Ìdí Tí Mo Fi Gba Bíbélì Gbọ́ Onímọ̀ Nípa Agbára Átọ́míìkì Sọ Ìtàn Ara Rẹ̀
GẸ́GẸ́ BÍ ALTON WILLIAMS ṢE SỌ Ọ́
IRE méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wọlé tọ̀ mí wá lọ́dún 1978. Lóṣù September, mo gboyè jáde ní yunifásítì gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa agbára átọ́míìkì, ẹ̀wẹ̀ nígbà tó di oṣù December, mo di òjíṣẹ́ tá a fi joyè gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Táwọn èèyàn bá ń gbọ́ pé onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni mí tí mo sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń ṣe kàyéfì nípa bí mo ṣe ń ṣe é tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mi ò fi ta ko Bíbélì tí mo gbà gbọ́. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ọdún lèmi náà fi ṣe kàyéfì pé bóyá ni onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lè gba Bíbélì gbọ́. Àmọ́ ṣá, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó dá mi lójú gbangba pé ohun tó wà nínú Bíbélì ò ta ko ẹ̀kọ́ tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fìdí ẹ̀ múlẹ̀. Báwo ni mo ṣe gbà bẹ́ẹ̀? Ẹ dúró ná, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ bí mo ṣe di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Ìwé Tí Mo Fi Ọdún Mọ́kàndínlógún Kà
Ọdún 1953 ni wọ́n bí mi nílùú Jackson, ní ìpínlẹ̀ Mississippi, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èmi sì ni ìkẹta nínú àwa mọ́kànlá táwọn òbí mi bí. Atàpáta dìde ni mí. Ńṣe là ń kó kiri nítorí àìrí owó ilé san. Ètò ìrànwọ́ kébi-má-pàlú tíjọba ṣe la fi ń gbéra lọ́pọ̀ ìgbà ká tó lè jẹun, aṣọ àlòkù tí wọ́n bá fún màmá mi láti ibi tó ti lọ báwọn tọ́jú ilé tàbí ọ́fíìsì là ń wọ̀.
Àwọn òbí mi sábà máa ń rán àwa ọmọ létí pé àfi tá a bá kàwé yanjú nìkan la tó lè bọ́ nínú òṣì. Nítorí náà, láti kékeré ni mo ti ní in lọ́kàn pé màá kàwé gboyè ní yunifásítì. Mo bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé lọ́mọ ọdún mẹ́fà, mo sì ń kàwé mi lọ geerege láìsí ìdádúró fún ọdún mọ́kàndínlógún. Mo fẹ́ràn sáyẹ́ǹsì àti ìṣirò gan-an ni, nítorí náà nígbà tí mo dé yunifásítì, ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì ni mo yàn láàyò.
Nígbà tí mo wà ní yunifásítì, mo pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Del. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń kọ́ wa ní sáyẹ́ǹsì ló ní kí Del wá bá mi kí n lè kọ́ ọ láwọn nǹkan kan nínú ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì tó ń kọ́ lọ́wọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ wa wá ń kọjá ká kọ́ra ní sáyẹ́ǹsì, bọ́rọ̀ ìfẹ́ ṣe wọ̀ ọ́ nìyẹn o. Lọ́jọ́ kẹwàá oṣù January, ọdún 1974, a ṣègbéyàwó láàárín ìsinmi wákàtí méjì ká tó padà sí kíláàsì! Lọ́dún mẹ́rin lẹ́yìn náà, lọ́dún 1978, mo gboyè ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní yunifásítì nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
Lójú ara mi, ọwọ́ mi ti tẹ kọ́kọ́rọ́ àṣeyọrí wàyí. Mo ti di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, kì í wá ṣe onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lásán, odindi onímọ̀ nípa agbára átọ́míìkì ni o! Léyìí tí mo ti wá ní ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ nípa àtúpalẹ̀ agbára átọ́míìkì yìí o, kí n bẹ̀rẹ̀ sí máa lábẹ̀ ẹ̀kọ́ tí mo fi ọdún gbọọrọ kọ́ ló kù. Ara mi ti wà lọ́nà láti di olókìkí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Yàtọ̀ síyẹn, kí n ṣà, kí n rọ̀ ni kí n tó mú ọ̀kan lára oríṣiríṣi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé táwọn iléeṣẹ́ aládàáni àti ti ìjọba ń fi lọ̀ mí.
Àmọ́, lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ní December 30, ọdún 1978, mo ṣe nǹkan kan tó yí ìgbésí ayé mi àtọjọ́ iwájú mi padà ju bí oyè tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe. Lọ́jọ́ náà ni mo fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣèrìbọmi tí mo sì tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Báwo ni mo ṣe rìn ín tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Ìwé Kan Là Mí Lójú
Nígbà tó kù díẹ̀ kí ọdún 1977 parí, tí mo ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ Yunifásítì Massachusetts tó wà nílùú Amherst, àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí kanlẹ̀kùn ilé mi. Mi ò sí nílé lọ́jọ́ náà, ṣùgbọ́n ìyàwó àtàwọn ọmọ mi wà nílé, ìyẹn ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́ta àti ọmọbìnrin tá a ṣẹ̀sẹ̀ bí. Ìyàwó mi gba àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn láyè láti wọlé. Lẹ́yìn ìjíròrò alárinrin tí wọ́n jọ ṣe, ó gbà pé káwọn Ẹlẹ́rìí náà máa wá sọ́dọ̀ òun lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà tí ìyàwó mi sọ fún mi nípa ètò tí wọ́n ṣe yìí, ojú ẹsẹ̀ ni mo sọ fún un pé mi ò fara mọ́ ọn. Mi ò ní kó má ṣe ẹ̀sín tó bá wù ú, kó ṣáà má ti jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Kì í kúkú ṣe pé mo ti mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa ni, àmọ́ ohun tèmi kàn rò nípa wọn ni pé èèyàn kan tó yàtọ̀ sáráyé tí wọ́n sì máa ń fi Bíbélì tan àwọn èèyàn jẹ ni wọ́n. Nítorí náà, mo pinnu láti yọ ìyàwó mi tí mo rò pé ó ti kó si akóló àwọn Ẹlẹ́rìí, mo lérò pé mo lè lo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mi láti yẹpẹrẹ àwọn ẹ̀kọ́ wọn.
Lọ́sẹ̀ kan báyìí, mo ṣíwọ́ fún wákàtí kan lẹ́nu ìwádìí tí mò ń ṣe ní yunifásítì mo sì lọ sílé kí n lè wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, ó pẹ́ mi kọjá bí mo ṣe rò, obìnrin tó ń kọ́ ìyàwó mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì ti fẹ́ máa lọ kí n tó délé. Ó fún mi níwèé kan lédè Gẹ̀ẹ́sì tó ní àkòrí náà, Did Man Get Here by Evolution or by Creation?a Ó tún sọ fún ìyàwó mi pé nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa tẹ̀lé e lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, àwọn á jíròrò àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó fi hàn pé ọdún mánigbàgbé lọdún 1914. Àǹfààní tí mo nílò gan-an ló yọjú yẹn! Mo sọ fún Ẹlẹ́rìí yẹn pé màá wà nílé nígbà ìjíròrò Bíbélì tá á tẹ̀ lé e. Mo fẹ́ wo bí ohun tó máa bá wa sọ nípa ọdún 1914 ṣe péye tó tá a bá gbé e lórí ìṣirò.
Alẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé tí Ẹlẹ́rìí yẹn fún mi. Ká sòótọ́, ohun tó wà nínú ẹ̀ wú mi lórí. Wọ́n kọ ọ́ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání, ọ̀pọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, látinú àwọn ìwé sáyẹ́ǹsì, ló wà nínú ẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi láti rí i pé Bíbélì láwọn ìsọfúnni tó péye nípa ìṣẹ̀dá tó pọ̀ kọjá bí mo ṣe rò. Mo kàwé yẹn tán láàárín ọjọ́ díẹ̀ mo sì gbà láìsí àwáwí pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀dá ò tako àwọn òtítọ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Mo Pinnu Láti Wá Àwọn Àléébù Inú Ẹ̀kọ́ Wọn Rí
Síbẹ̀síbẹ̀, mo ṣì ń ṣiyèméjì nípa ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ń dúró de fífi ìmọ̀ ìṣirò tí mo ní ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ọdún 1914. Mo rò pé mo lè fi ìyẹn kó obìnrin Ẹlẹ́rìí yẹn láyà jẹ, kí n sì fi àṣìṣe tó wà nínú ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń kọ́ni han ìyàwó mi.
Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, Ẹlẹ́rìí náà padà wá tòun ti ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yẹn. Alàgbà náà ló darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀hún. Ó ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní orí àti ìkẹsàn-án nínú ìwé Dáníẹ́lì, nípa ìgbà tí Jésù yóò fara hàn bíi Mèsáyà àti Ọba. Ọkàn mi ṣáà wà lórí bí mo ṣe máa rí àwọn ibi tí àlàyé tó ń ṣe ò ti ní í bá ìṣirò mu, àmọ́ mi ò rí ọ̀kan ṣoṣo. Dípò ìyẹn, ohun tó wú mi lórí ni rírí tí mo rí bí àwọn ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì ṣe lọ́gbọ́n nínú tó.
Títí di àkókò yẹn, èrò mi ni pé ohun téèyàn bá ti rò nípa Ọlọ́run náà ni ìgbàgbọ́ ẹ̀, pé kò sídìí pàtó kan téèyàn fi lè gba Ọlọ́run gbọ́. Àṣé mo ti ṣì í! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí yìí fún ìjíròrò tó kún rẹ́rẹ́ yẹn, mo sì sọ fún wọn pé mà á fẹ́ máa kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ náà nìṣó. Látìgbà náà, mò ń bá ìwádìí mi lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ ní yunifásítì, èmi àti ìyàwó mi sì ń bá a nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí. Kò tán síbẹ̀ o, èmi àti ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Láàárín oṣù díẹ̀, mo ti kọ́ ọ̀pọ̀ òtítọ́ Bíbélì tí mi ò mọ̀ tẹ́lẹ̀, kò sì pẹ́ tí mo fi tóótun láti máa báwọn Ẹlẹ́rìí lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Mo ráyè ṣe èyí bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti wà ní ìpele tó kẹ́yìn tí mà á fi gba oyè ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní yunifásítì, tó sì jẹ pé ó ń ná mi lákòókò tó pọ̀ gan-an. Mo parí ìwé àkọgboyè mi nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1978 mo sì ṣí lọ sí ìpínlẹ̀ Alabama, níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ físíìsì ní yunifásítì Alabama Agricultural and Mechanical University tó wà nílùú Huntsville. Kíá la ti wá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kó dé kàn, alàgbà kan àti ìyàwó ẹ̀ sì ń bá a nìṣó láti máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lóṣù mélòó kan sígbà náà, èmi àti ìyàwó mi ṣèrìbọmi lọ́jọ́ kan náà.
Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ni Mí Mo sì Tún Jẹ́ Oníwàásù
Ní tèmi o, jíjẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò ní kí n máà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́dún 1983, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ bí onímọ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà lójú òfuurufú ní Ibùdó Ìfọkọ̀fò Lójú Òfuurufú George C. Marshall tó jẹ́ ti àjọ NASA (ìyẹn Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ìfọkọ̀fò àti Gbalasa Òfuurufú Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà), ìlú Huntsville ni àjọ ọ̀hún wà.b Mo bá wọn lọ́wọ́ sí gbogbo bí wọ́n ṣe ṣe awò kan tí wọ́n fi ń wo ìtànṣán X-ray àti bí wọ́n ṣe lò ó wò. (Lọ́dún 1999 ni wọ́n láǹfààní láti sọ awò-awọ̀nàjíjìn náà, ìyẹn Ibi Ìdúrósí Wo Ìtànṣán ní Sánmà tí wọ́n ń pè ní Chandra, lọ́jọ̀ sójú òfuurufú nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú tó ń jẹ́ Columbia.) Mo gbádùn bí mo ṣe bá wọn lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà, lára iṣẹ́ yẹn ni pé ká máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtànṣán tó ń tara onírúurú ìràwọ̀ àti ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wá ká lè lóye bí àgbáálá ayé ṣe rí síwájú sí i.
Ayọ̀dèjì ni iṣẹ́ mi jẹ́ fún mi, nítorí pé kì í ṣe pé mò ń yanjú àwọn ìṣòro ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó gbomi mu nìkan ni àmọ́, ó tún ń jẹ́ kí n lè mọ bí agbára àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá ṣe pọ̀ tó. Àní sẹ́, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà tẹnu wòlíì Aísáyà ìgbàanì sọ nítumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ sí mi. Ẹlẹ́dàá sọ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.” (Aísáyà 40:26) Bí mo bá ṣe ‘gbé ojú mi sókè’ tó láti bẹjú wo fífẹ̀ tí àgbáyé fẹ̀ lọ salalu, bó ṣe díjú tó àti bó ṣe rẹwà tó, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe máa ń mọyì iṣẹ́ ọwọ́ afinúṣọgbọ́n Oníṣẹ́-ọnà tó ṣe gbogbo ẹ̀ pátá tó sì tún fòfin tá á jẹ́ kí wọ́n lè máa síṣẹ́ pa pọ̀ lélẹ̀.
Ní gbogbo àkókò yẹn, mo jókòó ti kíkọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n yóò máa gbé jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn tó ń sọ̀rọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì tó dá lórí ìwádìí mi nípa wíwo àwọn nǹkan tó wà lójú òfuurufú. Àmọ́, mo tún ń ṣe déédéé nínú ìjọ Kristẹni. Mò ń sìn bí alàgbà mo sì máa ń lò tó ogún wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù. Lákòókò yìí, ìyàwó mi ń ṣiṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ gẹ́gẹ́ bí alákòókò kíkún.
Lẹ́yìn tí mo ti fi bí ọdún mẹ́rin ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ àjọ NASA, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe mí bíi pé kí n yọ̀ǹda àkókò púpọ̀ sí i láti máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì. Báwo ni mo ṣe wá fẹ́ ṣe é o? Lẹ́yìn tí mo ti sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún ìyàwó mi tí mo sì ti fọ̀rọ̀ náà tó Jèhófà létí nínú àdúrà, mo rí i pé mo ní láti ṣe àwọn ìpinnu lílágbára kan.
Àwọn Ìpinnu Tó Lágbára Tí Mo Ṣe
Mo lọ bá ọ̀gá mi nílé iṣẹ́ àjọ NASA mo sì sọ fún un pé mo fẹ́ dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù láti ọjọ́ márùn-ún sí ọjọ́ mẹ́rin. Tó bá jẹ́ towó ni, mi o kọ̀ kówó tí mò ń gbà dín kù. Mo sọ fún ọ̀gá mi pé mo fẹ́ máa lo ọjọ́ mẹ́ta tó kù láàárín ọ̀sẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Ọ̀gá mi gbà bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí láàárín àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ àjọ NASA. Àmọ́, ó ní mà á ní láti bá ọ̀gá òun sọ̀rọ̀ ná. Mo kúkú lọ bá a sọ̀rọ̀, inú mi sì dún dédìí nígbà tí ọ̀gá àgbà yìí gbà mí láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà lóṣù September ọdún 1987, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mò ń lo nǹkan bí àádọ́rùn-ún wákàtí lóṣù láti máa wàásù láti ilé dé ilé àti nínú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kù.
Nígbà tó yá ọ̀gá kan ní Yunifásítì Alabama Agricultural and Mechanical University tó wà nílùú Huntsville pè mí lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù. Ó bi mí bóyá mà á lè máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ físíìsì. Mo dá a lóhùn pé mà á ṣe é tíṣẹ́ yẹn bá máa jẹ́ kí n ráyè lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò mi lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Mo fi dá a lójú pé bí mo ṣe ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ mi kò ní nípa tí ò dáa lórí bí ẹ̀kọ́ tí màá máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ á ṣe múná dóko tó. Ọ̀gá náà gbà bẹ́ẹ̀. Títí dòní, mo ṣì ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní yunifásítì náà, tí mo sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Kódà mo ráyè kọ́ èdè Spanish. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí èmi àti ìyàwó mi ń sìn pẹ̀lú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń sọ èdè Spanish nílùú Huntsville.
Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ò Tako Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run
Látọdún tí mo ti ń bá ìwádìí mi bọ̀ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, mi ò tíì rí ibì kan tí ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ta kora. Àìní ìmọ̀ tó ló sábà máa ń fa ohun tó dà bí ìtakora, bóyá àìní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì ni o tàbí ìmọ̀ ohun tí Bíbélì wí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì fi àṣìṣe rò pé Bíbélì sọ pé ọjọ́ mẹ́fà oníwákàtí mẹ́rìnlélógún ni Jèhófà fi dá àwọn irúgbìn, àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn sórí ilẹ̀ ayé. Eléyìí ì bá máà bá òtítọ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ mu ká ní Bíbélì sọ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Bíbélì ò kọ́ wa bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó fi hàn pé “àwọn ọjọ́” kọ̀ọ̀kan ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún nínú.c
Ohun tó tún máa ń fa ìdàrúdàpọ̀ ni èrò tó ní àṣìṣe nínú náà pé ohun téèyàn bá ti rò nípa Ọlọ́run náà ló wulẹ̀ máa gbà gbọ́. Irọ́ gbuu nìyẹn, orí òtítọ́ téèyàn lè fìdí ẹ̀ múlẹ̀ la máa ń gbé ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti Bíbélì kà. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀, “ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà [tàbí “ẹ̀rí dídánilójú,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀rí wà tá a fi ní ìgbàgbọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àsọtẹ́lẹ̀ ló ti ní ìmúṣẹ nígbà àtijọ́ àti nígbà ayé wa yìí. Látàrí èyí, kódà tá a bá lo ọ̀nà tí gbogbo onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbà gbé àbá èrò nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kalẹ̀, a lè nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Ọ̀kan nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ni ìlérí pé àwọn èèyàn yóò gbádùn Párádísè lórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn làásìgbò tí ọjọ́ ogbó, àìsàn, ikú, ogun àti àìsí ìdájọ́ òdodo ń fà kò ní sí mọ́. (Ìṣípayá 21:3, 4) Nígbà náà a óò láǹfààní láti wádìí ká sì kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá Jèhófà Ọlọ́run àti ọ̀pọ̀ àwọn òfin tó ti ṣe láti máa dárí àgbáálá ayé amúnikún-fún-ẹ̀rù yìí.
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí kọ́kọ́rọ́ sí ayọ̀ tòótọ́, ìyẹn àgbàyanu òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àdúrà mi ni pé kí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè rí kọ́kọ́rọ́ ṣíṣeyebíye náà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, ṣùgbọ́n a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
b Àjọ ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àjọ NASA, ó sì dá dúró gédégbé sí àwọn àjọ ìjọba tó kù.
c Wo àkòrí náà “An Ancient Creation Record—Can You Trust It?” [Ṣé O Lè Gba Àkọsílẹ̀ Bíbélì Nípa Ìṣẹ̀dá Gbọ́?], tó wà ní orí kẹfà ìwé èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, Is There a Creator Who Cares About You? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 18]
Gbogbo èrò mi ni pé ohun téèyàn bá ti rò nípa Ọlọ́run náà ni ìgbàgbọ́ ẹ̀ pé kò sídìí pàtó kan téèyàn fi lè gba Ọlọ́run gbọ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
Mi ò tíì rí ibì kan tí ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ àti ẹ̀kọ́ Bíbélì ti ta kora
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Iṣẹ́ olùkọ́ tí kò gba àkókò púpọ̀ ni mò ń ṣe láti gbọ́ bùkátà ìdílé mi
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ibi ìdúrósí wo ìtànṣán ní sánmà ti àjọ NASA tí ń wọ́n pè ní Chandra tó rí roboto àti àwòrán ìtànṣán X-ray ti èjíjóná ìràwọ̀ oníbejì
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò àjọ NASA
NASA/CfA/J. McClintock et al.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Èmi àti ìyàwó mi ń gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún