Ibo Lo Ti Lè Rí Ìrètí Tòótọ́?
AAGO ọwọ́ rẹ ti dákẹ́, ó sì dà bí i pé ojú rẹ̀ ti fọ́. Nígbà tó o wá fẹ́ tún un ṣe, o ò mọ ẹni tó ò bá gbé e fún. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń tún aago ṣe ló ń polówó, gbogbo wọn sì ń dánnu mọ́ iṣẹ́ ọwọ́ wọn pé àwọn làwọn lè tún un ṣe, ọ̀rọ̀ wọn ò sì dọ́gba. Ṣùgbọ́n bó o bá wá mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé aládùúgbò rẹ kan ni ọ̀jáfáfá tó ṣe aago yẹn lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn ńkọ́? Yàtọ̀ sí ìyẹn, o tún gbọ́ pé á bá ọ tún un ṣe lọ́fẹ̀ẹ́, láìgba kọ́bọ̀. Láìdéènà pẹnu, nǹkan tó o máa ṣe á ti yé ọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Fi bọ́ràn aago yẹn ṣe rí lára rẹ wé ọ̀ràn ìrètí. Bó o bá rí i pé o ti ń sọ̀rètí nù, bíi tàwọn mìíràn nínú ayé onídààmú yìí, ibo lo lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Àwọn tó láwọn lè yanjú ìṣòro yẹn lè tó ẹgbàágbèje o, ṣùgbọ́n àìmọye ìmọ̀ràn tí wọ́n ń mú wá ló lè ki orí ẹni bọgbó, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ wọn ò ṣọ̀kan. Láìṣe méní méjì, o ò ṣe kúkú forí lé ọ̀dọ̀ Ẹni tó ṣẹ̀dá aráyé lọ́nà tá a fi lè nírètí? Bíbélì sọ fún wa pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa” ó sì ń retí wa, ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́.—Ìṣe 17:27; 1 Pétérù 5:7.
Ohun Tí Ìrètí Túmọ̀ sí Gan-an
Bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ohun tó ń jẹ́ ìrètí gbòòrò, ó sì jinlẹ̀ ju báwọn dókítà, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àtàwọn afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá ṣe ń fẹnu yẹpẹrẹ ṣàlàyé rẹ̀ lóde òní lọ. Nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀sẹ, ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ìrètí” ni pé kéèyàn máa fi ìháragàgà dúró de nǹkan kó sì máa retí ohun tó dára. Ohun pàtàkì méjì ló wà nínú ìrètí. Àwọn ni ìfẹ́ àtọkànwá fún nǹkan tó dára àti ìdí tá a fi lè retí pé ohun tó dára yóò wá. Ìrètí tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kì í kàn ṣe ríronú pé ohun tó wù wá á ṣẹlẹ̀ lásán. A ní ìdí àtí ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ tá a fi lè rò pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ máa rí.
Ibi tí ìrètí fi jọ ìgbàgbọ́ nìyẹn, orí ẹ̀rí la sì gbọ́dọ̀ gbé e kà, a ò gbọ́dọ̀ gbé e ka orí ìgbàgbọ́ oréfèé. (Hébérù 11:1) Síbẹ̀, Bíbélì sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìrètí àti ìgbàgbọ́.—1 Kọ́ríńtì 13:13.
Bí àpẹẹrẹ: Bó o bá sọ fún ọ̀rẹ́ minú rẹ kan pé kó ṣèrànlọ́wọ́ kan fún ọ, o lè nírètí pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. O kò ṣàdédé nírú ìrètí bẹ́ẹ̀, nítorí pé o ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rẹ́ rẹ ni, ìyẹn ni pé o mọ̀ ọ́n dáadáa, o sì ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé onínúure àti ọlọ́làwọ́ ni. Ìgbàgbọ́ rẹ àti ìrètí rẹ jọ ń rìn ni, kódà wọ́n wọnú ara wọn, ṣùgbọ́n wọ́n yàtọ̀ síra. Báwo lo ṣe lè ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run?
Ìdí Tó O Fi Lè Ní Ìrètí
Ọlọ́run lorísun ìrètí tòótọ́. Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, Jèhófà ni wọ́n ń pè ní “ìrètí Ísírẹ́lì.” (Jeremáyà 14:8) Nítorí náà, ìrètí èyíkéyìí tó ṣeé gbára lé táwọn èèyàn rẹ̀ ní wá látọ̀dọ̀ rẹ̀, fún ìdí èyí, òun ló jẹ́ ìrètí wọn. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ kì í kàn ṣe ohun téèyàn fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ nìkan. Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìdí tó lágbára tí wọ́n fi lè nírètí. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti ń bá wọn lò, wọ́n ti rí, wọ́n sì ti gbọ́ bó ṣe mú gbogbo ìlérí tó ṣe ṣẹ. Jóṣúà, tó jẹ́ aṣáájú wọn sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa . . . pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.”—Jóṣúà 23:14.
Títí di ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà ṣì ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ọ̀pọ̀ ìlérí pípabanbarì tí Ọlọ́run ṣe àti bó ṣe mú wọn ṣẹ wà lákọọ́lẹ̀ pípé pérépéré nínú Bíbélì. Ìmúṣẹ àwọn ìlérí tó ṣe dájú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé nígbà míì a máa ń kọ wọ́n bíi pé wọ́n ti ní ìmúṣẹ nígbà tó ṣèlérí náà ni.
Ìdí rèé tá a fi lè pe Bíbélì ní ìwé ìrètí. Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn lò, bẹ́ẹ̀ ni ìdí tó o ní fún fífi ìrètí rẹ sínú rẹ̀ á ṣe máa lágbára sí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Ká Máa Retí?
Ìgbà wo la nílò ìrètí jù lọ? Ṣé kì í ṣe ìgbà tí ikú bá dojú kọ wá ni? Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, nírú àkókò báyẹn gan-an—bóyá nígbà tí ikú bá pa ẹnì kan tó sún mọ́ wọn—ni ìrètí á wá dàwátì. Àbí, kí ló tún kù téèyàn lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹni tó ti kú? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo wa la ti jẹ gbèsè ikú. Kò sí bá a ṣe lè sá fún un tó, ọjọ́ tíkú bá dé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ. Wẹ́kú lórúkọ tí Bíbélì pè é bá a mu, ìyẹn “ọ̀tá ìkẹyìn.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
Nígbà náà, báwo wá la ṣe lè nírètí tíkú bá dé? Tóò, ẹsẹ Bíbélì tó pe ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn yẹn náà tún sọ pé ọ̀tá yìí la ó “sọ di asán.” Jèhófà Ọlọ́run lágbára ju ikú lọ. Kì í ṣòní kì í ṣàná rèé tó ti ń fàjùlọ hàn án. Bíi báwo? Nípa jíjí tó ń jí òkú dìde ni. Bíbélì ròyìn pé ẹ̀ẹ̀mẹsàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run lo agbára rẹ̀ láti sọ àwọn òkú di alààyè.
Ọ̀kan tó pabanbarì ni ìgbà tí Jèhófà fún Jésù Ọmọ rẹ̀ lágbára láti jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n, Lásárù tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin dìde. Kọ̀rọ̀ kọ́ ni Jésù ti ṣe èyí, gbangba níṣojú gbogbo ayé ni.—Jòhánù 11:38-48, 53; 12:9, 10.
O lè máa rò ó pé, ‘Kí ló dé tá a tún fi jí àwọn èèyàn dìde? Ṣebí wọ́n ṣáà pàpà darúgbó tí wọ́n sì kú, àbí wọ́n ṣì wà dòní?’ Wọ́n kú lóòótọ́. Síbẹ̀, nítorí àkọsílẹ̀ tó ṣeé gbára lé nípa àjíǹde, irú bí ìwọ̀nyí, a lè ní kọjá ìfẹ́ ọkàn pé àwọn ẹni tá a fẹ́ràn tí wọ́n kú yóò jíǹde; a ní ìdí láti gbà gbọ́ pé wọ́n á jíǹde. Lédè mìíràn, a lè sọ pé a ní ìrètí tó yanran-n-tí.
Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Òun ni Jèhófà máa fún lágbára láti jí àwọn òkú dìde jákèjádò ayé. Jésù sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Kristi], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Kò sírọ́ ńbẹ̀, gbogbo àwọn tó ń sùn nínú ibojì ló ṣeé ṣe fún láti jíǹde sínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
Bí wòlíì Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àjíǹde yìí wúni lórí gan-an ni, ó sọ pé: “Àwọn òkú rẹ yóò yè, . . . wọn ó dìde. Ẹ jí, ẹ sì kọrin, ẹ̀yin tí ń gbé inú ekuru: torí ìrì rẹ ìrì ewébẹ̀ ni, ilẹ̀ yóò si sọ àwọn òkú jáde.”—Aísáyà 26:19, Bibeli Mimọ.
Ṣé ìyẹn ò tó tu èèyàn nínú? Kò sí ibi tó tún láàbò ju ibi táwọn òkú wà lọ, àfi bí ọmọ inú oyún tí ò sí nǹkan tó ń dà á láàmú nínú ọlẹ̀ ìyá rẹ̀. Àní, àwọn tó ń sinmi nínú ibojì wà nípamọ́ nínú ìrántí Ọlọ́run Olódùmarè, adánimágbàgbé. (Lúùkù 20:37, 38) Kò sì ní pẹ́ mọ́ tí wọ́n á fi padà sí ìyè, wọ́n á jíǹde sínú ayé tá ó ti kí wọn káàbọ̀ bí tẹbí tará ṣe máa ń kí ọmọ tuntun ní àríjó àríyọ̀! Nítorí náà, ìrètí ṣì wà fẹ́ni tó kú pàápàá.
Ohun Tí Ìrètí Lè Ṣé fún Ọ
Pọ́ọ̀lù kọ́ wa ní ohun tó pọ̀ nípa àǹfààní tó wà nínú ìrètí. Ó ka ìrètí kún ọ̀kan pàtàkì lára ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí, ó pè é ní àṣíborí. (1 Tẹsalóníkà 5:8) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fi ìrètí wé àṣíborí? Tóò, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, táwọn sójà bá ń lọ sójú ogun, wọ́n máa ń da àṣíborí onírin borí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dé fìlà híhun tàbí aláwọ. Ọpẹ́lọpẹ́ àṣíborí yẹn, gbogbo ọta tí ì bá ti fọ́ agbárí sójà máa ń ta dànù ni tó bá ti bà á. Kí ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ fà yọ nínú àpèjúwe yìí? Bí àṣíborí ṣe ń dàábò bo orí bẹ́ẹ̀ ni ìrètí ṣe ń dáàbò bo èrò inú, ìyẹn agbára ìrònú. Tó o bá ní ìrètí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ète Ọlọ́run, ìbẹ̀rù ò ní lè gba àlàáfíà rẹ lọ́wọ́ rẹ bẹ́ẹ̀ lo ò sì ní sọ̀rètí nù nígbà tí ìṣòro bá dé. Ta ló wá lè sọ pé òun ò nílò irú àṣíborí bẹ́ẹ̀ nínú wa o?
Pọ́ọ̀lù tún lo àpèjúwe kedere mìíràn láti fi bí ìrètí ṣe tan mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run hàn. Ó kọ̀wé pé: “Ìrètí yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.” (Hébérù 6:19) Pọ́ọ̀lù mọ bí ìdákọ̀ró ṣe ṣe pàtàkì tó nítorí ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí ọkọ̀ ojú omi tó wọ̀ rì. Tí ìjì bá ṣọwọ́ òdì sí ọkọ̀ ojú omi, ńṣe làwọn atukọ̀ máa ń sọ ìdákọ̀ró sísàlẹ̀ odò. Bó bá jàjà rí nǹkan kọ́ nísàlẹ̀ odò, ó ṣeé ṣe kí ọkọ yẹn má dà nù, ó lè gúnlẹ̀ láyọ̀ dípò tí ì bá fi forí sọ àpáta ní bèbè odò.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, bí àwọn ìlérí Ọlọ́run bá dà bí ‘ìrètí tó dájú, tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in’ fún wa, ìrètí yẹn á lè ràn wá lọ́wọ́ láti jàjàyè nínú ìjì tó ń jà láyé eléwu yìí. Jèhófà ṣèlérí pé láìpẹ́, àkókò ń bọ̀ tọmọ aráyé ò ní fojú winá ogun, ìwà ọ̀daràn, ìbànújẹ́ àti ikú pàápàá mọ́. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 20.) Tá a bá dìrọ̀ mọ́ ìrètí yìí, kò ní jẹ́ ká ṣe kòńgẹ́ ibi, á sì sún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run dípò tá ó fi máa báwọn hùwà pálapàla táráyé ń hù lóde òní tó sì ń dojú ayé rú.
Ìrètí tí Jèhófà ń nawọ́ rẹ̀ sí wa yìí kàn ọ́ gbọ̀ngbọ̀n. Ọlọ́run fẹ́ kó o gbé ìgbésí ayé rẹ gẹ́gẹ́ bó ṣe pète pé kó o gbé e. Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” Báwo la ṣe máa gbà wọ́n là? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, olúkúlùkù wọn gbọ́dọ̀ “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí gbà ọ́ níyànjú láti gba ìmọ̀ tó ń fúnni ní ìyè nípa òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. Ìrètí tí Ọlọ́run yóò tipa bẹ́ẹ̀ fún ọ á ju ìrètí èyíkéyìí tó o lè rí nínú ayé yìí.
Tó o bá ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kó o máa wo ara ẹ bí aláìnírètí, nítorí pé Ọlọ́run lè fún ọ lókun tó o nílò kọ́wọ́ rẹ lè tẹ ohunkóhun tó o bá ń lépa, tó wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13) Ṣe irú ìrètí tó o nílò kọ́ lèyí? Nítorí náà, tó o bá nílò ìrètí, tó o sì ti ń wá a káàkiri, mọ́kàn. Ìrètí ló dé tán yìí. Ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ìdí Tá A Fi Lè Ní Ìrètí
Àwọn èrò Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún ìrètí rẹ lágbára:
◼ Ọlọ́run ṣèlérí ọjọ́ iwájú aláyọ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé gbogbo àgbáyé yóò di Párádísè níbi tí gbogbo aráyé á ti máa gbé gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, tí wọ́n sì wà ní ìṣọ̀kan.—Sáàmù 37:11, 29; Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:3, 4.
◼ Ọlọ́run ò lè purọ́.
Ó kórìíra irọ́ pípa ní gbogbo ọ̀nà. Jèhófà mọ́ tónítóní láìlábààwọ́n tàbí ó mọ́ gaara, nítorí náà kò ṣeé ṣe fún un láti purọ́.—Òwe 6:16-19; Aísáyà 6:2, 3; Títù 1:2; Hébérù 6:18.
◼ Agbára Ọlọ́run ò láàlà.
Jèhófà nìkan ni alágbára ńlá. Kò sí nǹkan kan láyé yìí tó lè dí i lọ́wọ́ àtimú ète rẹ̀ ṣẹ.—Ẹ́kísódù 15:11; Aísáyà 40:25, 26.
◼ Ọlọ́run fẹ́ kó o wà láàyè títí láé.
—Jòhánù 3:16; 1 Tímótì 2:3, 4.
◼ Ọlọ́run lérò rere sí wa.
Ó mọ̀ọ́mọ̀ máa ń mójú kúrò lára àwọn ẹ̀bi àti ìkùdíẹ̀–káàtó wa, ṣùgbọ́n ó máa ń wo àwọn ànímọ́ rere àti ìsapá wa. (Sáàmù 103:12-14; 130:3; Hébérù 6:10) Ó máa ń retí pé a ó máa ṣe nǹkan tó dára, tá a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ inú rẹ̀ máa ń dùn.—Òwe 27:11.
◼ Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á ràn wá lọ́wọ́ kí ọwọ́ wa bàa lè tẹ ohun tá à ń lépa, tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.
Kò yẹ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa wo ara wọn bí ẹni tí kò nírètí. Ọlọ́run máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fàlàlà, ẹ̀mí Ọlọ́run yìí sì ni ipá tó lágbára jù tó lè ràn wá lọ́wọ́.—Fílípì 4:13.
◼ Ìrètí nínú Ọlọ́run kì í ṣákìí.
Atóófaratì bí òkè ni Ọlọ́run, ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, kò ní padà lẹ́yìn rẹ láé.—Sáàmù 25:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Bí àṣíborí ṣe ń dáàbò bo orí bẹ́ẹ̀ ni ìrètí ṣe ń dáàbò bo èrò inú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Bí ìdákọ̀ró, ìrètí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lè fọkàn ẹni balẹ̀
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda René Seindal/Su concessione del Museo Archeologico Regionale A. Salinas di Palermo