Bí O Ṣe Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run
LÁTỌWỌ́ òǹkàwé ni akọ̀ròyìn kan ti rí lẹ́tà yìí gbà, èyí tó kà pé: “Ó ti pẹ́ tí ìbéèrè yìí ti ń jà gùdù lọ́kàn mi, mo sì nírètí pé ẹ lè bá mi rí ìdáhùn sí i. Kí ni orúkọ Ọlọ́run? Àwọn Júù sọ pé orúkọ náà ti dìgbàgbé. Àwọn Kristẹni ń pè É ní Jésù. Àwọn Mùsùlùmí sì ń pè É ní Allah. . . . Nítorí náà, kí lorúkọ rẹ̀?” Ìwé ìròyìn yìí gbé ìbéèrè náà sójútáyé ó sì kọ ìdáhùn yìí síbẹ̀: “Gẹ́gẹ́ bí èdè Hébérù ìgbà ìjímìjí ti fi kọ́ni, alágbára gbogbo ni Ọlọ́run, nítorí náà orúkọ kan ṣoṣo ò lè tó o. Àmọ́ ṣá o, mo fẹ́ kó dá ọ lójú pé (yálà Akọ ni o tàbí Abo), yóò dá ọ lóhùn bó o ba fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ forúkọ èyíkéyìí tó o mọ̀ pè é.”
Irú ìwà àìbìkítà bẹ́ẹ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run ò ṣàì wọ́pọ̀ lóde òní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ ni ìsìn ń jẹ lọ́kàn, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́, kí lèrò Ọlọ́run nípa ìyẹn ná? Ṣé ọ̀ràn kékeré ni lójú rẹ̀?
Kì Í Ṣe Ọ̀ràn Kékeré O
Ìwọ ṣáà ronú nípa kókó náà pé Bíbélì mẹ́nu kan orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an, Jèhófà, ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà. Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, orúkọ Ọlọ́run fara hàn nígbà ẹgbẹ̀rìndínlógójì ó lé mẹ́wàá [7,210]!a Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló mí sí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láti lo orúkọ rẹ̀ ní fàlàlà. Ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé yìí, Ásáfù olórin, kọ̀wé pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Dáfídì náà kọ̀wé nínú sáàmù kan pé: “Àwa yóò máa sọ nípa orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa.”—Sáàmù 20:7.
Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run ń yẹ ọkàn wa wò láti mọ ojú tá a fi ń wo orúkọ rẹ̀. Onísáàmù náà sọ pé: “Ká ní àwa gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa ni, . . . Ọlọ́run tìkára rẹ̀ kì yóò ha wá èyí kàn bí? Nítorí pé ó mọ àwọn àṣírí ọkàn-àyà.” (Sáàmù 44:20, 21) Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. Ẹ sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.”—Aísáyà 12:4.
Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wọn yóò . . . ní láti mọ̀ pé orúkọ mi ni Jèhófà.” (Jeremáyà 16:21) Lákòókò mìíràn, ó sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò . . . sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́, èyí tí a ń sọ di aláìmọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, . . . àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 36:23) Díẹ̀ lára àwọn gbólóhùn yìí ń tọ́ka sí ìgbà kan tí Jèhófà yóò fìbínú hàn sí àwọn tí kò bá bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀. Ọ̀ràn nípa orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an kì í ṣe ohun ṣeréṣeré o.
Jèhófà Ọlọ́run Kò Jìnnà sí Ọ
Báwo lo ṣe lè mọ orúkọ Ọlọ́run? Kí ló túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́run? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò . . . gbẹ́kẹ̀ lé ọ.” (Sáàmù 9:10) Ní kedere, ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ orúkọ Ọlọ́run ju wíwulẹ̀ mọ ohun tí orúkọ náà jẹ́ lọ. O gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e. Ìyẹn túmọ̀ sí pé kó o mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́, kó o sì kọ́ nípa àwọn ànímọ́ àti ìrònú rẹ̀. Èyí ni yóò sún ọ láti gbẹ́kẹ̀ lé e.
Fífi tọkàntọkàn ka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìkan ló lè mú kó o túbọ̀ lóye sí i nípa irú Ọlọ́run tí Jèhófà jẹ́. Ó ṣèlérí pé òun á dáàbò bo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn sí òun, tí wọ́n sì tún fìfẹ́ hàn sí orúkọ òun. Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ẹni tó bá firú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn ni pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi. Òun yóò ké pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn. Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú wàhálà. Èmi yóò gbà á sílẹ̀, èmi yóò sì ṣe é lógo. Gígùn ọjọ́ ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi yóò sì jẹ́ kí ó rí ìgbàlà mi.”—Sáàmù 91:14-16.
Àgbàyanu gbáà mà ni àjọṣe tó máa ń wà láàárín Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn tó bá mọ orúkọ rẹ̀ o! Ìwọ náà lè gbádùn irú àjọṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àwọn àdúrà àtọkànwá rẹ, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti máa ké pe orúkọ rẹ̀. Yóò dá ọ lóhùn nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, jẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì kan tó fi àkọtọ́ tó bóde mu rọ́pò àwọn èdè àtijọ́ tó wà nínú àwọn ìtumọ̀ ògbólógbòó. Apá tó fani mọ́ra jù lọ nínú ìtumọ̀ yìí ni dídá tó dá orúkọ Ọlọ́run padà sí àwọn ibi tó yẹ kó wà nínú Bíbélì. Títí di báyìí, a ti tẹ ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù méjìlélọ́gọ́fà jáde ní èdè márùndínláàádọ́ta, lódindi tàbí lápá kan.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọlọ́run Mọ Orúkọ Rẹ
Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èmi fi orúkọ mọ̀ ọ́.” (Ẹ́kísódù 33:12) Àkọsílẹ̀ tá a mọ̀ bí ẹní mowó nípa iná tó ń jó lára igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, fẹ̀rí èyí hàn. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “pè é láti àárín igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà wí pé: ‘Mósè! Mósè!’” (Ẹ́kísódù 3:4) Àpẹẹrẹ kan lásán lèyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí Ọlọ́run forúkọ táwọn èèyàn ń jẹ́ pè wọ́n. Ní kedere, ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run lógún.
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀. (Aísáyà 40:26) Mélòómélòó wá ni àwọn ẹ̀dá èèyàn tí ń jọ́sìn rẹ̀! Ó dájú pé ó bìkítà nípa wọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (2 Tímótì 2:19) Èyí fi hàn pé kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run ń há orúkọ àwọn èèyàn sórí. Ó mọ àwọn olùjọsìn rẹ̀ lámọ̀dunjú. Ó ỵẹ kí àwa náà mọ orúkọ Ọlọ́run ká sì ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀.
Ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe ìwé ìṣàpẹẹrẹ kan nínú èyí tí Ọlọ́run kọ orúkọ gbogbo àwọn tó ti jẹ́ olùjọsìn rẹ̀ látayébáyé sí. Bíbélì pe ìwé náà ní “ìwé ìyè” nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí àwọn tá a bá kọ orúkọ wọn sínú rẹ̀. (Ìṣípayá 17:8) Ohun aláyọ̀ kan láti máa fojú sọ́nà fún lèyí jẹ́ fún gbogbo àwọn tó bá mọ orúkọ Ọlọ́run.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Wọ́n Polongo Orúkọ Ọlọ́run
● Orin tí Mósè kọ ní kété ṣáájú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí: “Èmi yóò polongo orúkọ Jèhófà.”—Diutarónómì 32:3.
● Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ fún Gòláyátì òmìrán: “Èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”—1 Sámúẹ́lì 17:45.
● Ọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ lẹ́yìn tó ti pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ sì ti kú ikú òjijì: “Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”—Jóòbù 1:21.
● Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá . . . ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Ìṣe 2:21.
● Wòlíì Aísáyà: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà! Ẹ ké pe orúkọ rẹ̀. . . . Ẹ mẹ́nu kàn án pé orúkọ rẹ̀ ni a gbé ga.”—Aísáyà 12:4.
● Nígbà tí Jésù Kristi ń kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá a ṣe ń gbàdúrà: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’”—Mátíù 6:9, 10.
● Jésù Kristi ń gbàdúrà sí Ọlọ́run: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere.”—Jòhánù 17:6.
● Ọlọ́run ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.”—Aísáyà 42:8.