
Èé Ṣe Tí A Fi Ń Rántí?
Ọlọ́gbọ́n èrò orí, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì òun Amẹ́ríkà náà, George Santayana, kọ̀wé pé: “Dandan ni kí àwọn ti kì í rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣe ohun kan náà.” Lọ́nà tó bani nínú jẹ́, ó jọ pé ìran ènìyàn ń yára gbàgbé àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i láàárín àwọn ẹgbẹ̀rúndún tó ti kọjá, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ ọ́ di dandan fún wọn láti tún ṣe àwọn àṣìṣe búburú kan náà léraléra.
Bí àwọn ènìyàn ṣe ń pa ara wọn lápalù léraléra láti ìgbà pípẹ́ wá ń fi hàn ní kedere pé, ìṣàkóso ènìyàn lórí àwọn ènìyàn mìíràn ti já sí ìkùnà pátápátá. Èé ṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé àwọn ènìyàn ti ń ṣe àṣìṣe kan náà léraléra—wọ́n ti kọ Ọlọ́run àti àwọn òfin rẹ̀ sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Oníwàásù 8:9) Gẹ́gẹ́ bí a sì ti sọ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì, lónìí, “ìran . . . onímàgòmágó” kan ń ṣe ohun kan náà, ó sì ń fojú winá àbájáde rẹ̀.—Fílípì 2:15; Sáàmù 92:7; 2 Tímótì 3:1-5, 13.
Níwọ̀n bí a ti mú Ẹlẹ́dàá, Jèhófà, wọnú ìjíròrò wa, kí ni èrò rẹ̀? Kí ni ó máa ń gbàgbé, kí ni ó sì máa ń rántí? Ǹjẹ́ a lè borí àwọn ìyọrísí onírora tí ìwà ìkà tí ènìyàn ti hù ń ní? Ǹjẹ́ “ìwà búburú àwọn ẹni burúkú” yóò “wá sí òpin”?—Sáàmù 7:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni lórí bí ohun tí àwọn òpìtàn alátùn-únṣe ń sọ ṣe jẹ́ irọ́ tó, jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìpakúpa-Rẹpẹtẹ Naa—Bẹẹni, Ó Ṣẹlẹ Niti Gidi!,” tí a tẹ̀ jáde nínú Jí! April 8, 1989, ojú ìwé 4 sí 8.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Dandan ni kí àwọn tí kì í rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún ṣe ohun kan náà.”—George Santayana
Ibi ìdánásun-òkú àti ibi ìdáná ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz
[Credit Line]
Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀m̀báyé-sí Oświęcim