Ká Lọ sí Ọjà Ẹja Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ JAPAN
ǸJẸ́ bí inú ọjà ṣe máa ń ṣe wìtìwìtì yẹn tiẹ̀ máa ń wù ọ́? Ọjà kan tá wù ọ́ láti dé tí àwọn arìnrìn-àjò káàkiri àgbáyé á sì fẹ́ láti yà wò ni Tsukiji, ọjà ẹja tí kò jìn ju ibi téèyàn lè fẹsẹ̀ rìn dé láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ láti àárín gbùngbùn Tokyo. Òun làwọn èèyàn kà sí ọjà ẹja tó tóbi jù lọ lágbàáyé.
Ọwọ́ ìdájí ló dára jù lọ láti lọ síbẹ̀. Nígbà tí àwọn ará ìlú Tokyo yòókù ṣì ń sùn lọ́wọ́, àwọn èrò ọjà ti ń nájà lọ ní pẹrẹu. Lójoojúmọ́ làwọn ọkọ̀ tí wọ́n fi ń kó ẹja máa ń já ẹja tó pọ̀ ju èyí tí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọkọ̀ akóyọỵọ lè kó lọ, wọ́n sì gbọ́dọ̀ tètè já gbogbo rẹ̀ nítorí pé tó bá ti di aago mẹ́ta òru, àwọn alájàpá tó fẹ́ ra ẹja á bẹ̀rẹ̀ sí dé. Àwọn ẹlẹ́ja tètè máa ń pàtẹ àpótí ẹja wọn, wọ́n á sì lẹ ìwé kan mọ́ ara àpótí ẹja náà. Lára ìwé yìí ni wọ́n máa ń kọ nọ́ńbà tá a fi ń dá ọjà mọ̀, ìwúwo ẹja náà àti ibi tí wọ́n ti pa á sí. Kò ṣòro láti dá àwọn tó fẹ́ ra ẹja mọ̀. Wọ́n máa ń wọ bàtà òjò, wọ́n á sì dé fìlà tí wọ́n kọ nọ́ńbà ìwé àṣẹ ìtajà wọn sí. Tiwọn ò dà bí àwọn arìnrìn-àjò tí wọ́n rọra ń rin ìrìn jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ńṣe làwọn alájàpá yìí máa ń sá sókè sódò, tí wọ́n á máa yẹ àwọn ẹja wò káàkiri kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe dára sí àti iye tí wọn yóò ná an sí. Ìwọ̀, iná àti aṣọ ìnura làwọn tó máa ń ra ẹja tuna máa ń gbé dání. Wọn ò lè ṣe kí wọ́n má tan iná yẹn tí wọ́n bá fẹ́ mọ bí àwọn ẹja tuna ńlá ńlá yẹn ṣe dára tó, wọ́n sì máa ń fi aṣọ ìnura nu ọwọ́ wọn tí wọ́n bá ti fọwọ́ kan ẹja.
Tó bá ti di aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí ni gbogbo ọjà á bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè. Aago á máa dún gbọngan-un gbọngan-un lọ́tùn-ún lósì, àwọn alágbàtà á sì máa ké sí àwọn alájàpá pé kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí díye lé ọjà tí wọ́n fẹ́ rà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi táwọn alágbàtà yìí kò sí láàárín ọjà náà. Àwọn oníṣòwò ńlá méje péré ló dìídì ń ṣòwò ẹja nínú ọjà yìí, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn nínú wọn ní alágbàtà bíi méjì, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì ń ta onírúurú ọjà pa pọ̀. Gbogbo àwọn alágbàtà yìí máa ń fi oríṣiríṣi ohùn pe nọ́ńbà ọjà wọn láti ṣàlàyé nǹkan tí wọ́n fẹ́ tà, àwọn oníbàárà tí wọ́n ní ìwé àṣẹ á sì máa du ọjà náà rà nípa fífọwọ́ ṣàpèjúwe. Páá-pàà-pá ni wọ́n máa ń ná ọjà tí wọ́n fẹ́ rà tó fi jẹ́ pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́ ìná á ti wọ̀. Àwọn alájàpá mìíràn máa ń nájà lọ́dọ̀ alágbàtà méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Ẹnì kan ṣoṣo ni wọ́n ń gbà láyè láti wọ inú ṣọ́ọ̀bù kan lẹ́ẹ̀kan, nítorí náà àwọn alájàpá yìí níláti tètè máa ti apá ibi kan bọ́ sí èkejì láti lọ ra ẹja tí wọ́n fẹ́ rà. Àwọn tó fẹ́ ra àràtúntà ẹja lójú páálí tí wọ́n sì ń fẹ́ oríṣiríṣi tí wọ́n á tà fún àwọn ilé ìtajà mìíràn ni gìrìgìrì tiwọn máa ń pọ̀ jù.
Gbàrà tí ìná bá ti wọ̀, ṣe ló máa ń ṣe àwọn alájàpá bíi kí wọ́n ti gbé ẹja wọn dé ibi tí wọ́n ń gbé e lọ. Àwọn aláàárù tó ń ti ọmọlanke àtàwọn ọkọ̀ kéékèèké tí wọ́n fi ń gbé ẹja gba àwọn ojú ọ̀nà tóóró á máa sá sọ́tùn-ún sósì. Ibi gbogbo á lọ́jú pọ̀, àwọn èèyàn á máa rọ́ lọ rọ́ bọ̀, ariwo á sì gba gbogbo ọjà kan. Àwọn tó ń wo bí nǹkan ṣe ń lọ lè máa rò pé ìdàrúdàpọ̀ ló ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́, kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan pátá ló ń lọ létòlétò. Láàárín wákàtí mélòó kan, wọ́n á ti ta èyí tó ju ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ páálí ẹja, tí àwọn tó rà wọ́n á sì ti gbé wọn lọ. Àwọn ṣọ́ọ̀bù kéékèèké tó wà lápá ibòmíràn nínú ọjà ni wọ́n máa ń kó àwọn ẹja kan lọ kí wọ́n lè tà wọ́n fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún oníbàárà mìíràn tí wọ́n ń dúró síbẹ̀ lọ́wọ́ àárọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti lè máa fojú inú wò ó, Ọjà Tsukiji tóbi gan-an. Àwọn ilé iṣẹ́ okòwò ńlá méjèèje tí wọ́n ń ta ẹja àtàwọn alájàpá kéékèèké tí wọ́n ju ẹgbẹ̀rún kan ni wọ́n ti forúkọ sílẹ̀ láti máa ṣòwò nínú ọjà yìí. Títí ọdún fi máa parí ni wọ́n ń tajà lọ ní pẹrẹu fáwọn oníbàárà tó ju ọ̀kẹ́ méjì [40,000] lọ tí wọ́n máa ń wá sí ọjà ẹja yìí lójoojúmọ́.
Àwọn wo gan-an ni oníbàárà wọ̀nyí? Lára wọn la ti rí àwọn tó ń ra ẹja tó pọ̀ fún àwọn ilé ìtura ńlá ńlá, ilé àrójẹ àti ṣọ́ọ̀bù ńlá ńlá tí wọ́n ti ń ta oríṣiríṣi nǹkan. Àwọn mìíràn tún ni àwọn tó ní búkà oúnjẹ, àwọn ọjà ẹja tó wà ládùúgbò, àti àwọn tó ní ṣọ́ọ̀bù kékeré tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ aládùn tí wọ́n máa ń fi ìrẹsì ṣe, èyí tí wọ́n ń pè ní sushi. Gbogbo àwọn oníbàárà yìí ló máa ń fẹ́ ra ẹja tó jojú ní gbèsè. Wọ́n sọ pé tá a bá ro gbogbo oríṣiríṣi ọjà tí wọ́n ń rà lọ́dún pọ̀, á tó ìwọ̀n tí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ọkọ̀ akóyọyọ lè kó tí iye owó tí wọ́n sì ń ná á to bílíọ̀nù márùn-ún owó dọ́là ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
Tá a bá wò ó dáadáa, Tsukiji kì í kàn ṣe ọjà ẹja nìkan. Ọjà ńlá tí wọ́n ti ń ta èso àti ewébẹ̀ ni pẹ̀lú. Ó wà lára ọjà ńlá mọ́kànlá tí ìjọba ìbílẹ̀ ìlú Tokyo ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń ná wọn. Látọdún 1603 ni àwọn ọjà tí wọ́n ti ń ta àwọn oúnjẹ bí ẹja àti ewébẹ̀ ti wà. Látọdún 1877 ni ìjọba ti ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń ná àwọn ọjà yìí kí wọ́n bàa lè rí i dájú pé oúnjẹ tí wọ́n ń tà níbẹ̀ dára, kò sì lẹ́gbin. Ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní ìlú Tokyo lọ́dún 1923 ba àwọn ọjà tó wà ní ìlú Tokyo jẹ́, òun ló wá jẹ́ kí wọ́n dá Ọjà Tsukiji tòde òní, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ná lọ́dún 1935 sílẹ̀.
Láti ìgbà náà wá ni ọjà yẹn ti wá ń gbèrú sí i. Ibo ló tún wà tí wọ́n ti ń ta ẹja tó pọ̀ tó báyìí ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan lágbàáyé? Wọ́n fojú bù ú pé wọ́n ń ta àwọn ẹja bí salmon, cod, ẹja onípẹ̀ẹ́pẹ́, mọ́ńkẹ̀rẹ̀, sole, àti herring títí kan urchin, sea cucumber àti ìṣáwùrú àtàwọn onírúurú nǹkan tẹ́nu ń jẹ tó wà nínú omi tó pọ̀ tó àádọ́ta lé nírínwó [450] lọ́jà yìí. Oríṣi ohun abẹ̀mí inú omi kan péré bí octopus tàbí edé ni wọ́n ń tà láwọn ṣọ́ọ̀bù kéékèèké mìíràn.
Àmọ́ ẹja kan wà lọ́jà yìí tó gborí lọ́wọ́ àwọn ẹja tó kù. Ìyẹn ẹja tuna ńlá tí wọ́n máa ń fi ọkọ̀ òfuurufú gbé wá láti iyànníyàn Òkun Mẹditaréníà àti Àríwá Amẹ́ríkà. Kò sí ẹja mìíràn tá a lè fi wé ẹja yìí ní ti bó ṣe tóbi tó àti iye tí wọ́n ń tà á. Wọ́n lè ta ẹja tuna ńlá kan ṣoṣo ní ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ dọ́là. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹja tuna tútù àtèyí tó dì ni wọ́n máa ń tà lọ́jà yìí lójoojúmọ́. Àwọn alájàpá máa ń gé ẹja tuna sí ìwọ̀nba tí agbára àwọn oníṣòwò àdúgbò yóò ká. Orí ìrẹsì sushi ló ṣeé ṣe kí apá ibi tó lọ́ràá ní igẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n ń pè ní toro gbẹ̀yìn sí.
Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ilẹ̀ Japan ni ọjà ẹja tó tóbi jù lágbàáyé wà. Ìdí ni pé òkun ńlá àti agbami mẹ́ta ló yí orílẹ̀-èdè náà ká, ó sì ti pẹ́ táwọn ará Japan ti fi kọ́ra láti máa jẹ àwọn nǹkan tó ń gbé inú omi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí oúnjẹ táwọn ará Japan fẹ́ràn tí wọn ò ní fi ẹja sí. Ẹja tí ọmọ orílẹ̀-èdè Japan kan ṣoṣo ń jẹ lọ́dún á tó páálí ẹja mẹ́ta àtààbọ̀, èyí tó sì pọ̀ jù nínú àwọn ẹja yìí ni wọ́n ń rà ní Ọjà Tsukiji. Nítorí náà tí ìrìn àjò bá gbé ẹ dé Tokyo, o ò ṣe kúkú dára pọ̀ mọ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn arìnrìn àjò tí wọ́n ń yà lọ wo ọjà ẹja tó tóbi jù lágbàáyé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwòrán ẹja: Láti inú ìwé L’Art Pour Tous, Encyclopedie de l’Art Industriel et Decoratif, Ìdìpọ̀ 31, ojú ìwé 1861 sí 1906
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
James L. Stanfield/NGS Image Collection
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
© Jeff Rotman/www.JeffRotman.com
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Tokyo Metropolitan Central Wholesale Market