Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ni Mo Lè Ṣe Láti Túbọ̀ Lẹ́wà Sí I?
“Ara mi kì í balẹ̀ nígbà tí mo bá ń bá àwọn ọmọbìnrin sọ̀rọ̀. Mi ò mọ ohun tí wọ́n ń rò nípa mi, mi ò mọ bí ọ̀rọ̀ mi ṣe ń rí létí wọn tàbí ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan.”—Tyler.
KÍ LÀWỌN ànímọ́ tí àwọn ọmọbìnrin máa ń fẹ́ràn jù lọ lára àwọn ọmọkùnrin? Ọ̀dọ́langba kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Emily sọ pé: “Dídára-ẹni-lójú.” Ọ̀dọ́ mìíràn tó ń jẹ́ Robyn sọ pé jíjẹ́ ẹni tó lè dẹ́rìn-ín pani ló máa ń wu òun jù lára àwọn ọmọkùnrin. Kí sì làwọn ohun tó máa ń fa àwọn ọmọkùnrin mọ́ra jù lọ lára àwọn ọmọbìnrin? Kò yani lẹ́nu pé, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti fi hàn, ẹwà ni ohun àkọ́kọ́ táwọn ọmọkùnrin máa ń wò lára ọmọbìnrin. Ipò kẹfà ni wọ́n fi níní èrò tó bára mu nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé sí.
Àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn ìwádìí tó dá lórí àjọṣe àárín ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin pọ̀ lọ jàra nínú àwọn ìwé ìròyìn tó wà fún àwọn ọ̀dọ́. Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba máa ń ronú gan-an nípa ojú tí ẹ̀yà kejì fi ń wò wọ́n, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa dààmú pàápàá nítorí èyí. Bóyá ó máa ń ṣe ìwọ alára bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Kì í kúkú ṣe pé o ti múra tán láti ṣègbéyàwó láìpẹ́. Àmọ́, ohun tó máa ń fà á ni pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n máa fojú òbùrẹ́wà wo òun tàbí kí wọ́n má gba tòun! Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Tyler sọ pé: “Nígbà tó o bá wà lọ́dọ̀ọ́, wàá fẹ́ kí gbogbo èèyàn gba tìẹ. Wàá fẹ́ bẹ́gbẹ́ mu, káwọn ojúgbà rẹ lọ́kùnrin lóbìnrin lè tẹ́wọ́ gbà ọ́.” Bákan náà, o lè máa rò pé lọ́jọ́ kan ṣá, wàá fẹ́ wá ẹni yíyẹ kan tí wàá bá ṣègbéyàwó. Bó bá di àsìkò yẹn, kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ kí onítọ̀hún gba tìẹ.
Bó ti wù kó rí, níwọ̀n bó o ti jẹ́ Kristẹni ọ̀dọ́, o lè máà tíì fi bẹ́ẹ̀ mọ béèyàn ṣe ń bá ẹ̀yà kejì kẹ́gbẹ́ pọ̀. Síwájú sí i, bí àwọn ojúgbà rẹ ṣe ń tẹnu mọ́ ọ̀ràn ẹwà tún lè máa nípa lórí rẹ. Bó o bá ń rí àwòrán àwọn òrékelẹ́wà tí wọ́n ń polówó ẹwà, àtàwọn òṣèré lọ́kùnrin tí wọ́n síngbọnlẹ̀ nínú tẹlifíṣọ̀n àtàwọn ìwé ìròyìn, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe ni wàá ro ara rẹ pin pé o ò tẹ́gbẹ́! Kí wá lohun tó o lè ṣe nígbà náà kó o lè jẹ́ ẹni tó fani mọ́ra lójú àwọn ẹlòmíràn—títí kan àwọn ẹ̀yà kejì, lọ́nà tó ń gbéni ró, tó sì fi ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn?
Kò Bọ́gbọ́n Mu Láti Máa Rò Pé O Ò Lè “Lábùkù” Kankan Lára
William S. Pollack, ẹni tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú, ṣàkíyèsí pé àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣagbátẹrù eré ìnàjú ló máa ń jẹ́ kí àìmọye ọ̀dọ́ lọ máa “lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí ṣíṣọ́ oúnjẹ jẹ, gbígbé irin wíwúwo, àti ṣíṣe àwọn eré ìmárale lóríṣiríṣi, torí àtilè yí ìrísí wọn padà.” Ńṣe làwọn kan tiẹ̀ máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu, tí wọ́n á máa dìídì febi pa ara wọn, torí kí wọ́n bàa lè ní ara tí kò “lábùkù” tí wọ́n máa ń polówó rẹ̀. Síbẹ̀, ìsọfúnni kan láti Ibùdó Tó Ń Ṣèwádìí Lórí Àwọn Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwùjọ sọ pé: “Iye àwọn obìnrin tó lè jẹ́ òrékelẹ́wà níbàámu pẹ̀lú bí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ṣe ń kéde fáráyé kò tó ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún—ìwọ̀nba yẹn gan-an sì tún sinmi lé bí wọ́n ṣe pẹ́lẹ́ńgẹ́ sí àti bí wọ́n ṣe ga sí. Bó bá jẹ́ pé ìdúró, ẹwà ojú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni ẹnì kan fẹ́ wò ní, gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n máa ń polówó rẹ̀, kìkì ìdá kan ṣoṣo nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ló lè rọ́wọ́ mú.”
Ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà ní Róòmù 12:2 bá a mu wẹ́kú: “Má ṣe jẹ́ kí ayé tó yí ẹ ká mú ẹ bá bátánì rẹ̀ mu.” (Phillips) Bó ti wù kó rí, èyí ò wá túmọ̀ sí pé kó o máà wá bìkítà rárá nípa ìrísí rẹ o. Kò sóhun tó burú nínú pé kó o máa mójú tó ara rẹ nípa ṣíṣe eré ìmárale níwọ̀nba, àti nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ aṣaralóore, tí èròjà rẹ̀ pé. (Róòmù 12:1; 1 Tímótì 4:8) Bó o bá ń fúnra rẹ ní ìsinmi dáadáa, tó o sì ń sùn dáadáa, èyí á mú kí ojú rẹ gún régé, kí ara rẹ sì dá ṣáṣá dé ìwọ̀n tó lè ṣeé ṣe dé. Lọ́wọ́ kan náà, jẹ́ onímọ̀ọ́tótó, kó o sì máa múra lọ́nà tó bójú mu. Ọ̀dọ́langba kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó ń jẹ́ David sọ pé: “Ọmọbìnrin kan wà tí ojú rẹ̀ fani mọ́ra, àmọ́ òórùn ara rẹ̀ kò bára dé rárá. Èyí mú káwọn èèyàn máa pa á tì.” Nítorí náà, máa wẹ̀ déédéé. Ọwọ́, irun, àti èékánná ọwọ́ tó mọ́ yóò jẹ́ kí ìrísí rẹ túbọ̀ fani mọ́ra.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì rọ̀ wá láti má ṣe sọ aṣọ wíwọ̀ di bàbàrà, ó gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn láti “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara [wa] lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.” (1 Tímótì 2:9) Máa wọ àwọn aṣọ tó máa gbé ìrísí rẹ yọ, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe ti aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ tàbí èyí tí kò bójú mu.a Jíjẹ́ kí ìrísí rẹ fani mọ́ra lè jẹ́ kó o túbọ̀ dá ara rẹ lójú. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Paul sọ ọ́ báyìí pé: “Ó lè máà jẹ́ pé ìwọ lo lẹ́wà jù lọ lágbàáyé, àmọ́ o lè túbọ̀ mú kí ìwọ̀nba ẹwà tó o ní yọ.”
Àwọn Ànímọ́ Téèyàn Ní
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú tó fani mọ́ra àti ìrísí tó dára lè jẹ́ káwọn èèyàn máa fẹ́ láti sún mọ́ wa, bópẹ́ bóyá “ẹwà máa ń yára pa rẹ́.” (Òwe 31:30, Byington) Ẹwà ojú kì í wà fún ìgbà pípẹ́, ó sì dájú pé a ò lè fi rọ́pò àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí a ní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Òwe 11:22) Tún rántí pé, “ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nítorí náà, dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa bó o ṣe pẹ́lẹ́ńgẹ́ sí tàbí sanra sí, tàbí bó o ṣe síngbọnlẹ̀ sí, ńṣe ló yẹ kó o sapá láti ní àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì, irú bíi jíjẹ́ “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 3:3, 4; Éfésù 4:24) Lóòótọ́ o, nínú ayé tá à ń gbé lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò bìkítà nípa àwọn ìwà ọmọlúwàbí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ àwọn ànímọ́ tẹ̀mí.b Àmọ́ àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run mọyì rẹ̀, ó sì máa ń wú wọn lórí!
Nígbà náà, ọ̀nà tó dára jù lọ láti jẹ́ ẹni tó lẹ́wà lójú àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí lọ́kùnrin lóbìnrin ni pé kí ìwọ náà jẹ́ ẹni tẹ̀mí fúnra rẹ. Máa tẹ̀ síwájú láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí nípa gbígbàdúrà, ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. (Sáàmù 1:1-3) Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ànímọ́ àti ìwà bíbójúmu mìíràn wà tó o lè ní. Kò dìgbà tó o bá lọ ń dájọ́ àjọròde pẹ̀lú ẹnì kan tàbí tó o lọ ń jẹ́ kí ìfẹ́ ẹnì kan kó sí ọ lórí kó o tó lè ní àwọn ànímọ́ wọ̀nyí. Kàkà bẹ́ẹ̀, o lè máa fi wọ́n dánra wò ní gbogbo ìgbà tó o bá ń bá àwọn ẹlòmíràn lò lójoojúmọ́.
Bí àpẹẹrẹ, ṣé ojú máa ń tì ọ́ tàbí ńṣe ni ara rẹ máa ń kó ṣìọ̀ nígbà tó o bá wà ní sàkáání ẹ̀yà kejì? Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Paul sọ pé: “Ara mi kì í balẹ̀ nígbà míì—torí pé wọ́n jẹ́ obìnrin, mi ò sì lóye àwọn obìnrin bí mo ṣe lóye àwọn ọkùnrin bíi tèmi. Mi ò sì fẹ́ dójú ti ara mi.” Báwo lo ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn kó o sì tún ní ìdára-ẹni-lójú lọ́nà tí ara á fi tu àwọn ẹlòmíràn? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o jàǹfààní látinú kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú onírúurú àwọn èèyàn tó wà nínú ìjọ Kristẹni. Nínú ìpàdé, máa fi hàn pé o bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan—kì í ṣe àwọn ẹ̀yà kejì tí wọ́n jẹ́ ojúgbà rẹ nìkan, àmọ́ èyí tún kan àwọn ọmọdé, àgbàlagbà, àtàwọn arúgbó. (Fílípì 2:4) Kíkọ́ láti bá onírúurú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lò lọ́nà tó bójú mu yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó dá ara rẹ̀ lójú.
Àmọ́ ṣọ́ra o. Jésù sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 19:19) Bó o bá dá ara rẹ lójú, o ò ní máa lọ́ra tàbí tijú tó o bá wà nítòsí àwọn ẹlòmíràn.c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó yẹ kéèyàn ní ọ̀wọ̀ ara ẹni dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ máà wá di aláṣejù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3.
Wá ṣàyẹ̀wò ìwà tìẹ náà fúnra rẹ àti ọ̀nà tó ò ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn lò. Ọmọbìnrin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tó ń jẹ́ Lydia sọ pé: “Ọmọkùnrin kan wà ní ilé ẹ̀kọ́ mi tó gbayì gan an lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin púpọ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mọ irú ẹni tó jẹ́, wọn kì í fẹ́ràn rẹ̀ mọ́, torí pé ó máa ń fi ìwọ̀sí lọni, ó sì máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà.” Àwọn èèyàn máa ń sún mọ́ ẹni tó bá ń sọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí, ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n, tó sì máa ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò. (Éfésù 4:29, 32; 5:3, 4) Dókítà T. Berry Brazelton ṣàkíyèsí pé: “Ńṣe ni híhùwà ọmọlúwàbí dà bíi kọ́kọ́rọ́ kan, èyí tó ń fún àwọn èèyàn lómìnira fàlàlà láti dé ọ̀dọ̀ ẹnì kan.” Ó tún sọ pé ìwà ọmọlúwàbí “ṣe kókó béèyàn bá fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn tẹ́wọ́ gba òun.”
Àwọn ìlànà àti àṣà àdúgbò kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra kárí ayé. Nítorí náà, máa kíyè sí bí àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú lọ́kùnrin lóbìnrin ṣe máa ń bá ara wọn lò. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ àṣà orílẹ̀-èdè yín ni pé kí ọkùnrin máa ṣílẹ̀kùn fún obìnrin? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣíṣe èyí yóò túbọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn lè mọ̀ ọ́ sí ẹni tó mọ̀wàá hù.
Níkẹyìn, á dáa tó o bá lè gbìyànjú láti máa dẹ́rìn-ín pani ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì sọ pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín” wà, ẹni tó bá sì máa ń dápàárá máa ń tètè ní ọ̀rẹ́.—Oníwàásù 3:1, 4.
Bíbánidọ́rẹ̀ẹ́ Yàtọ̀ sí Bíbánidọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀
Ìwé kan tí àwọn tó ṣe é pè ní “ìtọ́sọ́nà lórí dídájọ́ àjọròde pẹ̀lú àṣeyọrí” sọ pé ọ̀nà tí ẹnì kan fi lè jẹ́ kí ẹ̀yà kejì gba tòun ni nípa bíbá a dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀. Ìwé náà rọ àwọn òǹkàwé láti máa fi ẹ̀rín músẹ́ àti fífi ojú báni sọ̀rọ̀ dánra wò, kí wọ́n sì jẹ́ kí ‘ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa kọ́kọ́ sọ’ dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in. Irú ìdámọ̀ràn yẹn lòdì sí kókó tó wà nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, ìyẹn ni pé kó máa bá àwọn ẹ̀yà kejì lò “pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”—1 Tímótì 5:2.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, bíbánidọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ lè jẹ́ kí ẹnì kan máa rò pé òun fọmọ yọ, àmọ́ ó jẹ́ ìwà àìṣòótọ́ àti ìwà àgàbàgebè. Kò dìgbà tó o bá ń dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tàbí tó o bá ń díbọ́n pé ò ń yẹ́ ẹ sí kó o tó lè bá a fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà tó lárinrin. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì pọn dandan pé kó o máa béèrè àwọn ìbéèrè tó ń dójú tini tàbí tí kò ṣeé gbọ́ sétí kó o tó lè mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn ẹ̀yà kejì tàbí ohun tí wọ́n ń rò. Sọ ọ́ di àṣà rẹ láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó jẹ́ ‘òdodo, tó mọ́ níwà, tó sì dára ní fífẹ́,’ wàá lè tipa báyìí fi hàn pé lóòótọ́ lo ti ń di ọkùnrin tàbí obìnrin tó dàgbà dénú, ẹni tí àwọn ohun tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn. (Fílípì 4:8) Kì í ṣe lójú ẹ̀yà kejì nìkan ni ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà Ọlọ́run yóò ti sọ ọ́ di ẹlẹ́wà, wàá tún lẹ́wà lójú Ọlọ́run fúnra rẹ̀.d—Òwe 1:7-9.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo “Awọn Ọ̀dọ́ Beere Pe . . . Kinni Àṣírí Yíyàn Awọn Aṣọ Títọ́?” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde Jí! April 8, 1990.
b Gẹ́gẹ́ bí ohun tí olùwádìí kan sọ, ìwádìí fi hàn pé wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọ̀dọ́ tó mọ̀wé ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ìmọ̀ tí wọ́n ní. Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn á wá tìtorí èyí máa fojú kéré ọgbọ́n orí wọn.
c Àwọn ìdámọ̀ràn lóríṣiríṣi nípa ọ̀nà téèyàn lè gbà ní ọ̀wọ̀ ara ẹni ni a ṣàlàyé ní àkòrí 12 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
d Bó o bá kéré jù láti ṣègbéyàwó, ibi tí oríṣiríṣi èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin bá wà, ló bọ́gbọ́n mu kó o ti máa bá ẹ̀yà kejì kẹ́gbẹ́ pọ̀. Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Bí Àwọn Òbí Mi Bá Sọ Pé Mi Ò Tíì Tẹ́ni Ń Dájọ́ Àjọròde Ńkọ́?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! ti February 8, 2001.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá lórí bí ìrísí rẹ ṣe rí, sapá láti ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mọ bó o ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà tó o bá ń bá onírúurú èèyàn lò