Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tí Jíjíròrò Nípa Ìbálòpọ̀ Lórí Tẹlifóònù Fi Burú?
ÌWÉ ìròyìn kan táwọn èèyàn mọ̀ nílé-lóko nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé: “Ní báyìí, jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù ti rọ́pò lẹ́tà ìfẹ́ táwọn olólùfẹ́ méjì tí wọn ò jọ sí nítòsí ara wọn fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ ìfẹ́.”
Kí ni àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù? Òun ni pé kéèyàn máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tàbí kéèyàn máa fetí sí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.a Àwọn tó ń dá irú àṣà yìí tún sábà máa ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wọn kí ara wọn tó ti gbóná lè wálẹ̀. Yálà àárín àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ni ìsọkúsọ yìí ti ń wáyé ni o tàbí láàárín àwọn àjèjì, àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù ti wọ́pọ̀ gan-an, ó sì ń kọni lóminú. Àní, àwọn kan tiẹ̀ ń gbé e lárugẹ ní gbangba.
Obìnrin kan sọ pé: “Òun ni àṣà ìbálòpọ̀ tó dára jù lọ.” Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn díẹ̀ fara mọ́ ohun tó sọ. Bí àpẹẹrẹ, ní oṣù October, ọdún 2000, àwọn ògbógi kan nínú ọ̀ràn ìlera nílẹ̀ Rọ́ṣíà lo ìwé ìròyìn láti fi gbé àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù lárugẹ láti lè wá nǹkan ṣe sí bí kòkòrò àrùn tó ń fa éèdì ṣe ń ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn.
Àmọ́ o, lájorí ohun tó ń sún àwọn ẹlòmíràn láti gbé àṣà yìí lárugẹ ni owó tí wọ́n máa rí nídìí ẹ̀. Àwọn iléeṣẹ́ tó ń ṣètò ìjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù, ìyẹn àwọn táwọn èèyàn ń sanwó fún láti lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rírùn, ń pa owó tó tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là nílẹ̀ Amẹ́ríkà nìkan.
Kí lohun náà gan-an tó mú kí àṣà yìí wọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìwé The Fantasy Factory ṣàlàyé pé: “Níní ìbálòpọ̀ àti sísọ ẹlòmíràn di agbọ̀ràndùn léwu. Àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó jẹ yọ nìwọ̀nyí: àwọn àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìṣekúṣe, kí orúkọ ẹni bà jẹ́ láwùjọ àti kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹni bí àṣírí bá tú, ìbẹ̀rù káwọn èèyàn máa fojú burúkú woni, àtàwọn àbájáde tó wà nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Ìjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù máa ń mú kí ewu wọ̀nyí dín kù.”
Òótọ́ ni pé jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù kì í jẹ́ kí ẹnì kan àti ẹlòmíì fara kanra. Àmọ́, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sóhun tó burú nínú rẹ̀ tàbí pé kò sí ewu tàbí ìpalára èyíkéyìí níbẹ̀ ni?
Ṣé Ohun Tí Kò Lè Pani Lára Ni Àṣà Yìí Ni?
Ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an nígbà èwe. Bíbélì pe àkókò yìí, tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, ní “ìgbà ìtànná òdòdó èwe.” (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ní àkókò pàtàkì yìí nínú ìgbésí ayé, ọ̀dọ́ Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní láti mọ bí yóò ti “ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Ìyẹn ni pé, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tí wàá ṣe bí èrò nípa ìbálòpọ̀ bá ń wá sí ọ lọ́kàn. Èyí ṣe pàtàkì kéèyàn lè ní èrò tó mọ́gbọ́n dání tó sì bójú mu nípa ìbálòpọ̀.
Àmọ́ o, ńṣe ni àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù ń kọ́ni láti máa fi èrò nípa ìbálòpọ̀ tẹ́ ara ẹni lọ́rùn, dípò tí ì bá fi máa kọ́ni láti mú èrò yìí kúrò lọ́kàn. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń jẹ́ kéèyàn ní èrò tí kò tọ̀nà, tí kò sì bójú mu nípa ẹ̀yà kejì. Bíbélì kọ́ni pé kìkì àwọn tó bá jẹ́ tọkọtaya nìkan ló gbọ́dọ̀ gbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo. (Hébérù 13:4) Ṣùgbọ́n, ńṣe ni àṣà yìí ń fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti máa ní ìbálòpọ̀ láìṣègbéyàwó. Bíbélì sọ pé ohun tó ń fúnni ní ojúlówó ayọ̀ ni fífúnni, kì í ṣe rírígbà. (Ìṣe 20:35) Àmọ́, àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù ń kọ́ni láti máa kó àwọn ẹlòmíràn nífà. Bíbélì kọ́ àwọn tọkọtaya pé wọ́n ní láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì fọkàn tán ara wọn, nípa bẹ́ẹ̀ àjọṣe àárín wọn á lè dán mọ́rán. (Éfésù 5:22, 33) Ṣùgbọ́n, ńṣe ni àṣà búburú yìí ń mú kéèyàn di ẹni tí kì í fi ọ̀yàyà àti ìfẹ́ hàn sí ẹlòmíràn.
Àṣà Bárakú Tó Léwu
Ìlú Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un kún fún ìwà pálapàla. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀ pé: “Mo ń fòyà pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ti sún Éfà dẹ́ṣẹ̀ nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí rẹ̀, a lè sọ èrò inú yín di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 11:3) Jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí Sátánì Èṣù ń lò láti fi sọ àwọn èwe òde ìwòyí di oníwà pálapàla.
Lílo tẹlifóònù láti bá àwọn ẹlòmíràn tó nífẹ̀ẹ́ sí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ti di àṣà bárakú fún àwọn ọ̀dọ́ kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí a ó pè ní Jim fi hàn bí àwọn kan ṣe lè sọ ọ́ di bárakú tó. Jim rí nọ́ńbà tẹlifóònù kan tó jẹ́ ti àwọn tó ń jíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù lára pátákó ìpolówó ọjà kan. Ó há nọ́ńbà yìí sórí, ojúmìító sì sún un láti tẹ àwọn tó ni ín láago. Ó wá di pé kó máa pe nọ́ńbà yìí lemọ́lemọ́. Láìpẹ́, gbèsè tẹlifóònù tó jẹ ti pọ̀ gan-an débi pé ó ní láti san owó tó tó ẹgbẹ̀ta [600] dọ́là!
Mímú ara ẹni gbóná nígbà téèyàn ṣì jẹ́ àpọ́n lòdì sí ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”—Kólósè 3:5.
Àkóbá Tó Lè Ṣe fún Àwọn Tó Ń Fẹ́ra Wọn Sọ́nà
Àwọn tó ti dàgbà tó láti ṣègbéyàwó, tí wọ́n sì ní in lọ́kàn láti fẹ́ra wọn ńkọ́? Ká sòótọ́, ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fúnra wọn. Nígbà pípẹ́ sẹ́yìn, lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run sọ ohun kan nípa àfẹ́sọ́nà rẹ̀, ó ní: “Ti olólùfẹ́ mi ni èmi, ọ̀dọ̀ mi sì ni ọkàn rẹ̀ ń fà sí.” (Orin Sólómọ́nì 7:10) Nígbà tí ọjọ́ ìgbéyàwó bá kù dẹ̀dẹ̀, ohun tó tọ́ tó sì yẹ ni pé kí àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà jọ jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí kan. Àmọ́ o, ǹjẹ́ jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù jẹ́ ọ̀nà tí kò lè pani lára tí wọ́n fi lè máa bá ara wọn sọ ọ̀rọ̀ ìfẹ́?
Rárá o. Àní, àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà pàápàá ní láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìyẹn ni pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́. Nítorí ẹ mọ èyí, ní mímọ̀ ọ́n dájú fúnra yín, pé kò sí àgbèrè kankan tàbí aláìmọ́ tàbí oníwọra-èyí tí ó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà-tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.”—Éfésù 5:3-5; Kólósè 3:8.
Láìsí àní-àní, ọ̀rọ̀ àṣírí tá a fi ń dìídì ru èròkerò sókè lọ́kàn ẹni tàbí tó ń súnni láti máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni láti mú ara ẹni gbóná jẹ́ ohun àìmọ́ lójú Jèhófà. Bákan náà, ó lè yọrí sí títàpá sí àwọn ìlànà Ọlọ́run lọ́nà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí ọ̀nà wọn jìn síra ń fẹ́ra wọn sọ́nà. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ lórí tẹlifóònù láti fi mọ ara wọn dunjú. Àmọ́, kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn túbọ̀ wá ń dá lórí àwọn ohun tí kò bétí mu rárá. Látàrí èyí, kò yani lẹ́nu pé nígbà tí wọ́n láǹfààní lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti wà pa pọ̀, kò pẹ́ tí wọ́n fi hùwà àìmọ́.
Dájúdájú, àwa tá a fẹ́ láti mú inú Ọlọ́run dùn yóò ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti má ṣe jẹ́ kí àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù dẹkùn mú wa. Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
‘Máa Lu Ara Rẹ Kíkankíkan’
Àṣà jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù lè di bárakú. A ní láti máa ‘lu ara wa kíkankíkan, ká sì máa darí rẹ̀ bí ẹrú’ bá a bá fẹ́ kí Jèhófà fi ojúure wò wá. (1 Kọ́ríńtì 9:27) Bí àṣà yìí bá ti wọ̀ ẹ́ lẹ́wù, o ò ṣe wá ìrànwọ́? Sísọ fún àwọn òbí rẹ tó jẹ́ Kristẹni yóò jẹ́ ọ̀nà dáradára kan láti bẹ̀rẹ̀ sí wá ìrànwọ́. Lóòótọ́, wọ́n lè bínú sí ọ o. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ló máa lè ṣèrànwọ́ fún ọ jù láti gbógun ti àṣà yìí kí ìṣòro náà má bàa tún padà wá. Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ò ń dara pọ̀ mọ́ yóò tún fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
Bó o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, pinnu láti jẹ́ oníwà mímọ́, kódà nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù pàápàá. Leticia, obìnrin Kristẹni kan tó ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, sọ pé: “Èmi àti àfẹ́sọ́nà mi ti jọ ka àwọn àpilẹ̀kọ tá a gbé ka Bíbélì tó jíròrò nípa jíjẹ́ oníwà mímọ́. A mọrírì ọ̀nà tí wọ́n ti gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́.” Ní ìgboyà láti wá nǹkan míì sọ bí ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ bá ti ń di èyí tí kò bójú mu mọ́. Ẹ jọ jíròrò bó ti ṣe pàtàkì tó láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yín jẹ́ mímọ́.
Ní àwọn ilẹ̀ kan, nígbà tó bá ti dọwọ́ alẹ́ pátápátá ni wọ́n máa ń gbé àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń fúnni níṣìírí láti jíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù sáfẹ́fẹ́. Bóyá ohun tó máa dára jù lọ fún ọ láti ṣe ni pé kó o yẹra fún wíwo tẹlifíṣọ̀n di ọ̀gànjọ́ òru. Bákan náà, níwọ̀n bí àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni láti mú ara ẹni gbóná ti lè mú kí àwọn èròkerò dìde lọ́kàn rẹ, dípò kó mú wọn kúrò, ó ṣe pàtàkì pé kó o yẹra fún àṣà àìmọ́ yìí.b O lè mú àwọn èròkerò wọ̀nyí kúrò lọ́kàn nípa ríronú lórí àwọn ohun tó ń gbéni ró. (Fílípì 4:8) Máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ tó bójú mu, kó o sì máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lójoojúmọ́ láti mú kí ìpinnu rẹ túbọ̀ lágbára sí i. Lọ́nà yìí, o ò ní gba èròkerò láyè láti wọ̀ ọ́ lọ́kàn, èyí kò sì ní sọ ìrònú rẹ di ìbàjẹ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:6, 7.
Ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tó ń gbé orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Àwọn ohun tó lè sún àwọn èwe láti lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ pọ̀ gan-an ni.” Àmọ́ o, Jèhófà mọ àwọn ìṣòro tí ò ń kojú. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé yóò fún ọ ní gbogbo ìtìlẹyìn tó o nílò láti jẹ́ ẹni mímọ́ lójú rẹ̀.—Éfésù 6:14-18.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àṣà búburú kan tó tún fara jọ èyí ni wíwo àwòrán ìbálòpọ̀ tàbí jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
b O lè rí àwọn àbá nípa béèyàn ṣe lè borí àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni láti mú ara ẹni gbóná tàbí dídá nìkan hùwà ìbálòpọ̀ nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, ojú ìwé 198 sí 211, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù àti jíjíròrò nípa ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti ń wọ́pọ̀ gan-an báyìí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Àwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn má bàa di aláìmọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lè mú kí ìpinnu rẹ láti jẹ́ oníwà mímọ́ túbọ̀ lágbára sí i