Ìlera fún Gbogbo Èèyàn—Láìpẹ́!
ÌWÉ ìròyìn Jámánì náà, Focus sọ pé: “Èrò pé èèyàn ò ní ṣàìsàn mọ́ láé . . . ti wá gbajúmọ̀ báyìí bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta.” Èrò yìí kì í kúkú ṣe tuntun. Nígbà tí Ẹlẹ́dàá ṣẹ̀dá ènìyàn, kò ní i lọ́kàn pé kí ìran ènìyàn tiẹ̀ ṣàìsàn páàpáà. Oun tó ní lọ́kàn fún ìran ènìyàn kì í kàn ṣe “fífún gbogbo èèyàn lágbàáyé ní ìlera tó jọjú.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ara líle ni Ẹlẹ́dàá wa pète fún gbogbo èèyàn!
Kí ló fà á tí gbogbo wa fi ń ṣàìsàn tí àrùn sì ń kọ lù wá? Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run dá àwọn òbí ìran ènìyàn, ìyẹn Ádámù àti Éfà, pé pérépéré. Lẹ́yìn tó parí ìṣẹ̀dá rẹ̀, “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ kò fìgbà kan ní i lọ́kàn pé kí àìsàn àti ikú kó hílàhílo bá ìgbésí ayé ọmọ ènìyàn. Àmọ́ nígbà tí Ádámù àti Éfà pa ọ̀nà ìwàláàyè tí a fi lélẹ̀ fún wọn tì, wọ́n ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ikú làbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, ó sì tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Róòmù 5:12.
Jèhófà ò pa ìran ènìyàn tì o. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò pa ète tó ní lọ́kàn fún wọn àti fún ilẹ̀ ayé láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tì. Láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin Bíbélì, ó ti jẹ́ ká mọ ète rẹ̀ láti fún ìran ènìyàn onígbọràn ní ìlera pípé gẹ́gẹ́ bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Nígbà tí Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi agbára Ọlọ́run láti wo àìsàn hàn. Fún àpẹẹrẹ, Jésù la ojú afọ́jú, ó wo àrùn ẹ̀tẹ̀, ó mú kí adití gbọ́ràn, ó wo àrùn ògùdùgbẹ̀, àrùn wárápá, àti àrùn ẹ̀gbà sàn.—Mátíù 4:23, 24; Lúùkù 5:12, 13; 7:22; 14:1-4; Jòhánù 9:1-7.
Láìpẹ́, Ọlọ́run yóò sọ fún Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba, pé kó bẹ̀rẹ̀ sí darí gbogbo ìgbòkègbodò ìran ènìyàn. Lábẹ́ àbójútó rẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà á ti ní ìmúṣẹ pé: “Kò sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’ Àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ àwọn tí a ti dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” (Aísáyà 33:24) Báwo lèyí ṣe máa ṣẹlẹ̀?
A óò rí i pé wòlíì náà kọ̀wé nípa àwọn èèyàn táa ti “dárí ìṣìnà wọn jì.” Nítorí náà, ohun náà gan-an tó fa àìsàn, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ tí aráyé ti jogún, ni a óò mú kúrò. Báwo? Ìran ènìyàn onígbọràn yóò jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù, nípa báyìí kò ní sí ohun tó ń fa àìsàn àti ikú mọ́. Ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé ni ipò tó tuni lára yóò wà. Kristẹni àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Èyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́!—Ìṣípayá 21:3, 4; Mátíù, orí 24; 2 Tímótì 3:1-5.
Wíwà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì
Lọ́wọ́ táa ṣì wà yìí, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń bá àìsàn yí. Kò yẹ kó yani lẹ́nu nígbà náà láti rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa ìlera wọn àtàwọn èèyàn wọn.
Àwọn Kristẹni lónìí mọrírì akitiyan ìmọ̀ ìṣègùn gidi gan an. Wọ́n ń ṣe àwọn ohun tó bọ́gbọ́n mu láti rí i pé àwọ́n ní ìlera tó ṣe ṣámúṣámú. Àmọ́ ṣá, ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ iwájú tí kò ti ní sí àìsàn ló ń jẹ́ ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lórí ọ̀ràn yìí. Ó dìgbà tí Mèsáyà Ọba bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ìran ènìyàn kí ara líle tó ṣeé ṣe. Bí a ti rí i, pẹ̀lú àwọn àwárí tó kàmàmà tí ìmọ̀ ìṣègùn ti ṣe, ọwọ́ rẹ̀ kò tíì tó ọsàn tó lómi nínú jù lọ tó wà lókè igi, ìyẹn ìlera fún gbogbo èèyàn.
Láìpẹ́, ọwọ́ á tẹ góńgó “fífún gbogbo èèyàn lágbàáyé ní ìlera tó jọjú.” Àmọ́ kì í ṣe nípasẹ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tàbí Àjọ Ìlera Àgbáyé, kì í ṣe àwọn elétò àyíká kò sì lè jẹ́ àwọn tó ń tún àwùjọ tò tàbí àwọn oníṣègùn. Jésù Kristi nìkan ló lágbára láti ṣe é. Ayọ̀ ọ̀hún á mà ti lọ ga jù o, pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín “a óò dá [ìran ènìyàn] sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”!—Róòmù 8:21.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìlera tó jí pépé yóò jẹ́ ti gbogbo ènìyàn nínú ayé tuntun Ọlọ́run