ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 9/8 ojú ìwé 8-11
  • Ìgbà kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní Sí Ẹ̀tanú Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní Sí Ẹ̀tanú Mọ́
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀mí Tó Yẹ Kó Súnni Láti Borí Ẹ̀tanú
  • Lílé Ẹ̀tanú Wọgbó Lóde Òní
  • Ohun Tó Lè Ranni Lọ́wọ́ Láti Borí Ẹ̀tanú
  • Ká Jẹ́ Ọ̀kan Bí Jèhófà àti Jésù Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìwà ẹ̀tanú—ìṣòro tó kárí ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìgbà Wo Ni Ayé Yìí Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀tanú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ṣé O Ní Ìkórìíra?
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 9/8 ojú ìwé 8-11

Ìgbà kan Ń Bọ̀ Tí Kò Ní Sí Ẹ̀tanú Mọ́

ǸJẸ́ a lè mọ̀ bí àwa fúnra wa bá ní ẹ̀tanú? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ a máa ń sọ pé bákan lẹnì kan rí nítorí àwọ̀, ìlú ìbílẹ̀, tàbí ẹ̀yà rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ onítọ̀hún? Tàbí a lè mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan mọ àwọn ànímọ́ tiẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin?

Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn tó ń gbé ní Jùdíà àti Gálílì kì í sábà ní “ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.” (Jòhánù 4:9) Kò sí iyèméjì pé èrò ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n kọ sínú ìwé Talmud gbé jáde pé: “Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí n fojú mi kan ará Samáríà.”

Kódà, àfàìmọ̀ kí àwọn àpọ́sítélì Jésù pàápàá má ti ní ẹ̀tanú bákan bàkàn sáwọn ará Samáríà. Ìgbà kan wà tí àwọn ará abúlé kan ní Samáríà ò gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láyè. Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè bóyá káwọn pe iná sọ̀ kalẹ̀ sórí àwọn ọlọ́kàn yíyigbì tí wọ́n ń gbé lábúlé náà. Bíbá tí Jésù bá wọn wí fi hàn pé èrò tí wọ́n ní yẹn ò tọ̀nà.—Lúùkù 9:52-56.

Nígbà tó ṣe, Jésù ṣe àkàwé nípa ọkùnrin kan táwọn ọlọ́ṣà dá lọ́nà nígbà tó ń ti Jerúsálẹ́mù rìnrìn àjò lọ sí Jẹ́ríkò. Àwọn Júù méjì tí wọ́n jẹ́ ògúnná gbòǹgbò nínú ẹ̀sìn gba ibẹ̀ kọjá, kò sì ṣe wọ́n bí i pé kí wọ́n ran ọkùnrin náà lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, ará Samáríà kan dúró, ó sì di àwọn ojú ọgbẹ́ tó wà lára ọkùnrin náà. Lẹ́yìn náà ló ṣètò bí ọkùnrin náà á ṣe rí àbójútó gbà kí ọgbẹ́ ara rẹ̀ bàa lè jinná. Ará Samáríà yẹn fi hàn pé òun jẹ́ aládùúgbò rere. (Lúùkù 10:29-37) Àkàwé tí Jésù ṣe lè ti ran àwọn tó ń tẹ́tí sí i lọ́wọ́ láti lóye pé ẹ̀tanú táwọn ní kì í jẹ́ káwọn rí àwọn ànímọ́ rere àwọn ẹlòmíì. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, Jòhánù padà lọ sí Samáríà ó sì wàásù nínú ọ̀pọ̀ àwọn abúlé tó wà níbẹ̀, lára èyí tó ṣeé ṣe kí abúlé tó fẹ́ kó pa run lọ́jọ́sí wà.—Ìṣe 8:14-17, 25.

Àpọ́sítélì Pétérù náà tún ní láti fi hàn pé òun kì í ṣe olójúsàájú nígbà tí áńgẹ́lì kan sọ fún un pé kó lọ wàásù nípa Jésù fún Kọ̀nílíù, balógun ọ̀rún ará Róòmù. Kò mọ́ Pétérù lára láti máa bá àwọn tí kì í ṣe Júù da nǹkan pọ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ogun Róòmù. (Ìṣe 10:28) Ṣùgbọ́n nígbà tí Pétérù rí ibi tí Ọlọ́run ń darí ọ̀ràn gbà, ó sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Ẹ̀mí Tó Yẹ Kó Súnni Láti Borí Ẹ̀tanú

Ẹ̀tanú lòdì sí ìlànà pàtàkì tí Jésù fi kọ́ni pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ta ní jẹ́ gbà kí wọ́n gan òun nítorí ibi tó ti wá, nítorí àwọ̀, tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà? Ẹ̀tanú tún lòdì sí àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa àìṣojúsàájú. Bíbélì kọ́ni pé “láti ara ọkùnrin kan ni” Jèhófà “ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” (Ìṣe 17:26) Nítorí náà, ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo aráyé jẹ́.

Síwájú sí i, olúkúlùkù ni yóò jíhìn ohun tó bá ṣe níwájú Ọlọ́run. Kì í dá èèyàn lẹ́bi nítorí ohun táwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn baba ńlá rẹ̀ bá ṣe. (Ìsíkíẹ́lì 18:20; Róòmù 2:6) Kódà, ti pé orílẹ̀-èdè mìíràn kan ń fìyà jẹni kì í ṣe ìdí tó bófin mu tá a fi ní láti kórìíra àwọn tó bá wá láti orílẹ̀-èdè náà, àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n má tiẹ̀ mọ nǹkan kan nípa ìwà ìrẹ́nijẹ náà. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí wọn.’—Mátíù 5:44, 45.

Ọpẹ́lọpẹ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ bí èyí ló ran àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lọ́wọ́ láti borí ẹ̀tanú wọn tí wọ́n sì dí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tí kò láfiwé. Arákùnrin àti arábìnrin ni wọ́n máa ń pé ara wọn, wọ́n sì gbà pé ará làwọn jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ibi tó yàtọ̀ síra pátápátá ni wọ́n ti wá. (Kólósè 3:9-11; Jákọ́bù 2:5; 4:11) Àwọn ìlànà tó fa ìyípadà yìí lè mú kí irú àwọn àǹfààní kan náà jẹ́ tiwa lónìí.

Lílé Ẹ̀tanú Wọgbó Lóde Òní

Gbogbo wa pátá la ti gbin irú àwọn èrò kan sọ́kàn, ṣùgbọ́n irú ìwọ̀nyí ò sọ pé ká di ẹlẹ́tanú. Ìwé The Nature of Prejudice sọ pé: “Kìkì ìgbà téèyàn bá kọ̀ láti yí èrò tó ti gbìn sọ́kàn padà, lẹ́yìn tó ti gbọ́ ìsọfúnni tó yàtọ̀ ni irú èrò tó gbìn sọ́kàn náà máa ń di ẹ̀tanú.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni ẹ̀tanú á wábi gbà báwọn èèyàn bá mọ ara wọn dáadáa. Àmọ́ ṣá o, ìwé yẹn tún sọ pé “ìgbà téèyàn bá bá àwọn ẹlòmíì ṣe nǹkan pọ̀ nìkan ló ṣeé ṣe kí èrò téèyàn ní nípa wọn tẹ́lẹ̀ yí padà.”

Bí John, tó jẹ́ ọmọ Íbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe borí ẹ̀tanú tó ní sí àwọn Haúsá nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní yunifásítì, mo bá àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n jẹ́ Haúsá pàdé a sì ń bára wa ṣọ̀rẹ́, mo sì wá rí i pé àwọn náà ní ìlànà tó dáa tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Iṣẹ́ kan nílé ẹ̀kọ́ tiẹ̀ pa èmí àti ọmọ Haúsá kan pọ̀, a sì ṣiṣẹ́ náà ní ìrọ̀wọ́ rọ̀sẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì rèé o, Íbò bíi tèmi tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀, kàn fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́ náà ni.”

Ohun Tó Lè Ranni Lọ́wọ́ Láti Borí Ẹ̀tanú

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí wọ́n pè ní UNESCO Against Racism ṣe sọ, “ìmọ̀ ẹ̀kọ́ lè ranni lọ́wọ́ dáadáa láti ṣẹ́pá irú ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìdẹ́yẹsíni tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sójútáyé lákọ̀tun.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì gan-an ni ìrànlọ́wọ́ tó dára jù lórí ọ̀ràn yìí. (Aísáyà 48:17, 18) Nígbà táwọn èèyàn bá fi ohun tó ń kọ́ni sílò, wọ́n á ní ọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíràn dípò kí wọ́n máa fura sí wọn, ìfẹ́ á sì palẹ̀ ìkórìíra mọ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé Bíbélì ń ran àwọn lọ́wọ́ láti máa borí ẹ̀tanú. Ní tòótọ́, Bíbélì ń fún wọn ní ìṣírí ó sì tún ń fún wọn láǹfààní láti kópa nínú oríṣiríṣi ìgbòkègbodò pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n ti ibòmíràn wá tí ẹ̀yà tiwọn sì yàtọ̀. Christina tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ nínú ọ̀wọ́ yìí, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Àwọn ìpàdé tá à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ló fi mí lọ́kàn balẹ̀. Pẹ̀sẹ̀ lọkàn mi máa ń balẹ̀ níbẹ̀ nítorí pé kò ṣe mí bí ẹni pé ẹnikẹ́ni ní ẹ̀tanú sí mi.”

Jasmin, tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí, ráńtí pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni òun nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ẹ̀tanú sí òun. Ó sọ pé: “Ọjọ́ Thursday lára máa ń tù mí jù lọ lọ́sẹ̀ nítorí pé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ni mo máa ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn èèyàn máa ń fìfẹ́ hàn sí mi níbẹ̀. Dípò kí wọ́n fojú tẹ́ńbẹ́lú mi, wọ́n máa ń pọ́n mi lé ni.”

Àwọn iṣẹ́ ìyọ̀ọ̀da ara ẹni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe tún máa ń mú káwọn èèyàn tí ìlú wọn yàtọ̀ síra jọ pàdé pọ̀. Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n bí Simon sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti erékùṣù Caribbean ni ìdílé rẹ̀ ti wá. Wọ́n ti ṣe ẹ̀tanú sí i gan-an nígbà tó ń báwọn ilé iṣẹ́ kan ṣiṣẹ́ bíríkílà. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ fún un láwọn ọdún tó fi sìn pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ nídìí iṣẹ́ ìyọ̀ọ̀da ara ẹni. Simon sọ pé: “Mo ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tèmi tí wọ́n wá láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó yàtọ̀ síra ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n a kọ́ láti máa bá ara wa ṣiṣẹ́ láìjà láìta. Láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí mo ní ti wá, kì í sì í ṣe bákan náà ni wọ́n ṣe tọ́ gbogbo wa dàgbà.”

Àmọ́ ṣá o, aláìpé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà o. Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé ńṣe làwọn náà ní láti máa jà fitafita kí wọ́n má bàa ní ẹ̀tanú. Ṣùgbọ́n mímọ̀ tí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ló ń fún wọn lágbára tó pọ̀ tó láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Éfésù 5:1, 2.

Èrè tó wà nídìí kéèyàn máà jẹ́ ẹlẹ́tanú pọ̀ jaburata. Bá a ti ń bá àwọn tí ibi tí wọ́n ti dàgbà yàtọ̀ sí tiwa lò, ayé wa á túbọ̀ máa lárinrin sí i. Síwájú sí i, nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, Ọlọ́run máa tó fìdí àwùjọ ẹ̀dá èèyàn kan múlẹ̀, òdodo yóò sì máa gbé láàárín wọn. (2 Pétérù 3:13) Ní àkókò yẹn, a ó ti borí ẹ̀tanú títí láé fáàbàdà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Ṣé Ẹlẹ́tanú Ni Mí?

Bí ara rẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí kó o bàa lè mọ̀ bóyá o ti ń ní ẹ̀tanú sáwọn ẹlòmíràn láìmọ̀:

1. Ǹjẹ́ mo máa ń gbà pé àwọn èèyàn tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà pàtó kan, àgbègbè, tàbí orílẹ̀-èdè kan ní àwọn ànímọ́ burúkú, bíi jíjẹ́ arìndìn, ọ̀lẹ afàjò, tàbí ahun? (Ọ̀pọ̀ àpárá táwọn èèyàn ń dá kì í jẹ́ kí irú ẹ̀tanú yìí tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀.)

2. Ṣé ó máa ń ṣe mí bí i kí n máa di ẹ̀bi ru àwọn àjèjì tàbí àwùjọ àwọn èèyàn míì pé àwọn ló ń ba ọrọ̀ ajé jẹ́ tí wọ́n sì ń dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀?

3. Ṣé èmi náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kèéta sáwọn tó ti orílẹ̀-èdè mìíràn wá nítorí pé ìjà kan tí wà nílẹ̀ tó dá ọ̀tá sáàárín orílẹ̀-èdè tèmi àti tiwọn?

4. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún mi láti máa wo olúkúlùkù ẹni tí mo bá bá pàdé gẹ́gẹ́ bí èèyàn bíi tèmi, láìfi àwọ̀ ara, ibi tó ti wá, tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ ọ dàgbà pè?

5. Ṣé kì í ni mí lára láti bá àwọn èèyàn tí wọ́n ti ibi tó yàtọ̀ sí tèmi wá dọ́rẹ̀ẹ́? Ṣé mo máa ń sapá láti mọ̀ wọ́n?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa aláàánú ara Samáríà, ó kọ́ wa bá a ṣe lè borí ẹ̀tanú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nígbà tí Pétérù wà nílé Kọ̀nílíù, ó sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ẹ̀kọ́ Bíbélì ń so àwọn èèyàn tí wọ́n wá láti onírúurú ibi lágbàáyé pọ̀ ṣọ̀kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Christina—“Àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń mú kí ará tù mí pẹ̀sẹ̀”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jasmin—“Àwọn èèyàn ń fìfẹ́ hàn sí mi. Wọ́n ń mú kí n rí ara mi bí ẹni pàtàkì dípò kí ń máa rí ara mi bí ẹni tí à ń tẹ́ńbẹ́lú”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Simon, òṣìṣẹ́ olùyọ̀ọ̀da ara ẹni tó ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́—“A kọ́ láti máa bá ara wa ṣiṣẹ́ láìjà láìta”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́