ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 11/8 ojú ìwé 28-29
  • Ipa Tí Ìjọ Kátólíìkì Kó Nínú Ìpakúpa Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipa Tí Ìjọ Kátólíìkì Kó Nínú Ìpakúpa Náà
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Ìkórìíra Ìsìn Júù àti Ìkórìíra Ẹ̀yà Júù
  • Àìfọhùn Pius Kejìlá
  • Títi Ẹ̀bi Sọ́rùn Ẹlòmíràn
  • Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Jẹ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Tọrọ Àforíjì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣé ‘Ìsìn Tòótọ́’ Kan Ṣoṣo Ló Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Jí!—1998
g98 11/8 ojú ìwé 28-29

Ipa Tí Ìjọ Kátólíìkì Kó Nínú Ìpakúpa Náà

Láti ọwọ́ akọ̀ròyìn Jí! ní Ítálì

LÁTI 1987 ni ọ̀rọ̀ ti ń lọ nípa ètò tí Ìjọ Kátólíìkì ń ṣe láti gbé ìwé kan tí yóò sọ ipa tí ó kó nínú Ìpakúpa náà jáde. Nítorí náà, ojú àwọn ènìyàn ti wà lọ́nà gan-an nígbà tí Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Lórí Àjọṣe Ìsìn ti Vatican pẹ̀lú Àwọn Júù gbé ìwé tí wọ́n fún ní àkọlé náà, We Remember: A Reflection on the Shoah,a jáde ní March 1998.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan mọrírì ìwé náà, ọ̀pọ̀ ni ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ kò tẹ́ lọ́rùn. Kí ló fà á? Kí ni wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí nínú rẹ̀?

Èrò Ìkórìíra Ìsìn Júù àti Ìkórìíra Ẹ̀yà Júù

Ìwé tí Vatican gbé jáde náà fi ìyàtọ̀ sáàárín ìkórìíra ìsìn Júù, tí ìjọ náà gbà pé òun jẹ̀bi rẹ̀, àti ìkórìíra ẹ̀yà Júù, tí kò gbà pé òun jẹ̀bi rẹ̀. Ìyàtọ̀ tí wọ́n fi sáàárín rẹ̀ àti ibi tí ó múni parí èrò sí kò tẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́rùn. Rábì, ará Germany náà, Ignatz Bubis, sọ pé: “Lójú tèmi, ó jọ pé Ìjọ náà ń sọ pé, kì í ṣe ẹjọ àwọn ni; ẹjọ́ ẹlòmíràn ni.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Ítálì, tí ó jẹ́ Kátólíìkì náà, Giorgio Vecchio, gbà pẹ̀lú ìyàtọ̀ tí wọ́n fi sáàárín ìkórìíra ìsìn Júù àti ẹ̀yà Júù náà, ó sọ pé, “ìṣòro tó tún wà ni ti lílóye bí ìkórìíra tí Kátólíìkì ní sí ìsìn Júù ṣe lè ti kó ipa pàtàkì nínú mímú kí ìkórìíra ẹ̀yà Júù bẹ̀rẹ̀.” Ó dùn mọ́ni nínú pé ìwé ìròyìn Vatican náà, L’Osservatore Romano, ti November 22 sí 23, 1895, tẹ lẹ́tà kan jáde tí ó kà pé: “Ní pàtàkì, olùfọkànsìn ọmọ ìjọ Kátólíìkì èyíkéyìí jẹ́ olùkórìíra ẹ̀yà Júù: bẹ́ẹ̀ náà ló rí ní ti àwọn àlùfáà, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.”

Bí ó ti wù kí ó rí, apá tí àwọn ènìyàn ṣe àríwísí rẹ̀ jù lọ nínú ìwé tí Vatican gbé jáde náà ni bí wọ́n ṣe gbèjà ìgbésẹ̀ Pius Kejìlá, ẹni tí wọ́n yàn sípò póòpù lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀. Pius Kejìlá ṣiṣẹ́ bí aṣojú póòpù fún ìjọba ilẹ̀ Germany láti 1917 sí 1929.

Àìfọhùn Pius Kejìlá

Amòfin, ọmọ ilẹ̀ Ítálì náà, Francesco Margiotta Broglio, kò rò pé ìwé náà “sọ kókó tuntun tàbí kí ó ṣàlàyé tuntun nípa ọ̀ràn tí a pè ní ‘àìfọhùn’ Póòpù Pius Kejìlá, tí ó gbalẹ̀ kan, nípa àjọṣe tí a sọ pé ó ní pẹ̀lú ilẹ̀ Germany, àti nípa àwọn ìgbésẹ̀ ọlọ́gbọ́n ìṣèlú tí ó ń gbé pẹ̀lú ìṣàkóso Nazi kí ó tó di póòpù àti lẹ́yìn tí ó di póòpù.”

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ gbà pé láìka bí a bá ṣe wo èròǹgbà ìwé náà, We Remember, sí, ọ̀ràn nípa ìdí tí àwọn aṣáájú Ìjọ Kátólíìkì kò ṣe fọhùn nípa ìparun ẹ̀yà náà ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi “kò tíì yanjú.” Òpìtàn, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà, George Mosse, sọ pé, yíyàn tí Pius Kejìlá yàn láti má ṣe fọhùn “yọ ìjọ náà nínú ewu, àmọ́, ó mú kí ó pàdánù ojúṣe rere rẹ̀. Ó hùwà bí olórí Ìjọba, kì í ṣe bí póòpù.” Àwọn alálàyé tí wọ́n mọ̀ dáadáa nípa Vatican gbà gbọ́ pé ohun tí ó ṣèdíwọ́ fún títẹ ìwé náà jáde lásìkò ni ìṣòro tí ó wà nínú ṣíṣàlàyé ipa tí Pius Kejìlá kó nínú Ìpakúpa náà.

Gbígbèjà tí ìwé náà ń gbèjà Póòpù Pius Kejìlá ti bí ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú. Arrigo Levi kọ̀wé pé: “Àìsọ̀rọ̀ nípa àìfọhùn ‘póòpù’ ló mú kí ìwé yìí máà kúnjú ìwọ̀n.” Elie Wiesel, tí ó gba Ẹ̀bùn Nobel Lórí Àlàáfíà ní 1986, sọ pé: “Lójú tèmi, sísọ pé ó yẹ kí àwa Júù dúpẹ́ lọ́wọ́ Pius Kejìlá jẹ́ ìwà àdámọ̀, kí a wulẹ̀ lo èdè tó rọjú.”

Títi Ẹ̀bi Sọ́rùn Ẹlòmíràn

Ìwé náà lo àṣà ṣíṣe ìyàtọ̀ tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì máa ń ṣe, tí wọ́n fi ń sọ pé ìjọ náà jẹ́ mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àjọ kan, Ọlọ́run sì ń pa á mọ́ kúrò lọ́wọ́ àṣìṣe, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọ ìjọ, tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ló ń jẹ̀bi ìwà ibi èyíkéyìí tí wọ́n bá hù. Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ti Vatican náà kọ̀wé pé: “Àtakò tẹ̀mí àti ìgbésẹ̀ gúnmọ́ tí àwọn Kristẹni mìíràn gbé kì í ṣe èyí tí à bá retí lọ́dọ̀ ọmọlẹ́yìn Kristi. . . . [Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀] kò tóótun láti fọhùn lòdì sí i. . . . A tọrọ àforíjì nítorí àṣìṣe àti ìwà ìjánikulẹ̀ tí àwọn ọmọ Ìjọ hù náà.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, dídi ẹrù ẹ̀bi ru ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ ìjọ náà dípò gbígbà pé àwọn jẹ̀bi gẹ́gẹ́ bí àjọ kan dà bí ìjórẹ̀yìn ńlá kan lójú ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, tí a bá fi wé ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí. Fún àpẹẹrẹ, Ìjọ Kátólíìkì ti Róòmù ní ilẹ̀ Faransé gbé “Ìkéde Ìrònúpìwàdà” kan tí a fàṣẹ sí jáde, tí ń tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run àti àwọn Júù nítorí “ìwà àgunlá” tí Ìjọ Kátólíìkì hù nígbà inúnibíni tí ìjọba Vichy ṣe sí àwọn Júù ní àkókò ogun ilẹ̀ Faransé. Nínú ọ̀rọ̀ kan tí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Olivier de Berranger kà, ìjọ náà gbà pé òun ti jẹ́ kí àwọn ìdàníyàn tara òun “ṣíji bo àṣẹ inú Bíbélì láti bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run.”

Ìkéde tí wọ́n ṣe ní èdè Faransé náà sọ lápá kan pé: “Ìjọ náà gbọ́dọ̀ gbà pé, ní ti inúnibíni tí a ṣe sí àwọn Júù, àti ní pàtàkì, ní ti onírúurú ìgbésẹ̀ tí àwọn aláṣẹ Vichy pàṣẹ rẹ̀ lòdì sí àwọn Júù, ìdágunlá bo ìbínú mọ́lẹ̀ gidigidi. Àìfọhùn ló gbòde kan, sísọ̀rọ̀ ní ìgbèjà àwọn tí ìyà ń jẹ náà kò sì wọ́pọ̀. . . . A ń jẹ́wọ́ lónìí pé àṣìṣe ni àìfọhùn yìí. A sì tún gbà pé, ìjọ náà ní ilẹ̀ Faransé kùnà nínú iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn láti ní ẹ̀rí ọkàn rere.”

Nísinsìnyí tí ó ti lé ní 50 ọdún tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ Shoah, tàbí Ìpakúpa bíburújáì náà ti ṣẹlẹ̀, Ìjọ Kátólíìkì kò tíì gbìyànjú láti jẹ́wọ́ ipò rẹ̀ nínú ìtàn—tó kún fún àìdájú àti àìfọhùn, ká má fa ọ̀rọ̀ gùn. Àmọ́, àwọn kan wà tí wọn kò tíì gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn rí rárá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwùjọ ìsìn àwọn tí kò tó nǹkan, tí Nazi ṣenúnibíni bíburújáì sí, kò juwọ́ sílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe kedere sí i lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dà bí àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n dá ìwà ìkà òǹrorò ìjọba Nazi lẹ́bi. Kì í sì ṣe pé wọ́n ṣe é lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nìkan ni. Àwọn agbẹnusọ àti àwọn ìwé wọn ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Òpìtàn Christine King, igbákejì gíwá Yunifásítì Staffordshire ní England, ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ké gbàjarè. Wọ́n ké gbàjarè láti ìbẹ̀rẹ̀. Wọ́n pa ẹnu pọ̀ ké gbàjarè. Wọ́n sì ké gbàjarè pẹ̀lú ìgboyà tí ó kàmàmà, èyí tó kọ́ gbogbo wa lẹ́kọ̀ọ́ kan.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Shoah ni ọ̀rọ̀ Hébérù tí ó túmọ̀ sí Ìpakúpa, tí àwọn Nazi pa àwọn Júù, àwọn adúláwọ̀ ará Íńdíà, àwọn ará Poland, àwọn Slav, àti àwọn mìíràn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nípakúpa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Póòpù Pius Kejìlá kò fọhùn nígbà Ìpakúpa náà

[Credit Line]

Fọ́tò U.S. Army

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́