ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 4/8 ojú ìwé 18-21
  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àìfararọ àti Pákáǹleke Tó Wà Nínú Rẹ̀
  • Àwọn Oníbìínú Ọmọ
  • Kíkojú Àwọn Pákáǹleke Náà
  • Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà
    Jí!—1999
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lájọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Oríṣi Àwọn Òbí Àgbà “Tuntun”
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 4/8 ojú ìwé 18-21

Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ìpàdé kan tí a ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba dé ni. Mo gbọ́ tí àwọn kan ń kanlẹ̀kùn gbàgbàgbà, àwọn ọlọ́pàá méjì àti àwọn ọmọ méjì tí wọ́n dọ̀tí, tí irun wọn rí járinjàrin, tí ó jọ pé ó ti tó oṣù mélòó kan tí a ti wẹ̀ fún wọn gbẹ̀yìn ni mo bá níta. Èèyàn ò lè mọ̀ pé ọmọdé ni wọ́n! Ọmọ-ọmọ mi ni wọ́n, ìyá wọn tó jẹ́ ajòògùnyó ló dà wọ́n sílẹ̀. Opó ni mí nígbà yẹn, ọmọ mẹ́fà ni èmi alára sì ti bí. Ṣùgbọ́n mi ò lè sọ pé mi ò ní gbà wọ́n.”—Sally.a

“Ọmọ mi obìnrin béèrè bí mo bá lè gba àwọn ọmọ òun títí òun yóò fi tún ọ̀nà ìgbésí ayé òun ṣe. Mi ò mọ̀ pé ajòògùnyó ni. Èmi ni mo wá tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọmọ mi tún bímọ mìíràn. Mi ò fẹ́ gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ọmọ-ọmọ mi tó jẹ́ ọkùnrin bẹ̀ mí pé, ‘Ìyá àgbà, ṣé a ò lè gba ọ̀kan yìí si ni?’”—Willie Mae.

TẸ́LẸ̀ rí a máa ń pe ipò òbí àgbà ní “ipò fàájì tí kò ní ẹrù iṣẹ́ nínú.” Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Àwọn kan fojú díwọ̀n pé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ọmọdé tí ń gbé ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn àgbà. Ńṣe ni iye náà sì ń yára pọ̀ sí i.

Kí ló ń fa ìyọnu yìí? Àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn kọra sílẹ̀ lè wá di ẹni tí ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn àgbà. Bákan náà ni èyí lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn dà sílẹ̀ tàbí tí wọ́n fìyà jẹ. Ìwé àtìgbàdégbà Child Welfare sọ pé, ‘kokéènì tí a pa wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ń sọ ìran kan di èyí tí a pàdánù’ nítorí pé àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ajòògùnyó kì í lè ṣe ojúṣe wọn. Bákan náà, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé ni “kò ní òbí” nítorí pé a já wọn sílẹ̀, òbí wọn kú, tàbí pé òbí wọn ní àrùn ọpọlọ. Ó tún lè wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí àgbà ni yóò wá tọ́ àwọn ọmọ tí àrùn AIDS pa ìyá wọn.

Gbígba ẹrù iṣẹ́ ọmọ títọ́ ní ẹni ogójì ọdún sí ọgọ́ta ọdún tàbí ní “àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù” ìgbà arúgbó lè nini lára gan-an. (Oníwàásù 12:1-7) Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló jẹ́ pé wọn kò wulẹ̀ ní agbára láti bójú tó àwọn ọmọ kéékèèké ni. Àwọn òbí àgbà kan tilẹ̀ ń tọ́jú àwọn òbí tiwọn alára tó ti darúgbó. Bákan náà ni àwọn kan jẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ máa yí i mọ́ ọn láìsí ìrànlọ́wọ́ ẹnì kejì. Ọ̀pọ̀ ló sì ń rí i pé àwọn ò lówó láti fi gbé irú ẹrù bẹ́ẹ̀. Nínú ìwádìí kan, ìpíndọ́gba mẹ́rin lára àwọn òbí àgbà mẹ́wàá tó gbọmọ tọ́ ni owó tí ń wọlé fún wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ju ti òtòṣì lọ. Sally rántí pé: “Àwọn ọmọ náà ń ṣàìsàn. Ó di ọ̀ràn-anyàn fún mi láti náwó tó pọ̀ sórí oògùn. Ìwọ̀nba owó díẹ̀ ni ìjọba fi ràn mí lọ́wọ́.” Obìnrin arúgbó kan rántí pé: “Owó ìfẹ̀yìntì mi ni mo fi ń tọ́jú àwọn ọmọ-ọmọ mi.”

Àìfararọ àti Pákáǹleke Tó Wà Nínú Rẹ̀

Lọ́nà tí kò yani lẹ́nu, èsì ìwádìí kan fi hàn pé “títọ́ àwọn ọmọ-ọmọ ń fa àìfararọ púpọ̀ fún àwọn òbí àgbà, ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lára ọgọ́ta òbí àgbà tí a lò fún ìwádìí náà sì sọ pé àwọn máa ń ‘sorí kọ tàbí kí àwọn dààmú lọ́pọ̀ ìgbà.’” Ní gidi, ọ̀pọ̀ ló sọ pé àwọn ń ṣàìsàn. Elizabeth, obìnrin kan tí ń tọ́ ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba tó jẹ́ ọmọ-ọmọ rẹ̀ sọ pé: “Ó ní ipa lórí ara mi, ọpọlọ mi, àti ipò tẹ̀mí mi.” Willie Mae, tí àrùn ọkàn-àyà àti ẹ̀jẹ̀ ríru ń yọ lẹ́nu, sọ pé: “Dókítà mi gbà pé ó ní í ṣe pẹ̀lú àìfararọ tó wà nínú títọ́ ọmọ.”

Ọ̀pọ̀ ni kò múra sílẹ̀ fún ìyípadà ọ̀nà ìgbésí ayé tí títọ́ ọmọ-ọmọ ń béèrè. Òbí àgbà kan sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tí n kò ní lè lọ síbikíbi. Èrò pé kí n fi wọ́n ti ẹlòmíràn . . . máa ń mú kí n nímọ̀lára ẹ̀bi, nítorí náà, dípò lílọ síbikíbi tàbí kí n máa ṣe nǹkan kan, màá yáa kúkú jókòó sílé, n kò sì ní ṣe nǹkan náà.” Òmíràn sọ pé, àyè àtigbọ́ tara òun “kò yọ.” Àìlè lọ sí òde ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìnìkanwà sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Òbí àgbà kan sọ pé: “Nínú àwa tí a jọ jẹ́ ojúgbà, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀rẹ́ wa ni kò ní ọmọ [kéékèèké] lọ́dọ̀, nítorí náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a kì í lè lọ sí ibi tí wọ́n bá pè wá sí nítorí pé wọn kì í pe àwọn ọmọ [àwọn ọmọ-ọmọ] wa.”

Pákáǹleke ti ìmọ̀lára pẹ̀lú máa ń dunni. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára wọn [àwọn òbí àgbà] ni ìtìjú àti ẹ̀bi pé àwọn ọmọ wọn kò kẹ́sẹ járí bí òbí ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá—ọ̀pọ̀ lára wọ́n sì ń dá ara wọn lẹ́bi, wọ́n ń ṣe kàyéfì nípa ọ̀nà tí wọ́n ti ṣàṣìṣe bí òbí. Àwọn kan gbọ́dọ̀ gbé ọkàn kúrò nínú ọ̀ràn àwọn ọmọ wọn tí ń jòògùn yó kí wọ́n baà lè pèsè ilé tó láàbò, tí ìfẹ́ sì wà fún àwọn ọmọ-ọmọ wọn.”

Èsì ìwádìí kan sọ pé: “Ó lé ní ìdá mẹ́rin wọn . . . tó sọ pé, ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n ń rí nínú ipò ìbátan lọ́kọláya ti dín kù látàrí pé àwọn ń tọ́mọ.” Ní pàtàkì, àwọn ọkọ sábà máa ń lérò pé a ti pa àwọn tì nítorí pé àwọn ìyàwó wọn ló ń gbé èyí tó pọ̀ jù nínú ẹrù títọ́ ọmọ-ọmọ. Àwọn ọkọ kan ronú pé àwọn kò wulẹ̀ lè kojú pákáǹleke náà ni. Obìnrin kan sọ nípa ọkọ rẹ̀ pé: “Ó já wa sílẹ̀. . . . Mo lérò pé ó wulẹ̀ ronú pé òun wà nínú àkámọ́ kan ni.”

Àwọn Oníbìínú Ọmọ

Ìwé ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Ohun tó túbọ̀ ń mú kí àìfararọ náà le sí i ni pé díẹ̀ lára àwọn ọmọ tí [àwọn òbí àgbà] náà gbà tọ́ wà lára àwọn ọmọ tó nílò ìrànlọ́wọ́ jù lọ, tí ọkàn wọn dà rú jù lọ, tí wọ́n sì jẹ́ oníbìínú jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà.”

Ṣàgbéyẹ̀wò ọmọdébìnrin tó jẹ́ ọmọ-ọmọ Elizabeth. Bàbá ọmọ náà kàn gbé e jù sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà níbi tí Elizabeth ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ tí ń bá àwọn ọmọdé wọ̀nà tí wọ́n bá fẹ́ sọdá títì ni. Elizabeth sọ pé: “Oníbìínú ọmọ ni. A ti pa á lára.” Àwọn ọmọ-ọmọ Sally náà ní irú ìmọ̀lára kan náà pé a ti pa àwọn lára. “Oníbìínú ni ọmọ-ọmọ mi ọkùnrin. Ó máa ń ronú pé kò sí ẹni tó gba tòun.” Ogun ìbí ọmọ kan ni kí ó ní bàbá àti ìyá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Finú wòye bí yóò ṣe rí lára ọmọdé kan tí a já sílẹ̀, tí a gbé jù sílẹ̀, tàbí tí wọ́n kọ̀! Lílóye àwọn ìmọ̀lára wọ̀nyí lè jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà fi sùúrù bá àwọn ọmọ tí ìwà wọn kò dára lò. Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”

Fún àpẹẹrẹ, ọmọ kan tí a já sílẹ̀ lè ṣàìgbà pé kí a tọ́jú òun. Lílóye ohun tí ń ba ọmọ náà lẹ́rù àti ohun tí ń dà á láàmú lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ìyọ́nú hùwà padà sí i. Bóyá sísọ fún un pé o mọ àwọn ohun tí ń bà á lẹ́rù kí o sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé wàá ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti bójútó o yóò ṣèrànwọ́ gan-an láti dín ẹ̀rù tí ń bà á kù.

Kíkojú Àwọn Pákáǹleke Náà

‘Ara ti ń ni mí, àánú ara mi sì ń ṣe mí. Àwa kọ́ ló yẹ kí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ yìí ṣe.’ Ohun tí òbí àgbà kan tí ń gbọmọ tọ́ wí nìyẹn. Bí o bá wà nínú ipò yẹn, o lè máa ronú lọ́nà kan náà. Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kò sí ọ̀nà àbáyọ nínú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ náà. Ìdí kan ni pé bí o ṣe ń dàgbà sí i ni agbára àtiṣe nǹkan rẹ yóò máa dín kù, ṣùgbọ́n ohun iyebíye ni ọjọ́ orí jẹ́ tí a bá ń sọ nípa ọgbọ́n, sùúrù, àti òye. Lọ́nà tí kò yani lẹ́nu, èsì ìwádìí kan fi hàn pé, “àwọn ọmọ tí kìkì àwọn òbí wọn àgbà tọ́ máa ń ṣe dáadáa tí a bá fi wọ́n wé àwọn ọmọ tí a tọ́ nínú ìdílé olóbìíkan.”

Bíbélì rọ̀ wá láti ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà, nítorí ó bìkítà fún wa.’ (1 Pétérù 5:7) Nítorí náà, máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé fún okun àti ìtọ́sọ́nà, bí onísáàmù náà ti ṣe. (Fi wé Sáàmù 71:18.) Fiyè sí àwọn àìní ìwọ alára nípa tẹ̀mí. (Mátíù 5:3) Obìnrin Kristẹni kan sọ pé: “Àwọn ìpàdé Kristẹni àti wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn ló ràn mí lọ́wọ́ láti là á já.” Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti kọ́ àwọn ọmọ-ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà Ọlọ́run. (Diutarónómì 4:9) Dájúdájú, Ọlọ́run yóò ti ìsapá rẹ lẹ́yìn láti tọ́ àwọn ọmọ-ọmọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.b

Má ṣe bẹ̀rù láti wá ìrànlọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọ̀rẹ́ lè ṣèrànwọ́, ní pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni. Sally rántí pé: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú ìjọ ṣètìlẹ́yìn gan-an. Nígbà tí mo bá sorí kọ́, wọ́n máa ń gbé mi ró. Àwọn kan tilẹ̀ fún mi lówó.”

Má ṣe gbójú fo ìrànlọ́wọ́ tí o lè rí lọ́dọ̀ ìjọba. (Róòmù 13:6) Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, èsì ìwádìí kan tí a ṣe nípa àwọn òbí àgbà fi hàn pé, “ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò mọ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n lè rí gbà tàbí ibi tí wọ́n ti lè rí i.” (Child Welfare) Àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re àti agbèfọ́ba tí ń ran àwọn arúgbó lọ́wọ́ ládùúgbò lè darí rẹ síbi iṣẹ́ tí o ti lè rí ìrànwọ́ gbà.

Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ló fà á tó jẹ́ kí àwọn òbí àgbà máa gbọmọ tọ́. (2 Tímótì 3:1-5) Ó ṣe tán, àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí jẹ́ àmì pé Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ láìpẹ́, yóò sì dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” níbi tí àwọn ipò tí ń ba ọ̀pọ̀ ìdílé nínú jẹ́ lónìí yóò ti di ohun àtijọ́. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ní báyìí ná, àwọn òbí àgbà tí ń gbọmọ tọ́ gbọ́dọ̀ sapá láti lo ipò wọn dáadáa. Àwọn púpọ̀ ti ṣàṣeyọrí nínú ìsapá wọn! Ẹ máa rántí nígbà gbogbo pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjákulẹ̀ ń wà, ẹ ṣì lè máa láyọ̀. Kódà, ẹ tilẹ̀ lè ní ayọ̀ rírí i tí àwọn ọmọ-ọmọ yín ń di adúróṣinṣin tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run! Ǹjẹ́ ìyẹn kò ní túmọ̀ sí pé gbogbo làálàá yín kò já sásán?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

b Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe) ní ọ̀pọ̀ ìlànà Bíbélì tó wúlò, tí àwọn òbí àgbà tí ń gbọmọ tọ́ lè mú lò ní títọ́ àwọn ọmọ-ọmọ wọn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọ̀ràn Òfin

Bóyá kí òbí àgbà gba ìwé òfin ìgbọmọtọ́ tàbí kí ó má gbà á jẹ́ ìbéèrè ẹlẹgẹ́, tó sì díjú. Mary Fron, tó jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn náà ṣàlàyé pé: “Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìwọ̀nba ẹ̀tọ́ lo ní lábẹ́ òfin láìgba àṣẹ ìgbọmọtọ́. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀ jù lọ, àwọn òbí ọmọ náà gan-an lè padà wá gbé ọmọ tàbí àwọn ọmọ náà nígbàkigbà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ òbí àgbà ń lọ́ra láti gba àṣẹ ìgbọmọtọ́, nítorí pé ìyẹn yóò túmọ̀ sí pé wọ́n ní láti jẹ́rìí ní ilé ẹjọ́ pé ọmọ àwọn kì í ṣe òbí tó tóótun.”—Good Housekeeping.

Àwọn òbí àgbà sábà máa ń ní ìṣòro àtifi ọmọ-ọmọ wọn sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ gbé e lọ fún ìtọ́jú ìṣègùn bí wọn kò bá gba àṣẹ ìgbọmọtọ́ lábẹ́ òfin. Bí ó ti wù kí ó rí, gbígba àṣẹ ìgbọmọtọ́ lè jẹ́ ìrírí agbonijìgì tí ń náni lówó, tí ń gba àkókò, tó sì ń tánni lókun. Kódà, bí àwọn òbí àgbà bá tilẹ̀ gbà á, a lè yọ wọ́n kúrò nínú ìṣètò ìtìlẹ́yìn ti ìjọba. Ìwé àtìgbàdégbà Child Welfare náà wá gba àwọn òbí àgbà nímọ̀ràn láti “wá ìrànlọ́wọ́ amòfin kan ládùúgbò, tí ó mọ̀ nípa òfin ìjọba nípa ìdílé, ọ̀ràn ìgbọmọtọ́, àti ire ọmọdé dáadáa.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

Gbígbé Ìṣirò Lé E

Inú èèyàn máa ń bà jẹ́ gan-an tí a bá rí ọmọ tí ìyà ń jẹ ní pàtàkì tó bá tan mọ́ni. Bíbélì sì pa á láṣẹ fún àwọn Kristẹni láti pèsè fún ‘àwọn tí í ṣe tiwọn.’ (1 Tímótì 5:8) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, ó bọ́gbọ́n mu kí òbí àgbà kan ronú dáadáa kí ó tó gba irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. (Òwe 14:15; 21:5) A ní láti gbé ìṣirò lé e.—Fi wé Lúùkù 14:28.

Gbàdúrà, kí o sì ronú nípa ọ̀rọ̀ náà pé: Ǹjẹ́ ipò rẹ nípa ti ara, ìmọ̀lára, tẹ̀mí, àti ìṣúnná owó yóò jẹ́ kí o lè gbọ́ bùkátà ọmọ yìí? Kí ni èrò ẹnì kejì rẹ nínú ìgbéyàwó nípa ọ̀ràn náà? Ọ̀nà èyíkéyìí ha wà tí o lè gbà fún àwọn òbí ọmọ náà níṣìírí tàbí tí o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n baà lè bójú tó ọmọ wọn fúnra wọn bí? Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí kan tí wọ́n ya pòkíì wulẹ̀ ń bá a lọ ní ọ̀nà oníwà pálapàla wọn ni. Inú ìyá àgbà kan bà jẹ́ bí ó ti rántí pé: “Àwọn mélòó kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ ni mo gbà tọ́. Àmọ́, kò jáwọ́ jíjòògùnyó, bẹ́ẹ̀ ló sì ń bímọ sí i. Ó dé àyè kan tí mo ní láti sọ pé ó tó gẹ́ẹ́!”

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí o kò bá gba àwọn ọmọ-ọmọ rẹ tọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ǹjẹ́ ara rẹ yóò lè gba ìdààmú tí yóò kó bá ọ tí o bá mọ̀ pé ẹlòmíràn ló ń tọ́ wọn, bóyá kí ó tilẹ̀ jẹ́ ará ìta? Àìní àwọn ọmọ náà nípa tẹ̀mí ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn ẹlòmíràn yóò lè fi àwọn ìlànà Ọlọ́run kọ́ wọn? Àwọn kan lè sọ pé lójú àwọn ìṣòro tó so mọ́ ọn, kò sí ohun tí àwọn lè ṣe ju kí àwọn gbé ẹrù náà.

Àwọn ọ̀ràn tí ń roni lára gbáà nìwọ̀nyí, olúkúlùkù ló sì gbọ́dọ̀ dá ìpinnu tirẹ̀ ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ó ṣòro gan-an fún ọ̀pọ̀ òbí àgbà láti kájú àìní títọ́ àwọn ọmọ kéékèèké

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn òbí àgbà tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìsapá wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́