ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 14-16
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Òtítọ́ Di Tèmi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Òtítọ́ Di Tèmi?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣàwárí Rẹ̀ Fúnra Rẹ
  • Ọwọ́ Rẹ Ha Dí Jù Láti Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bí?
  • Ṣàjọpín Ohun Tí O Ń Kọ́
  • Ṣọ́ Irú Ẹgbẹ́ Tí O Ń Kó
  • Àwọn Kristẹni Ń jọ́sìn Ní Ẹ̀mí Àti Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Èmi Yóò Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Rẹ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 14-16

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Sọ Òtítọ́ Di Tèmi?

“Wọ́n tọ́ mi dàgbà bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìgbà gbogbo ni mo sì máa ń ronú pé bí ó bá jẹ́ pé bí a ṣe tọ́ ẹnì kan dàgbà nìyẹn, ẹni náà mọ Jèhófà ní tòótọ́. Àmọ́, èrò mi náà kò tọ̀nà rárá!”—Antoinette.

“KÍ NI òtítọ́?” Pọ́ńtíù Pílátù, ọkùnrin tó fa Jésù lé àwọn tí wọ́n pa á lọ́wọ́, ló béèrè ìbéèrè tí a mọ̀ dáadáa yẹn. (Jòhánù 18:38) Àmọ́, ó ṣe kedere pé kì í ṣe nítorí àtibẹ̀rẹ̀ ìjíròrò aláìlábòsí èyíkéyìí ni Pílátù ṣe béèrè ìbéèrè tí kò dọ́kàn náà, bí kò ṣe nítorí àtipaná rẹ̀. Kò nífẹ̀ẹ́ sí “òtítọ́” ní ti gidi. Ṣùgbọ́n, ìwọ ńkọ́? Ǹjẹ́ o nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́?

Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ń ronú nípa ohun tí òtítọ́ jẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ojú sì ń gbà wọ́n tì nítorí pé ohun tó tìdíi gbogbo kìràkìtà wọn wá kò ní láárí. Ṣùgbọ́n, o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè Pílátù. Jésù Kristi kọ́ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni òtítọ́. Ó tún sọ pé òun alára ni “òtítọ́.” Àpọ́sítélì Jòhánù sì kọ̀wé pé: “Òtítọ́ wá wà nípasẹ̀ Jésù.” (Jòhánù 1:17; 14:6; 17:17) Ìdí nìyẹn tí a tún fi pe àpapọ̀ gbogbo ẹ̀kọ́ Kristẹni, tí ó wá di apá kan Bíbélì, ní “òtítọ́” tàbí “òtítọ́ ìhìn rere.” (Títù 1:14; Gálátíà 2:14; 2 Jòhánù 1, 2) Orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, ìgbékalẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run, àjíǹde, àti ìràpadà Jésù wà lára àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni wọ̀nyí.—Sáàmù 83:18; Mátíù 6:9, 10; 20:28; Jòhánù 5:28, 29.

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ni àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ti kọ́ ní òtítọ́ Bíbélì. Àmọ́, èyí ha túmọ̀ sí pé irú àwọn bẹ́ẹ̀ “ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́” bí? (3 Jòhánù 3, 4) Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n tọ́ Jennifer, tó ti pé 20 ọdún, dàgbà bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rántí pé: “Màmá mi máa ń mú mi lọ sí àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì gbà mí nímọ̀ràn pé kí n máa ronú nípa ìrìbọmi. Ṣùgbọ́n mo rò nínú ara mi pé, ‘N kò fẹ́ di Ẹlẹ́rìí rárá. Mo wulẹ̀ fẹ́ gbádùn ara mi ni!’”

Àwọn èwe kan gba ohun tí a kọ́ wọn gbọ́, àmọ́ wọn kò mú òye jíjinlẹ̀ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni dàgbà ní gidi. Ewu wo ni èyí lè fà? Jésù kìlọ̀ pé àwọn kan “kò ní gbòǹgbò kankan nínú ara wọn.” Irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè máa “bá a lọ fún àkókò kan; lẹ́yìn náà, gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀.” (Máàkù 4:17) Àwọn mìíràn lè ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì dé àyè kan, àmọ́ wọn kò mọ Ọlọ́run dunjú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń jẹ́ Aneesa sọ pé: “N kò rò pé mo wà nínú ipò ìbátan kan pẹ̀lú Jèhófà nígbà tí mo wà lọ́mọdé . . . Mo rò pé ipò ìbátan tí àwọn òbí mi ní pẹ̀lú rẹ̀ ló ṣe pàtàkì.”

Ìwọ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run àwọn òbí rẹ nìkan ni o ka Jèhófà sí? Àbí, ìwọ náà lè sọ bí onísáàmù náà ṣe sọ nínú Bíbélì pé: “Ìwọ Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé. Mo ti wí pé: ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi’”? (Sáàmù 31:14) Ó lè béèrè ìgboyà láti mú ọ̀rọ̀ náà lógìírí. Ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Alexander sọ pé: “Ní tèmi, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ fífi tọkàntọkàn wádìí ara mi.” Lẹ́yìn yíyẹ ọkàn rẹ wò, o lè wá mọ̀ pé o kò tíì ṣàwárí òtítọ́ (gbogbo àpapọ̀ ẹ̀kọ́ Kristẹni) fúnra rẹ. O lè ṣàìní ìdánilójú tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí náà, ó lè jọ pé ìgbésí ayé rẹ kò nítumọ̀, pé o kò ní ohun gidi tí o fẹ́ fi ṣe.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń kọrin kan tí ó ní àkọlé náà, “Sọ Òtítọ́ náà Di Tìrẹ,”a ní àwọn ìpàdé Kristẹni wọn. Àmọ̀ràn yẹn lè wúlò fún ọ. Àmọ́, báwo ni o ṣe lè ṣe é? Ibo ni wàá ti bẹ̀rẹ̀?

Ṣàwárí Rẹ̀ Fúnra Rẹ

Ní Róòmù 12:2, a rí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani pé: “Ẹ . . . ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” Báwo gan-an lo ṣe lè ṣe ìyẹn? Nípa níní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (Títù 1:1) Àwọn olùgbé ìlú ńlá Bèróà níjìímìjí kò gba àwọn ohun tí wọ́n gbọ́ láìjanpata. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n “fẹ̀sọ̀ [ṣàyẹ̀wò] Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan [tí wọ́n ń kọ́] wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tí ń jẹ́ Erin rí ìdí tí ó fi yẹ kí òun náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ó rántí pé: “Mo máa ń ṣe ìwádìí. Mo máa ń bi ara mi léèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé ìsìn yìí ló tọ̀nà? Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ń jẹ́ Jèhófà?’” O kò ṣe bẹ̀rẹ̀ ètò ìdákẹ́kọ̀ọ́ tìrẹ náà? O lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìwé tí a gbé karí Bíbélì náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.b Fara balẹ̀ kà á. Ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, sì kíyè sí bí wọ́n ṣe tan mọ́ ohun tí a kọ sílẹ̀. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti rí i bí èrò rẹ nípa òtítọ́ ṣe yàtọ̀ sí ti ìgbà tí o di “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́”!—2 Tímótì 2:15.

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé àwọn ohun kan nínú Bíbélì “nira láti lóye,” wàá sì rí i pé òtítọ́ ni èyí jẹ́. (2 Pétérù 3:16) Àmọ́, ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn kókó tí ó ṣòro pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 2:11, 12) Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ó bá ṣòro fún ọ láti lóye ohun kan. (Sáàmù 119:10, 11, 27) Gbìyànjú láti ṣe àwọn ìwádìí díẹ̀ sí i nínú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society. Bí o kò bá mọ bí o ṣe lè ṣe ìyẹn, ní kí ẹnì kan ràn ọ́ lọ́wọ́. Àwọn òbí rẹ tàbí àwọn ará mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

Rántí pé kì í ṣe nítorí àtifi ìmọ̀ rẹ yangàn sí àwọn ẹlòmíràn lo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Èwe kan tí ń jẹ́ Collin ṣàlàyé pé: “Wàá mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà.” Fara balẹ̀ ṣàṣàrò lórí ohun tí o kà, kí ó bàa lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn.—Sáàmù 1:2, 3.

Kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ìjọ ní àwọn ìpàdé Kristẹni lè ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ó ṣe tán, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́” ni ìjọ jẹ́. (1 Tímótì 3:15) Àwọn èwe kan ṣàròyé pé àwọn ìpàdé Kristẹni máa ń súni. Ọ̀dọ́mọdé Collin ránni létí pé: “Tí o kì í bá múra ìpàdé sílẹ̀, o kò ní fi bẹ́ẹ̀ jàǹfààní rẹ̀.” Nítorí náà, múra àwọn kókó ẹ̀kọ́ ìpàdé sílẹ̀. Ìpàdé máa ń dùn mọ́ni gan-an tí a bá jẹ́ olùkópa—tí a kì í ṣe òǹwòran lásán.

Ọwọ́ Rẹ Ha Dí Jù Láti Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bí?

Lóòótọ́, ó lè ṣòro fún ọ láti wá àkókò láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nítorí gbogbo iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ilé tí o ní láti ṣe. Ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Susan kọ̀wé pé: “Mo fi ọ̀pọ̀ ọdún tiraka ní mímọ̀ pé mo ní láti múra ìpàdé sílẹ̀, kí n sì ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ pàbó ló já sí.”

Susan kọ́ bí a ṣe ń ‘ra àkókò padà’ lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. (Éfésù 5:15, 16) Lákọ̀ọ́kọ́, ó ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ohun tí yóò kọ́. Lẹ́yìn náà, ó ṣètò àkókò tí yóò fi kọ́ wọn. Àmọ́, ó tún fi àkókò díẹ̀ fún eré ìtura kún ìṣètò àkókò rẹ̀. Ó kìlọ̀ pé: “Má ṣàìṣẹ́ àkókò díẹ̀ kù. Gbogbo wa ló yẹ ká lásìkò ìgbádùn.” Ṣíṣètò àkókò lè ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ pẹ̀lú.

Ṣàjọpín Ohun Tí O Ń Kọ́

Fífi ohun tí o ń kọ́ sílò ń ṣàǹfààní láti mú kí ó mọ́ ọ lára. Gbìyànjú láti kọ́ ẹlòmíràn. Onísáàmù sọ pé: “Ẹnu mi yóò sọ àwọn ohun ọgbọ́n, àṣàrò inú ọkàn-àyà mi yóò sì jẹ́ ti àwọn ohun òye.”—Sáàmù 49:3.

Bí o kò bá tijú ìhìn rere náà, o kò ní lọ́ra láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn mìíràn tí o lè bá pàdé. (Róòmù 1:16) Nípa lílo irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ láti sọ nípa òtítọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, ìwọ yóò máa fi ohun tí o ń kọ́ sílò; lọ́nà yìí, ìwọ yóò pa òtítọ́ mọ́ ní èrò àti ọkàn-àyà rẹ.

Ṣọ́ Irú Ẹgbẹ́ Tí O Ń Kó

Àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní tẹ̀ síwájú dáradára nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn láìpẹ́, ó sì béèrè pé: “Ta ní dí yín lọ́wọ́ nínú bíbá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí òtítọ́?” (Gálátíà 5:7) Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí èwe kan tí ń jẹ́ Alex nìyẹn. Ó jẹ́wọ́ pé, “fífẹsẹ̀ palẹ̀ kiri pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́” ló ba ìsapá òun láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Kí o lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ìwọ pẹ̀lú lè ní láti ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ọ̀ràn yìí.

Ní ọ̀nà kejì, ẹgbẹ́ rere lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú ní ti gidi. Òwe 27:17 sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” Wá àwọn tí ó ṣeé fi ṣe àwòkọ́ṣe dáradára—àwọn tí ń lo òtítọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Wọ́n lè wà nínú ìdílé rẹ gan-an. Ọ̀dọ́mọdé Jennifer rántí pé: “Bàbá àgbà ni àwòkọ́ṣe mi dídára jù lọ. Ó sábà máa ń fi wákàtí mẹ́ta múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìjọ wa sílẹ̀ ní ọjọ́ Sunday. Ó máa ń ka gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà nínú onírúurú ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì, ó sì máa ń wo ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ nínú ìwé atúmọ̀ èdè rẹ̀. Ògbóǹtagí ni nínú àwọn òkodoro òtítọ́ tí àwọn ènìyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nínú Bíbélì. Yóò rí ìdáhùn sí ohun yòówù tí o bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

Tí o bá sọ òtítọ́ di tìrẹ, ìwọ yóò jèrè ohun iyebíye kan—ohun tí nǹkan kan kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ. Nítorí náà, má ṣe wò ó pé òtítọ́ wulẹ̀ jẹ́ “ìsìn àwọn òbí mi.” Èrò rẹ ní láti jẹ́ bí ti onísáàmù tí ó wí pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Nípa mímọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ní gidi, gbígbà á gbọ́, ṣíṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti, lékè gbogbo rẹ̀, nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyí, ìwọ yóò fi hàn pé o ti sọ òtítọ́ di tìrẹ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti inú ìwé orin náà, Kọrin Ìyìn sí Jehofah, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

b Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ṣàwárí òtítọ́ fúnra rẹ nípa ṣíṣe ìwádìí àti ìdákẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́