ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 18-21
  • Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Tó Dáa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Tó Dáa
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Kò Fi Rọrùn
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ọlọ́run Fi Lélẹ̀
  • Ó Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀
  • Wá Àkókò fún Wọn!
  • O Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Dáàbò Bo Ogún Iyebíye Tẹ́ Ẹ Ní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Kó Lè Sin Jèhófà—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kò Sí Bàbá Tó Dà Bíi Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 18-21

Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Tó Dáa

ÀPILẸ̀KỌ kan tí wọ́n kọ sínú ìwé ìròyìn Economist tó sọ nípa bí ìgbésí ayé ìdílé ṣe ń jó rẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú gbólóhùn gbankọgbì náà pé: “Àtibímọ ò tó pọ́n, àtiṣe bàbá ọmọ ló ṣòro.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣòro ṣe láyé yìí, síbẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣòro ṣe jù tó sì wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù ni jíjẹ́ bàbá dáadáa. Olúkúlùkù bàbá tó bímọ ló fẹ́ jẹ́ bàbá tó dáa, níwọ̀n bó ti mọ̀ pé àṣeyọrí àti ayọ̀ ìdílé òun ṣe pàtàkì.

Ìdí Tí Kò Fi Rọrùn

Lájorí ohun tó mú kó ṣòro láti jẹ́ bàbá tó dáa ni àìpé tá a jogún, àti bàbá àtọmọ. Bíbélì sọ pé: “Ìtẹ̀sí èrò ọkàn-àyà ènìyàn jẹ́ búburú láti ìgbà èwe rẹ̀ wá.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Ìdí nìyẹn tí ọ̀kan nínú àwọn tó kọ Bíbélì fi jẹ́wọ́ pé: “Nínú ẹ̀ṣẹ̀ . . . ni ìyá mi lóyún mi.” (Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Ọ̀kan péré ni ìtẹ̀sí ọkàn láti ṣe búburú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá jẹ́ lára àwọn ohun tó mú kó ṣòro láti jẹ́ bàbá.

Ayé yìí tàbí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí gan-an tún jẹ́ òkè ìṣòro mìíràn. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” Bíbélì tún pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” Abájọ tí Jésù fi sọ pé gẹ́gẹ́ bí òun, àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “apá kan ayé”!—1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:9; 2 Kọ́ríńtì 4:4; Jòhánù 17:16.

Béèyàn bá fẹ́ jẹ́ bàbá tó dáa, ó ṣe pàtàkì pé kó máa rántí pé ẹ̀dá aláìpé ni wá, kó sì máa fi sọ́kàn pé Sátánì Èṣù wà níbẹ̀, àti pé òun ló ń darí ayé yìí. Àwọn ìṣòro yìí kì í ṣe àròbájọ o. Wọ́n wà lóòótọ́! Níbo ni ká wá ti lọ kọ́ bá a ṣe lè borí àwọn ìṣòro yìí o, tá ó sì tún kọ́ bí a ó ṣe jẹ́ bàbá tó dáa?

Àwọn Àpẹẹrẹ Tí Ọlọ́run Fi Lélẹ̀

Bàbá kan lè ṣàyẹ̀wò Bíbélì láti lè borí àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn lókè yìí. Àpẹẹrẹ àwọn bàbá tó dára wà nínú ẹ̀. Jésù fi bàbá tó dáa jù lọ hàn wá nígbà tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe Bàbá wa ọ̀run, ó sọ pọ́ńbélé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Kí ló yẹ káwọn bàbá tí wọ́n wà láyé ṣe nípa àpẹẹrẹ onífẹ̀ẹ́ tí babá wa ọ̀run fi lélẹ̀ yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, . . . kí ẹ sì máa bá a lọ ní rírìn nínú ìfẹ.”—Mátíù 6:9, 10; 1 Jòhánù 4:8; Éfésù 5:1, 2.

Bó o bá jẹ́ bàbá, ṣàgbéyẹ̀wó nǹkan tó o lè rí kọ́ látinú ìṣẹ̀lẹ̀ kan pére nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣe sí Jésù Ọmọ rẹ̀. Mátíù 3:17 sọ pé nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi nínú omi, àwọn èèyàn gbọ́ ohùn Ọlọ́run láti ọ̀run tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” Kí la lè rí kọ́ látinú èyí?

Àkọ́kọ́, ronú lórí bó ṣe máa rí lára ọmọ kan tí bàbá ẹ̀ bá sọ fún ẹnì kan tìdùnnú-tìdùnnú pé ‘Ọmọkùnrin mi nìyí’ tàbí ‘Ọmọbìnrin mi nìyí.’ Orí àwọn ọmọdé máa ń wú nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn òbí àwọn ń ṣàkíyèsí àwọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé inú wọn ń dùn sí ohun tí wọ́n ń ṣe. Ó ṣeé ṣe kí ọmọ kan tún fẹ́ jára mọ́ ohun tó ń ṣe kó bàa lè gba oríyìn.

Èkejì, Ọlọ́run sọ èrò rẹ̀ nípa Jésu jáde, ó pè é ní “olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Gbólóhùn tó ń fi ìfẹ́ àtọkànwá Bàbá rẹ̀ hàn yẹn ní láti mú kí inú Jésù dùn gan-an ni. Orí àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú yóò wú bó o bá lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn látọkanwá nípa lílo àkókò rẹ pẹ̀lú wọn, nípa fífún wọn láfiyèsí àti ríronú lórí ọ̀rọ̀ wọn.

Ẹ̀kẹ́ta, Ọlọ́run sọ fún Ọmọ rẹ̀ pé: “Mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” (Máàkù 1:11) Ìyẹn náà ṣe pàtàkì pẹ̀lú, pé kí bàbá máa sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, inú òun dùn sí wọn. Lóòótọ́, àwọn ọmọdé ò lè má ṣàṣìṣe. Gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bíi bàbá, máa ń wá ọ̀nà láti ṣe káre láé fáwọn ọmọ rẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe nǹkan tó wúni lórí tàbí nígbà tí wọ́n bá sọ nǹkan tó dáa?

Jésù gbẹ̀kọ́ tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run kọ́ ọ. Nígbà tó wà láyé, nínú ọ̀rọ̀ àti nínú àpẹẹrẹ, ó fi ohun tó wà lọ́kàn Bàbá rẹ̀ nípa àwọn ọmọ Rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé hàn. (Jòhánù 14:9) Kódà nígbà tó rẹ Jésù tí wàhálà sì pọ̀ lọ́rùn rẹ̀, ó pàpà wáyè láti jókòó ti àwọn ọmọdé ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” (Máàkù 10:14) Ǹjẹ́ ẹ̀yin bàbá lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Ọmọ rẹ̀ délẹ̀délẹ̀?

Ó Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀

Bí fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó kò ṣeé fẹnu sọ. Ìṣapá tó o bá ṣe láti “máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” lè má fi bẹ́ẹ̀ méso jáde bí ìwọ alára kì í bá gba ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó ò sì jẹ́ kó máa darí ìgbésí ayé ẹ. (Éfésù 6:4) Àmọ́ ṣá, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, o lè borí òkè ìṣòro èyíkéyìí tó lè máa dí ọ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀ pé kó o bójú tó àwọn ọmọ rẹ.

Wo àpẹẹrẹ ti Viktor Gutshmidt, ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Soviet Union àtijọ́. Ní oṣù October, ọdún 1957, wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá nítorí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́. Ó fi ọmọdébìnrin méjì àti ìyàwó ẹ̀, Polina sílé nígbà tó lọ sẹ́wọ̀n. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, wọ́n fún un láyè láti kọ lẹ́tà sí aya àtọmọ ẹ̀, àmọ́ wọ́n ní kò gbọ́dọ̀ sọ ohun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí ẹ̀kọ́ kankan nípa ìsìn. Pẹ̀lú gbogbo ohun tó dojú kọ yìí, Viktor pinnu pé òun á pàpà ṣe bàbá ọmọ òun lọ́nà tó dáa, ó sì mọ̀ pé kíkọ́ àwọn ọmọ òun láti mọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Ọgbọ́n wo ló wá dá sí i?

Viktor sọ pé: “Nínú àwọn ìwé ìròyìn Young Naturalist àti Nature tí wọ́n ń tẹ̀ nílẹ̀ Rọ́ṣíà ni mo ti máa ń rí àwọn àwòrán. Mo máa ń ya oríṣiríṣi àwòrán ẹranko àti ènìyàn sínú káàdì kan tí mò ń fi ránṣẹ́ mo sì máa ń fi ìtàn tàbí ìrírí kan nípa àwọn ìṣẹ̀dá gbè é nídìí.”

Polina sọ pé: “Bá a bá ṣe rí àwọn àwòrán náà báyìí, kíá la ó ti mọ ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣàlàyé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá ń wo àwọn káàdì tó ń fi àwòrán ẹwà ìṣẹ̀dá, igbó tàbí odò hàn, mo máa ń ka Aísáyà orí 65,” tó ń sọ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run láti sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.

Yulia, ọmọbìnrin Victor, sọ pé: “Màmá á wá gbàdúrà pẹ̀lú wa, à á sì máa sunkún. Kékeré kọ́ ni iṣẹ́ àwọn káàdì wọ̀nyí nínú bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà.” Polina sọ pé látàrí èyí “láti kékeré ni àwọn ọmọbìnrin wa ti fẹ́ràn Ọlọrun gan-an.” Báwo ni ìdílé náà ṣe rí báyìí?

Viktor ṣàlàyé pé: “Nísinsìnyí àwọn ọmọbìnrin mi méjèèjì ti di ìyàwó àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni, àwọn méjèèjì sì ti di ìyá fáwọn ìdílé tó lágbára nípa tẹ̀mí táwọn ọmọ wọn sì ń fi òtítọ́ sin Jèhófà.”

Fífi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ kọjá ọgbọ́n inú nìkan o, ó ń bèèrè pé kéèyàn sapá gidigidi. Ó ṣeé ṣe kó gún àwọn ọmọ ní kẹ́ṣẹ́ nígbà tí wọ́n bá rí bí bàbá wọn ṣe ń sapá tó láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Ọmọkùnrin kan tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ alákòókò kíkún fi ìmọrírì sọ̀rọ̀ nípa bàbá ẹ̀ nígbà tó dàgbà tán, ó sọ pé: “Nígbà míì tí Bàbá bá fi máa ti ibi iṣẹ́ dé, á ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu débi tóorun á fi fẹ́ máa kùn ún níbi tó bá wà, ṣùgbọ́n a pàpà máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìdílé wa máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, èyí sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó.”

Ó ṣe kedere pé fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe ṣe pàtàkì gan-an béèyàn bá fẹ́ jẹ́ bàbá tó dáa. O ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá fẹ́ mọ bí òwe Bíbélì kan ṣe jẹ́ òótọ́ tó, òwe ọ̀hún ni pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”—Òwe 22:6.

Nítorí náà, máa rántí pé kì í ṣe ohun tó o sọ nìkan ló ṣe pàtàkì; ohun tó o ṣe gan-an ló ṣe pàtàkì jù, ìyẹn àpẹẹrẹ tó o fi lélẹ̀. Ògbógi kan lórí ètò ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Ọ̀nà tó dáa jù lọ láti mú káwọn ọmọ wa hùwà tó dáa [bá a ṣe fẹ́] ni pé ká hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ kí wọ́n rí i.” Ní tòdodo, bó o bá fẹ́ káwọn ọmọ ẹ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀ fúnra ẹ.

Wá Àkókò fún Wọn!

Àwọn ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ rí àpẹẹrẹ rẹ. Ìyẹn fi han pé o ní láti lo àkókò pẹ̀lú wọn, àkókò tó pọ̀ ni o, kì í kàn ṣe ní ìdákúrekú. Fi ọgbọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì náà pé ká ‘ra àkókò padà,’ ìyẹn ni pé kéèyàn mójú kúrò lára àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, kó bàa lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ. (Éfésù 5:15, 16) Rò ó wò ná, kí ló ṣe pàtàkì ju àwọn ọmọ rẹ lọ? Ṣé wíwo tẹlifíṣọ̀n ní gbogbo ìgbà ni, ṣíṣeré ìdárayá, ilé ginrinmijin, àbí iṣẹ́ rẹ?

Wọ́n máa ń pa ọ̀rọ̀ yìí lówe pé, ‘Ọmọ tá ò kọ́, ni yóò gbélé tá a kọ́ tà.’ Àwọn bàbá táwọn ọmọ wọn ti ń ṣèṣekúṣe tàbí tí ìgbésí ayé wọn ti dojú dé nípa tẹ̀mí sábà máa ń kábàámọ̀. Wọ́n máa ń kẹ́dùn pé ibi táwọn ti kùnà ni pé àwọn kì í sábà sí nítòsí àwọn ọmọ àwọn nígbà tí wọ́n kéré tí wọ́n ṣì nílò bàbá tá á máa bójú tó wọn!

Rántí o, ìgbà táwọn ọmọ ẹ bá ṣì kéré gan-an ló yẹ kó o ronú lórí ohun tó máa tẹ̀yìn ìpinnu tó o bá ṣe jáde. Bíbélì pe àwọn ọmọ rẹ ní “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” ìyẹn ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti fi síkàáwọ́ rẹ. (Sáàmù 127:3) Nítorí náà máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé wàá jíhìn fún Ọlọ́run nípa àwọn ọmọ tó fún ọ ṣọ́!

O Lè Rí Ìrànlọ́wọ́ Gbà

Bàbá tó dáa máa ń ronú nípa bó ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ tó lè ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ láǹfààní gbà. Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì kan sọ fún ìyàwó Mánóà pé á bí ọmọ kan, Mánóà gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó tún tọ̀ wá wá, kí ó sì fún wa ní ìtọ́ni ní ti ohun tí ó yẹ kí a ṣe sí ọmọ náà tí a óò bí.” (Onídàájọ́ 13:8, 9) Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí ayé òde òní, irú ìrànlọ́wọ́ wo ni Mánóà nílò? Ṣá máa kà á nìṣó.

Brent Burgoyne tó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ìwé gíga University of Cape Town, ní Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè fún ọmọ kan ni kíkọ́ ọ níwà ọmọlúwàbí.” A lè rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká kọ́ ọmọ ní irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìròyìn kan tí ìwé ìròyìn Daily Yomiuri nílẹ̀ Japan gbé jáde, èyí tó sọ pé: “Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fi hàn pé bá a bá fi àwọn ọmọ tó wà nílẹ̀ Japan dá ọgọ́rùn-ún, mọ́kànléláàádọ́rin nínú wọn làwọn bàbá wọn ò tíì sọ fún rí pé kí wọ́n má parọ́.” Ìyẹn ò wa burú bí?

Ta ló lè fún wa ní ìlànà ìwà rere? Ẹni tó fún Mánóà ní ìlànà nípa bó ṣe máa tọ́ ọmọ rẹ̀ náà ni, ìyẹn Ọlọ́run fúnra rẹ̀! Láti lè pèsè ìrànlọ́wọ́ fún wa, Ọlọ́run rán Jésù, Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, sí wa gẹ́gẹ́ bí Olùkọ́, ohun táwọn èèyàn sì máa ń sábà pè é nìyẹn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ìwé náà, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, tó ṣàlàyé àwọn ohun tá a lè rí kọ́ látinú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ti wà ní èdè púpọ̀, o sì lè lò wọ́n fún kíkọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ.

Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà kò fi mọ sórí ṣíṣàlàyé àwọn ìlànà ìwà híhù tá a fà yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan, àmọ́ ó tún fi àwọn àwòrán tó lé ní ọgọ́jọ ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ sínú rẹ̀. Àwọn ìbéèrè tó lè mú kéèyàn ronú lórí kókó tí àwòrán yẹn ń ṣàlàyé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwòrán ọmọkùnrin kan àti bàbá rẹ̀ wà ní orí 22 tó ní àkòrí náà, “Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́.” Ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sójú ewé ibi tí àwòrán náà wà sọ pé: “Tàbí kí ọmọdékùnrin kan sọ fún bàbá rẹ̀ pé: ‘Rára, mi ò gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé o.’ Kó sì wá jẹ́ pé lóòótọ́ ló gbá bọ́ọ̀lù nínú ilé. Ṣé yóò dára kí ó sọ pé òun ò gbá bọ́ọ̀lù níbẹ̀?”

Àwọn ẹ̀kọ́ tó wọni lọ́kàn ṣinṣin ló wà nínú àwọn àkòrí méjìdínláàádọ́ta tó wà nínú ìwé náà, lára wọn la ti rí “Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́,” “A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò,” “Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure,” “Má Ṣe Di Olè!,” “Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?,” “Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn,” “Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

A kádìí ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé náà pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí á darí àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Orísun gbogbo ọgbọ́n, ìyẹn Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà Ọlọ́run. Ohun tí Jésù, Olùkọ́ Ńlá, máa ń ṣe nígbà gbogbo nìyẹn. Àdúrà wa ni pé kí ìwé yìí ran ìwọ àti ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé yín di èyí tó ń mú inú Jèhófà dùn, kí ẹ lè jèrè ìbùkún ayérayé.”a

Ó ṣe kedere pé kó o tó lè jẹ́ bàbá rere o gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ, kó o máa lo àkókò tó pọ̀ lọ́dọ̀ wọn kó o sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì mu.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìwé mìíràn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe láti ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ ni Iwe Itan Bibeli Mi, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n ni Viktor Gutschmidt wà, ó pàpà gbìyànjú láti jẹ́ bàbá rere

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ ẹ̀, Viktor ya àwọn àwòrán yìí láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn ọmọbìnrin Viktor lọ́dún 1965

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ó yẹ káwọn bàbá máa dá sí kíkọ́ àwọn ọmọ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́