ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 10/8 ojú ìwé 4-8
  • Oríṣiríṣi Ohun Ọ̀gbìn Ṣe Kókó fún Ìwàláàyè Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oríṣiríṣi Ohun Ọ̀gbìn Ṣe Kókó fún Ìwàláàyè Èèyàn
  • Jí!—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ètò Kébimápàlú
  • Yíyí Àbùdá Àwọn Ohun Ọ̀gbìn Padà
  • Fífi Àwọn Hóró Irúgbìn Pa Mọ́—Ṣé Òun Ni Kò Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Kú Àkúrun?
  • Àwọn Ìṣòro Níbi Tí Wọ́n Kó Wọn Pa Mọ́ Sí
  • Onírúurú Ohun Ọ̀gbìn Ń pòórá Èé Ṣe?
    Jí!—1998
  • Ṣé Èèyàn Ń Pa Oúnjẹ Ara Rẹ̀ Run Ni?
    Jí!—2001
  • Ta Ni Yóò Bọ́ Aráyé?
    Jí!—2001
  • Kẹ́míkà Apakòkòrò Jewéjewé Ń pa Ju Kòkòrò Lọ
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 10/8 ojú ìwé 4-8

Oríṣiríṣi Ohun Ọ̀gbìn Ṣe Kókó fún Ìwàláàyè Èèyàn

LÁWỌN ọdún 1840, iye ènìyàn tó ń gbé ilẹ̀ Ireland lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ, ìyẹn sì mú kó jẹ́ orílẹ̀-èdè tí èrò pọ̀ sí jù lọ ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù. Ànàmọ́ lolórí oúnjẹ wọn, oríṣi kan báyìí tó máa ń ta bọ̀ọ̀pà-bọ̀ọ̀pà ni wọ́n máa ń gbìn jù lọ.

Lọ́dún 1845, àwọn àgbẹ̀ gbin ànàmọ́ yìí bí ìṣe wọn, ṣùgbọ́n kòkòrò bá a jà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú àkúrun. Nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Last Harvest—The Genetic Gamble That Threatens to Destroy American Agriculture, Paul Raeburn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Ireland la ọdún lílekoko yẹn já. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìparun yìí tún ṣẹlẹ̀. Kò sí nǹkan táwọn àgbẹ̀ lè ṣe ju pé kí wọ́n tún irú ànàmọ́ yẹn gbìn lọ. Wọn ò ní oríṣi mìíràn. Rírun ló mà tún run o, àmọ́ ti ọ̀tẹ̀ yìí wá kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ohun tójú wọn rí kò ṣeé máa fẹnu sọ.” Àwọn òpìtàn fojú bù ú pé ó tó mílíọ̀nù kan èèyàn tébi pa kú, tí mílíọ̀nù kan ààbọ̀ mìíràn sì ṣí lọ síbòmíràn, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ṣí lọ. Ìṣẹ́ sì han àwọn tó kù léèmọ̀.

Ní Andes, tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà, oríṣiríṣi ẹ̀yà ànàmọ́ tó wà làwọn àgbẹ̀ ibẹ̀ gbìn, kìkì ìwọ̀nba díẹ̀ péré sì ni wàhálà náà kọ lù. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó kàn kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ó wá hàn gbangba pé, ààbò ló jẹ́ láti ní àwọn ọ̀wọ́ yìí lónírúurú ẹ̀yà. Gbígbin kìkì ẹ̀yà irúgbìn kan kò bá ìlànà tó ń dá ẹ̀mí àwọn nǹkan ọ̀gbìn wọ̀nyí sí mu ó sì máa ń fi wọ́n sínú ewu àrùn tàbí kòkòrò, èyí tó lè mú kí irè oko gbogbo àgbègbè kan ṣòfò dànù. Ìyẹn ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbẹ̀ gbára lé lílo oríṣiríṣi oògùn apakòkòrò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kẹ́míkà yìí sábà máa ń ṣe àyíká ní jàǹbá.

Kí ló mú àwọn àgbẹ̀ pa gbígbin oríṣiríṣi àwọn ohun ọ̀gbìn ìbílẹ̀ tì tí wọ́n sì wá gbájú mọ́ ẹ̀yà kan ṣoṣo? Ìṣòro ọrọ̀ ajé ló sábà ń mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀. Gbígbin ẹ̀ya irúgbìn kan ṣoṣo máa ń mú kí ìkórè rọrùn, ó máa ń jẹ́ káwọn èso fani mọ́ra, kì í jẹrà, wọ̀ǹtìwọnti ló sì máa ń so. Ọdún 1960 ni àṣà yìí wá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu èyí tí wọ́n wá pè ní ètò kébimápàlú.

Ètò Kébimápàlú

Bí ìkéde ṣe ń wá lọ́tùn-ún lósì látọ̀dọ̀ ìjọba àtàwọn oríṣiríṣi àjọ, wọ́n rọ àwọn àgbẹ̀ tó ń gbé láwọn apá ibi tó ṣeé ṣe kí ìyàn ti mú pé kí wọ́n fi gbígbin kìkìdá àwọn irúgbìn oníhóró tó máa ń so wọ̀ǹtìwọnti rọ́pò onírúurú ohun ọ̀gbìn tí wọ́n ti máa ń gbìn tẹ́lẹ̀, pàápàá jù lọ ìrẹsì àti àlìkámà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kókìkí àwọn ohun ọ̀gbìn oníhóró yìí pé àwọn ni “bá-n-tán-ṣẹ̀ẹ́” tí yóò lé ebi aráyé lọ. Ṣùgbọ́n, owó pọ́ọ́kú kọ́ ni wọ́n ń ta àwọn oúnjẹ oníhóró náà, wọ́n sì fi ìlọ́po mẹ́ta wọ́n ju iye tí wọ́n ń tà wọ́n tẹ́lẹ̀. Orí lílo àwọn kẹ́míkà, títí kan ajílẹ̀, sì ni àwọn irè oko sinmi lé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tàwọn irinṣẹ́ olówó gegere bí ẹ̀rọ katakata tí wọ́n ń lò. Àmọ́, nígbà tówó ìrànwọ́ dé látọ̀dọ̀ ìjọba, kíá ni ètò kébimápàlú bẹ̀rẹ̀ ní rẹbutu. Raeburn sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò yìí ti gba ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi, [ó] ti dá ìbẹ̀rù sílẹ̀ báyìí nípa àkóbá tó lè ṣe fún ọ̀nà tí aráyé á gbà fi máa rí oúnjẹ jẹ.”

Lẹ́nu kan, ètò kébimápàlú lè ti mú àǹfààní ojú ẹsẹ̀ wá tó sì wá dá wàhálà ọlọ́jọ́ pípẹ́ sílẹ̀. Kò pẹ́ kò jìnnà, àṣà gbígbin oríṣi irè oko kan wá di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ń ṣe, lílo ajílẹ̀ lójú méjèèjì túbọ̀ ń ran àwọn èpò lọ́wọ́ láti máa dàgbà sí i, àwọn oògùn apakòkòrò náà sì ń pa àwọn kòkòrò tó ṣàǹfààní àtàwọn tí kò ṣàǹfààní. Láwọn àkùrọ̀ tí wọ́n máa ń gbin ìrẹsì sí, àwọn kẹ́míkà olóró ti pa ẹja, edé, akàn, àkèré, àtàwọn ewéko tó wúlò fún jíjẹ àtàwọn irúgbìn inú igbó—tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ṣe pàtàkì fún àfikún oúnjẹ. Kẹ́míkà táwọn àgbẹ̀ sì ń fà símú ti ṣàkóbá fáwọn àgbẹ̀.

Olùkọ́ kan ní Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Nípa Ohun Alààyè ní Yunifásítì àwọn àgbàlagbà tó wà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ọ̀mọ̀wé Mae-Wan Ho kọ̀wé pé: “Kò sẹ́ni tó lè jiyàn rẹ̀ mọ́ pé àṣà gbígbin oríṣi irè oko kan tí wọ́n dá sílẹ̀ látìgbà ‘Ètò Kébimápàlú’ ti ní ipa tí kò dára lórí níní àwọn irè oko lónírúurú tó sì ti ṣàkóbá fún mímú kí oúnjẹ wà káàkiri àgbáyé.” Gẹ́gẹ́ bí Ètò Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ṣe sọ, ìpín márùndínlọ́gọ́rin lára ọgọ́rùn-ún onírúurú àbùdá táa máa ń rí nínú àwọn ohun tí a ń gbìn ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn ló ti sọnù báyìí, iṣẹ́ àgbẹ̀ tó ti wá di iṣẹ́ òwò sì ni lájorí ohun tó fà á.

Ìwé kan tí Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé tẹ̀ jáde kìlọ̀ pé “ìṣòro kékeré kọ́ ni àṣà sísọ àbùdá àwọn irè oko di oríṣi kan náà máa dá sílẹ̀.” Ọ̀nà wo ni wọ́n fi ń kápá àwọn ewu yìí? Wọ́n nílò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn àtàwọn kẹ́míkà ajẹ́bíidán títí kan ìpèsè owó fáwọn àgbẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, kò tíì sí ìdánilójú pé ìwọ̀nyí á kápá ìṣòro náà. Fífi àbùdá sọ irè oko di oríṣi kan wà lára ohun tó mú kí oko ọkà Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà rẹ̀ dànù tó sì mú kí ilẹ̀ Indonesia pàdánù ìrẹsì tó tó ìdajì mílíọ̀nù sarè ilẹ̀. Àmọ́ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, oríṣi iṣẹ́ àgbẹ̀ tuntun kan tún ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pípa ayé àwọn nǹkan alààyè dà kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà rárá—ìyẹn àbùdá wọn.

Yíyí Àbùdá Àwọn Ohun Ọ̀gbìn Padà

Wíwádìí àbùdá ti yọrí sí ìdásílẹ̀ iṣẹ́ tuntun kan tí ń mówó gegere wọlé tí wọ́n pè ní àpapọ̀ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ohun alààyè. Bí orúkọ yẹn ṣe fi hàn, ó jẹ́ dída ẹ̀kọ́ nípa ohun alààyè pọ̀ mọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní, ní lílo àwọn ọ̀nà bíi yíyí àbùdá padà. Díẹ̀ lára àwọn iléeṣẹ́ yìí mọ tinú-tòde iṣẹ́ àgbẹ̀ wọ́n sì ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu láti lè ní àṣẹ lórí àwọn irúgbìn tó máa ń so wọ̀ǹtìwọnti, tí àrùn, ọ̀dá, tàbí òjò dídì kò lè ṣe ní nǹkan kan, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ nílò àwọn kẹ́míkà eléwu. Tọ́wọ́ wọn bá lè tẹ àwọn ìlépa yìí, àǹfààní tó máa tìdí ẹ̀ yọ kì í ṣe kékeré. Ṣùgbọ́n àwọn kan ti fi àìbalẹ̀ ọkàn hàn lórí yíyí àbùdá àwọn irúgbìn padà.

Ìwé Genetic Engineering, Food, and Our Environment sọ pé: “Ní ti ìṣẹ̀dá, ó níbi táa lè fi àwọn àbùdá tó wà nínú wọn lúra wọn mọ. Wọ́n lè fi oríṣi ẹ̀ya òdòdó kan lú òmíràn, àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe lè fi òdòdó lú ànàmọ́ láéláé. . . . Nínú yíyí àbùdá padà sì rèé, ohun tó sábà ń béèrè ni pé kí wọ́n mú ohun kan láti ara irú ọ̀wọ́ kan kí wọ́n sì fi sínú òmíràn kó lè ní irú ìṣesí kan tàbí àbùdá kan tí wọ́n fẹ́ kó ní. Fún àpẹẹrẹ, ó lè túmọ̀ sí mímú àbùdá tí kì í jẹ́ kí ẹja tó ń gbé inú omi oníyìnyín gan (ẹja bíi flounder), kí wọ́n sì fi sínú ànàmọ́ tàbí èso míì, tí ojú ọjọ́ tútù kò fi ní rí i gbé ṣe. Ó ti wá ṣeé ṣe báyìí láti mú àbùdá láti ara àwọn bakitéríà, fáírọ́ọ̀sì, kòkòrò, ẹran tàbí lára àwọn èèyàn pàápàá kí wọ́n sì fi sínú ohun ọ̀gbìn.”a Lédè kan, àpapọ̀ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ti ohun alààyè ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn ènìyàn láti rí fìn-ín ìdí kókò àwọn àbùdá tó mú kí àwọn ọ̀wọ́ kan yàtọ̀ sí àwọn ọ̀wọ́ mìíràn.

Bíi ti ètò kébimápàlú, ohun táwọn kan pè ní fífi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yí àwọn ohun ọ̀gbìn padà, ń pa kún ìṣòro sísọ àbùdá àwọn ohun ọ̀gbìn di oríṣi kan—èyí táwọn kan sọ pé ó tún bògìrì, nítorí pé ó ti ṣeé ṣe fáwọn onímọ̀ nípa àbùdá láti mú irú ohun kan náà jáde tàbí kí irú rẹ̀ hù lára òmíràn, tí kò sì ní sí ìyàtọ̀ kankan láàárín wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù nípa bí onírúurú ọ̀wọ́ àwọn ohun ọ̀gbìn ṣe ń dín kù ṣì wà síbẹ̀. Àmọ́, àwọn ohun ọ̀gbìn tí wọ́n ti fi ìmọ̀ ẹ̀rọ yí àbùdá wọn padà ti wá gbé àwọn ìbéèrè tuntun dìde o, irú bí àkóbá tí wọ́n lè ṣe fún wa àti fún àyíká wa. Jeremy Rifkin, òǹkọ̀wé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Ńṣe la kàn forí lé sànmánì tuntun ti iṣẹ́ ọ̀gbìn onímọ̀ ẹ̀rọ pẹ̀lú àwọn ìrètí kàǹkà-kàǹkà lọ́kàn wa láìmọ ibi tó máa sìn wá dé, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tó ń dá wa lọ́wọ́ kọ́, òye wa nípa ohun tó lè tìdí rẹ̀ jáde kò sì tó nǹkan.”b

Àmọ́, ńṣe ni agbára tó ti dọ́wọ́ àwọn ilé iṣẹ́ tó ń yí àbùdá ohun alààyè padà yìí ń gbé wọn nínú, bẹ́ẹ̀ ni ìbáradíje sì ń lọ láàárín wọn ní pẹrẹu kí wọ́n lè máa fi orúkọ wọn pé àwọn irúgbìn tuntun àtàwọn ohun alààyè mìíràn tí wọ́n ti yí padà. Ní báyìí ná, kíkú táwọn irúgbìn ń kú àkúrun kò dáwọ́ dúró o. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ níbẹ̀rẹ̀, àwọn ìjọba kan àtàwọn àjọ aládàáni kan ti lọ dá àwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró irúgbìn pa mọ́ sí sílẹ̀ láti lè yẹra fún àkúrun. Ṣé àwọn hóró irúgbìn tí wọ́n ń kó pa mọ́ yìí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ìràn ọjọ́ iwájú láti ní oríṣiríṣi èso irúgbìn ní ànító àti àníṣẹ́kù fún gbígbìn kí wọ́n sì kórè wọn?

Fífi Àwọn Hóró Irúgbìn Pa Mọ́—Ṣé Òun Ni Kò Ní Jẹ́ Kí Wọ́n Kú Àkúrun?

Ọgbà Ìmọ̀ Nípa Ewéko ti Ìjọba èyí tó wà ní Kew, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ti bẹ̀rẹ̀ ohun kan tó kan sáárá sí pé ó jẹ́ “ètò fún ìdáàbòbò tó kàmàmà jù lọ tí ẹnikẹ́ni kò tíì ṣe irú rẹ̀ rí lágbàáyé,” ìyẹn Ètò Fífi Hóró Irúgbìn Pa Mọ́ ti Ẹgbẹ̀rúndún Yìí. Àwọn lájorí ìdí tí wọ́n fi dá ètò yìí sílẹ̀ ni (1) láti kó ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún irú ọ̀wọ́ hóró irúgbìn tó wà lágbàáyé jọ, ìyẹn ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún [24,000] nígbà tó bá fi máa di ọdún 2010 àti (2) kó tó di ìgbà yẹn, kí wọ́n ti ṣa gbogbo àwọn irúgbìn oníhóró tó jẹ́ ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì jọ kí wọ́n sì ti tọ́jú wọn pa mọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn náà ti ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró irúgbìn pa mọ́ sí tàbí àwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú àbùdá sí, bí wọ́n ṣe máa ń pè wọ́n nígbà mìíràn.

John Tuxill, onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé ó kéré tán, ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn hóró irúgbìn tí wọ́n kó pa mọ́ ló wúlò fún jíjẹ àti fún nǹkan mìíràn, àwọn bí àlìkámà, ìrẹsì, ọkà, sorghum, ànàmọ́, àlùbọ́sà, aáyù, ìrèké, òwú, sóyà, àtàwọn ẹ̀wà míì lóríṣiríṣi, ka kàn mẹ́nu kan díẹ̀. Àmọ́ ohun ẹlẹ́mìí làwọn irúgbìn, bí okun inú wọn bá sì ti tán wọn ò wúlò mọ́ nìyẹn. Torí náà, báwo la ṣe lè gbára lé àwọn hóró irúgbìn tí wọ́n kó pa mọ́ tó?

Àwọn Ìṣòro Níbi Tí Wọ́n Kó Wọn Pa Mọ́ Sí

Owó tabua ni wọ́n ń ná sí àwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró irúgbìn pa mọ́ sí o. Gẹ́gẹ́ bí Tuxill ṣe sọ, àròpọ̀ iye tó ń gbà lọ́dún kan ń lọ sí ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù dọ́là. Àmọ́ o, iye yìí gan-an tiẹ̀ lè máà tó, nítorí ó sọ pé “kìkì ìpín mẹ́tàlá péré nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn hóró irúgbìn tí wọ́n fi àbùdá wọn pa mọ́ yìí ló wà níbi tí wọ́n ti ń rí àbójútó tó dára tí ó lè mú ẹ̀mí wọn gùn.” Nítorí pé àwọn hóró tí wọn ò bá fi pa mọ́ dáadáa kì í tọ́jọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gbìn wọ́n ní kíákíá kí wọ́n lè rí irè mìíràn kó lára wọn; láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ibi tí wọ́n kó wọn pa mọ́ sí yìí ni wọ́n máa bà jẹ́ sí. Dájúdájú, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣìṣẹ́ àti ọ̀pọ̀ jaburata owó, ìyẹn á sì tún wá dá kún wàhálà àìsí owó láti fi ṣàtúnṣe àwọn ibi tí ń fẹ́ àbójútó yìí.

Ìwé Seeds of Change—The Living Treasure ṣàlàyé pé Ibi Ìwádìí fún Fífi Hóró Pa Mọ́ ti Ìjọba Nílùú Colorado, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti “dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, bíi kí iná mànàmáná máa ṣe ségesège, àwọn ẹ̀rọ amú-nǹkan-tutù tó ti daṣẹ́ sílẹ̀, àti àìtó òṣìṣẹ́ tó mú kí òbítíbitì hóró irúgbìn kàn wà nílẹ̀ ṣáá láìní àmì tí wọ́n lè fi dá wọn mọ̀.” Bẹ́ẹ̀ sì làwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró pa mọ́ sí yìí kò bọ́ lọ́wọ́ rúkèrúdò òṣèlú, ọrọ̀ ajé tó lè dojú dé, àti ìjábá àìròtẹ́lẹ̀.

Kíkó wọn pa mọ́ fún ìgbà pípẹ́ tún láwọn ìṣòro mìíràn tó ń dá sílẹ̀. Nínú oko, àwọn irúgbìn yìí ní ọ̀nà tí wọ́n fi ń mú ara wọn bá ipò èyíkéyìí mu bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn náà níbi tó mọ, èyí sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ àrùn àtàwọn wàhálà mìíràn. Àmọ́ níbi tí wọ́n lọ kó wọn pa mọ́ sí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n pàdánù díẹ̀ lára agbára yìí bí ìgbà ṣe ń lọ lórí wọn. Síbẹ̀, àwọn hóró irúgbìn tí wọ́n bá tọ́jú dáadáa lè wà fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kó tó di pé yóò nílò pé kí wọ́n tún wọn gbìn. Láìka àwọn ìdíwọ́ àti àìsí ìdálójú yìí sí, dídá tí wọ́n dá àwọn ibi tí wọ́n ń kó hóró irúgbìn pa mọ́ sí sílẹ̀ fi hàn pé ńṣe ni àníyàn nípa bí ọmọ aráyé ṣe máa rí oúnjẹ jẹ lọ́jọ́ iwájú túbọ̀ ń ròkè si.

Lóòótọ́, ọ̀nà tó dára jù lọ láti dín àkúrun kù ni pé ká dáàbò bo àwọn irúgbìn yìí nínú igbó ká sì padà sí àṣà gbígbin onírúurú irè oko. Ṣùgbọ́n kí ìyẹn tó lè di ṣíṣe, Tuxill sọ pé a gbọ́dọ̀ “kọ́ láti ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa àwọn ohun tí ènìyàn nílò àti ti àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn nínú ayé.” Síbẹ̀, báwo ni ọkàn ṣe lè balẹ̀ pé àwọn èèyàn á “kọ́ láti ní èrò tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì” ní ti bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn tó wà láyé nígbà tí wọn ò yé fi taratara lépa ìtẹ̀síwájú iléeṣẹ́ àti ọrọ̀ ajé? Iṣẹ́ àgbẹ̀ pàápàá, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ti wá di èyí tí wọ́n ti mú wọnú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga, ó sì ti di òwò ńlá lọ́jà àgbáyé. Ìdáhùn tó yàtọ̀ gbọ́dọ̀ wà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awuyewuye ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí àkóbá tó ṣeé ṣe kí àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti yí àbùdá wọn padà ṣe fún ìlera èèyàn àti ti ẹranko àti àyíká. Dída àbùdá àwọn ohun alààyè kan pọ̀ mọ́ ti àwọn mìíràn tí wọn ò fi ibì kankan jọra ti mú káwọn kan gbé ìbéèrè dìde lórí ohun tó bójú mu àtohun tí kò bójú mu.—Wo Jí!, April 22, 2000, ojú ìwé 25 sí 27 (Gẹ̀ẹ́sì).

b Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé ewébẹ̀ ilẹ̀ Yúróòpù kan báyìí, “tí wọ́n yí àbùdá rẹ̀ padà pé kí oríṣi oògùn apakoríko kan má lè nípa lórí rẹ̀ ló ti ṣèèṣì ní àbùdá mìíràn tí kò ní jẹ́ kí oògùn mìíràn ràn án.” Àbùdá ọ̀tọ̀ náà ráyè wọnú ewébẹ̀ yìí nígbà tí èso irú ewébẹ̀ yẹn tí wọ́n yí àbùdá rẹ̀ padà fún ète mìíràn ṣèèṣì fọ́n sára tàkọ́kọ́. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ti wá ń bẹ̀rù pé, bí wọ́n ṣe ń lo àwọn oògùn apakoríko yàlàyàlà fún àwọn irè oko lè mú àwọn èpò tó ya bóorán jáde, tí oògùn náà kò sì ní lè tu irun kan lára wọn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé Iṣẹ́ Àgbẹ̀—‘Ń Pa Run’ Ni?

Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Láti ọdún 1950 ni iye àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ti ń dín kù gidi gan-an láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú, iye tí wọ́n sì fi dín kù láwọn ibì kan ju ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lọ.” Fún àpẹẹrẹ, àwọn àgbẹ̀ tó wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kò tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀. Kí ló mú káwọn àgbẹ̀ máa ṣí kúrò nílẹ̀ náà?

Olórí ohun tó fà á ni owó tí kò tówó mọ́ tó ń wọlé fún wọn, gbèsè gọbọi, ipò òṣì tó túbọ̀ ń burú sí i, àti iṣẹ́ àgbẹ̀ àfẹ̀rọṣe tó gbòde kan. Lọ́dún 1910, iye tó jọjú ló ń kan àgbẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nínú gbogbo owó táwọn èèyàn bá ná sórí oúnjẹ, àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 1997, ìpín tó ń kàn wọ́n ti dín kù jọjọ. Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Kìkì iye táṣẹ́rẹ́ báyìí ni tàwọn àgbẹ̀ nínú iye owó búrẹ́dì kan tí ẹnì kan bá rà.” Èyí túmọ̀ sí pé iye owó kan náà táwọn oníbàárà ń san fún ọ̀rá ìdibúrẹ́dì ni àgbẹ̀ ń rí gbà lórí àlìkámà rẹ̀. Ọ̀ràn tàwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló tiẹ̀ wá burú jù. Àgbẹ̀ kan tó ń gbé ní Ọsirélíà tàbí Yúróòpù lè rówó yá ní báńkì láti fi dí gbèsè tó bá jẹ lọ́dún kan; ṣùgbọ́n fún àwọn àgbẹ̀ tó ń gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ó lè máà ṣeé ṣe. Ó tiẹ̀ lè máà gbérí mọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

“Àṣà gbígbin oríṣi irè oko kan ṣoṣo tí wọ́n dá sílẹ̀ látìgbà ‘Ètò Kébimápàlú’ ti ní ipa tí kò dára lórí níní irè oko ní oríṣiríṣi ẹ̀yà ó sì ti ṣàkóbá fún mímú kí oúnjẹ wà káàkiri àgbáyé.”—Ọ̀mọ̀wé Mae-Wan Ho

[Àwọn Credit Line]

Àwòrán ojú ewé 7: Ẹ̀ka Tó Ń Mójú Tó Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà

Centro Internacional de Mejoramiento de Maíz y Trigo (CIMMYT)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ibi Ìfihóró-Irúgbìn-Pa-Mọ́ Ti Ẹgbẹ̀rúndún Yìí, Nílẹ̀ẹ Gẹ̀ẹ́sì, ń fi àwọn hóró irúgbìn tó ṣe pàtàkì pa mọ́

[Credit Line]

© Àwọn Alábòójútó Ọgbà Ìmọ̀ Nípa Ewéko ti Ìjọba, ní Kew

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́