Ojú Ìwòye Bíbélì
Ta Ni Òjíṣẹ́?
LÁLẸ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú ikú ìrúbọ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn tó gbóná janjan. Níbàámu pẹ̀lú nǹkan tó wà nínú Lúùkù 22:24, “awuyewuye gbígbóná janjan kan dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn àpọ́sítélì Jésù nìyẹn. Ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mejì ṣáájú ìgbà yìí ni Jésù ti tún èrò wọn ṣe.
Báwo ló ti bani nínú jẹ́ tó pé ní alẹ́ tó ṣe kókó gan-an yìí, Jésù rí i pé òún ṣì ní láti tún máa rán wọn létí nǹkan tí Kristẹni òjíṣẹ́ kan gbọ́dọ̀ jẹ́ ní tòótọ́. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín dà bí ẹni tí ó kéré jù lọ, kí ẹni tí ó sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí dà bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.”—Lúùkù 22:26.
Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn àpọ́sítélì náà ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìjẹ́pàtàkì ipò àti ìyọrí ọlá. Kó tó di pé Jésù dé, àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ni wọ́n ń fi ṣe àwòkọ́ṣe nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn. Dípò kí wọ́n fún àwọn ènìyàn ní ìtọ́sọ́nà àti ìdarí tẹ̀mí, àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtàwọn òfin tí kò ṣeé yí padà, tó “sé ìjọba ọ̀run pa níwájú àwọn ènìyàn” ni àwọn òjíṣẹ́ èké wọ̀nyí fọwọ́ sí. Ọ̀rọ̀ ipò jẹ wọ́n lógún, wọ́n máa ń wá ìyọrí ọlá ṣáá, wọ́n sì jẹ́ anìkànjọpọ́n ẹ̀dá, tó jẹ́ pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ wọn nítorí “kí àwọn ènìyàn lè rí wọn.”—Mátíù 23:4, 5, 13.
Irú Òjíṣẹ́ Tuntun Kan
Bó ti wù kó rí, Jésù nawọ́ èròǹgbà tuntun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tẹ̀mí sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó kọ́ wọn pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. . . . Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín.” (Mátíù 23:8-11) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ní láti fara wé àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ wọn. Bí wọ́n bá fẹ́ láti jẹ́ ojúlówó òjíṣẹ́, Jésù ni wọ́n máa fara wé. Irú àpẹẹrẹ wo ló fi lélẹ̀?
Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹko·nos fún “òjíṣẹ́.” The Encyclopedia of Religion ṣàlàyé pé “kì í ṣe ipò ọlá” ni ọ̀rọ̀ yìí dúró fún “bí kò ṣe ipò ìránṣẹ́ tí òjíṣẹ́ náà wà sí ẹni tó ń ṣiṣẹ́ sìn: títẹ̀lé àpẹẹrẹ Kristi . . . ló jẹ́ kókó tó wà nínú bí Kristẹni ṣe mọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sí.”
Níbàámu pẹ̀lú ìtumọ̀ tó péye fún ọ̀rọ̀ náà “òjíṣẹ́,” Jésù fi ara rẹ̀ fún àwọn mìíràn pátápátá. Ó fi sùúrù ṣàlàyé pé: “Ọmọ ènìyàn wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Jésù fi àìmọtara-ẹni-nìkan lo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀, àti ìtóótun rẹ̀ láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ nípa tara àti tẹ̀mí. Èé ṣe? Nítorí pé àánú àwùjọ ènìyàn tí wọ́n ti fìyà oúnjẹ tẹ̀mí jẹ, tí wọ́n ń rọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣe é. Ó fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìfẹ́ ọlọ́làwọ́ ló sún un ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà fi irú ẹ̀mí fífúnni bẹ́ẹ̀ hàn.—Mátíù 9:36.
Jálẹ̀ ìgbésí ayé Jésù, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn tó ń bọ̀ wá jẹ́ òjíṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú. Ó sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:37, 38) Dájúdájú, ó yẹ kí àwọn òjíṣẹ́ Kristi ṣe nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ayé tí ì rí rí—kí wọ́n máa pèsè ìtùnú tẹ̀mí fún gbogbo aráyé nípa wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 28:19, 20.
Dídarí àfiyèsí sí fífúnni àti ṣíṣiṣẹ́sìn nítorí àìní àwọn ẹlòmíràn yìí ló mú kí ọ̀nà ìgbàṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti Kristi yàtọ̀ pátápátá. Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti jẹ́ òṣìṣẹ́, àwọn apẹja tẹ̀mí, àti olùṣọ́ àgùntàn, kò kọ́ wọn láti jẹ́ pidánpidán àti ọ̀mọ̀wé tó kó sí aṣọ mérìíyìírí gẹ̀rẹ̀jẹ̀ àti aṣọ oyè.—Mátíù 4:19; 23:5; Jòhánù 21:15-17.
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ó bani nínú jẹ́ pé, bí ọ̀rúndún kan ti ń lọ tí òmíràn ń dé, èrò gíga aláìnímọtara-ẹni-nìkan tí a ní nípa àwọn òjíṣẹ́, pé wọ́n jẹ́ oníwàásù àti olùkọ́ olùfara-ẹni-rúbọ ni wọ́n ti sọ dìdàkudà. Ohun tó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ti wá yí padà di ti ẹgbẹ́ àlùfáà kan tí wọ́n di onírúurú ipò mú. Wọ́n dá oríṣiríṣi ẹgbẹ́ àti ipò sílẹ̀, wọn ò sì mọ̀ ju níní ipò iyì àti agbára lọ, tó sì jẹ́ pé ọrọ̀ rẹpẹtẹ ni wọ́n ń kó jọ. Èyí dá ìpínyà sílẹ̀. Wọ́n dá àwùjọ àlùfáà sílẹ̀, pípín ara Olúwa àti gbígba àwọn tó bá dẹ́ṣẹ̀ nímọ̀ràn sì ni lájorí iṣẹ́ wọn. Ìsìn Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, tó jẹ́ pé olúkúlùkù ẹni tó bá wà nínú rẹ̀ ló jẹ́ òjíṣẹ́, ti yí padà ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, kì í tún ṣe ìsìn kan tó múná dóko mọ́, kò gbéṣẹ́ mọ́, ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ tí wọ́n sì dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nìkan ló gbọ́dọ̀ wàásù kí wọ́n sì kọ́ni.
Àmọ́ o, kì í ṣe aṣọ mérìíyìírí gẹ̀rẹ̀jẹ̀, ààtò ìsìn onípẹ́pẹ́fúrú, owó oṣù, tàbí òfin onísìn bíi ti ológun, ni Bíbélì sọ pé a o fi dá Kristẹni òjíṣẹ́ kan mọ̀, bí kò ṣe nípa iṣẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù to irú ìṣarasíhùwà tí àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ fi hàn lẹ́sẹẹsẹ. Ó rọ̀ wọ́n láti má ṣe ‘ohunkóhun láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.’—Fílípì 2:3.
Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù fi ohun tó ń wàásù rẹ̀ sílò. Bí ó ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi láìyà kúrò nínú rẹ̀, kò fìgbà kan rí wá ‘àǹfààní ti ara rẹ̀ bí kò ṣe ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí a bàa lè gbà wọ́n là.’ Ó mọ̀, ó sì tún ronú gidigidi nípa ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ pé ó jẹ́ láti “mú ìhìn rere wá láìgba owó, kí n má bàa lo ọlá àṣẹ mi nínú ìhìn rere ní ìlòkulò.” Kì í ṣe pé ó “ń wá ògo láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.”—1 Kọ́ríńtì 9:16-18; 10:33; 1 Tẹsalóníkà 2:6.
Àpẹẹrẹ títayọ gbáà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni òjíṣẹ́ tòótọ́ kan lèyí jẹ́ o! Àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ títayọ, tí wọ́n sì ń rìn nínú àwòkọ́ṣe olùfara-ẹni-rúbọ tí Jésù Kristi fi lélẹ̀, tí wọ́n ń lo ara wọn pátápátá lọ́fẹ̀ẹ́ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí àti ìtùnú ìhìn rere fún àwọn ẹlòmíràn, ń fi ara wọn hàn bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́.—1 Pétérù 2:21.