Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan!
Kí ni orúkọ Ọlọ́run? Gbogbo èèyàn pátá ló ní orúkọ. Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ ẹran ọ̀sìn wọn pàápàá lórúkọ! Ṣé kò wá bọ́gbọ́n mu pé kí Ọlọ́run ni orúkọ? Ó dájú pé níní orúkọ tara ẹni àti lílo orúkọ náà ṣe pàtàkì gan-an nínú àjọṣe ẹ̀dá. Ṣé kò wá yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run? Ibi tọ́rọ̀ wá burú sí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó sọ pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tó ni Bíbélì ni wọn kì í lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an. Síbẹ̀, ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ orúkọ Ọlọ́run. Bó o ti ń ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wàá mọ̀ nípa àwọn àkókò kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn lo orúkọ náà. Ní pàtàkì jù lọ, wàá rí ohun tí Bíbélì sọ nípa mímọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́.
NÍGBÀ tó fi máa di ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan nílẹ̀ Yúróòpù ti ń ṣe àwọn owó wẹ́wẹ́ tó ní orúkọ Ọlọ́run jáde. Gàdàgbà gadagba ni orúkọ náà Jèhófà fara hàn lára owó wẹ́wẹ́ ilẹ̀ Jámánì kan tí wọ́n ṣe jáde lọ́dún 1634. Káàkiri ibi gbogbo ni wọ́n wá mọ irú owó bẹ́ẹ̀ sí owó wẹ́wẹ́ Jèhófà, ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n sì fi ṣe é jáde.
Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé Jèhófàa ni orúkọ Ọlọ́run. Lédè Hébérù, tí wọ́n ń kà láti apá ọ̀tún sí apá òsì, orúkọ náà fara hàn gẹ́gẹ́ bíi kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin, ìyẹn ni יהוה. Àwọn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin yìí—tá a yí padà sí YHWH—ni à ń pè ní Tetragrammaton [lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run]. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún làwọn ará Yúróòpù fi tẹ orúkọ Ọlọ́run tá a kọ lọ́nà yìí sára owó wẹ́wẹ́ wọn.
Orúkọ Ọlọ́run tún wà lára àwọn ilé, àwọn ohun ìrántí àtàwọn iṣẹ́ ọnà, bákan náà ló tún wà nínú àwọn ìwé orin tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń lò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Brockhaus lédè Jámánì ṣe sọ, ìgbà kan wà tó jẹ́ àṣà àwọn alákòóso tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì láti máa lo àmì tí wọ́n fi oòrùn àti lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ṣe ọ̀ṣọ́ sí. Àmì yìí, tí wọ́n tún fi sára àsíá àti owó wẹ́wẹ́, ni wọ́n máa ń pè ní àmì ẹ̀yẹ Jèhófà-òun-Oòrùn. Dájúdájú, àwọn olùgbé ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún tí wọn ò fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré mọ̀ pé Ọlọ́run Olódùmarè ní orúkọ kan. Èyí tó ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé ẹ̀rù ò bà wọ́n láti lò ó.
Orúkọ Ọlọ́run kì í ṣohun àjèjì láwọn àgbègbè àdádó tó para pọ̀ di orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tí Ethan Allen, sójà ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tó jẹ́ ajàjàgbara, sọ. Gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀, lọ́dún 1775, ó pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ túúbá “lórúkọ Jèhófà Ẹni Gíga.” Lẹ́yìn náà, nígbà tí Abraham Lincoln fi wà nípò ààrẹ, ọ̀pọ̀ lára àwọn olùgbaninímọ̀ràn rẹ̀ máa ń mẹ́nu kan Jèhófà lemọ́lemọ́ nínú lẹ́tà tí wọ́n ń kọ sí i. Àwọn ìwé ìtàn ilẹ̀ Amẹ́ríkà mìíràn tó ní orúkọ Ọlọ́run nínú wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìlò àwọn aráàlú ní ọ̀pọ̀ ibi ìkówèésí. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ọ̀nà tí wọ́n gbà lo orúkọ Ọlọ́run nílé lóko fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Lọ́jọ́ tòní wá ńkọ́ o? Ṣé orúkọ Ọlọ́run ti dìgbàgbé ni? Ká má ri. Orúkọ náà fara hàn nínú ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìtumọ̀ Bíbélì. Bó o bá dákán lọ síbi ìkówèésí kan tàbí tó o ṣèwádìí fún ìṣẹ́jú díẹ̀ nínú ìwé atúmọ̀ èdè rẹ, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé wọ́n gbà nílé lóko pé orúkọ náà, Jèhófà, jẹ́ ìtumọ̀ tó ṣe rẹ́gí lédè Yorùbá pẹ̀lú lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia International ṣàpèjúwe orúkọ náà Jèhófà, lọ́nà tó ṣe kedere, gẹ́gẹ́ bí “èdè ìgbàlódé fún orúkọ mímọ́ Ọlọ́run lédè Hébérù.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica kan tí wọ́n tẹ̀ jáde lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ṣàlàyé pé Jèhófà ni “orúkọ táwọn ẹlẹ́sìn Júù àtàwọn Kristẹni fi ń pe Ọlọ́run.”
Ṣùgbọ́n, ó lè máa ṣe ọ́ ní kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tiẹ̀ ka orúkọ Ọlọ́run kún mọ́ lóde òní?’ Lọ́nà kan tàbí òmíràn, a ṣì ń rí orúkọ Ọlọ́run níbi tí wọ́n kọ ọ́ sí láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò sí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ orúkọ náà, Jèhófà sára òkúta igun ilé kan nílùú New York. Ní ìlú yìí kan náà, wọ́n tún ti rí orúkọ náà lédè Hébérù nínú àwòrán aláràbarà tí wọ́n yà sára ibùdó ọkọ̀ ojú irin abẹ́ ilẹ̀ kan. Àmọ́ ṣá o, kò sí àsọdùn níbẹ̀ pé lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ti gba àwọn ibi táà ń sọ̀rọ̀ wọn yìí kọjá, ìwọ̀nba làwọn tó ka orúkọ náà sí pàtàkì.
Ṣé orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì lójú àwọn èèyàn lápá ibi tóò ń gbé lórí ilẹ̀ ayé? Àbí “Ọlọ́run” làwọn tó pọ̀ jù lọ mọ Ẹlẹ́dàá sí, bí ẹni pé orúkọ oyè yẹn lorúkọ rẹ̀ gan-an? Ìwọ fúnra rẹ ti lè kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í tiẹ̀ ronú rárá nípa bóyá Ọlọ́run ní orúkọ kan. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ó bá ọ lára mu láti máa fi orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, pè é?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lókè ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀nà mọ́kàndínlógójì la gbà kọ orúkọ náà Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́ ní ohun tó lé ní èdè márùndínlọ́gọ́rùn-ún.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọba Kan Tó Sọ Orúkọ Jèhófà Di Mímọ̀
Lọ́dún 1852, àwùjọ àwọn míṣọ́nnárì kan gbéra láti Hawaii wọ́n sì forí lé àwọn erékùṣù Micronesia. Wọ́n mú lẹ́tà ìfinimọni kan dání, èyí tí òǹtẹ̀ Ọba Kamehameha Kẹta wà lára rẹ̀. Ọba yìí ni ọba alayé tó ń ṣàkóso àwọn Erékùṣù Hawaii nígbà náà lọ́hùn-ún. Apá kan lẹ́tà tí wọ́n fi èdè Hawaii kọ tí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí onírúurú àwọn olùṣàkóso tó wà ní Erékùṣù Pàsífíìkì yìí kà pé: “Àwọn mélòó kan tí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni nípa Jèhófà, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, ti ń múra àtiwá sí erékùṣù yín báyìí o. Kí wọ́n lè fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ yín kẹ́ ẹ lè rí ìgbàlà ayérayé. . . . Mo fọwọ́ sí i pé kẹ́ ẹ ṣàpọ́nlé àwọn olùkọ́ rere wọ̀nyí bó bá ṣe tọ́, kẹ́ ẹ sì mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, mo sì gbà yín níyànjú pé kẹ́ ẹ tẹ́tí sí àwọn ìtọ́ni wọn. . . . Ìmọ̀ràn mi fún yín ni pé kẹ́ ẹ kó àwọn ère yín dà nù, kẹ́ ẹ gba Olúwa Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run yín, kẹ́ ẹ sìn ín, kẹ́ ẹ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ẹ ó sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà, yóò sì gbà yín.”
[Àwòrán]
Ọba Kamehameha Kẹta
[Credit Line]
Hawaii State Archives
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Tetragrammaton, tó túmọ̀ sí “lẹ́tà mẹ́rin,” ló dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù