Wúrà—Ìdí Tí A Fi Kà á Sí Bàbàrà
Wúrà—láti ọdún gbọ́nhan ni a ti ń fojú bàbàrà wo mẹ́táàlì aláwọ̀ ìyeyè títànyòyò, tí kò le gbagidi yìí. Àwọ̀ rẹ̀, bí ó ṣe ń dán yanran, bí ó ṣe ṣeé sọ di nǹkan mìíràn, àti bí ó ṣe lè wà láìdógùn-ún mú kí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ láàárín àwọn mẹ́táàlì. Nítorí bí wúrà ṣe níye lórí tó lọ́kàn àwọn tí wọ́n ti wá a kiri, ọ̀rọ̀ ìtàn wúrà yàtọ̀ sí ti àwọn mẹ́táàlì tó kù.
“WÚRÀ! Wúrà ni, ó dá mi lójú! Wúrà!” Àwárí wúrà ti mú kí ayọ̀ gbani lọ́kàn, kí àyà yára lù kìkì, kí ìfojúlọ́nà sì ga. A ti wá a lórí ilẹ̀, nínú odò, kódà, ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún mítà lábẹ́ ilẹ̀.
Nítorí pé wúrà jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ oníyebíye, àwọn ọba àti ayaba ti fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́. A ti fi ṣe àwọn ìtẹ́ àti ògiri ààfin lọ́ṣọ̀ọ́. Àwọn ènìyàn ti bọ àwọn ère ẹja, ẹyẹ, ẹranko, àti àwọn nǹkan mìíràn, tí a fi wúrà ṣe, bí òrìṣà. Wíwá wúrà kiri láìdábọ̀ ti gbilẹ̀ gan-an, ó sì ti nípa gidigidi lórí ìdàgbàsókè.
Wúrà Nínú Ìtàn
Ní Íjíbítì ìgbàanì, àwọn fáráò máa ń rán àwọn oníṣòwò àti ológun wọn láti wá wúrà lọ síbi jíjìnnà, nítorí wọ́n ka wúrà sí ohun èlò àwọn òrìṣà àti ti fáráò ilẹ̀ Íjíbítì nìkan. Ibojì Tutankhamen, tí wọ́n wá rí ní 1922, kún fún ìṣúra wúrà tí kò ṣeé díye lé. Kódà, ojúlówó wúrà ni wọ́n fi ṣe pósí rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn kan ṣe sọ, “àwọn ìtàn nípa ìṣúra wúrà tó wà ní Páṣíà ló kọ́kọ́ fa” Alexander Ńlá “wọ Éṣíà.” Ìròyìn sọ pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹran tí ń ru ẹrù ni àwọn ológun rẹ̀ fi kó wúrà tó fipá gbà ní Páṣíà wá sí Gíríìsì. Nípa bẹ́ẹ̀, Gíríìsì wá di orílẹ̀-èdè tó ní ọ̀pọ̀ wúrà.
Òpìtàn kan sọ pé “àwọn ọba” Róòmù “lo wúrà ní fàlàlà láti jèrè àìyẹhùn àwọn òṣìṣẹ́ wọn, àti láti nípa lórí àwọn ẹni jàǹkàn-jàǹkàn ní àwọn ilẹ̀ mìíràn. Bí wọ́n ṣe lọ́rọ̀ jaburata tó, tí wọ́n sábà máa ń fi hàn nípa ìlò ohun ọ̀ṣọ́ wúrà lọ́nà àṣehàn, wọ àwọn ènìyàn wọn lọ́kàn, ó sì ń ba àwọn ènìyàn náà lẹ́rù nígbà púpọ̀.” Ìwé kan sọ pé ilẹ̀ Róòmù rí ọ̀pọ̀ yanturu wúrà kó nípa ṣíṣẹ́gun ilẹ̀ Sípéènì, tí wọ́n sì gba àwọn ibi ìwakùsà wúrà ilẹ̀ Sípéènì.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìjíròrò àwọn kókó pàtàkì nípa wúrà kò lè kún bí a kò bá sọ nípa ìtàn rẹ̀ tó la ẹ̀mí lọ. Ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtàn ìṣẹ́gun, ìwà òǹrorò, ìsọnidẹrú, àti ikú.
Ìtàn Tó Gba Ẹ̀mí Púpọ̀
Bí ojú ti ń là sí i, àwọn ọkọ̀ òkun tó túbọ̀ tóbi, tó sì túbọ̀ lágbára sí i bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti ṣàwárí àwọn ilẹ̀ tuntun, láti dá ilẹ̀ àgbókèèrè-ṣàkóso sílẹ̀, àti láti ṣàwárí wúrà. Ṣíṣàwárí wúrà wá di lájorí ohun tí ọ̀pọ̀ olùṣàwárí ń lé, títí kan aṣíwájú arìnrìn-àjò ojú òkun náà, Christopher Columbus (1451 sí 1506).
Nígbà kan tí Columbus ń wá wúrà, ẹ̀mí àwọn ọmọ onílẹ̀ kò já mọ́ nǹkan kan lójú rẹ̀. Nígbà tí Columbus ń ròyìn ohun tí ó ṣe ní erékùṣù kan fún ọba àti ayaba ilẹ̀ Sípéènì, tí wọ́n fowó ti ìrìn àjò àwárí rẹ̀ lẹ́yìn, ó kọ àkọsílẹ̀ pé: “Gbogbo ohun tí ẹnì kan ní láti ṣe kí ó lè ṣàkóso ibí yìí ni kí olúwa rẹ̀ fìdí kalẹ̀ síbí, kí ó sì jẹ gàba lórí àwọn ọmọ onílẹ̀, tí yóò máa ṣe ohunkóhun tí a bá pàṣẹ fún wọn láti ṣe. . . . Àwọn Àmẹ́ríńdíà . . . ń rìnhòòhò, wọn kò sì ní ohun ìjà, nípa bẹ́ẹ̀, ó rọrùn láti pàṣẹ fún wọn àti láti kó wọn ṣiṣẹ́.” Columbus gbà gbọ́ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí iṣẹ́ òun. Àwọn ìṣúra wúrà náà yóò jẹ́ kí ilẹ̀ Sípéènì rí owó ja àwọn ogun mímọ́ rẹ̀. Nígbà kan, lẹ́yìn tí ó gba ẹ̀bùn agọ̀ oníwúrà kan, ó sọ pé, ‘kí Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi àánú rẹ̀ hàn sí mi, kó jẹ́ kí n rí wúrà.’
Ọba Ferdinand, ti ilẹ̀ Sípéènì, pàṣẹ fún àwọn aṣẹ́gun ará Sípéènì, tí wọ́n rìnrìn àjò ojú òkun ní ọ̀nà kan náà tẹ̀ lé Columbus, pé: “Ẹ mú wúrà bọ̀ fún mi! Bí ó bá ṣeé ṣe, ẹ mú un lọ́nà ti ọmọlúwàbí. Àmọ́ lọ́nàkọ́nà tí ẹ̀ báà gbà rí i, ẹ mú un bọ̀ fún mi.” Àwọn aláìláàánú olùṣàwárí náà pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ìbílẹ̀ tí wọ́n bá pàdé ní Mexico, ní Àáríngbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà. Lọ́nà àfiṣàpẹẹrẹ, ẹ̀jẹ̀ ń ro tó tó tó lára wúrà tí àwọn aṣẹ́gun náà rù padà lọ sí Sípéènì.
Ìgbà yẹn ni àwọn olè ojú omi tún yọjú, tí àwọn ò tilẹ̀ ṣojú orílẹ̀-èdè kankan. Lójú òkun ni wọ́n ti ń jí ẹrù wúrà àti àwọn ìṣúra iyebíye mìíràn tí ilẹ̀ Sípéènì ń fi ọkọ̀ ìṣòwò ojú omi rẹ̀ ko lọ gbé. Àwọn ọkọ̀ ìṣòwò ojú omi náà kò ní ohun ìjà tàbí àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ tó láti kojú àwọn olè ojú omi tí wọ́n dìhámọ́ra tẹnutẹnu náà. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, jíjalè lójú omi ló jẹ́ ìṣòro tí ń kojú ìrìn àjò ojú òkun, pàápàá ní West Indies àti etíkun ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Sísáré Lọ Síbi Ìwakùsà Wúrà Tuntun ní Ọ̀rúndún Kọkàndínlógún
Ní 1848, wọ́n ṣàwárí wúrà rẹpẹtẹ ní Àfonífojì Sacramento, ní California. Òkìkí rẹ̀ kàn láìpẹ́, àwọn abulẹ̀dó sì ń tú yááyáá lọ gbalẹ̀ tiwọn. Nígbà tí ó fi di ọdún kejì, ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn “aduwúrà ilẹ̀ California”—àwọn tí ń wá ọ̀nà àtilà láti onírúurú ibi lágbàáyé ti rọ́ dé California. Àwọn olùgbé California tó jẹ́ nǹkan bí 26,000 ní 1848 ti di nǹkan bí 380,000 ní 1860. Àwọn àgbẹ̀ pa ilẹ̀ wọn tì, àwọn atukọ̀ ojú omi ò yàdí iṣẹ́ ọkọ̀ títù mọ́, àwọn jagunjagun gbàgbé iṣẹ́ ológun—kí wọ́n lè ráyè lọ wá ọ̀nà àtilà nídìí wúrà. Wọ́n ṣàpèjúwe àwọn kan bí “olè tí kò kọkú.” Bí àkólù ènìyàn yìí ṣe dé ni ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá pẹ̀lú dé. Àwọn tí ẹ̀tàn ọ̀ràn wúrà yìí dẹkùn mú, ṣùgbọ́n tí wọn kò fẹ́ ṣiṣẹ́ kí wọ́n tó ní in, bẹ̀rẹ̀ sí jalè, wọ́n ń dá àwọn ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin àti ọkọ̀ ojú irin lọ́nà, wọ́n sì ń jí ẹrù wọn kó.
Ní 1851, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn sísáré lọ síbi ìwakùsà wúrà tuntun ní California, ni òkìkí tún kàn pé wọ́n tún rí wúrà rẹpẹtẹ ní Ọsirélíà. Ìròyìn náà sọ pé: “Ohun tó tibẹ̀ wá pọ̀ yanturu ní tòótọ́.” Ní sáà ráńpẹ́ kan, Ọsirélíà ni a ti ń wa kùsà wúrà jù lágbàáyé. Àwọn kan tí wọ́n ti kó lọ sí California tẹ́lẹ̀ tún kẹ́rù wọn lọ sí Ọsirélíà láìpẹ́. Àwọn olùgbé Ọsirélíà yára pọ̀ rẹpẹtẹ—láti 400,000 ní 1850, wọ́n lé ní 1,100,000 ní 1860. Iṣẹ́ àgbẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ mìíràn dáwọ́ dúró ná, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ló sáré wá ọ̀nà àtilà lọ sídìí wúrà.
Nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ, eré àsápajúdé nídìí a ń wá wúrà tún forí lé Yukon àti Alaska, nígbà tí wọ́n tún rí wúrà lágbègbè wọ̀nyẹn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tún kó lọ sí ìhà Àríwá Jíjìn Réré, ní àgbègbè Klondike òun Alaska, tí wọ́n ń fojú winá ojú ọjọ́ títutùjù tó wà níbẹ̀, kí wọ́n lè gbalẹ̀ tiwọn nínú ilẹ̀ tí wúrà ti pọ̀ rẹpẹtẹ náà.
Ìṣúra Tó Rì Sókun
Bí mímòòkùn sísàlẹ̀ òkun ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún, àwọn tí ń wá wúrà kiri tún yíjú sí abẹ́ òkun. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń lọ tú àwọn ọkọ̀ òkun tó ti dà láti lè kó àwọn ìṣúra tó ti rì sókun—àwọn ohun ọ̀ṣọ́ oníwúrà àti àwọn iṣẹ́ ọnà àtọdúnmọ́dún.
Ní September 20, 1638, ọkọ̀ ìṣòwò ojú omi ilẹ̀ Sípéènì, tí ń jẹ́ Concepción, rì ní Òkun Pàsífíìkì, ní etíkun Saipan, lẹ́yìn tí ìjì líle ti forí rẹ̀ sọ àpáta. Ó kó ẹrù wúrà àti àwọn ìṣúra tí iye owó rẹ̀ jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là tòde òní. Àwọn 400 ènìyàn tó wà nínú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Àwọn òmùwẹ̀ ti rí àwọn gbẹ̀dẹ̀ oníwúrà 32, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan gùn tó mítà 1.5, tí ó sì wúwo tó ọ̀pọ̀ kìlógíráàmù, kó jáde láti inú èéfọ́ ọkọ̀ náà. Lápapọ̀, àwọn òmùwẹ̀ ti rí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ oníwúrà tó pọ̀ tó 1,300—gbẹ̀dẹ̀, àgbélébùú, bọ́tìnnì, òrùka, àti ìdè ìgbànú—kó jáde.
Wọ́n tún ti rí àwọn èéfọ́ ọkọ̀ mìíràn. Ní 1980, àwọn òmùwẹ̀ rí èéfọ́ ọkọ̀ ìṣòwò ojú omi kan, Santa Margarita, tí ilẹ̀ Sípéènì lò ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ní etíkun Florida, ní United States. Nígbà tí ó fi di ìparí ọdún tó tẹ̀ lé e, àwọn òmùwẹ̀ ti rí wúrà àìfọ̀ tí ó lé ní kìlógíráàmù 44, àti àwọn iṣẹ́ ọnà oníwúrà mìíràn kó jáde.
Wúrà Tí Wọ́n Jí Kó Nígbà Ogun
Lẹ́yìn tí ìjọba ilẹ̀ Germany ti túúbá ní 1945, àwọn ọmọ ogun Àwọn Orílẹ̀-Èdè Alájọṣe rí nǹkan ìyanu kan ní ibi ìwakùsà iyọ̀ Kaiseroda, ní Thuringia, Germany. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Atlanta Journal ṣe sọ, “wọ́n rí wúrà àìfọ̀, àwọn iṣẹ́ ọnà, owó gidi àti àwọn ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan tí a fi wúrà ṣe gbogbo wọn, tó jẹ́ bílíọ̀nù 2.1 dọ́là níbi ìwakùsà náà.” Bákan náà ni wọ́n tún rí àwọn àpò tí wọ́n ti jí gbé lọ́dọ̀ àwọn tí ó kú nínú Ìpakúpa náà, tí àwọn eyín tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe kún inú wọn, tí àwọn kan nínú wọn sì ti yòrò. Ìṣúra àfipamọ́ rẹpẹtẹ yìí ti ran àwọn babaàsàlẹ̀ ogun Nazi lọ́wọ́ láti máa jagun lọ fún àkókò pípẹ́. Ìwé ìròyìn Journal náà sọ pé a ti dá ìwọ̀n wúrà tí a fojú bù sí bílíọ̀nù 2.5 dọ́là padà fún àwọn orílẹ̀-èdè tí Hitler ti gbà nígbà kan rí. Nítorí pé àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé a kò ì rí gbogbo wúrà Nazi tí a kó pamọ́ tán, wọ́n ṣì ń wá sí i.
Ó dájú pé wúrà níye lórí. Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì sọ pé, bí ti àwọn ohun ìní mìíràn, wúrà kò lè fún àwọn tí ń wá a ní ìyè. (Sáàmù 49:6-8; Sefanáyà 1:18) Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Níní ọgbọ́n, ó mà kúkú sàn ju wúrà o!” (Òwe 16:16) Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá, ní ń fúnni ní ọgbọ́n tòótọ́, a sì lè rí i nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń wá irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ lè kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin, ìlànà, àti ìmọ̀ràn Ọlọ́run, kí ó sì wá máa lò wọ́n nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ọgbọ́n tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀ ní wúlò púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ènìyàn tíì rí lọ. Irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ lè túmọ̀ sí ìgbésí ayé tí ó gbámúṣé nísinsìnyí àti ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 3:13-18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé]
Àwọn Kókó Pàtàkì Díẹ̀ Nípa Wúrà
• Wúrà ṣeé dà, ó sì ṣeé lù di tín-ínrín ju àwọn mẹ́táàlì mìíràn lọ. A lè lù ú di tín-ínrín, kó má ju micrometre 0.1 lọ. A lè lu ìwọ̀n gíráàmù 28 rẹ̀ kí ó fẹ̀ tó nǹkan bí mítà 17 níbùú lóròó. A sì lè lu ìwọ̀n gíráàmù 28 rẹ̀ kí ó gùn tó 70 kìlómítà.
• Nítorí pé wúrà àìfọ̀ kò le rárá, a sábà máa ń pò ó pọ̀ mọ́ àwọn mẹ́táàlì mìíràn kí ó lè le tó láti fi ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti àwọn nǹkan oníwúrà mìíràn. A ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpòpọ̀ oníwúrà ní ìwọ̀n ìpín 1 nínú 24, tí a ń pè ní karat; nípa bẹ́ẹ̀, wúrà ìwọ̀n karat 12 ní wúrà ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún nínú, wúrà ìwọ̀n karat 18 ní wúrà ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún nínú, wúrà ìwọ̀n karat 24 jẹ́ wúrà tí kò lábùlà.
• Àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti ń rí wúrà jù lọ ni Gúúsù Áfíríkà àti United States.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
Alexander Ńlá: The Walters Art Gallery, Baltimore
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwòrán tí ń fi Christopher Columbus hàn nígbà tó dé sí Bahamas ní 1492 tí ó ń wá ìṣúra wúrà kiri
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Museo Naval, Madrid (Sípéènì), àti ìyọ̀ǹda onínúure Don Manuel González López