Bí Àníyàn Nípa Ìrísí Ẹni Bá Gbani Lọ́kàn Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ
NÍGBÀ tí ọ̀pọ̀ lára wa bá wo ara wa nínú dígí, a máa ń rí àwọn apá ibi tá a rò pé ó yẹ ká tún ṣe lára wa. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń tún aṣọ tàbí irun wa ṣe tàbí ká fi nǹkan ìṣaralóge díẹ̀ sára ká tó máa bá iṣẹ́ òòjọ́ wa lọ. Kò sì sóhun tó burú nínú níní irú àníyàn bẹ́ẹ̀ nípa ìrísí wa. Ṣùgbọ́n àwọn kan ti ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ títún ara ṣe, débi tó ti wá fẹ́ di nǹkan táwọn dókítà kà sí àárẹ̀.
Ìwé ìṣègùn náà, The Merck Manual of Diagnosis and Therapy ṣàpèjúwe àárẹ̀ yìí bíi “kíkó èrò nípa àléébù ara sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ débi tó fi máa fa ìdààmú ọkàn tó pọ̀ féèyàn, tàbí kí òde má wuni lọ mọ́, kí iṣẹ́ má wuni ṣe mọ́, kí olúwa rẹ̀ má sì fẹ́ máa lọ sáwọn ibi tó ṣe pàtàkì mọ́.”a Nítorí pé àwọn tó ní ìṣòro yìí máa ń rò pé àléébù kan wà lára àwọn, tàbí kí wọ́n máa sọ gẹ̀gẹ̀ dàrùn, làwọn èèyàn ṣe ń pe èrò tí wọ́n ní yẹn ni bíburẹ́wà lójú ara ẹni.
Ọ̀jọ̀gbọ́n J. Kevin Thompson ti ilé ìwé gíga University of South Florida, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìṣòro yìí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, “tá a bá pín gbogbo àwọn tó wà láyé sí ọgọ́rùn-ún, bóyá la lè rí ju ẹnì kan sí méjì tó ní àárẹ̀ yìí. Kò sì lè ju ìdá mẹ́wàá sí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn tó máa ń lọ gbàtọ́jú lórí àìsàn ìrònú àti ìwà híhù nílé ìwòsàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí àárẹ̀ yìí wà lára wọn.” Àmọ́, ó fi kún un pé: “Àwọn olùṣèwádìí gbà gbọ́ pé bó wá ṣe di pé àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò àwọn tó ní àárẹ̀ yìí ti pọ̀ tó sì múná dóko sí i báyìí, àwọn tí wọ́n rí pé wọ́n ní àárẹ̀ náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtàgbà àtọmọdé ló lè níṣòro yìí, ìgbà téèyàn bá wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún ló sábà máa ń bẹ̀rẹ̀. Ní tàwọn àgbàlagbà, bó ṣe ń ṣe ọkùnrin ló ń ṣe obìnrin. Ó fi ìyẹn yàtọ̀ sáwọn ìṣòro àìlèjẹun dáadáa tó jẹ́ pé àwọn obìnrin ló máa ń ṣe jù.
Ohun tá a fi máa ń dá àwọn tó ní ìṣòro yìí mọ̀ ni pé wọ́n á máa ṣàníyàn púpọ̀ jù lórí bí ara wọn ṣe rí, ìyẹn lá á wá sọ wọ́n dẹni tá á máa wo dígí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, kódà, ó lè mú kí wọ́n ya ara wọn láṣo. Ìwé ìṣègùn náà, Merck Manual sọ pé èyí tó tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ ni pé “ìrora àti ìṣiṣẹ́gbòdì tó máa ń fà fún ara lè sọ èèyàn dẹni tó fi ilé ìwòsàn ṣe ilé, ó sì lè mú kéèyàn máa ṣe bí ẹní fẹ́ para ẹ̀.” Kò jọjú pé àwọn tó níṣòro yìí máa ń fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ́ tó máa ń yí ìrísí padà. Dókítà Katharine Phillips, obìnrin kan tó ti kọ ìwé kan lórí àárẹ̀ yìí ṣàlàyé pé: “Mo máa ń fún wọn nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe iṣẹ́ abẹ́ yìí. Iṣẹ́ abẹ ò ṣeé yí padà, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n tìtorí ìṣòro yìí ṣiṣẹ́ abẹ sì ti rí i pé iṣẹ́ abẹ náà kò tún ìrísí àwọn ṣe.”b
Nígbà míì, àtikékeré ni àárẹ̀ yìí ti máa ń yọjú. Ìwé ìròyìn George Street Journalc ròyìn nípa ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́fà kan “tó gbà pé eyín òun rí ràkọ̀ràkọ̀, ikùn òun ‘tóbi,’ tí irun òun sì rí wúruwùru. Kò sí èyíkéyìí nínú ‘àwọn àléébù’ rẹ̀ yìí tó hàn sáwọn ẹlòmíràn. Ó máa ń fi bíi wákàtí kan ya irun rẹ̀ láràárọ̀, bí ò bá sì tíì ‘dára’ lójú ẹ̀, á ki orí bọmi á bẹ̀rẹ̀ sí túnra mú, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì ti tìtorí èyí pẹ́ dé ilé ìwé.” Lọ́jọ́ kan, nígbà tó dé ọ́fíìsì dókítà, ó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ láti wo ara ẹ̀ níbì kan tó ń dán lára ìjókòó.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ayé Máa Darí Ìrònú Rẹ
Àwọn ìwé ìròyìn oníbébà-dídán àti irú ìwé ìròyìn míì àti àwọn ìpolówó ọjà orí tẹlifíṣọ̀n máa ń gbé àwọn àwọ̀ ara tó dùn ún wò jáde láti yán àwọn èèyàn lójú. Ọgbọ́n táwọn tó ń polówó ọjà ń dá ò le: Tí wọ́n bá ti gbé àwòrán ara ẹnì kan jáde tí wọ́n sì sọ pé bó ṣe yẹ kára èèyàn rí nìyẹn, orí báwọn èèyàn á ṣe jẹ́ kára wọn rí bẹ́ẹ̀ ni wọn á máa náwó òógùn ojú wọn lé. Láfikún sí èyí, báwọn ẹlẹgbẹ́ ẹnì kan bá ń yọ ọ́ lẹ́nu láti ṣe é, àgàgà táwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ náà bá tún ń dá tiwọn sí i láìro bó ṣe rí lára ẹ̀, ó di kí onítọ̀hún máa wo ara ẹ̀ bí ẹni tí ò lẹ́wà tó.d A mọ̀ pé àwọn míì náà wà tí wọ́n máa ń lérò tí ò tọ̀nà nípa ara wọn tí ohun tó ń ṣe wọ́n ò sí fi nǹkan kan jọ àárẹ̀ yìí.
Kò bójú mu láti máa rò pé tó ò bá ti jẹ́ arẹwà, àwọn èèyàn ò ní nífẹ̀ẹ́ sí ọ, irọ́ ni. Ẹwà ara kọ́ làwọn èèyàn sábà máa ń wò kí wọ́n tó yan ọ̀rẹ́. Lóòótọ́, ìrísí ẹnì kan lè kọ́kọ́ fa àwọn èèyàn mọ́ra, àmọ́ ìwà èèyàn, béèyàn ṣe jẹ́ ọmọlúàbí sí àti bó ṣe ṣèèyàn tó ló máa ń mú kí ìdè ọ̀rẹ́ lágbára. Gbogbo wa la jọ ìwé kan lọ́nà kan, èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ lè fani mọ́ra, ṣùgbọ́n táwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ ò bá dùn ún kà, àwọn tó ń kà á ò ní pẹ́ gbé e jù sílẹ̀. Àmọ́, bó ti wù kí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ rí, tí nǹkan tó wà nínú ẹ̀ bá dùn, àwọn tó ń kà á máa wo mọ́ ọn ni. Nítorí náà, o ò sé máa ronú nípa àwọn ànímọ́ tó o ní gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan? Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì rọ̀ ọ́ pé kó o máa ṣe nìyẹn.—Òwe 11:22; Kólósè 3:8; 1 Pétérù 3:3, 4.
Ká sì sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, bá a bá ṣe ń yí padà sí i ni ìrísí wa á máa yí padà. Bó bá jẹ́ pé iye ọ̀rẹ́ tá a máa ní àti ayọ̀ wa sinmi lórí bí ara wa ṣe máa ń rí rèǹtèrente bíi tìgbà ọ̀dọ́, a jẹ́ pé gbogbo wa ṣì ni ìbànújẹ́ ń dúró dè lọ́jọ́ iwájú nìyẹn! Àmọ́, ọ̀rọ̀ tiwa lè máà rí bẹ́ẹ̀. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
Ẹwà Tí Ò Ní Ṣá Láé
Òwe 16:31 sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” Lójú Jèhófà Ọlọ́run, àti lójú gbogbo àwọn tó gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, àwọn tí wọ́n ń sin Ọlọ́run títí wọ́n fi darúgbó kì í ṣá. Kódà, nítorí ìtara àti ìfọkànsìn Ọlọ́run tí wọ́n ti ní látẹ̀yìn wá, ewú orí wọn ti di adé ẹwà mọ́ wọn lórí. Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ irú àwọn ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ ká sì bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún wọn.—Léfítíkù 19:32.
Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nínú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí, yóò mú ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ń ní lórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin kúrò, ì báà ṣe arúgbó tàbí ọ̀dọ́. Bí ojúmọ́ kọ̀ọ̀kan bá ṣe ń mọ́ ni wọ́n á máa rí bí ara wọn á ṣe máa lẹ́wà sí i títí tí ará wọn á fi pé pérépéré. (Jóòbù 33:25; Ìṣípayá 21:3, 4) Ọjọ́ iwájú yìí á mà kọyọyọ o! Ṣé ìwọ náà á fẹ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣiṣẹ́ kára kí ọkàn rẹ lè wà lórí ẹwà tó ṣe pàtàkì jù, kó o má sì jẹ́ kí àìláròjinlẹ̀ àti èrò ọ̀dájú ayé yìí ràn ẹ́. Tó o bá fi lè ṣe ìyẹn ayọ̀ rẹ á pọ̀ sí i, wàá sì dẹni fífanimọ́ra sí i.—Òwe 31:30.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé ìròyìn The Medical Journal of Australia sọ pé: “Kí ìrísí ẹni máa gbani lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ wà lára àwọn àmì tí wọ́n sábà fi máa ń dá ọ̀pọ̀ ìṣòro tó jẹ́ mọ́ ìrònú mọ̀.” Lára àwọn àmì náà ni àárẹ̀ ọkàn, àìlèṣàkóso ìrònú àti ìṣesí ara ẹni àti ìṣòro àìlèjẹun dáadáa, irú bíi kẹ́rù àtijẹun máa bani nítorí àìfẹ́sanra. Abájọ tí àìsàn yìí fi ṣòro láti dá mọ̀ tó bá wà lára.
b Jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà “Young People Ask . . . Should I Have Cosmetic Surgery?” [“Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣó Yẹ Kí N Ṣe Iṣẹ́ Abẹ Láti Yí Ìrísí Mi Padà?”], tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 22, 2002 lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bó bá jẹ́ ìṣòro lílágbára lórí ìrònú lẹnì kan ní ṣá o, ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè gba kó lọ rí olùtọ́jú ọpọlọ tó níwèé àṣẹ ìjọba.
c Ilé ìwé gíga Brown University, tó wà ní Rhode Island, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń tẹ̀ ẹ́ jáde.
d Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, jọ̀wọ́ wo àkòrí náà “Bawo Ni Irisi Ti Ṣe Pataki To?” nínú ìwé náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.