‘Ọ̀kan-ò-jọ̀kan Ìṣòro Bíburú Jáì Nípa Àbójútó Àrùn Ọpọlọ’
Àpilẹ̀kọ kan tí ó jáde nínú lẹ́tà ìròyìn Synergy tí Ẹgbẹ́ Ìlera Àgbáyé ti Kánádà ṣe, sọ pé: “Láìka ìtẹ̀síwájú tí ìmọ̀ ìṣègùn ti ní nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀ka àbójútó ìlera sí, a ṣì ń dojú kọ ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìṣòro bíburújáì nípa àbójútó àrùn ọpọlọ jákèjádò ayé.”
Ìròyìn kan sọ pé ẹnì kan lára ènìyàn mẹ́rin jákèjádò ayé ló ní ìṣòro ọpọlọ, ìmọ̀lára, tàbí tí wọ́n ń hùwà lódìlódì. Ìwádìí mìíràn sọ pé bí ẹni mẹ́ta bá wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ òṣìṣẹ́ tí ń bójú tó ìlera, ọ̀kan nínú wọn yóò jẹ́ nítorí ìṣòro ìsoríkọ́ tàbí àìfararọ. Àwọn olùwádìí sì sọ pé, ńṣe ni iye wọn ń pọ̀ sí i.
Kí ló mú kí iye wọn máa pọ̀ sí i? Ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Ìwádìí Ìṣègùn Nípa Okùnfà Àrùn Tí Ń Yọ Ẹ̀dá Lẹ́nu ní Yunifásítì Harvard ṣe sọ pé, ńṣe ni àwọn àrùn bí ìsoríkọ́, àrùn ọpọlọ dídàrú, àti ìsínwín ń pọ̀ sí i nítorí pé “ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń dàgbà di arúgbó.” Ṣùgbọ́n dídàgbà di arúgbó nìkan kọ́ ló ń fà á. Àwọn ìṣòro owó, kòókòó-jàn-ánjàn-án tí ń pọ̀ sí i nínú ìgbésí ayé òde òní pẹ̀lú ń dá kún un.
Báwo ni a ṣe lè yí ipò tí ń múni sorí kọ́ yìí padà? Àwọn ògbógi sọ pé, nínú gbogbo ẹ̀ka àbójútó ìlera tó wà, àbójútó àrùn ọpọlọ ló yẹ kí a fún ní àfiyèsí jù nítorí pé ó “jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀ka iṣẹ́ ìdàgbàsókè tuntun nínú mímú ipò ẹ̀dá sunwọ̀n sí i.”