ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 3/8 ojú ìwé 26-27
  • Ìbẹ̀wò Mánigbàgbé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀wò Mánigbàgbé Kan
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹ̀ Ò Gba Ẹsẹ̀
  • Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn Ni Wọ́n Ra Ilé Iṣẹ́ Àkọ́kọ́
    Jí!—2001
  • Aráàlú Ṣèbẹ̀wò Tó Mórí Wọn Wú
    Jí!—2003
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Pe Tonílé Tàlejò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Sísìn Tọkàntọkàn Lójú Onírúurú Àdánwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Jí!—2004
g04 3/8 ojú ìwé 26-27

Ìbẹ̀wò Mánigbàgbé Kan

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ

NÍ March 15, 2003, ó lé ní ogójì orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti wá, tí wọ́n sì péjọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nítòsí Ìlú Mẹ́síkò láti ṣayẹyẹ ìyàsímímọ́ ilé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ tó wà lójú ìwé yìí. Ilé gbígbé àti ilé ìtẹ̀wé yìí wà lára ìmúgbòòrò tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mẹ́síkò.

Lọ́dún 1974, nígbà tó jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́ta [65,000] àwọn Ẹlẹ́rìí ló ṣì wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, la ṣe ìyàsímímọ́ àwọn ilé tá a kọ́kọ́ kọ́ sórí ilẹ̀ kan náà yìí. Nítorí pé ńṣe ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ń pọ̀ sí i ṣáá, a ya àwọn ilé mìíràn sí mímọ́ lọ́dún 1985 àti lọ́dún 1989. Lára àwọn ilé tó ju méjìlá lọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ kún àwọn tó ti wà tẹ́lẹ̀ ni ilé ìtẹ̀wé gbàràmù kan àti ilé gbígbé tó lè gba àwọn òṣìṣẹ́ tó tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300].

Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tá a ya ilé náà sí mímọ́ tán, a ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà sílẹ̀ gbayawu fún àwọn aládùúgbò tó wà nítòsí ẹ̀ka náà láti wá wò ó. Lára àwọn tá a fìwé pè ni àwọn aláṣẹ tó wà ládùúgbò yẹn, àwọn ọmọ iléèwé àtàwọn olùkọ́ tó wà ní yunifásítì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tó wà lódìkejì ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ló ń ṣe kàyéfì nípa iye àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kó wá.

Ibẹ̀ Ò Gba Ẹsẹ̀

Iye àwọn èèyàn tó jẹ́ ọ̀rìnlérúgba ó dín mẹ́jọ [272] ló wá, títí kan àwọn ọmọ iléèwé, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn aláṣẹ ìjọba ìbílẹ̀. Àwọn olùṣèbẹ̀wò náà sọ̀rọ̀ lórí bí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ yìí ṣe lẹ́wà, tó sì mọ́ tónítóní, wọ́n sì tún fi ìmoore wọn hàn fún bí wọ́n ṣe ṣe wọ́n lálejò. Obìnrin kan kọ ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí sínú ìwé mo-bá-ọ-yọ̀ tá a ṣí sílẹ̀ fáwọn àlejò, ó ní: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí màá ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ yìí. Àwọn ohun tí mo rí gbádùn mọ́ni gan-an. Látilẹ̀ wá ni mo ti gba tiyín, tí mo sì máa ń bọ̀wọ̀ fún yin, àmọ́ ní báyìí o, màá túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ sí i.”

Ọkùnrin mìíràn sọ pé: “Ọ̀tọ̀ ni ohun tá a rò pé ẹ̀ ń ṣe níbí tẹ́lẹ̀. Oríṣiríṣi àhesọ là ń gbọ́ nípa yín. . . . Ṣùgbọ́n ní báyìí mo ti wá rí i pé irọ́ pátápátá gbáà ni. Inú mi yóò dùn láti gbà yín sílé, nítorí mo gbà pé ohun tó ní láárí lẹ̀ ń ṣe.”

Obìnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ ní yunifásítì, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí, kó gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì méjì wá láti ṣèbẹ̀wò. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ káwọn ọ̀dọ́ mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n á rí kọ́ látàrí ìbẹ̀wò wọn síbí.” Báwo ni ìbẹ̀wò yìí ṣe nípa lórí àwọn ọmọ iléèwé náà?

Ọmọbìnrin kan kọ̀wé pé: “Ẹ ṣeun, ẹ kú àlejò wa o. Èmi àtàwọn ọmọ kíláàsì mi ò lè gbà gbé ọjọ́ yẹn láé.” Ọmọbìnrin mìíràn sọ pé àwọn èèyàn tí kì í fetí sílẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá wá sọ́dọ̀ wọn kò mọ ohunkóhun nípa irú ẹni tí àwọn Ẹlẹ́rìí jẹ́ gan-an. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó rí ara gba nǹkan sí, ká fẹ́ láti máa gbọ́ ohun táwọn mìíràn bá fẹ́ sọ, ká sì tún máa gbé èrò wọn yẹ̀ wò.” Ọ̀dọ́kùnrin kan tó wà ládùúgbò yẹn sọ pé: “Èrò tí mo ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí yàtọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ti wá rí i pé ẹ máa ń bá ara yín fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ńṣe lẹ̀ ń rọ́ wìtìwìtì bí èèrùn, ọwọ́ yín dí gan-an ni.”

Àwọn mẹ́rin lára àwọn ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò yẹn wà lára àwọn tó ṣèbẹ̀wò. Obìnrin kan lára wọn sọ pé: “Èyí mà wúni lórí o. Kò sí ojúsàájú níbí. Kò sí ọ̀gá nínú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìmọ́tótó, àtàwọn tó ń géko. . . . Ohun ìyàlẹ́nu gbáà lèyí jẹ́.”

Àwọn ọmọkùnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án àti ọdún mẹ́wàá, tí wọ́n ń gbé ládùúgbò yẹn sọ pé: “Èyí ti lọ wà jù, ó mà ga o.” “Ohun tí mo fẹ́ràn jù lọ ni àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyẹn. Wọ́n yára gan-an. Pàápàá jù lọ, àwọn ẹ̀rọ tó ń gé ìwé.”

Dókítà kan tó ń tọ́jú àwọn tó bá fara pa gan-an, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì wà lára àwọn tó wá. Nígbà tí wọ́n ń fi gbogbo àyíká hàn wọ́n, ìyàwó dókítà náà béèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè nínú Bíbélì. Ó sọ pé àtìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí ti máa ń wá sọ́dọ̀ bàbá òun tó ń ṣe ẹ̀sìn ajíhìnrere lòun ti nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí inú bá ń bí bàbá òun, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí yẹn máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ó sọ pé: “Ìsinsìnyí ni mo wá mọ ohun tó mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”

Dókítà náà àti ìyàwó rẹ̀ sọ pé ìbẹ̀wò táwọn ṣe yẹn ti yí èrò táwọn ní tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí padà. José tó ń fi àyíká hàn wọ́n rí i pé wọ́n fìfẹ́ hàn, ó pè wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, ó sì tún sọ pé òun yóò kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n fara mọ́ ohun tí José sọ, wọ́n sì sọ pé inú àwọn yóò dùn láti máa wá sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́.

Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, wọ́n wá, inú José àti Beatriz tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ dùn láti gbà wọ́n sí yàrá wọn. Dókítà náà àti ìyàwó rẹ̀ béèrè ìbéèrè tó pọ̀ débi pé ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ yẹn gbà wọ́n tó wákàtí mẹ́tà àtààbọ̀! Ìdílé náà àti bàbá ìyàwó dókítà náà wá sí Ìṣe Ìrántí ní April 16—bẹ́ẹ̀ ni o, ìyẹn bàbá tí inú máa ń bí táwọn Ẹlẹ́rìí bá ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ohun pàtàkì tó múnú ẹni dùn jù lọ ni ti iye ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn olùṣèbẹ̀wò náà gbà lọ sílé wọn—gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500], èyí tó sì pọ̀ jù nínú rẹ̀ ló jẹ́ Bíbélì. Àwọn kan nínú wọn sọ pé àwọn ò ní Bíbélì tẹ́lẹ̀.

Obìnrin kan tó ń gbé nítòsí sọ fún Armando tó ń bójú tó àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé: “Láti òní lọ, màá máa wá sí àwọn ìpàdé yín, nítorí mo ti wá mọ̀ pé òtítọ́ nìyí.” Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó tẹ̀ lé e, inú Armando dùn nígbà tó rí obìnrin yìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó sọ pé: “Obìnrin yìí mú ìwé tó gbà nígbà tó ṣèbẹ̀wò dání. Nígbà tí mo kí i, ó sọ fún mi pé: ‘Wò ó, mo ti ń ṣe ohun tí mo sọ fún ọ pé mà á ṣe.’”

Kíá lọjọ́ mẹ́ta táwọn èèyàn fi ṣèbẹ̀wò náà yára kọjá lọ. Ṣùgbọ́n àwọn ọjọ́ náà gbéni ró gan-an. Gbígbọ́ táwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà gbọ́ ohun táwọn tó ń ṣèbẹ̀wò fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ nípa ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọrírì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní láti sìn ní ọ̀kan lára ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

1. Ilé tí wọ́n ti ń tún ọkọ̀ ṣe, 2. ilé tí wọ́n tí ń ṣe onírúurú iṣẹ́, 3. ilé tí wọ́n ti ń tún àwọn ohun èlò ṣe, 4. ilé gbígbé, 5. ilé ìtẹ̀wé, 6. gbọ̀ngàn àpéjọ, 7. ilé àwọn àlejò

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́, títí kan àwọn ọmọ iléèwé àtàwọn ọlọ́pàá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́