ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 3/8 ojú ìwé 22-23
  • Ìrètí Tó Dájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrètí Tó Dájú
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrètí Wo Ni Aṣebi Náà Ní?
  • Ìgbésí Ayé Wa Lè Lójú
  • Ṣé Ọ̀run Ni Jésù Sọ Pé Aṣebi Tó Wà Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òun Yóò Lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Àá Pàdé ní Párádísè!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 3/8 ojú ìwé 22-23

Ìrètí Tó Dájú

NÍ NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, wọ́n ṣi ẹjọ́ kan dá, wọ́n dájọ́ ikú fún Jésù, táa sábà máa ń pè ní ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí. Bó ti wà lórí òpó igi oró, ọkùnrin aṣebi kan tí wọ́n gbé kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní: “Ìwọ ni Kristi, àbí ìwọ kọ́? Gba ara rẹ àti àwa là.”

Bó ti ń sọ ìyẹn lọ́wọ́, aṣebi míì tóun náà ń kú lọ bá ọkùnrin yìí wí, ó ní: “Ṣé ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run rárá ni, nísinsìnyí tí ìwọ wà nínú ìdájọ́ kan náà? Ní tòótọ́, ó rí bẹ́ẹ̀ fún wa lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu, nítorí ohun tí ó tọ́ sí wa ni àwa ń gbà ní kíkún nítorí àwọn ohun tí a ṣe; ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun kan tí kò tọ̀nà.” Ó wá yíjú sí Jésù, ó bẹ̀ ẹ́ pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.”

Jésù dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:39-43.

Ìrètí àgbàyanu ń bẹ níwájú Jésù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ipa tí ìrètí yìí ní lórí Jésù, ó sọ pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú.”—Hébérù 12:2.

Ara “ìdùnnú” táa gbé ka iwájú Jésù ni gbígbé pẹ̀lú Baba rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní ọ̀run àti dídi Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Kò tán síbẹ̀ o, yóò tún ní ìdùnnú kíkí àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí yóò jọba pẹ̀lú rẹ̀ lé ilẹ̀ ayé lórí, káàbọ̀ sí ọ̀run. (Jòhánù 14:2, 3; Fílípì 2:7-11; Ìṣípayá 20:5, 6) Kí wá ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣèlérí fún aṣebi náà tó ronú pìwà dà pé yóò wọ Párádísè?

Ìrètí Wo Ni Aṣebi Náà Ní?

Ọkùnrin yẹn kò tóótun láti lọ jọba pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. Kò sí lára àwọn tí Jésù sọ fún pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28, 29) Síbẹ̀, Jésù ṣèlérí pé aṣebi yẹn yóò wà pẹ̀lú òun ní Párádísè. Báwo ni ìlérí yẹn yóò ṣe ní ìmúṣẹ?

Inú Párádísè, ọgbà ìtura táa ń pè ní Édẹ́nì ni Jèhófà Ọlọ́run fi Ádámù àti Éfà, ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́, sí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 15) Orí ilẹ̀ ayé ni Édẹ́nì wà, ète Ọlọ́run sì ni pé kí gbogbo ilẹ̀ ayé di párádísè. Àmọ́, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì lé wọn kúrò nínú ilé ẹlẹ́wà wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24) Ṣùgbọ́n Jésù ṣí i payá pé a óò mú Párádísè padà bọ̀ sípò, yóò sì kárí ayé nígbà tó bá yá.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa èrè tí òun àtàwọn àpọ́sítélì ẹlẹgbẹ́ òun yóò gbà fún títẹ̀lé e, Jésù ṣèlérí pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá.” (Mátíù 19:27, 28) Ó yẹ kí a kíyè sí i pé nígbà tí Lúùkù ń ròyìn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yìí, kàkà kí ó sọ pé “ní àtúndá,” ohun tó ní Jésù sọ ni pé “nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀.”—Lúùkù 18:28-30.

Fún ìdí yìí, nígbà tí Jésù Kristi bá jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀ ní ọ̀run, pẹ̀lú àwọn tí yóò jọba pẹ̀lú rẹ̀, ni yóò fìdí ètò àwọn nǹkan tuntun òdodo múlẹ̀. (2 Tímótì 2:11, 12; Ìṣípayá 5:10; 14:1, 3) Nípasẹ̀ ìṣàkóso ọ̀run ti Kristi, ni ète Ọlọ́run fún gbogbo ilẹ̀ ayé ní àtètèkọ́ṣe yóò fi ní ìmúṣẹ!

Ìgbà ìṣàkóso Ìjọba yìí ni Jésù yóò mú ìlérí tó ṣe fún ọ̀daràn tí wọ́n jọ kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn ṣẹ. Òun yóò jí i dìde, ọkùnrin náà yóò sì di ọmọ abẹ́ ìjọba Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Yóò fún aṣebi náà ní àǹfààní láti dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run béèrè, kí ó lè láǹfààní láti wà láàyè títí láé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà. Ká máa yọ̀ ló kù o jàre, nínú ìrètí tí Bíbélì gbé kalẹ̀ níwájú wa, ìyẹn ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé!

Ìgbésí Ayé Wa Lè Lójú

Fojú inú wo bí ìrètí àgbàyanu yẹn yóò ti jẹ́ kí ìgbésí ayé wa lójú tó. Ó lè dáàbò bo èrò inú wa lọ́wọ́ ríro ara wa pin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí yẹn wé apá pàtàkì nínú ìhámọ́ra wa nípa tẹ̀mí. Ó sọ pé a ní láti gbé “ìrètí ìgbàlà” wọ̀ “gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.”—1 Tẹsalóníkà 5:8; Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

Ìrètí yẹn ń gbé ẹ̀mí ró. Nínú Párádísè tí ń bọ̀, nínìkan wà kò ní sí mọ́, ohun tí yóò rọ́pò rẹ̀ ni ẹkún ayọ̀, nígbà tí “Ọlọ́run ẹni tí ń gbé òkú dìde” bá ń mú àwọn olólùfẹ́ wa padà bọ̀ sí ìyè. (2 Kọ́ríńtì 1:9) Nígbà náà, ìbànújẹ́ dídi hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ìrora, àti àìlèkúrò lójú kan yóò dohun ìgbàgbé, nítorí pé “ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.” ‘Ara’ èèyàn ‘yóò jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe,’ àti pé yóò “padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.”—Aísáyà 35:6; Jóòbù 33:25.

Nígbà yẹn, tí “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí,’” àròdùn tí àrùn kògbóògùn ń fà yóò ti dohun ìgbàgbé. (Aísáyà 33:24) Rádaràda tí akọ ìsọríkọ́ ń sọ ayé ẹni dà kò ní sí mọ́, dípò rẹ̀ “ayọ̀ yíyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin” ni yóò wà. (Aísáyà 35:10) Àìnírètí tó máa ń wáyé nígbà tí wọ́n bá sọ féèyàn pé ó ti kó àìsàn tó máa gbẹ̀mí ẹ̀ yóò pòórá, àtòun àti ikú pàápàá, tí í ṣe ọ̀tá ìran ènìyàn láti ayébáyé.—1 Kọ́ríńtì 15:26.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23, 24]

Fi ìrètí àgbàyanu ayé tuntun Ọlọ́run sọ́kàn gidigidi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́